Sefanáyà
2 Kí àṣẹ náà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́,
Kí ọjọ́ náà tó kọjá lọ bí ìyàngbò,*
Kí ìbínú tó ń jó fòfò látọ̀dọ̀ Jèhófà tó wá sórí yín,+
Kí ọjọ́ ìbínú Jèhófà tó dé bá yín,
3 Ẹ wá Jèhófà,+ gbogbo ẹ̀yin oníwà pẹ̀lẹ́* ayé,
Tó ń pa àṣẹ òdodo* rẹ̀ mọ́.
Ẹ wá òdodo, ẹ wá ìwà pẹ̀lẹ́.*
Bóyá* ẹ ó rí ààbò ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.+
4 Nítorí Gásà máa di ìlú tí a pa tì;
Áṣíkẹ́lónì á sì di ahoro.+
5 “Ẹ gbé! Ẹ̀yin tó ń gbé etí òkun, orílẹ̀-èdè àwọn Kérétì.+
Jèhófà ti bá yín wí.
Ìwọ Kénáánì, ilẹ̀ àwọn Filísínì, màá pa ọ́ run,
Tí kò fi ní sí olùgbé kan tó máa ṣẹ́ kù.
6 Etí òkun náà á di ilẹ̀ ìjẹko,
Tó ní àwọn kànga fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn àti àwọn ọgbà tí a fi òkúta ṣe fún àwọn àgùntàn.
7 Á sì di agbègbè fún àwọn tó ṣẹ́ kù lára ilé Júdà;+
Ibẹ̀ ni wọ́n á ti máa jẹun.
Wọ́n á dùbúlẹ̀ sí àwọn ilé Áṣíkẹ́lónì ní ìrọ̀lẹ́.
8 “Mo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn láti ẹnu Móábù+ àti èébú àwọn ọmọ Ámónì,+
Àwọn tó kẹ́gàn àwọn èèyàn mi, tí wọ́n sì ń halẹ̀ mọ́ wọn láti gba ilẹ̀ wọn.+
9 Nítorí náà, bí mo ti wà láàyè,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí,
“Móábù máa dà bíi Sódómù gẹ́lẹ́,+
Àti àwọn ọmọ Ámónì bíi Gòmórà,+
Ibi tí èsìsì wà, tí kòtò iyọ̀ wà, tó sì ti di ahoro títí láé.+
Àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn èèyàn mi á kó wọn lọ,
Àwọn tó ṣẹ́ kù nínú orílẹ̀-èdè mi á sì gba tọwọ́ wọn.
10 Èyí ni ohun tí wọ́n máa gbà nítorí ìgbéraga wọn,+
Torí pé wọ́n kẹ́gàn, wọ́n sì ń gbé ara wọn ga sí àwọn èèyàn Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.
11 Jèhófà máa dẹ́rù bà wọ́n;*
Nítorí ó máa mú kí gbogbo àwọn ọlọ́run tó wà ní ayé di asán,*
Gbogbo erékùṣù àwọn orílẹ̀-èdè á sì forí balẹ̀ fún un,*+
Láti ibi tí kálukú wọn wà.
12 Ẹ̀yin ará Etiópíà, idà mi ni yóò pa ẹ̀yin náà.+
14 Àwọn agbo ẹran máa dùbúlẹ̀ sí àárín rẹ̀, gbogbo àwọn ẹranko ìgbẹ́.*
Ẹyẹ òfú àti òòrẹ̀ máa sùn mọ́jú láàárín àwọn ọpọ́n orí òpó rẹ̀.
Ohùn kan á kọrin lójú fèrèsé.*
Ibi àbáwọlé á di ahoro;
Torí pé, ó máa mú kí ilẹ̀kùn kédárì jẹ.
15 Èyí ni ìlú agbéraga tó wà ní ààbò,
Tó ń sọ nínú ọkàn rẹ̀ pé, ‘Èmi ni, kò sì sí ẹlòmíì.’
Ẹ wo bó ṣe di ohun àríbẹ̀rù,
Ibi tí àwọn ẹranko ìgbẹ́ dùbúlẹ̀ sí!
Gbogbo ẹni tó bá ń gba ọ̀dọ̀ rẹ̀ kọjá á súfèé, á sì mi orí rẹ̀.”+