Ẹ́sírà
2 Àwọn yìí ni àwọn èèyàn ìpínlẹ̀,* tí wọ́n pa dà lára àwọn tó wà nígbèkùn,+ àwọn tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì kó lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì,+ àmọ́ tí wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù àti Júdà nígbà tó yá, kálukú pa dà sí ìlú rẹ̀,+ 2 àwọn tí wọ́n tẹ̀ lé ni Serubábélì,+ Jéṣúà,+ Nehemáyà, Seráyà, Reeláyà, Módékáì, Bílíṣánì, Mísípárì, Bígífáì, Réhúmù àti Báánà.
Iye àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì nìyí:+ 3 àwọn ọmọ Páróṣì jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé méjìléláàádọ́sàn-án (2,172); 4 àwọn ọmọ Ṣẹfatáyà jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé méjìléláàádọ́rin (372); 5 àwọn ọmọ Áráhì+ jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó lé márùndínlọ́gọ́rin (775); 6 àwọn ọmọ Pahati-móábù,+ látinú àwọn ọmọ Jéṣúà àti Jóábù jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti méjìlá (2,812); 7 àwọn ọmọ Élámù+ jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba àti mẹ́rìnléláàádọ́ta (1,254); 8 àwọn ọmọ Sátù+ jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé márùnlélógójì (945); 9 àwọn ọmọ Sákáì jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó lé ọgọ́ta (760); 10 àwọn ọmọ Bánì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé méjìlélógójì (642); 11 àwọn ọmọ Bébáì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mẹ́tàlélógún (623); 12 àwọn ọmọ Ásígádì jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba àti méjìlélógún (1,222); 13 àwọn ọmọ Ádóníkámù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti ọgọ́ta ó lé mẹ́fà (666); 14 àwọn ọmọ Bígífáì jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (2,056); 15 àwọn ọmọ Ádínì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mẹ́rìnléláàádọ́ta (454); 16 àwọn ọmọ Átérì láti ilé Hẹsikáyà jẹ́ méjìdínlọ́gọ́rùn-ún (98); 17 àwọn ọmọ Bísáì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé mẹ́tàlélógún (323); 18 àwọn ọmọ Jórà jẹ́ méjìléláàádọ́fà (112); 19 àwọn ọmọ Háṣúmù+ jẹ́ igba ó lé mẹ́tàlélógún (223); 20 àwọn ọmọ Gíbárì jẹ́ márùndínlọ́gọ́rùn-ún (95); 21 àwọn ọmọ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́fà (123); 22 àwọn ọkùnrin Nétófà jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (56); 23 àwọn ọkùnrin Ánátótì+ jẹ́ méjìdínláàádóje (128); 24 àwọn ọmọ Ásímáfẹ́tì jẹ́ méjìlélógójì (42); 25 àwọn ọmọ Kiriati-jéárímù, Kéfírà àti Béérótì jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó lé mẹ́tàlélógójì (743); 26 àwọn ọmọ Rámà+ àti Gébà+ jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mọ́kànlélógún (621); 27 àwọn ọkùnrin Míkímásì jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà (122); 28 àwọn ọkùnrin Bẹ́tẹ́lì àti Áì+ jẹ́ igba ó lé mẹ́tàlélógún (223); 29 àwọn ọmọ Nébò+ jẹ́ méjìléláàádọ́ta (52); 30 àwọn ọmọ Mágíbíṣì jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́jọ (156); 31 àwọn ọmọ Élámù kejì jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba àti mẹ́rìnléláàádọ́ta (1,254); 32 àwọn ọmọ Hárímù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ogún (320); 33 àwọn ọmọ Lódì, Hádídì àti Ónò jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (725); 34 àwọn ọmọ Jẹ́ríkò jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé márùnlélógójì (345); 35 àwọn ọmọ Sénáà jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti ọgbọ̀n (3,630).
36 Àwọn àlùfáà nìyí:+ àwọn ọmọ Jedáyà+ láti ilé Jéṣúà+ jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé mẹ́tàléláàádọ́rin (973); 37 àwọn ọmọ Ímérì+ jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé méjìléláàádọ́ta (1,052); 38 àwọn ọmọ Páṣúrì+ jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba àti mẹ́tàdínláàádọ́ta (1,247); 39 àwọn ọmọ Hárímù+ jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé mẹ́tàdínlógún (1,017).
40 Àwọn ọmọ Léfì nìyí:+ àwọn ọmọ Jéṣúà àti Kádímíélì,+ látinú àwọn ọmọ Hodafáyà jẹ́ mẹ́rìnléláàádọ́rin (74). 41 Àwọn akọrin nìyí:+ àwọn ọmọ Ásáfù,+ wọ́n jẹ́ méjìdínláàádóje (128). 42 Àwọn ọmọ àwọn aṣọ́bodè nìyí:+ àwọn ọmọ Ṣálúmù, àwọn ọmọ Átérì, àwọn ọmọ Tálímónì,+ àwọn ọmọ Ákúbù,+ àwọn ọmọ Hátítà, àwọn ọmọ Ṣóbáì, gbogbo wọn lápapọ̀ jẹ́ mọ́kàndínlógóje (139).
43 Àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì* nìyí:+ àwọn ọmọ Síhà, àwọn ọmọ Hásúfà, àwọn ọmọ Tábáótì, 44 àwọn ọmọ Kérósì, àwọn ọmọ Síáhà, àwọn ọmọ Pádónì, 45 àwọn ọmọ Lébánà, àwọn ọmọ Hágábà, àwọn ọmọ Ákúbù, 46 àwọn ọmọ Hágábù, àwọn ọmọ Sálímáì, àwọn ọmọ Hánánì, 47 àwọn ọmọ Gídélì, àwọn ọmọ Gáhárì, àwọn ọmọ Reáyà, 48 àwọn ọmọ Résínì, àwọn ọmọ Nékódà, àwọn ọmọ Gásámù, 49 àwọn ọmọ Úúsà, àwọn ọmọ Páséà, àwọn ọmọ Bésáì, 50 àwọn ọmọ Ásínà, àwọn ọmọ Méúnímù, àwọn ọmọ Néfúsímù, 51 àwọn ọmọ Bákíbúkì, àwọn ọmọ Hákúfà, àwọn ọmọ Háhúrì, 52 àwọn ọmọ Básílútù, àwọn ọmọ Méhídà, àwọn ọmọ Háṣà, 53 àwọn ọmọ Bákósì, àwọn ọmọ Sísérà, àwọn ọmọ Téémà, 54 àwọn ọmọ Nesáyà àti àwọn ọmọ Hátífà.
55 Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì nìyí: àwọn ọmọ Sótáì, àwọn ọmọ Sóférétì, àwọn ọmọ Pérúdà,+ 56 àwọn ọmọ Jálà, àwọn ọmọ Dákónì, àwọn ọmọ Gídélì, 57 àwọn ọmọ Ṣẹfatáyà, àwọn ọmọ Hátílì, àwọn ọmọ Pokereti-hásébáímù àti àwọn ọmọ Ámì.
58 Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì* àti ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé àádọ́rùn-ún àti méjì (392).
59 Àwọn tó lọ láti Tẹli-mélà, Tẹli-háṣà, Kérúbù, Ádónì àti Ímérì, àmọ́ tí wọn kò lè sọ agbo ilé bàbá wọn àti ibi tí wọ́n ti ṣẹ̀ wá láti fi hàn pé ọmọ Ísírẹ́lì ni wọ́n nìyí:+ 60 àwọn ọmọ Deláyà, àwọn ọmọ Tòbáyà àti àwọn ọmọ Nékódà, wọ́n jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé méjìléláàádọ́ta (652). 61 Àwọn tó wá látinú àwọn ọmọ àwọn àlùfáà nìyí: àwọn ọmọ Habáyà, àwọn ọmọ Hákósì,+ àwọn ọmọ Básíláì tó fẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Básíláì+ ọmọ Gílíádì, tó sì wá ń jẹ́ orúkọ wọn. 62 Wọ́n wá àkọsílẹ̀ wọn láti mọ ìdílé tí wọ́n ti wá, àmọ́ wọn kò rí i, torí náà, wọn ò gbà kí wọ́n ṣiṣẹ́ àlùfáà.*+ 63 Gómìnà* sọ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ lára àwọn ohun mímọ́ jù lọ,+ títí wọ́n á fi rí àlùfáà tó máa bá wọn fi Úrímù àti Túmímù wádìí.+
64 Iye gbogbo ìjọ náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógójì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti ọgọ́ta (42,360),+ 65 yàtọ̀ sí àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin wọn, tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti mẹ́tàdínlógójì (7,337); wọ́n tún ní àwọn akọrin lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n jẹ́ igba (200). 66 Ẹṣin wọn jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó lé mẹ́rìndínlógójì (736), ìbaaka wọn jẹ́ igba ó lé márùnlélógójì (245), 67 ràkúnmí wọn jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé márùndínlógójì (435), kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti ogún (6,720).
68 Nígbà tí wọ́n dé ilé Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù, lára àwọn olórí agbo ilé ṣe ọrẹ àtinúwá+ fún ilé Ọlọ́run tòótọ́, kí wọ́n lè tún un kọ́* sí àyè rẹ̀.+ 69 Ohun tí wọ́n kó wá sí ibi ìṣúra iṣẹ́ ilé náà gẹ́gẹ́ bí agbára wọn ṣe tó ni, ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélọ́gọ́ta (61,000) owó dírákímà* wúrà àti ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) mínà* fàdákà+ pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún (100) aṣọ fún àwọn àlùfáà. 70 Àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn kan lára àwọn èèyàn náà, àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́bodè pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì* bẹ̀rẹ̀ sí í gbé inú àwọn ìlú wọn, gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì yòókù* sì ń gbé inú àwọn ìlú wọn.+