Ìsíkíẹ́lì
48 “Orúkọ àwọn ẹ̀yà náà nìyí, bẹ̀rẹ̀ láti ìkángun àríwá: ìpín Dánì+ wà lẹ́bàá ọ̀nà Hẹ́tílónì lọ dé Lebo-hámátì*+ dé Hasari-énánì, lẹ́bàá ààlà Damásíkù sí apá àríwá, lẹ́gbẹ̀ẹ́ Hámátì;+ ó bẹ̀rẹ̀ láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn títí dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn. 2 Ìpín Áṣérì+ bẹ̀rẹ̀ láti ààlà Dánì, láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn. 3 Ìpín Náfútálì+ bẹ̀rẹ̀ láti ààlà Áṣérì, láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn. 4 Ìpín Mánásè+ bẹ̀rẹ̀ láti ààlà Náfútálì, láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn. 5 Ìpín Éfúrémù bẹ̀rẹ̀ láti ààlà Mánásè,+ láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn. 6 Ìpín Rúbẹ́nì bẹ̀rẹ̀ láti ààlà Éfúrémù,+ láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn. 7 Ìpín Júdà bẹ̀rẹ̀ láti ààlà Rúbẹ́nì,+ láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn. 8 Bẹ̀rẹ̀ láti ààlà Júdà, láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn, kí fífẹ̀ ilẹ̀ tí ẹ ó yà sọ́tọ̀ láti fi ṣe ọrẹ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́,*+ kí gígùn rẹ̀ sì dọ́gba pẹ̀lú ilẹ̀ àwọn ẹ̀yà yòókù láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn. Àárín rẹ̀ ni ibi mímọ́ máa wà.
9 “Kí ilẹ̀ tí ẹ ó yà sọ́tọ̀ láti fi ṣe ọrẹ fún Jèhófà jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́. 10 Èyí ló máa jẹ́ ilẹ̀ mímọ́ tó jẹ́ ti àwọn àlùfáà.+ Yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní apá àríwá, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ní apá ìwọ̀ oòrùn, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ní apá ìlà oòrùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní apá gúúsù. Ibi mímọ́ Jèhófà yóò wà ní àárín rẹ̀. 11 Yóò jẹ́ ti àwọn àlùfáà tó jẹ́ ọmọ Sádókù+ tí wọ́n ti sọ di mímọ́, àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ tó yẹ kí wọ́n ṣe fún mi, tí wọn ò sì fi mí sílẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ọmọ Léfì fi mí sílẹ̀.+ 12 Wọn yóò ní ìpín lára ilẹ̀ tí wọ́n yà sọ́tọ̀ láti jẹ́ ohun mímọ́ jù lọ, ní ààlà àwọn ọmọ Léfì.
13 “Nítòsí ilẹ̀ àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì yóò ní ilẹ̀ kan tí gígùn rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́, tí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́. (Gbogbo rẹ̀ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25,000] ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, fífẹ̀ rẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] ìgbọ̀nwọ́.) 14 Wọn ò gbọ́dọ̀ ta èyíkéyìí lára ibi tó dáa jù nínú ilẹ̀ náà tàbí kí wọ́n fi ṣe pàṣípààrọ̀, wọn ò sì gbọ́dọ̀ fún ẹlòmíì torí ohun mímọ́ ló jẹ́ fún Jèhófà.
15 “Ibi tó ṣẹ́ kù jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀, lẹ́bàá ààlà tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́. Ó máa jẹ́ ti gbogbo ìlú,+ wọ́n á máa gbé ibẹ̀, ẹran wọn á sì máa jẹko níbẹ̀. Ìlú náà yóò wà ní àárín rẹ̀.+ 16 Ìwọ̀n ìlú náà nìyí: Ààlà tó wà ní àríwá jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (4,500) ìgbọ̀nwọ́, ti gúúsù jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (4,500) ìgbọ̀nwọ́, ti ìlà oòrùn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (4,500) ìgbọ̀nwọ́, ti ìwọ̀ oòrùn sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (4,500) ìgbọ̀nwọ́. 17 Ibi ìjẹko ìlú náà yóò jẹ́ igba ó lé àádọ́ta (250) ìgbọ̀nwọ́ sí apá àríwá, igba ó lé àádọ́ta (250) ìgbọ̀nwọ́ sí apá gúúsù, igba ó lé àádọ́ta (250) ìgbọ̀nwọ́ sí apá ìlà oòrùn àti igba ó lé àádọ́ta (250) ìgbọ̀nwọ́ sí apá ìwọ̀ oòrùn.
18 “Gígùn ilẹ̀ tó ṣẹ́ kù yóò dọ́gba pẹ̀lú ilẹ̀ mímọ́,+ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ sí apá ìlà oòrùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ sí apá ìwọ̀ oòrùn. Yóò dọ́gba pẹ̀lú ilẹ̀ mímọ́ náà, èso rẹ̀ ni àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ìlú náà yóò sì máa jẹ. 19 Àwọn tó wá láti gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ nínú ìlú náà yóò máa dá oko níbẹ̀.+
20 “Gbogbo ilẹ̀ tí wọ́n fi ṣe ọrẹ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Kí ẹ yà á sọ́tọ̀ láti jẹ́ ilẹ̀ mímọ́ pẹ̀lú ohun ìní ìlú náà.
21 “Ohun tó bá ṣẹ́ kù lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì ilẹ̀ mímọ́ náà àti ohun ìní ìlú náà yóò jẹ́ ti ìjòyè.+ Yóò wà lẹ́bàá àwọn ààlà tó wà ní apá ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ mímọ́ náà, tí gígùn wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́. Yóò dọ́gba pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ tí wọ́n jọ pààlà, yóò sì jẹ́ ti ìjòyè. Àárín rẹ̀ ni ilẹ̀ mímọ́ náà àti ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì náà yóò wà.
22 “Ohun ìní àwọn ọmọ Léfì àti ohun ìní ìlú náà yóò wà láàárín ohun tó jẹ́ ti ìjòyè. Ilẹ̀ ìjòyè náà yóò wà láàárín ààlà Júdà+ àti ààlà Bẹ́ńjámínì.
23 “Ní ti àwọn ẹ̀yà tó ṣẹ́ kù, láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn ni ìpín Bẹ́ńjámínì.+ 24 Ìpín Síméónì bẹ̀rẹ̀ láti ààlà Bẹ́ńjámínì,+ láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn. 25 Ìpín Ísákà+ bẹ̀rẹ̀ láti ààlà Síméónì, láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn. 26 Ìpín Sébúlúnì bẹ̀rẹ̀ láti ààlà Ísákà,+ láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn.+ 27 Ìpín Gádì bẹ̀rẹ̀ láti ààlà Sébúlúnì,+ láti ààlà tó wà ní ìlà oòrùn dé ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn. 28 Ààlà tó wà ní gúúsù lẹ́gbẹ̀ẹ́ ààlà Gádì, yóò jẹ́ láti Támárì+ dé omi Mẹriba-kádéṣì,+ dé Àfonífojì,*+ títí dé Òkun Ńlá.*
29 “Ilẹ̀ yìí ni ogún tí ẹ máa pín fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì,+ ìwọ̀nyí sì ni ìpín wọn,”+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
30 “Àwọn ibi tí wọ́n á máa gbà jáde nínú ìlú náà nìyí: Apá àríwá yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (4,500) ìgbọ̀nwọ́.+
31 “Orúkọ àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni wọ́n á máa pe àwọn ẹnubodè ìlú náà. Ẹnubodè mẹ́ta yóò wà ní àríwá, ọ̀kan jẹ́ ti Rúbẹ́nì, ọ̀kan jẹ́ ti Júdà, ọ̀kan sì jẹ́ ti Léfì.
32 “Apá ìlà oòrùn yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (4,500) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ẹnubodè mẹ́ta ló sì wà níbẹ̀: ọ̀kan jẹ́ ti Jósẹ́fù, ọ̀kan jẹ́ ti Bẹ́ńjámínì, ọ̀kan sì jẹ́ ti Dánì.
33 “Apá gúúsù yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (4,500) ìgbọ̀nwọ́, ẹnubodè mẹ́ta ló sì wà níbẹ̀: ọ̀kan jẹ́ ti Síméónì, ọ̀kan jẹ́ ti Ísákà, ọ̀kan sì jẹ́ ti Sébúlúnì.
34 “Apá ìwọ̀ oòrùn yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (4,500) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ẹnubodè mẹ́ta ló sì wà níbẹ̀: ọ̀kan jẹ́ ti Gádì, ọ̀kan jẹ́ ti Áṣérì, ọ̀kan sì jẹ́ ti Náfútálì.
35 “Ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) ìgbọ̀nwọ́ ni yóò jẹ́ yí ká. Láti ọjọ́ yẹn lọ, orúkọ ìlú náà yóò máa jẹ́ Jèhófà Wà Níbẹ̀.”+