Jẹ́nẹ́sísì
8 Àmọ́ Ọlọ́run yí àfiyèsí rẹ̀ sí* Nóà àti gbogbo ẹran inú igbó àti ẹran ọ̀sìn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú áàkì,+ Ọlọ́run sì mú kí atẹ́gùn fẹ́ sórí ayé, omi náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í fà. 2 Àwọn orísun omi àti àwọn ibodè omi ọ̀run tì pa, òjò ò sì rọ̀ mọ́* láti ọ̀run.+ 3 Omi náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í fà lórí ilẹ̀. Lẹ́yìn àádọ́jọ (150) ọjọ́, omi náà ti lọ sílẹ̀. 4 Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù keje, áàkì náà gúnlẹ̀ sórí àwọn òkè Árárátì. 5 Omi náà ń lọ sílẹ̀ ṣáá títí di oṣù kẹwàá. Ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹwàá, téńté àwọn òkè fara hàn.+
6 Lẹ́yìn ogójì (40) ọjọ́, Nóà ṣí fèrèsé*+ tó ṣe sí áàkì náà, 7 ó sì rán ẹyẹ ìwò kan jáde; ẹyẹ náà ń fò jáde, ó sì ń pa dà wá títí omi náà fi gbẹ lórí ilẹ̀.
8 Lẹ́yìn náà, ó rán àdàbà kan jáde kó lè mọ̀ bóyá omi náà ti fà lórí ilẹ̀. 9 Àdàbà náà ò rí ibi ìsinmi kankan tó lè bà lé,* torí náà, ó pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀ nínú áàkì torí omi ṣì bo gbogbo ayé.+ Ó wá na ọwọ́ rẹ̀, ó sì mú un wọlé sínú áàkì. 10 Ó dúró fún ọjọ́ méje, ó sì rán àdàbà náà jáde lẹ́ẹ̀kan sí i látinú áàkì. 11 Nígbà tí àdàbà náà wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, ó rí i pé ewé ólífì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ já wà ní ẹnu rẹ̀! Nóà wá mọ̀ pé omi náà ti lọ sílẹ̀.+ 12 Ó tún dúró fún ọjọ́ méje míì. Ó wá rán àdàbà náà jáde, àmọ́ kò pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́.
13 Ní ọjọ́ kìíní, oṣù kìíní, ọdún kọkànlélẹ́gbẹ̀ta (601),+ omi náà ti fà lórí ilẹ̀; Nóà ṣí ìbòrí áàkì náà, ó sì rí i pé ilẹ̀ ti ń gbẹ. 14 Ilẹ̀ náà wá gbẹ tán ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù kejì.
15 Ọlọ́run wá sọ fún Nóà pé: 16 “Jáde nínú áàkì, ìwọ, ìyàwó rẹ, àwọn ọmọ rẹ àti ìyàwó àwọn ọmọ rẹ.+ 17 Kó onírúurú ẹran ara+ tó jẹ́ ohun alààyè jáde pẹ̀lú rẹ, àwọn ẹ̀dá tó ń fò, àwọn ẹran àti gbogbo ẹran tó ń rákò lórí ilẹ̀, kí wọ́n lè máa pọ̀ sí i* ní ayé, kí wọ́n máa bímọ, kí wọ́n sì pọ̀ ní ayé.”+
18 Torí náà, Nóà jáde, òun àti àwọn ọmọ rẹ̀,+ ìyàwó rẹ̀ àti ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀. 19 Gbogbo ohun alààyè, gbogbo ẹran tó ń rákò, gbogbo ẹ̀dá tó ń fò àti gbogbo ohun tó ń rìn lórí ilẹ̀ jáde nínú áàkì náà lọ́wọ̀ọ̀wọ́.+ 20 Nóà sì mọ pẹpẹ+ kan fún Jèhófà, ó mú lára gbogbo ẹran tó mọ́ àti lára gbogbo ẹ̀dá tó ń fò+ tó sì mọ́, ó sì rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ náà.+ 21 Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ òórùn dídùn.* Jèhófà wá sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: “Mi ò tún ní fi ilẹ̀+ gégùn-ún* mọ́ torí èèyàn, torí pé kìkì ibi ni èèyàn ń rò lọ́kàn láti ìgbà èwe rẹ̀ wá;+ mi ò sì tún ní pa gbogbo ohun alààyè run mọ́, bí mo ti ṣe.+ 22 Láti ìsinsìnyí lọ, ìgbà ìfúnrúgbìn àti ìgbà ìkórè kò ní tán ní ayé, bẹ́ẹ̀ ni òtútù àti ooru, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù, ọ̀sán àti òru.”+