A Kórìíra Wọn Nítorí Ìgbàgbọ́ Wọn
“Ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn ní tìtorí orúkọ mi.”—MÁTÍÙ 10:22.
1, 2. O ha lè sọ àwọn ìrírí kan tó ṣẹlẹ̀ ní ti gidi, èyí tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fara dà nítorí fífi ẹ̀sìn wọn ṣèwà hù?
NÍ ERÉKÙṢÙ Kírétè, ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ọlọ́pàá mú òǹtajà kan tó ń fòtítọ́ inú tajà, wọ́n sì wọ́ ọ lọ sílé ẹjọ́ ilẹ̀ Gíríìkì léraléra. Gbogbo-ẹ̀ gbògbò-ẹ̀, ó lò ju ọdún mẹ́fà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, láìfojú kan ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ márààrún. Ní Japan, wọ́n lé akẹ́kọ̀ọ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún kúrò níléèwé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọlúwàbí ni, tó tún mọ̀wé débi pé òun ló ń gbapò kìíní ní kíláàsì rẹ̀ tó ní akẹ́kọ̀ọ́ méjìlélógójì. Ní ilẹ̀ Faransé, ọ̀pọ̀ èèyàn ni wọ́n ṣàdédé lé dà nù lẹ́nu iṣẹ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní ti pé ká faápọn ṣiṣẹ́ ní àṣeyanjú, irú wọn ṣọ̀wọ́n lágbo òṣìṣẹ́. Ìjọra wo ló wà nínú gbogbo àwọn ìrírí gidi wọ̀nyí?
2 Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni gbogbo wọn. Kí ni “ẹ̀ṣẹ̀” wọn? Kò ju nítorí pé wọ́n ń fi ẹ̀sìn wọn ṣèwà hù. Ẹ̀kọ́ Jésù Kristi ni òǹtajà náà ṣègbọràn sí, èyí ló mú kó máa ṣàjọpín ìgbàgbọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. (Mátíù 28:19, 20) Wọ́n dá a lẹ́bi lábẹ́ òfin aláìbágbàmu ti ilẹ̀ Gíríìkì tó sọ pé ẹni tó bá ń wàásù nípa ẹ̀sìn rẹ̀ dáràn. Wọ́n lé akẹ́kọ̀ọ́ yẹn kúrò níléèwé torí pé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tí ó ti fi Bíbélì kọ́ kò jẹ́ kí ó kópa nínú eré kendo àfipámúniṣe (eré àfidàjà ti àwọn ará Japan). (Aísáyà 2:4) A sì sọ fún àwọn tí a lé dà nù lẹ́nu iṣẹ́ ní ilẹ̀ Faransé pé ìdí pàtàkì tí iṣẹ́ fi bọ́ lọ́wọ́ wọn ni pé wọ́n sọ ọ́ síta pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwọn.
3. Kí ni ìdí tí kì í fi í ṣe gbogbo Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń jẹ ìyà ńlá lọ́wọ́ àwọn ẹ̀dá ènìyàn mìíràn?
3 Irú àwọn ìrírí lílekoko báwọ̀nyẹn ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fara dà ní àwọn orílẹ̀-èdè kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Àmọ́ o, kì í ṣe gbogbo Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń jẹ irú ìyà ńlá bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀dá ènìyàn mìíràn. Kárí ayé ni a ti mọ àwọn ènìyàn Jèhófà sí ọmọlúwàbí—ìfùsì tí kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ní ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láti ṣe wọ́n níbi. (1 Pétérù 2:11, 12) Wọn kì í dìtẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í ṣeni lọ́ṣẹ́. (1 Pétérù 4:15) Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n ń gbìyànjú láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé kí wọ́n tẹrí ba fún Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́, lẹ́yìn náà fún àwọn ìjọba ayé. Wọ́n ń san owó orí tí òfin là sílẹ̀, wọ́n sì ń sapá láti “jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 12:18; 13:6, 7; 1 Pétérù 2:13-17) Nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì tí wọ́n fi ń kọ́ni, wọ́n ń gbé ìbọ̀wọ̀ fún òfin, ìwà ọmọlúwàbí nínú ìdílé, àti ìwà rere lárugẹ. Ọ̀pọ̀ àwọn alákòóso ló ń yìn wọ́n fún pípa tí wọ́n ń pa òfin ìlú mọ́. (Róòmù 13:3) Ṣùgbọ́n o, gẹ́gẹ́ bí ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ ti fi hàn, wọ́n ti fojú winá àtakò nígbà mìíràn—ní àwọn ilẹ̀ kan, kódà àwọn ìjọba kan ti fòfin gbé wọn dè. Ǹjẹ́ ó yẹ kí èyí yà wá lẹ́nu?
Ohun Tí Dídi Ọmọlẹ́yìn “Ń Náni”
4. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ti wí, kí ni èèyàn lè retí ní gbàrà tó bá di ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀?
4 Jésù Kristi kò fi wá sínú iyèméjì rárá nípa ohun tí dídi ọmọlẹ́yìn òun wé mọ́. Ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹrú kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ. Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú.” Wọ́n kórìíra Jésù “láìnídìí.” (Jòhánù 15:18-20, 25; Sáàmù 69:4; Lúùkù 23:22) Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lè retí ohun kan náà—àtakò tí kò nídìí. Lóhun tó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ, ó kìlọ̀ fún wọn pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra.”—Mátíù 10:22; 24:9.
5, 6. (a) Kí ni ìdí tí Jésù fi rọ àwọn tó fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti “gbéṣirò lé ohun tí ń náni”? (b) Kí wá ni ìdí tí kò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu nígbà tí a bá bẹ̀rẹ̀ sí dojú kọ àtakò?
5 Lójú ìwòye èyí, Jésù rọ àwọn tó fẹ́ di ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n “gbéṣirò lé ohun tí” dídi ọmọ ẹ̀yìn òun “ń náni.” (Lúùkù 14:28, Revised Standard Version) Èé ṣe? Kì í ṣe láti pinnu bóyá kí wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn òun tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n kí wọ́n lè pinnu láti dójú ìlà ohun tó wé mọ́ ọn. A gbọ́dọ̀ gbára dì láti fara da àdánwò tàbí ìṣòro èyíkéyìí tó bá bá àǹfààní náà rìn. (Lúùkù 14:27) Kò sẹ́ni tó fipá mú wa láti sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Ìpinnu àfínnú-fíndọ̀ ṣe ni; a mọ ohun tí ìpinnu náà wé mọ́. A ti mọ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ pé ní àfikún sí àwọn ìbùkún tí a óò rí gbà láti inú yíya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run, a ó jẹ́ “ẹni ìkórìíra.” Nítorí náà, kò yẹ kí ó yà wá lẹ́nu pé a ń dojú kọ àtakò. A ti ‘gbéṣirò lé ohun tó ń náni,’ a sì ti pinnu pé ohun tó bá gbà la máa fún un.—1 Pétérù 4:12-14.
6 Kí ló dé tí àwọn kan, títí kan àwọn aláṣẹ kan, fi ń tako àwọn Kristẹni tòótọ́? Láti lè rí ìdáhùn, yóò dáa tí a bá ṣàyẹ̀wò ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ méjì ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. Ẹ̀sìn méjèèjì ni a kórìíra—ṣùgbọ́n fún ìdí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Àwọn Olùkórìíra àti Ẹni Ìkórìíra
7, 8. Àwọn ẹ̀kọ́ wo ló fa títẹ́ńbẹ́lú àwọn Kèfèrí, kí sì ni ẹ̀mí tó tìtorí èyí gbèèràn láàárín àwọn Júù?
7 Nígbà tó máa fi di ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, Ísírẹ́lì ti wà lábẹ́ àkóso Róòmù, ètò ẹ̀sìn àwọn Júù sì ti wà lábẹ́ ìjẹgàba àwọn aṣáájú bí àwọn Farisí àti akọ̀wé òfin. (Mátíù 23:2-4) Àwọn aṣáájú agbawèrèmẹ́sìn wọ̀nyí yí àwọn ìlànà Òfin Mósè padà nípa yíya ara ẹni sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n ní ohun tó sọ ni pé kí àwọn Júù máa tẹ́ńbẹ́lú àwọn tí kì í ṣe Júù. Lẹ́nu ṣíṣe èyí, wọ́n dá ẹ̀sìn kan sílẹ̀ tí ń fúnni níṣìírí láti kórìíra àwọn Kèfèrí, èyí ẹ̀wẹ̀, mú kí àwọn Kèfèrí kórìíra àwọn náà.
8 Kò ṣòro fún àwọn aṣáájú Júù láti wàásù títẹ́ńbẹ́lú àwọn Kèfèrí, nítorí pé àwọn Júù ìgbàanì ka àwọn Kèfèrí sí èèyànkéèyàn. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn náà kọ́ni pé obìnrin Júù kò gbọ́dọ̀ wà, lóun nìkan, pẹ̀lú àwọn Kèfèrí, nítorí pé wọ́n “lè hu ìwàkíwà.” Ọkùnrin Júù kò gbọ́dọ̀ “dá wà pẹ̀lú wọn nítorí pé wọ́n lè tàjẹ̀ sílẹ̀.” Wọn kò lè lo wàrà tí Kèfèrí fún, àyàfi bí Júù kan bá wà níbẹ̀ tó rí bó ṣe ń fún un. Nítorí èrò tí àwọn aṣáájú wọn gbìn sí wọn lọ́kàn, àwọn Júù wá ta kété, wọ́n dá dúró gedegbe.—Fi wé Jòhánù 4:9.
9. Kí ni ìyọrísí ẹ̀kọ́ àwọn aṣáájú Júù nípa àwọn tí kì í ṣe Júù?
9 Irúfẹ́ ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ nípa àwọn tí kì í ṣe Júù ba àjọṣe tó wà láàárín àwọn Júù àti Kèfèrí jẹ́. Àwọn Kèfèrí wá bẹ̀rẹ̀ sí wo àwọn Júù gẹ́gẹ́ bí olùkórìíra gbogbo aráyé. Tacitus, òpìtàn ará Róòmù (tí a bí ní nǹkan bí ọdún 56, Sànmánì Tiwa) sọ nípa àwọn Júù pé “wọ́n ka gbogbo èèyàn yòókù sí ọ̀tá.” Tacitus tún sọ pé wọ́n kọ́ àwọn Kèfèrí tó di aláwọ̀ṣe Júù pé kí wọ́n kẹ̀yìn sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn, kí wọ́n má sì jẹ́ kí ìdílé àti ọ̀rẹ́ jọ wọ́n lójú. Dé ìwọ̀n kan, àwọn ará Róòmù fàyè gba àwọn Júù, nítorí pípọ̀ tí wọ́n pọ̀ jẹ́ kí wọ́n ṣòroó kọlù. Ṣùgbọ́n ọ̀tẹ̀ kan tí àwọn Júù dì ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa, mú kí àwọn ará Róòmù fìbínú gbẹ̀san, ìyẹn ló sì fa ìparun Jerúsálẹ́mù ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa.
10, 11. (a) Báwo ni Òfin Mósè ṣe sọ pé ó yẹ kí a máa ṣe sí àwọn àjèjì? (b) Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ láti inú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀sìn àwọn Júù?
10 Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín ojú ìwòye yẹn nípa àwọn àjèjì àti ojú ìwòye tí a là sílẹ̀ nínú ọ̀nà ìjọsìn tó wà nínú Òfin Mósè? Òtítọ́ ni Òfin sọ pé kí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n èyí jẹ́ láti dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ní pàtàkì ìjọsìn mímọ́. (Jóṣúà 23:6-8) Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Òfin là á sílẹ̀ pé kí wọ́n ṣe ẹ̀tọ́ àti òdodo fún àwọn àjèjì, kí wọ́n sì gbà wọ́n tọwọ́ tẹsẹ̀—níwọ̀n ìgbà tí wọn kò bá fi ìmójúkuku ṣàìgbọràn sí àwọn òfin Ísírẹ́lì. (Léfítíkù 24:22) Nípa yíyàbàrá kúrò nínú ohun tó ṣe kedere pé ó bọ́gbọ́n mu, tí Òfin sọ nípa àwọn àjèjì, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù lọ́jọ́ Jésù gbé ọ̀nà ìjọsìn kan kalẹ̀ tó dá ìkórìíra sílẹ̀, ọ̀nà ìjọsìn ọ̀hún sì wá di èyí tí a kórìíra. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, orílẹ̀-èdè àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní pàdánù ojú rere Jèhófà.—Mátíù 23:38.
11 Ǹjẹ́ a lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú èyí? Bẹ́ẹ̀ ni o! Ìwà jíjẹ́ olódodo lójú ara ẹni, ìwà mo-tó-tán, èyí tí ń fojú pa àwọn ẹlẹ́sìn tó yàtọ̀ sí tiwa rẹ́, kì í ṣe ìwà tó yẹ ìjọsìn mímọ́ Jèhófà rárá, inú Rẹ̀ kò dùn sírú ìwà bẹ́ẹ̀. Ronú nípa àwọn Kristẹni olóòótọ́ ní ọ̀rúndún kìíní. Wọn kò kórìíra àwọn tí kì í ṣe Kristẹni, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbé ọ̀tẹ̀ dìde sí Róòmù. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n jẹ́ “ẹni ìkórìíra.” Èé ṣe? Àwọn wo sì ni ó kórìíra wọn?
Àwọn Kristẹni Ìjímìjí —Àwọn Wo Ló Kórìíra Wọn?
12. Báwo ló ṣe ṣe kedere láti inú Ìwé Mímọ́ pé Jésù fẹ́ kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun ní èrò tó wà déédéé nípa àwọn tí kì í ṣe Kristẹni?
12 Ó ṣe kedere nínú ẹ̀kọ́ Jésù pé ó fẹ́ kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun ní èrò tó wà déédéé nípa àwọn tí kì í ṣe Kristẹni. Lọ́wọ́ kan, ó sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun yóò ta kété sí ayé—ìyẹn ni pé, wọn yóò yàgò fún àwọn èrò àti ìṣesí tó forí gbárí pẹ̀lú ọ̀nà òdodo Jèhófà. Wọn kò ní dá sí tọ̀tún tòsì nínú ọ̀ràn ogun àti òṣèlú. (Jòhánù 17:14, 16) Ṣùgbọ́n o, dípò wíwàásù títẹ́ńbẹ́lú àwọn tí kì í ṣe Kristẹni, Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n ‘nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn.’ (Mátíù 5:44) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni pé: “Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní ohun kan láti mu.” (Róòmù 12:20) Ó sì tún sọ fún àwọn Kristẹni pé kí wọ́n “máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn.”—Gálátíà 6:10.
13. Kí ló dé tí àtakò àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àwọn Júù sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀?
13 Síbẹ̀, kò pẹ́ tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi rí i pé àwọn ti di “ẹni ìkórìíra” lọ́dọ̀ ẹgbẹ́ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àkọ́kọ́ ni àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àwọn Júù. Ìdí tí wọ́n fi tètè dójú sọ àwọn Kristẹni kò mù rárá! Àwọn Kristẹni ń tẹ̀ lé ìlànà ìwà híhù tó pegedé, wọ́n ń pa ìwà títọ́ mọ́, wọ́n sì ń fi tìtara-tìtara tan ìhìn tí ń fúnni nírètí kálẹ̀. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún pa ẹ̀sìn àwọn Júù tì, wọ́n sì fayọ̀ tẹ́wọ́ gba ẹ̀sìn Kristẹni. (Ìṣe 2:41; 4:4; 6:7) Lójú àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àwọn Júù, apẹ̀yìndà gbáà ni àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tí í ṣe Júù! (Fi wé Ìṣe 13:45.) Àwọn aṣáájú tí inú ń bí wọ̀nyí nímọ̀lára pé ẹ̀sìn Kristẹni sọ àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ wọn di òtúbáńtẹ́. Kódà, ó tilẹ̀ sọ pé irọ́ gbuu ni èrò wọn nípa àwọn Kèfèrí! Láti ọdún 36 Sànmánì Tiwa síwájú, àwọn Kèfèrí bẹ̀rẹ̀ sí di Kristẹni, wọ́n ń ṣàjọpín ìgbàgbọ́ kan náà, wọ́n sì ń gbádùn àwọn àǹfààní tí àwọn Kristẹni tí í ṣe Júù ń gbádùn.—Ìṣe 10:34, 35.
14, 15. (a) Kí ló dé tí àwọn abọ̀rìṣà fi kórìíra àwọn Kristẹni? Mú àpẹẹrẹ wá. (b) Àwọn wo ni àwùjọ kẹta tí àwọn Kristẹni ìjímìjí tún jẹ́ “ẹni ìkórìíra” lọ́dọ̀ wọn?
14 Èkejì, àwọn abọ̀rìṣà kórìíra àwọn Kristẹni. Fún àpẹẹrẹ, ní Éfésù ìgbàanì, èrè ńlá ló ń wọlé nídìí ṣíṣe àwọn ojúbọ fàdákà ti abo ọlọ́run Átẹ́mísì. Ṣùgbọ́n nígbà tí Pọ́ọ̀lù wàásù níbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ará Éfésù gbọ́ ìwàásù, wọ́n fi ìjọsìn Átẹ́mísì sílẹ̀. Nígbà tí àwọn alágbẹ̀dẹ fàdákà rí i pé iṣẹ́ àwọn fẹ́ kógbá sílé, wọ́n dàgboro rú. (Ìṣe 19:24-41) Ohun tó jọ èyí ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ẹ̀sìn Kristẹni tàn dé Bítíníà (tó wà ní àríwá ìwọ̀ oòrùn Turkey báyìí). Láìpẹ́ lẹ́yìn tí a parí Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, Pliny Kékeré, tí í ṣe gómìnà Bítíníà, ròyìn pé àwọn èèyàn pa àwọn tẹ́ńpìlì abọ̀rìṣà tì, àti pé òkùtà bá ọjà oúnjẹ tí a ń fún àwọn ẹran tí a fi ń ṣe ẹbọ. Wọ́n ní àwọn Kristẹni ló fà á—wọ́n sì ṣenúnibíni sí wọn—níwọ̀n bí ìjọsìn wọn kò ti fàyè gba fífi ẹran rúbọ tàbí bíbọ̀rìṣà. (Hébérù 10:1-9; 1 Jòhánù 5:21) Dájúdájú, ìtànkálẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni ṣàkóbá fún àwọn okòwò kan tí ń bá ìbọ̀rìṣà rìn, inú sì bí àwọn tí ọjà wọ́n kùtà, tí owó wọn sì wọmi.
15 Ẹ̀kẹta, àwọn Kristẹni jẹ́ “ẹni ìkórìíra” lọ́dọ̀ àwọn ará Róòmù onífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè wọn. Lákọ̀ọ́kọ́, ojú tí àwọn ará Róòmù fi ń wo àwọn Kristẹni ni ti àwùjọ ẹlẹ́sìn kékeré tó tún jọ ti àwọn agbawèrèmẹ́sìn. Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, ẹni tó bá sọ pé Kristẹni lòun dáràn, pípa ni wọn yóò pa á. Èé ṣe tí a fi wá ń ka àwọn ọmọlúwàbí tí ń gbé ìgbé ayé Kristẹni sí àwọn tó tọ́ sí inúnibíni àti ikú?
Àwọn Kristẹni Ìjímìjí —Èé Ṣe Tí A Fi Kórìíra Wọn Lágbo Àwọn Ará Róòmù?
16. Ní àwọn ọ̀nà wo ni àwọn Kristẹni fi ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé, èé sì ti ṣe tí wọ́n fi tìtorí èyí gborúkọ burúkú lágbo àwọn ará Róòmù?
16 Ìdí pàtàkì tí a fi kórìíra àwọn Kristẹni lágbo àwọn ará Róòmù ni pé wọ́n ń fi ẹ̀sìn wọn ṣèwà hù. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé. (Jòhánù 15:19) Nítorí náà, wọn kò tẹ́wọ́ gba ipò òṣèlú, wọ́n sì kọ iṣẹ́ ológun. Fún ìdí yìí, òpìtàn náà, Augustus Neander sọ pé, wọ́n “kà wọ́n sí àwọn tí kò gbọ́ èyí táráyé ń wí, àwọn tí kò mọ ohun tó ń lọ rárá nílùú.” Ṣíṣàìjẹ́ apá kan ayé tún túmọ̀ sí yíyẹra fún àwọn ìwà burúkú tó wọ́pọ̀ lágbo àwọn ará Róòmù oníwà ìbàjẹ́. Òpìtàn náà, Will Durant ṣàlàyé pé: “Ìfọkànsìn àti ìwà ẹ̀yẹ àwùjọ kékeré ti àwọn Kristẹni kó ìdààmú bá ẹ̀rí ọkàn àwọn abọ̀rìṣà wọnnì tí ayé ìjẹkújẹ ti fọ́ lórí.” (1 Pétérù 4:3, 4) Bóyá ọ̀nà àtipa ẹ̀rí ọkàn tó ń yọ wọ́n lẹ́nu mọ́ ló fà á tí àwọn ará Róòmù fi bẹ̀rẹ̀ sí ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni, tí wọ́n sí ń pa wọ́n.
17. Kí ló fi hàn pé iṣẹ́ ìwàásù àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kẹ́sẹ járí?
17 Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní fi ìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run láìṣàárẹ̀. (Mátíù 24:14) Nígbà tó fi máa di nǹkan bí ọdún 60 Sànmánì Tiwa, Pọ́ọ̀lù lè sọ pé ìhìn rere náà ni a ti “wàásù nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” (Kólósè 1:23) Nígbà tó fi máa di òpin ọ̀rúndún kìíní, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ti sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn jákèjádò Ilẹ̀ Ọba Róòmù—ní Éṣíà, ní Yúróòpù, àti ní Áfíríkà! Àní àwọn kan lára mẹ́ńbà “agbo ilé Késárì” ti di Kristẹni.a (Fílípì 4:22) Ìwàásù onítara yìí ru ìkórìíra sókè. Neander wí pé: “Ẹ̀sìn Kristẹni bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ síwájú láìsọsẹ̀ láàárín kóówá, ó fẹjú mọ́ ẹ̀sìn tó wà lójú ọpọ́n lórílẹ̀-èdè yẹn, ó fẹ́ bì í ṣubú.”
18. Kí ló dé tí inú fi ń bí ìjọba Róòmù nítorí pé àwọn Kristẹni ń fún Jèhófà ní ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe?
18 Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ń fún Jèhófà ní ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe. (Mátíù 4:8-10) Àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé apá yìí nínú ìjọsìn wọn ló bí Róòmù nínú jù lọ. Àwọn ará Róòmù kò bá àwọn ẹ̀sìn yòókù jà, bí àwọn ẹlẹ́sìn náà bá sáà ti ń lọ́wọ́ nínú jíjọ́sìn ọba. Àwọn Kristẹni ìjímìjí kọ̀ jálẹ̀ láti lọ́wọ́ nínú irú ìjọsìn bẹ́ẹ̀. Wọ́n gbà pé, Jèhófà Ọlọ́run, aláṣẹ tó ga ju Orílẹ̀-èdè Róòmù, ni àwọn yóò jíhìn fún. (Ìṣe 5:29) Fún ìdí yìí, bó ṣe wù kí Kristẹni kan jẹ́ ọmọlúwàbí tó nílùú, ọ̀tá Orílẹ̀-èdè ni wọ́n kà á sí.
19, 20. (a) Àwọn wo ló sábà máa ń wà nídìí irọ́ burúkú tí a pa mọ́ àwọn Kristẹni olóòótọ́? (b) Àwọn ẹ̀sùn èké wo la fi kan àwọn Kristẹni?
19 Ó ṣì ku ìdí mìíràn tí àwọn Kristẹni olóòótọ́ fi jẹ́ “ẹni ìkórìíra” lágbo àwọn ará Róòmù: Àwọn èèyàn tètè máa ń gba irọ́ burúkú tí wọ́n bá pa mọ́ wọn gbọ́, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àwọn Júù ló sì sábà máa ń wà nídìí irú ìgbékèéyíde bẹ́ẹ̀. (Ìṣe 17:5-8) Ní nǹkan bí ọdún 60 tàbí 61 Sànmánì Tiwa, tí Pọ́ọ̀lù wà ní Róòmù tó ń dúró de ìgbẹ́jọ́ níwájú Ọba Nero, àwọn òléwájú Júù sọ nípa àwọn Kristẹni pé: “Lóòótọ́, ní ti ẹ̀ya ìsìn yìí, a mọ̀ pé níbi gbogbo ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.” (Ìṣe 28:22) Kò sí ni, kí Nero máà gbọ́ àwọn ìtàn èké tí a fi ń bà wọ́n lórúkọ jẹ́. Ní ọdún 64 Sànmánì Tiwa, nígbà tí àwọn èèyàn fẹ̀sùn kan Nero pé iná tó jó Róòmù ráúráú kò ṣẹ̀yìn rẹ̀, kíá ló ti yí i lé àwọn Kristẹni lórí, ó láwọn tí wọ́n ń purọ́ mọ́ tẹ́lẹ̀ náà ló gbọ́dọ̀ mọ̀ nípa rẹ̀. Èyí ló jọ pé ó fa òjò inúnibíni oníkà tí wọ́n rọ̀ lé àwọn Kristẹni lórí, tí wọ́n fẹ́ pa wọ́n rẹ́ pátápátá.
20 Àwọn ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi ń kan àwọn Kristẹni sábà máa ń jẹ́ irọ́ burúkú tí a yí mọ́ àwọn ìgbàgbọ́ wọn táwọn èèyàn túmọ̀ gbòdì. Torí pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ni wọ́n gbà gbọ́, tí wọn kì í sì í jọ́sìn ọba, wọ́n sọ wọ́n ní aláìgbọlọ́rungbọ́. Torí pé àwọn mẹ́ńbà ìdílé tí kì í ṣe Kristẹni máa ń tako àwọn ẹbí wọn tó jẹ́ Kristẹni, wọ́n ní ṣe ni àwọn Kristẹni ń tú ìdílé ká. (Mátíù 10:21) Wọ́n ní ajẹ̀ẹ̀yàn ni wọ́n, àwọn kan sì sọ pé ẹ̀sùn yìí jáde nítorí lílọ́ ọ̀rọ̀ Jésù po, èyí tó sọ nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa.—Mátíù 26:26-28.
21. Ìdí méjì wo ló sọ àwọn Kristẹni di “ẹni ìkórìíra”?
21 Nítorí náà, àwọn Kristẹni olóòótọ́ jẹ́ “ẹni ìkórìíra” lọ́dọ̀ àwọn ará Róòmù fún ìdí pàtàkì méjì: (1) ìgbàgbọ́ àti ìṣesí wọn tí a gbé ka Bíbélì, àti (2) àwọn ẹ̀sùn èké tí a fi kàn wọ́n. Ohun yòówù kó fà á, góńgó kan ṣoṣo ni àwọn alátakò ní—láti tẹ ẹ̀sìn Kristẹni rì. Àmọ́ ṣá o, àwọn alátakò tó ga ju ẹ̀dá lọ, àwọn agbára ẹ̀mí àìrí burúkú, ni àwọn ẹni náà gan-an tó wà nídìí inúnibíni sí àwọn Kristẹni.—Éfésù 6:12.
22. (a) Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sapá láti “ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn”? (Wo àpótí lójú ìwé 11.) (b) Kí ni a óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?
22 Bí ti àwọn Kristẹni ìjímìjí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní ti di “ẹni ìkórìíra” ní onírúurú ilẹ̀. Bẹ́ẹ̀ rèé, àwọn Ẹlẹ́rìí kì í kórìíra àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí; a ò sì gbọ́ ọ rí pé wọ́n da ìlú rú mọ́ ìjọba lọ́wọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, a mọ̀ wọ́n kárí ayé pé wọ́n ń fi ojúlówó ìfẹ́ hàn, ìfẹ́ tí a kò fi mọ sáàárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà kan, ìran kan, tàbí ẹ̀yà kan. Kí wá ló dé tí wọ́n fi ń ṣe inúnibíni sí wọn? Báwo sì ni wọ́n ṣe ń hùwà padà sí àtakò? A óò jíròrò ìbéèrè wọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gbólóhùn náà, “agbo ilé Késárì” kò fi dandan jẹ́ àwọn mẹ́ńbà ìdílé Nero gangan, tí ń ṣàkóso nígbà yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó lè jẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ilé àti àwọn òṣìṣẹ́ onípò rírẹlẹ̀, bóyá àwọn tí ń ṣe àwọn iṣẹ́ ilé bí gbígbọ́únjẹ àti gbígbálẹ̀ fún ìdílé ọba àti àwọn òṣìṣẹ́ onípò gíga.
Báwo ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Èé ṣe tí Jésù fi rọ àwọn tó fẹ́ di ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n gbéṣirò lé ohun tí dídi ọmọ ẹ̀yìn ń náni?
◻ Ipa wo ni ojú ìwòye tó gbòde kan nípa àwọn tí kì í ṣe Júù ní lórí ẹ̀sìn àwọn Júù, kí sì ni ẹ̀kọ́ tí a rí kọ́ láti inú èyí?
◻ Ọ̀dọ̀ àwọn mẹ́ta wo ni àwọn Kristẹni olóòótọ́ ìjímìjí ti dojú kọ àtakò?
◻ Àwọn ìdí pàtàkì wo ló jẹ́ kí àwọn Kristẹni ìjímìjí jẹ́ “ẹni ìkórìíra” lọ́dọ̀ àwọn ará Róòmù?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]
‘Ṣíṣe Ohun Rere sí Gbogbo Ènìyàn’
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sapá láti ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Bíbélì láti “máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn.” (Gálátíà 6:10) Ní àkókò àìní, ìfẹ́ ọmọnìkejì ẹni máa ń sún wọn láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tí kì í ṣe mẹ́ńbà ẹ̀sìn wọn. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí kutupu hu ní Rwanda ní ọdún 1994, Àwọn Ẹlẹ́rìí láti Yúróòpù fínnú fíndọ̀ yọ̀ǹda láti lọ sí Áfíríkà láti lọ pèsè àwọn ìrànlọ́wọ́ adínṣòro-kù. Lẹ́yẹ-ò-sọkà, wọ́n ti gbé àwọn ibùdó tí a ṣètò dáradára àti àwọn ilé ìwòsàn onígbà díẹ̀ kalẹ̀ láti pèsè ìrànlọ́wọ́. Wọ̀ǹtì-wọnti loúnjẹ, aṣọ, àti bùláńkẹ́ẹ̀tì tí wọ́n fi ọkọ̀ òfuurufú kó wá. Iye àwọn olùwá-ibi-ìsádi tó jàǹfààní láti inú ètò yìí ju ìlọ́po mẹ́ta Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní àgbègbè yẹn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní fi ìtara wàásù ìhìn rere láìṣàárẹ̀