Àkọsílẹ̀ Mátíù
15 Lẹ́yìn náà, àwọn Farisí àti àwọn akọ̀wé òfin+ wá sọ́dọ̀ Jésù láti Jerúsálẹ́mù, wọ́n sọ pé: 2 “Kí ló dé tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ ò tẹ̀ lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn èèyàn àtijọ́? Bí àpẹẹrẹ, wọn kì í wẹ* ọwọ́ wọn tí wọ́n bá fẹ́ jẹun.”+
3 Ó dá wọn lóhùn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń tẹ àṣẹ Ọlọ́run lójú torí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yín?+ 4 Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run sọ pé, ‘Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ’+ àti pé, ‘Kí ẹ pa ẹni tó bá sọ̀rọ̀ òdì sí* bàbá tàbí ìyá rẹ̀.’+ 5 Àmọ́ ẹ sọ pé, ‘Ẹnikẹ́ni tó bá sọ fún bàbá tàbí ìyá rẹ̀ pé: “Ẹ̀bùn tí mo yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run ni ohunkóhun tí mo ní tó lè ṣe yín láǹfààní,”+ 6 kò yẹ kó bọlá fún bàbá rẹ̀ rárá.’ Ẹ ti wá sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di èyí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nítorí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yín.+ 7 Ẹ̀yin alágàbàgebè, bí Àìsáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀ nípa yín ló rí gẹ́lẹ́, nígbà tó sọ pé:+ 8 ‘Àwọn èèyàn yìí ń fi ètè wọn bọlá fún mi, àmọ́ ọkàn wọn jìnnà gan-an sí mi. 9 Lásán ni wọ́n ń jọ́sìn mi, torí pé àṣẹ èèyàn ni ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni.’”+ 10 Ó wá pe àwọn èrò náà sún mọ́ tòsí, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ fetí sílẹ̀, kó sì yé yín:+ 11 Ohun tó ń wọ ẹnu èèyàn kọ́ ló ń sọ èèyàn di aláìmọ́, àmọ́ ohun tó ń ti ẹnu rẹ̀ jáde ló ń sọ ọ́ di aláìmọ́.”+
12 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ fún un pé: “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn Farisí kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí o sọ?”+ 13 Ó fèsì pé: “Gbogbo ohun tí Baba mi ọ̀run kò gbìn la máa fà tu. 14 Ẹ fi wọ́n sílẹ̀. Afọ́jú tó ń fini mọ̀nà ni wọ́n. Tí afọ́jú bá wá ń fi afọ́jú mọ̀nà, inú kòtò ni àwọn méjèèjì máa já sí.”+ 15 Pétérù sọ pé: “La àpèjúwe náà yé wa.” 16 Ló bá sọ pé: “Ṣé kò tíì yé ẹ̀yin náà ni?+ 17 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé ohunkóhun tó bá wọ ẹnu máa ń gba inú ikùn, tí a sì máa yà á jáde sínú kòtò ẹ̀gbin? 18 Àmọ́ ohunkóhun tó bá ń ti ẹnu jáde, inú ọkàn ló ti ń wá, àwọn nǹkan yẹn ló sì ń sọ èèyàn di aláìmọ́.+ 19 Bí àpẹẹrẹ, inú ọkàn ni àwọn èrò burúkú ti ń wá,+ irú bí: ìpànìyàn, àgbèrè, ìṣekúṣe,* olè jíjà, ìjẹ́rìí èké, ọ̀rọ̀ òdì. 20 Àwọn nǹkan yìí ló ń sọ èèyàn di aláìmọ́; àmọ́ èèyàn ò lè di aláìmọ́ tó bá jẹun láìwẹ* ọwọ́.”
21 Jésù kúrò níbẹ̀, ó lọ sí agbègbè Tírè àti Sídónì.+ 22 Wò ó! obìnrin ará Foníṣíà kan láti agbègbè yẹn wá, ó sì ń ké jáde pé: “Ṣàánú mi, Olúwa, Ọmọ Dáfídì. Ẹ̀mí èṣù ń yọ ọmọbìnrin mi lẹ́nu gidigidi.”+ 23 Àmọ́ kò dá a lóhùn rárá. Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ ọ́ pé: “Ní kó máa lọ, torí kò yéé ké tẹ̀ lé wa.” 24 Ó fèsì pé: “A kò rán mi sí ẹnikẹ́ni àfi àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tó sọ nù.”+ 25 Àmọ́ obìnrin náà wá tẹrí ba* fún un, ó sì ń sọ pé: “Olúwa, ràn mí lọ́wọ́!” 26 Ó fèsì pé: “Kò tọ́ ká mú búrẹ́dì àwọn ọmọ, ká sì jù ú sí àwọn ajá kéékèèké.” 27 Obìnrin náà sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, àmọ́ ká sòótọ́, àwọn ajá kéékèèké máa ń jẹ lára èérún tó ń já bọ́ látorí tábìlì àwọn ọ̀gá wọn.”+ 28 Jésù wá dá a lóhùn pé: “Ìwọ obìnrin yìí, ìgbàgbọ́ rẹ lágbára gan-an; kó ṣẹlẹ̀ sí ọ bí o ṣe fẹ́.” Ara ọmọbìnrin rẹ̀ sì yá láti wákàtí yẹn lọ.
29 Jésù kúrò níbẹ̀, ó wá lọ sí tòsí Òkun Gálílì,+ ó lọ sórí òkè, ó sì jókòó síbẹ̀. 30 Lẹ́yìn náà, èrò rẹpẹtẹ wá bá a, wọ́n mú àwọn èèyàn tó yarọ wá, àwọn aláàbọ̀ ara, afọ́jú, àwọn tí kò lè sọ̀rọ̀ àti ọ̀pọ̀ àwọn míì, wọ́n tẹ́ wọn síbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì wò wọ́n sàn.+ 31 Ẹnu ya àwọn èrò náà bí wọ́n ṣe rí i tí àwọn tí kò lè sọ̀rọ̀ ń sọ̀rọ̀, tí ara àwọn aláàbọ̀ ara ń yá, tí àwọn arọ ń rìn, tí àwọn afọ́jú sì ń ríran, wọ́n sì yin Ọlọ́run Ísírẹ́lì lógo.+
32 Àmọ́ Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó sì sọ pé: “Àánú àwọn èèyàn yìí ń ṣe mí,+ torí ọjọ́ kẹta nìyí tí wọ́n ti wà lọ́dọ̀ mi, tí wọn ò sì ní ohunkóhun tí wọ́n máa jẹ. Mi ò fẹ́ kí wọ́n lọ láìjẹun,* torí kí okun wọn má bàa tán lójú ọ̀nà.”+ 33 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ fún un pé: “Ibo la ti máa rí oúnjẹ tó máa tó bọ́ adúrú èrò yìí ní àdádó yìí?”+ 34 Jésù wá sọ fún wọn pé: “Búrẹ́dì mélòó lẹ ní?” Wọ́n sọ pé: “Méje àti ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀.” 35 Torí náà, lẹ́yìn tó sọ fún àwọn èrò náà pé kí wọ́n jókòó sílẹ̀,* 36 ó mú búrẹ́dì méje àti àwọn ẹja náà, lẹ́yìn tó sì dúpẹ́, ó bù ú, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì fún àwọn èrò náà.+ 37 Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó, ohun tó ṣẹ́ kù tí wọ́n kó jọ sì kún apẹ̀rẹ̀ ńlá* méje.+ 38 Ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) ọkùnrin làwọn tó jẹ pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé. 39 Níkẹyìn, lẹ́yìn tó ní kí àwọn èrò náà máa lọ, ó wọ ọkọ̀ ojú omi, ó sì wá sí agbègbè Mágádánì.+