Sáàmù
Sí olùdarí; kí a kọ ọ́ pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín. Másíkílì.* Ti Dáfídì.
2 Fiyè sí mi, kí o sì dá mi lóhùn.+
Àníyàn mi ò jẹ́ kí n ní ìsinmi,+
Ọkàn mi ò sì balẹ̀
3 Nítorí ohun tí ọ̀tá ń sọ
Àti bí ẹni burúkú ṣe ń dà mí láàmú.
Wọ́n ń rọ̀jò wàhálà lé mi lórí,
Wọ́n sì dì mí sínú torí pé wọ́n ń bínú mi.+
5 Ìbẹ̀rù àti ìwárìrì dé bá mi,
Gbogbo ara mi sì ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀.
6 Mò ń sọ pé: “Ká ní mo ní ìyẹ́ apá bí àdàbà ni!
Mi ò bá fò lọ, mi ò bá sì máa gbé lábẹ́ ààbò.
7 Wò ó! Màá lọ jìnnà réré.+
Màá lọ máa gbé inú aginjù.+ (Sélà)
8 Màá yára lọ sí ibi tó láàbò
Kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù líle àti kúrò lọ́wọ́ ìjì.”
10 Tọ̀sántòru ni wọ́n ń rìn kiri lórí ògiri rẹ̀;
Èrò ibi àti ìjàngbọ̀n ló wà nínú rẹ̀.+
11 Ìparun wà nínú rẹ̀;
Ìnilára àti ẹ̀tàn kì í kúrò ní ojúde rẹ̀.+
Kì í ṣe elénìní ló dìde sí mi;
Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, mi ò bá sá pa mọ́ fún un.
14 Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni wá tẹ́lẹ̀, a sì gbádùn ọ̀rẹ́ wa;
A máa ń bá ọ̀pọ̀ èèyàn rìn lọ sí ilé Ọlọ́run.
15 Kí ìparun dé bá wọn!+
Kí wọ́n wọnú Isà Òkú* láàyè;
Nítorí ìwà ibi wà láàárín wọn, ó sì ń gbé inú wọn.
16 Ní tèmi, màá ké pe Ọlọ́run,
Jèhófà yóò sì gbà mí sílẹ̀.+
18 Yóò gbà mí sílẹ̀* lọ́wọ́ àwọn tó ń bá mi jà, yóò sì jẹ́ kí n* ní àlàáfíà,
Nítorí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn ló ń gbéjà kò mí.+
Wọn ò ní yí pa dà,
Àwọn tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run.+
21 Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ jọ̀lọ̀ ju bọ́tà lọ,+
Àmọ́ ìjà ló wà lọ́kàn rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tuni lára ju òróró lọ,
Àmọ́ idà tí a fà yọ ni wọ́n.+
Kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú* láé.+
23 Àmọ́ ìwọ, Ọlọ́run, yóò rẹ̀ wọ́n wálẹ̀ sínú kòtò tó jìn jù lọ.+
Àwọn tó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, tí wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́tàn kò ní lo ààbọ̀ ọjọ́ ayé wọn.+
Àmọ́ ní tèmi, màá gbẹ́kẹ̀ lé ọ.