Jóòbù
37 “Èyí mú kí ọkàn mi lù kìkì,
Ó sì ń fò sókè láti àyè rẹ̀.
2 Ẹ fara balẹ̀ tẹ́tí sí ohùn rẹ̀ tó ń kù rìrì,
Àti ààrá tó ń ti ẹnu rẹ̀ jáde.
3 Ó ń tú u jáde lábẹ́ gbogbo ọ̀run,
Ó sì ń rán mànàmáná+ rẹ̀ lọ dé àwọn ìkángun ayé.
4 Lẹ́yìn náà ni ìró tó ń bú ramúramù;
Ó ń fi ohùn tó ga lọ́lá sán ààrá,+
Kì í sì í dá a dúró tí wọ́n bá gbọ́ ohùn rẹ̀.
8 Àwọn ẹran igbó lọ sí ibùba wọn,
Wọn ò sì kúrò ní ibùgbé wọn.
11 Àní, ó fi ìrì sínú àwọsánmà* kó lè wúwo;
Ó fọ́n ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká+ sínú àwọsánmà;*
12 Wọ́n ń lọ yí ká sáwọn ibi tó ń darí wọn sí;
Wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tó bá pa láṣẹ+ fún wọn lórí ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.*
16 Ṣé o mọ bí àwọsánmà* ṣe ń léfòó?+
Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ẹni tí ìmọ̀ rẹ̀ pé nìyí.+
17 Kí ló dé tí aṣọ rẹ ń gbóná,
Nígbà tí afẹ́fẹ́ gúúsù mú kí ayé dúró jẹ́ẹ́?+
19 Sọ fún wa, ohun tí a máa sọ fún un;
A ò lè fèsì torí inú òkùnkùn la wà.
20 Ṣé ó yẹ ká sọ fún un pé mo fẹ́ sọ̀rọ̀ ni?
Àbí ẹnì kankan sọ̀rọ̀ tó yẹ ká lọ sọ fún un?+
21 Wọn ò lè rí ìmọ́lẹ̀* pàápàá,
Bó tiẹ̀ mọ́lẹ̀ yòò lójú ọ̀run,
Títí atẹ́gùn fi kọjá tó sì fẹ́ ìkùukùu* lọ.
22 Iyì tó ń tàn bíi wúrà jáde wá láti àríwá;
Ògo Ọlọ́run+ yẹ ní ohun tí à ń bẹ̀rù.
23 Ó kọjá agbára wa láti lóye Olódùmarè;+
Agbára rẹ̀ pọ̀ gan-an,+
Kì í ṣe ohun tó lòdì sí ìdájọ́ òdodo+ rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ tó pọ̀ gidigidi.+
24 Torí náà, ó yẹ kí àwọn èèyàn bẹ̀rù rẹ̀.+