Orin Dáfídì.
23 Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi.+
Èmi kì yóò ṣaláìní.+
2 Ó mú mi dùbúlẹ̀ ní ibi ìjẹko tútù;
Ó darí mi sí àwọn ibi ìsinmi tó lómi dáadáa.+
3 Ó tù mí lára.+
Ó darí mi ní ipa ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀.+
4 Bí mo tilẹ̀ ń rìn nínú àfonífojì tó ṣókùnkùn biribiri,+
Mi ò bẹ̀rù ewukéwu,+
Nítorí o wà pẹ̀lú mi;+
Ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá rẹ ń fi mí lọ́kàn balẹ̀.
5 O tẹ́ tábìlì fún mi níwájú àwọn ọ̀tá mi.+
O fi òróró pa orí mi;+
Ife mi kún dáadáa.+
6 Dájúdájú, ire àti ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn ní gbogbo ọjọ́ ayé mi,+
Èmi yóò sì máa gbé inú ilé Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé mi.+