Ìsíkíẹ́lì
5 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, mú idà kan tó mú kí o lè lò ó bí abẹ ìfárí. Fá orí rẹ àti irùngbọ̀n rẹ, kí o sì mú òṣùwọ̀n kí o lè wọn irun náà, kí o sì pín in. 2 O máa fi iná sun ìdá mẹ́ta irun náà nínú ìlú náà nígbà tí ọjọ́ tí wọ́n dó tì í bá pé.+ O máa kó ìdá mẹ́ta míì, o sì máa fi idà gé e káàkiri ìlú náà,+ kí o wá fọ́n ìdá mẹ́ta yòókù sínú afẹ́fẹ́, èmi yóò sì mú idà kí n lè lé wọn bá.+
3 “Kí o tún mú fọ́nrán díẹ̀ nínú irun náà, kí o sì wé e mọ́ aṣọ rẹ. 4 Kí o mú díẹ̀ sí i lára rẹ̀, kí o jù ú sínú iná, kí o sì sun ún di eérú. Láti ibẹ̀ ni iná yóò ti ran gbogbo ilé Ísírẹ́lì.+
5 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èyí ni Jerúsálẹ́mù. Mo ti fi í sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ìlú sì yí i ká. 6 Àmọ́, ó ti kọ àwọn ìdájọ́ àti àṣẹ mi, ìwà rẹ̀ sì burú ju ti àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ìlú tó yí i ká lọ.+ Torí wọ́n ti kọ àwọn ìdájọ́ mi, wọn ò sì tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi.’
7 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Torí pé agídí yín pọ̀ ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tó yí yín ká, tí ẹ kò tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi, tí ẹ sì kọ àwọn ìdájọ́ mi; àmọ́ ẹ tẹ̀ lé ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tó yí yín ká,+ 8 ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò kọjú ìjà sí ọ, ìwọ ìlú,+ èmi fúnra mi yóò sì ṣèdájọ́ ní àárín rẹ lójú àwọn orílẹ̀-èdè.+ 9 Ohun tí mi ò ṣe rí ni màá ṣe fún ọ, mi ò sì tún ní ṣe irú rẹ̀ mọ́, torí gbogbo ohun ìríra tí ò ń ṣe.+
10 “‘“Ṣe ni àwọn bàbá tó wà ní àárín yín yóò jẹ àwọn ọmọ wọn,+ àwọn ọmọ yóò sì jẹ àwọn bàbá wọn, màá ṣe ìdájọ́ yín, màá sì fọ́n àwọn tó ṣẹ́ kù nínú yín káàkiri.”’*+
11 “‘Torí náà, bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘torí pé ẹ fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin yín àti àwọn ohun ìríra tí ẹ̀ ń ṣe sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́,+ èmi náà yóò kọ̀ yín;* mi ò ní ṣàánú yín, mi ò sì ní yọ́nú sí yín.+ 12 Àjàkálẹ̀ àrùn* tàbí ìyàn máa pa ìdá mẹ́ta lára yín. Wọ́n á sì fi idà pa ìdá mẹ́ta míì láyìíká yín.+ Màá fọ́n ìdá mẹ́ta yòókù káàkiri,* màá sì fa idà yọ láti fi lé wọn.+ 13 Mi ò sì ní bínú mọ́, inú mi ò ní ru sí wọn mọ́, màá ti tẹ́ ara mi lọ́rùn.+ Nígbà tí mo bá ti bínú gidigidi sí wọn tán, wọ́n á mọ̀ pé èmi, Jèhófà, ti sọ pé èmi nìkan ni mo fẹ́ kí ẹ máa jọ́sìn.+
14 “‘Èmi yóò sọ ọ́ di ahoro, màá sì mú kí àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká àti àwọn tó ń kọjá lọ máa gàn ọ́.+ 15 Wọ́n á gàn ọ́, wọ́n á sì fi ọ́ ṣẹlẹ́yà.+ Wọ́n á kọ́gbọ́n lára rẹ, ẹ̀rù á sì ba àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká, nígbà tí mo bá fi ìbínú àti ìrunú dá ọ lẹ́jọ́ tí mo sì fìyà jẹ ọ́ gidigidi. Èmi, Jèhófà, ti sọ ọ́.
16 “‘Màá fi ìyàn kọ lù wọ́n, ó máa pa wọ́n run bí ìgbà tí mo bá ta wọ́n ní ọfà olóró. Ọfà tí mo bá ta yóò run yín.+ Màá mú kí ìyàn náà le sí i torí pé màá dáwọ́ oúnjẹ yín dúró.*+ 17 Màá fi ìyàn kọ lù yín, màá rán àwọn ẹranko burúkú sí yín,+ wọ́n á sì pa yín lọ́mọ jẹ. Àjàkálẹ̀ àrùn máa bò yín, ìtàjẹ̀sílẹ̀ á kún ilẹ̀ yín, màá sì fi idà kọ lù yín.+ Èmi, Jèhófà, ti sọ ọ́.’”