ORÍ 84
Iṣẹ́ Kékeré Kọ́ Lẹnì Kan Máa Ṣe Kó Tó Lè Di Ọmọ Ẹ̀yìn
OHUN TÓ MÁA NÁ ẸNÌ KAN KÓ TÓ LÈ DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN
Jésù ti kọ́ àwọn èèyàn ní ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ pàtàkì nígbà tó lọ jẹun nílé aṣáájú àwọn Farisí kan. Àmọ́ bó ṣe ń pa dà sí Jerúsálẹ́mù, àwọn èrò ń wọ́ tẹ̀ lé e. Kí nìdí? Ṣé torí pé wọ́n fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni, láìka ohunkóhun tó bá máa gbà?
Bí wọ́n ṣe ń lọ, Jésù sọ ohun kan tó ṣeé ṣe kó ya àwọn kan lẹ́nu, ó sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá wá sọ́dọ̀ mi, tí kò sì kórìíra bàbá, ìyá, ìyàwó, àwọn ọmọ, àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin rẹ̀, àní ẹ̀mí òun fúnra rẹ̀ pàápàá, kò lè di ọmọ ẹ̀yìn mi.” (Lúùkù 14:26) Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ̀rọ̀ yìí?
Jésù ò sọ pé káwọn tó bá fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn òun kórìíra àwọn mọ̀lẹ́bí wọn o. Ohun tó túmọ̀ sí láti kórìíra wọn ni pé wọ́n gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ òun ju àwọn mọ̀lẹ́bí wọn lọ, kò sì fẹ́ kí wọ́n dà bí ọkùnrin inú àpèjúwe nípa àsè oúnjẹ alẹ́ tó kọ̀ láti wá síbi àsè náà torí pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó. (Lúùkù 14:20) Bákan náà, nígbà tí Bíbélì sọ pé Jékọ́bù tó jẹ́ baba ńlá àwọn Júù “kórìíra” Líà tó sì fẹ́ràn Réṣẹ́lì, ohun tó túmọ̀ sí ni pé Jékọ́bù nífẹ̀ẹ́ Líà, àmọ́ ìfẹ́ tó ní fún un kò tó èyí tó ní fún Réṣẹ́lì.—Jẹ́nẹ́sísì 29:31; àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.
Ẹ kíyè sí i pé Jésù tún sọ pé ọmọ ẹ̀yìn kan máa ní láti kórìíra “ẹ̀mí òun fúnra rẹ̀ pàápàá,” tàbí ọkàn rẹ̀. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé ẹni tó bá jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù lóòótọ́ gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jésù ju bó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ lọ, kódà ẹni náà gbọ́dọ̀ ṣe tán láti kú tó bá gbà bẹ́ẹ̀. Ó ṣe kedere pé ohun kékeré kọ́ ló máa ná ẹnì kan tó bá fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Kì í ṣe ohun téèyàn ń fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú, láìkọ́kọ́ ronú jinlẹ̀ kó tó dáwọ́ lé e.
Ó yẹ kí ẹni tó bá fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn retí pé òun máa kojú ìṣòro àti àtakò, torí Jésù sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbé òpó igi oró rẹ̀, kó sì máa tẹ̀ lé mi, kò lè di ọmọ ẹ̀yìn mi.” (Lúùkù 14:27) Bọ̀rọ̀ sì ṣe rí gan-an nìyẹn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gbọ́dọ̀ múra tán láti kojú ìṣòro bíi ti Jésù. Kódà, ó ti sọ fún wọn pé àwọn ọ̀tá ló máa pa òun.
Torí náà, àwọn èrò tó wà pẹ̀lú Jésù gbọ́dọ̀ ronú dáadáa nípa ohun tó túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Jésù túbọ̀ tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ṣe àpèjúwe kan, ó ní: “Bí àpẹẹrẹ, èwo nínú yín ló máa fẹ́ kọ́ ilé gogoro, tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kó ṣírò ohun tó máa ná an, kó lè mọ̀ bóyá àwọn ohun tó ní máa tó parí ilé náà? Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó lè fi ìpìlẹ̀ ilé náà lélẹ̀, àmọ́ kó má lè parí rẹ.” (Lúùkù 14:28, 29) Ìyẹn ni pé kí àwọn tó ń tẹ̀ lé Jésù tó di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ló yẹ kí wọ́n ti pinnu pé àwọn máa ṣe gbogbo ohun tó bá gbà. Ó tún fi àpèjúwe míì ṣàlàyé ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Ó sọ pé: “Ọba wo, tó fẹ́ lọ bá ọba míì jagun, ni kò ní kọ́kọ́ jókòó, kó sì gba ìmọ̀ràn láti mọ̀ bóyá òun máa lè fi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọmọ ogun gbéjà ko ẹni tó ń kó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún (20,000) bọ̀ wá bá a jà? Ní tòótọ́, tí kò bá lè ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé nígbà tí ọ̀nà ẹni yẹn ṣì jìn, ó máa rán àwọn ikọ̀ lọ, á sì bẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà. Lọ́nà kan náà, ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé, ìkankan nínú yín tí kò bá sọ pé ó dìgbòóṣe sí gbogbo ohun ìní rẹ̀, kò lè di ọmọ ẹ̀yìn mi.”—Lúùkù 14:31-33.
Àwọn èrò tó ń tẹ̀ lé Jésù nígbà yẹn nìkan kọ́ lọ̀rọ̀ yẹn kàn. Gbogbo àwọn tó bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Kristi ló gbọ́dọ̀ ṣe tán láti tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ yìí. Ìyẹn ni pé kí wọ́n tó lè di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe tán láti yááfì gbogbo ohun tí wọ́n ní, títí kan ẹ̀mí wọn pàápàá. Ọ̀rọ̀ yìí gba àròjinlẹ̀, ó sì tún yẹ kéèyàn gbàdúrà nípa rẹ̀.
Lẹ́yìn náà, Jésù sọ̀rọ̀ nípa kókó kan tó ti mẹ́nu kàn tẹ́lẹ̀ nínú Ìwàásù Lórí Òkè nígbà tó pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní “iyọ̀ ayé.” (Mátíù 5:13) Ọ̀rọ̀ tó sọ yìí fi hàn pé bí iyọ̀ kì í ṣe jẹ́ kí nǹkan bà jẹ́, bẹ́ẹ̀ làwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe máa dáàbò bo àwọn èèyàn kí ohunkóhun má bàa ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Ní báyìí tí Jésù ń parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó wá sọ pé: “Ó dájú pé iyọ̀ dáa. Àmọ́ tí iyọ̀ ò bá lágbára mọ́, kí la máa fi mú kó ní adùn?” (Lúùkù 14:34) Àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ̀ pé àwọn iyọ̀ kan wà tí kò dáa, torí pé wọ́n ti dà pọ̀ mọ́ ìdọ̀tí, èyí ò sì ní jẹ́ kí wọ́n wúlò mọ́.
Fún ìdí yìí, Jésù jẹ́ ká rí i pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí òun tutù, kódà tó bá tiẹ̀ ti pẹ́ tí wọ́n ti ń tẹ̀ lé òun. Tó bá lọ tutù pẹ́nrẹ́n, ṣe ni wọ́n máa dà bí iyọ̀ tí ò wúlò mọ́, àwọn èèyàn á sì fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Èyí tó wá le jù ni pé wọn ò ní wúlò fún Ọlọ́run mọ́, ìyẹn sì máa kó ẹ̀gàn bá orúkọ rẹ̀. Jésù wá tẹnu mọ́ ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti ṣọ́ra kírú nǹkan bẹ́ẹ̀ má bàa ṣẹlẹ̀, ó ní: “Kí ẹni tó bá ní etí láti gbọ́, fetí sílẹ̀.”—Lúùkù 14:35.