Àwọn Ọba Kìíní
14 Ní àkókò yẹn, Ábíjà ọmọkùnrin Jèróbóámù ń ṣàìsàn. 2 Torí náà, Jèróbóámù sọ fún ìyàwó rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, dìde, yí ìmúra rẹ pa dà kí wọ́n má bàa mọ̀ pé ìyàwó Jèróbóámù ni ọ́, kí o sì lọ sí Ṣílò. Wò ó! Wòlíì Áhíjà wà níbẹ̀. Òun ni ó sọ nípa mi pé màá di ọba lórí àwọn èèyàn yìí.+ 3 Mú búrẹ́dì mẹ́wàá dání àti kéèkì tí a bu nǹkan wọ́n àti ṣágo* oyin, kí o sì lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó máa sọ ohun tí á ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà fún ọ.”
4 Ìyàwó Jèróbóámù ṣe ohun tí ọkọ rẹ̀ sọ. Ó dìde, ó lọ sí Ṣílò,+ ó sì wá sí ilé Áhíjà. Ojú Áhíjà là sílẹ̀, àmọ́ kò ríran mọ́ nítorí ọjọ́ orí rẹ̀.
5 Àmọ́ Jèhófà ti sọ fún Áhíjà pé: “Wò ó, ìyàwó Jèróbóámù ń bọ̀ wá wádìí nípa ọmọ rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ, torí pé ọmọ náà ń ṣàìsàn. Màá sọ fún ọ, ohun tí o máa sọ fún un.* Tí ó bá dé, kò ní jẹ́ kí o dá òun mọ̀.”
6 Bí Áhíjà ṣe gbọ́ ìró ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ó ń bọ̀ lẹ́nu ọ̀nà, ó sọ pé: “Wọlé, ìyàwó Jèróbóámù. Kí ló dé tí o fi ṣe bíi pé ẹlòmíràn ni ọ́? Iṣẹ́ tó lágbára kan wà tí Ọlọ́run ní kí n jẹ́ fún ọ. 7 Lọ sọ fún Jèróbóámù pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Mo gbé ọ dìde láti àárín àwọn èèyàn rẹ, kí n lè sọ ọ́ di aṣáájú àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.+ 8 Lẹ́yìn náà, mo fa ìjọba ya kúrò ní ilé Dáfídì, mo sì fún ọ.+ Àmọ́, o kò ṣe bí ìránṣẹ́ mi Dáfídì, ẹni tí ó pa àwọn àṣẹ mi mọ́, tí ó sì fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀ lé mi, tí ó ṣe kìkì ohun tí ó tọ́ lójú mi.+ 9 Ohun tí o ṣe burú ju ti gbogbo àwọn tó ṣáájú rẹ, o ṣe ọlọ́run míì fún ara rẹ àti àwọn ère onírin* láti mú mi bínú,+ o sì kẹ̀yìn sí mi.+ 10 Nítorí ohun tí o ṣe yìí, màá mú àjálù bá ilé Jèróbóámù, màá pa gbogbo ọkùnrin* ilé Jèróbóámù rẹ́,* títí kan àwọn aláìní àti àwọn aláìníláárí ní Ísírẹ́lì, màá sì gbá ilé Jèróbóámù+ dà nù, bí ìgbà tí èèyàn gbá ìgbẹ́ ẹran kúrò láìku nǹkan kan! 11 Èèyàn Jèróbóámù èyíkéyìí tí ó bá kú sí ìlú ni ajá yóò jẹ; èyí tí ó bá sì kú sí pápá ni àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run yóò jẹ, nítorí Jèhófà ti sọ ọ́.”’
12 “Ní báyìí, gbéra; máa lọ sí ilé rẹ. Bí o bá ṣe wọ ìlú náà, ọmọ náà máa kú. 13 Gbogbo Ísírẹ́lì á ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, wọ́n á sì sin ín, torí òun nìkan ni wọ́n máa sin sínú sàréè lára àwọn ará ilé Jèróbóámù, nítorí pé òun nìkan ni Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì rí ohun rere nínú rẹ̀ ní ilé Jèróbóámù. 14 Jèhófà yóò gbé ọba kan dìde fún ara rẹ̀ lórí Ísírẹ́lì, tí ó máa mú* ilé Jèróbóámù+ kúrò láti ọjọ́ náà lọ, kódà ó lè jẹ́ nísinsìnyí. 15 Jèhófà yóò kọ lu Ísírẹ́lì, á sì dà bí esùsú* tó ń mì lòólòó lójú omi, yóò fa Ísírẹ́lì tu kúrò lórí ilẹ̀ dáradára yìí tó fún àwọn baba ńlá wọn,+ yóò sì tú wọn ká kọjá Odò,*+ nítorí wọ́n ṣe àwọn òpó òrìṣà,*+ tí wọ́n sì ń mú Jèhófà bínú. 16 Yóò pa Ísírẹ́lì tì nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù dá àti èyí tó mú kí Ísírẹ́lì dá.”+
17 Ni ìyàwó Jèróbóámù bá dìde, ó bọ́ sọ́nà, ó sì dé Tírísà. Bí ó ṣe ń dé ibi àbáwọlé, ọmọ náà kú. 18 Torí náà, wọ́n sin ín, gbogbo Ísírẹ́lì sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gba ẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì Áhíjà sọ.
19 Ní ti ìyókù ìtàn Jèróbóámù, bí ó ṣe jagun+ àti bí ó ṣe ṣàkóso, wọ́n wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì. 20 Gbogbo ọdún* tí Jèróbóámù fi jọba jẹ́ ọdún méjìlélógún (22), lẹ́yìn náà, ó sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀;+ Nádábù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+
21 Ní àkókò yẹn, Rèhóbóámù ọmọ Sólómọ́nì ti di ọba ní Júdà. Ẹni ọdún mọ́kànlélógójì (41) ni Rèhóbóámù nígbà tó di ọba, ó sì fi ọdún mẹ́tàdínlógún (17) jọba ní Jerúsálẹ́mù, ìlú tí Jèhófà yàn+ nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti fi orúkọ rẹ̀ sí.+ Orúkọ ìyá Rèhóbóámù ni Náámà, ọmọ Ámónì+ sì ni. 22 Júdà ń ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà,+ wọ́n fi ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá mú un bínú ju bí àwọn baba ńlá wọn ṣe mú un bínú lọ.+ 23 Àwọn náà ń kọ́ ibi gíga àti àwọn ọwọ̀n òrìṣà pẹ̀lú àwọn òpó òrìṣà*+ fún ara wọn sórí gbogbo òkè+ àti sábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀.+ 24 Àwọn aṣẹ́wó ọkùnrin tó wà ní tẹ́ńpìlì tún wà ní ilẹ̀ náà.+ Ohun ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ni àwọn náà ń ṣe.
25 Ní ọdún karùn-ún Ọba Rèhóbóámù, Ṣíṣákì+ ọba Íjíbítì wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù.+ 26 Ó kó àwọn ìṣúra ilé Jèhófà àti ìṣúra ilé* ọba.+ Gbogbo nǹkan pátá ló kó, títí kan gbogbo apata wúrà tí Sólómọ́nì ṣe.+ 27 Nítorí náà, Ọba Rèhóbóámù ṣe àwọn apata bàbà láti fi rọ́pò wọn, ó sì fi wọ́n sí ìkáwọ́ àwọn olórí ẹ̀ṣọ́* tó ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé ọba. 28 Nígbàkigbà tí ọba bá wá sí ilé Jèhófà, àwọn ẹ̀ṣọ́ á gbé àwọn apata náà, lẹ́yìn náà, wọ́n á dá wọn pa dà sí yàrá ẹ̀ṣọ́.
29 Ní ti ìyókù ìtàn Rèhóbóámù, gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà?+ 30 Ìgbà gbogbo ni ogun ń wáyé láàárín Rèhóbóámù àti Jèróbóámù.+ 31 Níkẹyìn, Rèhóbóámù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ ní Ìlú Dáfídì.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Náámà, ọmọ Ámónì+ sì ni. Ábíjámù*+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.