Ìsíkíẹ́lì
8 Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹfà, ọdún kẹfà, nígbà tí mo jókòó sínú ilé mi, tí àwọn àgbààgbà Júdà sì jókòó síwájú mi, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ fún mi lágbára níbẹ̀. 2 Bí mo ṣe ń wò, mo rí ẹnì kan tó rí bí iná; ó jọ pé iná wà níbi ìbàdí rẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀.+ Láti ìbàdí rẹ̀ lọ sókè, ó mọ́lẹ̀, ó rí bí àyọ́pọ̀ wúrà àti fàdákà tó ń dán yanran.+ 3 Ó wá na ohun tó dà bí ọwọ́ jáde, ó fa irun orí mi, ẹ̀mí kan sì gbé mi nínú ìran látọ̀dọ̀ Ọlọ́run lọ sí agbedeméjì ayé àti ọ̀run. Ó gbé mi wá sí Jerúsálẹ́mù, sí ẹnubodè inú,+ èyí tó kọjú sí àríwá, níbi tí ère* owú tó ń múni jowú wà.+ 4 Wò ó! ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì wà níbẹ̀,+ ó dà bí ohun tí mo rí ní pẹ̀tẹ́lẹ̀.+
5 Ó wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, jọ̀ọ́ gbójú sókè kí o wo àríwá.” Torí náà, mo wo àríwá, mo sì rí ère* owú náà ní àríwá ẹnubodè pẹpẹ. 6 Ó sì sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, ṣé o rí ohun ìríra tó burú jáì tí ilé Ísírẹ́lì ń ṣe níbí,+ tó mú kí n jìnnà sí ibi mímọ́ mi?+ O máa rí àwọn ohun tó ń ríni lára tó tún burú ju èyí lọ.”
7 Ó wá mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá, nígbà tí mo sì wo ibẹ̀, mo rí ihò kan lára ògiri. 8 Ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, jọ̀ọ́ dá ògiri náà lu.” Ni mo bá dá ògiri náà lu, mo sì rí ẹnu ọ̀nà kan. 9 Ó sọ fún mi pé: “Wọlé, kí o lè rí iṣẹ́ ibi tó ń ríni lára tí wọ́n ń ṣe níbí.” 10 Torí náà, mo wọlé, mo wò ó, mo sì rí oríṣiríṣi àwòrán ohun tó ń rákò àti ẹranko tó ń kóni nírìíra+ àti gbogbo òrìṣà ẹ̀gbin* ilé Ísírẹ́lì;+ wọ́n gbẹ́ ẹ sí ara ògiri káàkiri. 11 Àádọ́rin (70) ọkùnrin lára àwọn àgbààgbà ilé Ísírẹ́lì dúró níwájú wọn, Jasanáyà ọmọ Ṣáfánì+ sì wà lára wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn mú àwo tùràrí rẹ̀ dání, èéfín tùràrí tó ní òórùn dídùn sì ń gòkè lọ.+ 12 Ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, ṣé o rí ohun tí àwọn àgbààgbà ilé Ísírẹ́lì ń ṣe nínú òkùnkùn, kálukú nínú yàrá inú tó kó* àwọn ère rẹ̀ sí? Wọ́n ń sọ pé, ‘Jèhófà ò rí wa. Jèhófà ti fi ilẹ̀ wa sílẹ̀.’”+
13 Ó wá sọ fún mi pé: “Wàá rí àwọn ohun tó ń ríni lára tí wọ́n ń ṣe tó tún burú ju èyí lọ.” 14 Torí náà, ó mú mi wá sí ẹnubodè àríwá ní ilé Jèhófà, mo sì rí àwọn obìnrin tí wọ́n jókòó síbẹ̀, tí wọ́n ń sunkún torí ọlọ́run tí wọ́n ń pè ní Támúsì.
15 Ó sọ fún mi síwájú sí i pé: “Ọmọ èèyàn, ṣé ìwọ náà rí i? Wàá rí àwọn ohun ìríra tó tún burú ju èyí lọ.”+ 16 Torí náà, ó mú mi wá sí àgbàlá inú ní ilé Jèhófà.+ Ní ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì Jèhófà, láàárín ibi àbáwọlé* àti pẹpẹ, nǹkan bí ọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) wà níbẹ̀ tí wọ́n kẹ̀yìn sí tẹ́ńpìlì Jèhófà, tí wọ́n sì kọjú sí ìlà oòrùn; wọ́n ń forí balẹ̀ fún oòrùn níbẹ̀.+
17 Ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, ṣé ìwọ náà rí i? Ṣé ohun tí kò tó nǹkan ni lójú ilé Júdà láti ṣe àwọn ohun ìríra yìí, tí wọ́n ń hu ìwà ipá ní gbogbo ilẹ̀ náà,+ tí wọ́n sì ń ṣẹ̀ mí? Wọ́n ń na ẹ̀ka* sí mi ní imú. 18 Torí náà, màá bínú sí wọn. Mi ò ní ṣàánú wọn, mi ò sì ní yọ́nú sí wọn.+ Bí wọ́n bá tiẹ̀ kígbe tantan kí n lè gbọ́, mi ò ní dá wọn lóhùn.”+