Sí Àwọn Hébérù
10 Nígbà tó jẹ́ pé Òfin ní òjìji+ àwọn nǹkan rere tó ń bọ̀,+ àmọ́ tí kì í ṣe bí àwọn nǹkan náà ṣe máa rí gan-an, kò lè* sọ àwọn tó ń wá sí tòsí di pípé láé nípasẹ̀ àwọn ẹbọ kan náà tí wọ́n ń rú léraléra láti ọdún dé ọdún.+ 2 Tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé wọn ò ti ní dáwọ́ rírú àwọn ẹbọ náà dúró? Torí tí a bá ti wẹ àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ mọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, wọn ò ní mọ̀ ọ́n lára pé àwọn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ mọ́. 3 Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni àwọn ẹbọ yìí ń ránni létí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ láti ọdún dé ọdún,+ 4 torí ẹ̀jẹ̀ àwọn akọ màlúù àti ti àwọn ewúrẹ́ kò lè mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.
5 Torí náà, nígbà tó wá sí ayé, ó sọ pé: “‘Ẹbọ àti ọrẹ kọ́ ni ohun tí o fẹ́, àmọ́ ìwọ pèsè ara kan fún mi. 6 O ò fọwọ́ sí àwọn odindi ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.’+ 7 Lẹ́yìn náà, mo sọ pé: ‘Wò ó! Mo ti dé (a ti kọ ọ́ nípa mi sínú àkájọ ìwé*) láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.’”+ 8 Lẹ́yìn tó kọ́kọ́ sọ pé: “O ò fẹ́ àwọn ẹbọ, ọrẹ, odindi ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, o ò sì fọwọ́ sí i”—àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú, bí Òfin ṣe sọ— 9 ó wá sọ pé: “Wò ó! Mo ti dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ.”+ Ó fi òpin sí èyí àkọ́kọ́ kó lè fìdí ìkejì múlẹ̀. 10 Nípasẹ̀ “ìfẹ́” yìí,+ a ti fi ara Jésù Kristi tó fi rúbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé sọ wá di mímọ́.+
11 Bákan náà, gbogbo àwọn àlùfáà máa ń lọ sẹ́nu iṣẹ́ wọn lójoojúmọ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́,*+ kí wọ́n sì lè rú àwọn ẹbọ kan náà léraléra,+ èyí tí kò lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò pátápátá.+ 12 Àmọ́ ẹbọ kan ṣoṣo ni ọkùnrin yìí rú fún ẹ̀ṣẹ̀ láìtún ní ṣe é mọ́ láé, ó sì jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run,+ 13 látìgbà yẹn, ó ń dúró de ìgbà tí a máa fi àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀.+ 14 Torí ẹbọ kan ṣoṣo tó rú ló fi sọ àwọn tí à ń sọ di mímọ́ di pípé+ láìtún ní ṣe é mọ́ láé. 15 Bákan náà, ẹ̀mí mímọ́ náà ń jẹ́rìí fún wa, torí lẹ́yìn tó sọ pé: 16 “‘Májẹ̀mú tí màá bá wọn dá lẹ́yìn ìgbà yẹn nìyí,’ ni Jèhófà* wí. ‘Màá fi àwọn òfin mi sínú ọkàn wọn, inú èrò wọn ni màá sì kọ ọ́ sí.’”+ 17 Ó wá sọ pé: “Mi ò sì ní rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́ àti àwọn ìwà wọn tí kò bófin mu.”+ 18 Torí náà, tí a bá ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yìí jini, kò tún sí ẹbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.
19 Torí náà, ẹ̀yin ará, nígbà tó jẹ́ pé a ní ìgboyà* láti wá sí ọ̀nà tó wọnú ibi mímọ́+ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jésù, 20 èyí tó ṣí sílẹ̀* fún wa bí ọ̀nà tuntun, tó sì jẹ́ ọ̀nà ìyè tó la aṣọ ìdábùú kọjá,+ ìyẹn ẹran ara rẹ̀, 21 nígbà tó sì jẹ́ pé a ní àlùfáà ńlá lórí ilé Ọlọ́run,+ 22 ẹ jẹ́ ká fi ọkàn tòótọ́ àti ìgbàgbọ́ tó kún rẹ́rẹ́ wá, nígbà tí a ti wẹ ọkàn wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀rí ọkàn burúkú,+ tí a sì ti fi omi tó mọ́ wẹ ara wa.+ 23 Ẹ jẹ́ ká tẹra mọ́ ìkéde ìrètí wa ní gbangba* láìṣiyèméjì,+ torí pé olóòótọ́ ni ẹni tó ṣèlérí. 24 Ẹ sì jẹ́ ká gba ti ara wa rò* ká lè máa fún ara wa níṣìírí* láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere,+ 25 ká má ṣe máa kọ ìpàdé wa sílẹ̀,+ bí àṣà àwọn kan, àmọ́ ká máa gba ara wa níyànjú,+ ní pàtàkì jù lọ bí ẹ ṣe ń rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.+
26 Torí tí a bá mọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà lẹ́yìn tí a ti gba ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́,+ kò tún sí ẹbọ kankan fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́,+ 27 àfi ká máa fi ìbẹ̀rù retí ìdájọ́ àti ìbínú tó le, tó sì máa jó àwọn tó ń ṣàtakò run.+ 28 A kì í ṣàánú ẹnikẹ́ni tí kò bá ka Òfin Mósè sí, ó máa kú tí ẹni méjì tàbí mẹ́ta bá ti jẹ́rìí sí i.+ 29 Báwo lẹ ṣe wá rò pé ó yẹ kí ìyà tó máa jẹ ẹni tó tẹ Ọmọ Ọlọ́run mọ́lẹ̀ pọ̀ tó, tó ti ka ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú+ tí a fi sọ ọ́ di mímọ́ sí nǹkan yẹpẹrẹ, tó sì fi ìwà àfojúdi mú ẹ̀mí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí bínú?+ 30 Torí a mọ Ẹni tó sọ pé: “Tèmi ni ẹ̀san; màá gbẹ̀san.” Àti pé: “Jèhófà* máa dá ẹjọ́ àwọn èèyàn rẹ̀.”+ 31 Ohun tó ń bani lẹ́rù ló jẹ́ láti kó sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè.
32 Àmọ́, ẹ máa rántí àwọn ọjọ́ àtijọ́, tí ẹ fara da ìjàkadì ńlá pẹ̀lú ìyà, lẹ́yìn tí a là yín lóye.+ 33 Nígbà míì, wọ́n máa ń tú yín síta gbangba* fún ẹ̀gàn àti ìpọ́njú, nígbà míì sì rèé, ẹ máa ń ṣe alábàápín pẹ̀lú* àwọn tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí. 34 Torí ẹ bá àwọn tó wà ní ẹ̀wọ̀n kẹ́dùn, ẹ sì fi ayọ̀ gba bí wọ́n ṣe kó ẹrù yín,+ torí ẹ mọ̀ pé ẹ̀yin fúnra yín ní ohun ìní tó dáa jù, tó sì wà pẹ́ títí.+
35 Torí náà, ẹ má sọ ìgboyà yín* nù, èyí tí a máa torí rẹ̀ fún yín ní èrè tó kún rẹ́rẹ́.+ 36 Nítorí ẹ nílò ìfaradà,+ pé lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ lè rí ohun tí ó ṣèlérí náà gbà. 37 Torí ní “ìgbà díẹ̀ sí i”+ àti pé “ẹni tó ń bọ̀ máa dé, kò sì ní pẹ́.”+ 38 “Àmọ́ ìgbàgbọ́ yóò mú kí olódodo mi wà láàyè”+ àti pé “tó bá fà sẹ́yìn, inú mi* ò ní dùn sí i.”+ 39 Ní báyìí, a kì í ṣe irú àwọn tó ń fà sẹ́yìn sí ìparun,+ àmọ́ irú àwọn tó ní ìgbàgbọ́ kí a lè dá ẹ̀mí* wa sí.