Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì
7 Nítorí náà, ẹ̀yin ẹni ọ̀wọ́n, nígbà tí a ti gba àwọn ìlérí yìí,+ ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ara àti ti ẹ̀mí,+ kí a jẹ́ mímọ́ pátápátá nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
2 Ẹ fàyè gbà wá nínú ọkàn yín.+ A kò ṣe àìtọ́ sí ẹnì kankan, a kò sọ ẹnì kankan dìbàjẹ́, a kò sì yan ẹnì kankan jẹ.+ 3 Mi ò sọ èyí láti dá yín lẹ́bi. Nítorí mo ti sọ ṣáájú pé ẹ wà lọ́kàn wa, bóyá a kú àbí a wà láàyè. 4 Mo lè bá yín sọ̀rọ̀ fàlàlà. Mò ń fi yín yangàn púpọ̀. Ara tù mí gan-an, kódà ayọ̀ mi kún nínú gbogbo ìpọ́njú wa.+
5 Ní tòótọ́, nígbà tí a dé Makedóníà,+ ara* ò tù wá rárá, ṣe ni wọ́n ń fìyà jẹ wá ní gbogbo ọ̀nà—ìjà wà lóde, ìbẹ̀rù wà nínú. 6 Àmọ́ Ọlọ́run tó ń tu àwọn tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá nínú,+ ti tù wá nínú bí Títù ṣe wà pẹ̀lú wa; 7 síbẹ̀, kì í ṣe bó ṣe wà pẹ̀lú wa nìkan, àmọ́ bó ṣe rí ìtùnú gbà nítorí yín, tó sọ fún wa pé ó ń wù yín láti rí mi, bí ẹ ṣe ń kẹ́dùn púpọ̀ àti bí ọ̀rọ̀ mi ṣe jẹ yín lọ́kàn;* torí náà, ṣe ni ayọ̀ mi pọ̀ sí i.
8 Nítorí ká ní mo tiẹ̀ fi lẹ́tà mi bà yín nínú jẹ́,+ mi ò kábàámọ̀ rẹ̀. Ká tiẹ̀ ní mo kọ́kọ́ kábàámọ̀ rẹ̀, (bí mo ṣe rí i pé lẹ́tà yẹn bà yín nínú jẹ́, bó tiẹ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀,) 9 ní báyìí, inú mi ń dùn, kì í kàn ṣe torí pé a bà yín nínú jẹ́, àmọ́ torí pé ìbànújẹ́ yìí mú kí ẹ ronú pìwà dà. A bà yín nínú jẹ́ ní ọ̀nà Ọlọ́run, kí ẹ má bàa fara pa nítorí wa. 10 Nítorí ìbànújẹ́ ní ọ̀nà Ọlọ́run ń múni ronú pìwà dà, ó sì ń yọrí sí ìgbàlà láìfi àbámọ̀ kún un;+ àmọ́ ìbànújẹ́ ti ayé ń mú ikú wá. 11 Ẹ wo bí ìbànújẹ́ tó bá yín ní ọ̀nà Ọlọ́run ṣe mú kí ẹ túbọ̀ máa fìtara ṣe nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni, ó mú kí ẹ wẹ ara yín mọ́, ó múnú bí yín sí àìtọ́ tó wáyé, ó mú kí ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, ó mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run wà lọ́kàn yín, ó mú kí ẹ nítara, ó sì mú kí ẹ ṣe àtúnṣe sí àìtọ́ náà!+ Ní gbogbo ọ̀nà, ẹ ti fi hàn pé ẹ jẹ́ mímọ́* nínú ọ̀ràn yìí. 12 Òótọ́ ni pé mo kọ̀wé sí yín, àmọ́ kì í ṣe torí ẹni tó ṣe àìtọ́ ni mo ṣe kọ ọ́+ tàbí torí ẹni tí wọ́n ṣe àìtọ́ sí, ṣùgbọ́n ó jẹ́ nítorí kó lè hàn kedere láàárín yín pé ẹ̀ ń fìtara ṣe nǹkan tí a sọ fún yín níwájú Ọlọ́run. 13 Ìdí nìyẹn tí a fi rí ìtùnú gbà.
Àmọ́ yàtọ̀ sí ìtùnú tí a rí gbà, ìdùnnú wa tún pọ̀ sí i lórí ayọ̀ tí Títù ní, nítorí gbogbo yín mára tu ẹ̀mí rẹ̀. 14 Mo ti fi yín yangàn lójú rẹ̀, ojú ò sì tì mí; bí gbogbo ohun tí a sọ fún yín ṣe jẹ́ òótọ́, bẹ́ẹ̀ ni bí a ṣe fi yín yangàn níwájú Títù ṣe jẹ́ òótọ́. 15 Bákan náà, ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó ní sí yín ń pọ̀ sí i bó ṣe ń rántí ìgbọràn gbogbo yín,+ bí ẹ ṣe gbà á pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì. 16 Inú mi dùn pé ní gbogbo ọ̀nà, mo lè fọkàn tán yín.*