Àkọsílẹ̀ Lúùkù
14 Ní àkókò míì, ó lọ jẹun ní ilé ọ̀kan nínú àwọn aṣáájú àwọn Farisí ní Sábáàtì, wọ́n sì ń ṣọ́ ọ lójú méjèèjì. 2 Wò ó! ọkùnrin kan wà níwájú rẹ̀ tí ara rẹ̀ wú.* 3 Jésù wá bi àwọn tó mọ Òfin dunjú àti àwọn Farisí pé: “Ṣé ó bófin mu láti ṣe ìwòsàn ní Sábáàtì àbí kò bófin mu?”+ 4 Àmọ́ wọn ò fèsì. Ló bá di ọkùnrin náà mú, ó wò ó sàn, ó sì ní kó máa lọ. 5 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ta ni ọmọ rẹ̀ tàbí akọ màlúù rẹ̀ máa já sí kànga nínú yín,+ tí kò ní fà á jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ní ọjọ́ Sábáàtì?”+ 6 Wọn ò sì lè fèsì ọ̀rọ̀ yìí.
7 Ó wá sọ àpèjúwe kan fún àwọn èèyàn tí wọ́n pè síbẹ̀, nígbà tó kíyè sí bí wọ́n ṣe ń yan àwọn ibi tó lọ́lá jù lọ fún ara wọn.+ Ó sọ fún wọn pé: 8 “Tí ẹnì kan bá pè ọ́ síbi àsè ìgbéyàwó, má ṣe jókòó* síbi tó lọ́lá jù.+ Ó ṣeé ṣe kó ti pe ẹnì kan tí wọ́n kà sí pàtàkì jù ọ́ lọ. 9 Ẹni tó pe ẹ̀yin méjèèjì á wá sọ fún ọ pé, ‘Dìde fún ọkùnrin yìí.’ O máa wá fi ìtìjú dìde lọ jókòó síbi tó rẹlẹ̀ jù lọ. 10 Àmọ́ tí wọ́n bá pè ọ́, lọ jókòó síbi tó rẹlẹ̀ jù, kó lè jẹ́ pé tí ẹni tó pè ọ́ wá bá dé, ó máa sọ fún ọ pé, ‘Ọ̀rẹ́, lọ síbi tó ga.’ Ìgbà yẹn lo máa wá gbayì níṣojú gbogbo àwọn tí ẹ jọ jẹ́ àlejò.+ 11 Torí gbogbo ẹni tó bá gbé ara rẹ̀ ga, a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, a máa gbé e ga.”+
12 Lẹ́yìn náà, ó tún sọ fún ọkùnrin tó pè é wá, ó ní: “Tí o bá se àsè oúnjẹ ọ̀sán tàbí oúnjẹ alẹ́, má pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tàbí àwọn arákùnrin rẹ tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ tàbí àwọn aládùúgbò rẹ tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀. Torí tó bá yá, àwọn náà lè pè ọ́ wá, wọ́n á sì fìyẹn san án fún ọ. 13 Àmọ́ tí o bá se àsè, àwọn aláìní, arọ, àwọn tí kò lè rìn dáadáa àti afọ́jú ni kí o pè;+ 14 o sì máa láyọ̀, torí wọn ò ní ohunkóhun láti fi san án pa dà fún ọ. A máa san án pa dà fún ọ nígbà àjíǹde+ àwọn olódodo.”
15 Nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ àlejò gbọ́ àwọn nǹkan yìí, ó sọ fún un pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tó ń jẹun* ní Ìjọba Ọlọ́run.”
16 Jésù sọ fún un pé: “Ọkùnrin kan ń se àsè oúnjẹ alẹ́ rẹpẹtẹ,+ ó sì pe ọ̀pọ̀ èèyàn. 17 Ó rán ẹrú rẹ̀ jáde ní wákàtí tí wọ́n fẹ́ jẹ oúnjẹ alẹ́ náà láti sọ fún àwọn tó pè wá pé, ‘Ẹ máa bọ̀, torí gbogbo nǹkan ti wà ní sẹpẹ́ báyìí.’ 18 Àmọ́ ohun kan náà ni gbogbo wọn ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá àwáwí.+ Ẹni àkọ́kọ́ sọ fún un pé, ‘Mo ra pápá kan, ó sì yẹ kí n jáde lọ wò ó; jọ̀ọ́, yọ̀ǹda mi.’ 19 Ẹlòmíì sọ pé, ‘Mo ra màlúù mẹ́wàá,* mo sì fẹ́ lọ yẹ̀ wọ́n wò; jọ̀ọ́, yọ̀ǹda mi.’+ 20 Ẹlòmíì tún sọ pé, ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó ni, torí náà, mi ò ní lè wá.’ 21 Ẹrú náà wá, ó sì jábọ̀ àwọn nǹkan yìí fún ọ̀gá rẹ̀. Inú wá bí baálé ilé náà, ó sì sọ fún ẹrú rẹ̀ pé, ‘Tètè jáde lọ sí àwọn ọ̀nà tó bọ́ sí gbangba àti àwọn ọ̀nà tóóró nínú ìlú, kí o sì mú àwọn òtòṣì, arọ, afọ́jú àti àwọn tí kò lè rìn dáadáa wọlé wá síbí.’ 22 Nígbà tó yá, ẹrú náà sọ pé, ‘Ọ̀gá, mo ti ṣe ohun tí o pa láṣẹ, àmọ́ àyè ṣì kù.’ 23 Ọ̀gá náà wá sọ fún ẹrú náà pé, ‘Jáde lọ sí àwọn ojú ọ̀nà àti àwọn ọ̀nà tí kò fẹ̀, kí o sì fi dandan mú wọn wọlé wá, kí ilé mi lè kún.+ 24 Torí mò ń sọ fún yín pé, ìkankan nínú àwọn èèyàn tí mo pè yẹn ò ní tọ́ oúnjẹ alẹ́ mi wò.’”+
25 Nígbà tí èrò rẹpẹtẹ ń bá a rìnrìn àjò, ó yíjú pa dà, ó sì sọ fún wọn pé: 26 “Tí ẹnikẹ́ni bá wá sọ́dọ̀ mi, tí kò sì kórìíra* bàbá, ìyá, ìyàwó, àwọn ọmọ, àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin rẹ̀, àní ẹ̀mí*+ òun fúnra rẹ̀ pàápàá, kò lè di ọmọ ẹ̀yìn mi.+ 27 Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbé òpó igi oró* rẹ̀, kó sì máa tẹ̀ lé mi, kò lè di ọmọ ẹ̀yìn mi.+ 28 Bí àpẹẹrẹ, èwo nínú yín ló máa fẹ́ kọ́ ilé gogoro, tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kó ṣírò ohun tó máa ná an, kó lè mọ̀ bóyá àwọn ohun tó ní máa tó parí ilé náà? 29 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó lè fi ìpìlẹ̀ ilé náà lélẹ̀, àmọ́ kó má lè parí rẹ̀, gbogbo àwọn tó ń wò ó sì máa bẹ̀rẹ̀ sí í fi ṣe ẹlẹ́yà, 30 wọ́n á ní: ‘Ọkùnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́lé àmọ́ kò lè parí rẹ̀.’ 31 Àbí ọba wo, tó fẹ́ lọ bá ọba míì jagun, ni kò ní kọ́kọ́ jókòó, kó sì gba ìmọ̀ràn láti mọ̀ bóyá òun máa lè fi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọmọ ogun gbéjà ko ẹni tó ń kó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún (20,000) bọ̀ wá bá a jà? 32 Ní tòótọ́, tí kò bá lè ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé nígbà tí ọ̀nà ẹni yẹn ṣì jìn, ó máa rán àwọn ikọ̀ lọ, á sì bẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà. 33 Lọ́nà kan náà, ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé, ìkankan nínú yín tí kò bá sọ pé ó dìgbòóṣe sí* gbogbo ohun ìní rẹ̀, kò lè di ọmọ ẹ̀yìn mi.+
34 “Ó dájú pé iyọ̀ dáa. Àmọ́ tí iyọ̀ ò bá lágbára mọ́, kí la máa fi mú kó ní adùn?+ 35 Kò ṣeé lò fún iyẹ̀pẹ̀ tàbí ajílẹ̀. Ṣe ni àwọn èèyàn máa ń dà á nù. Kí ẹni tó bá ní etí láti gbọ́, fetí sílẹ̀.”+