Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì
10 Èmi fúnra mi, Pọ́ọ̀lù, fi ìwà tútù àti inú rere Kristi bẹ̀ yín,+ torí ẹ̀ ń fojú ẹni yẹpẹrẹ wò mí tí a bá ríra lójúkojú,+ àmọ́ ẹ̀ ń fojú ẹni tó le wò mí tí mi ò bá sí lọ́dọ̀ yín.+ 2 Mo bẹ̀bẹ̀ pé tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín, mi ò ní nílò láti fi ọwọ́ líle tí mo gbà pé ó yẹ mú àwọn tí wọ́n rò pé à ń rìn nípa ti ara. 3 Bí a tiẹ̀ ń rìn nípa ti ara, kì í ṣe ohun tí a jẹ́ nínú ara la fi ń jagun. 4 Nítorí àwọn ohun ìjà wa kì í ṣe ti ara,+ àmọ́ Ọlọ́run ti mú kí wọ́n lágbára+ láti borí àwọn nǹkan tó ti fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in. 5 Nítorí à ń borí àwọn ìrònú àti gbogbo ohun gíga tí kò bá ìmọ̀ Ọlọ́run mu,+ a sì ń mú gbogbo ìrònú lẹ́rú kí ó lè ṣègbọràn sí Kristi; 6 a ti múra tán láti fìyà jẹ ẹnikẹ́ni tó bá ṣàìgbọràn,+ ní gbàrà tí ẹ bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀.
7 Ẹ̀ ń wo àwọn nǹkan bí wọ́n ṣe rí lójú. Bí ẹnikẹ́ni bá dá ara rẹ̀ lójú pé òun jẹ́ ti Kristi, kí ó rántí òtítọ́ yìí pé: Bí òun ṣe jẹ́ ti Kristi, bẹ́ẹ̀ ni àwa náà ṣe jẹ́ ti Kristi. 8 Nítorí ká tiẹ̀ sọ pé mo yangàn díẹ̀ jù nípa àṣẹ tí Olúwa fún wa láti gbé yín ró, tí kì í ṣe láti fà yín lulẹ̀,+ ìtìjú ò ní bá mi. 9 Nítorí mi ò fẹ́ kó dà bíi pé mò ń fi àwọn lẹ́tà mi dẹ́rù bà yín. 10 Wọ́n ń sọ pé: “Àwọn lẹ́tà rẹ̀ le, wọ́n sì lágbára, àmọ́ tí òun fúnra rẹ̀ bá dé, bí ẹni tí kò lókun nínú ló rí, ọ̀rọ̀ kò sì dá lẹ́nu rẹ̀.” 11 Kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ gbà pé ohun tí a sọ* nínú àwọn lẹ́tà wa nígbà tí a kò sí lọ́dọ̀ yín náà la máa ṣe* nígbà tí a bá wà lọ́dọ̀ yín.+ 12 Nítorí a ò jẹ́ ka ara wa mọ́ àwọn tó ń dámọ̀ràn ara wọn, a ò sì fara wé wọn.+ Bí wọ́n ṣe ń gbé ara wọn yẹ̀ wò, tí wọ́n sì ń fi ara wọn wéra, fi hàn pé wọn kò ní òye.+
13 Síbẹ̀, a ò ní yangàn kọjá ààlà àwọn ìpínlẹ̀ tí a yàn fún wa, inú ààlà agbègbè tí Ọlọ́run pín* fún wa, tó sì mú kó lọ jìnnà, kódà dé ọ̀dọ̀ yín la máa wà.+ 14 Ní ti gidi, a ò kọjá àyè wa nígbà tí a wá sọ́dọ̀ yín, torí àwa la kọ́kọ́ mú ìhìn rere nípa Kristi dé ọ̀dọ̀ yín.+ 15 Kì í ṣe pé à ń yangàn kọjá ààlà àwọn ìpínlẹ̀ tí a yàn fún wa lórí iṣẹ́ ẹlòmíì, àmọ́ a retí pé, bí ìgbàgbọ́ yín ṣe ń lágbára sí i, ohun tí a ṣe náà á máa pọ̀ sí i láàárín ìpínlẹ̀ wa. Nígbà náà, a máa túbọ̀ pọ̀ sí i, 16 kí a lè kéde ìhìn rere fún àwọn ìlú tó wà ní ìkọjá ọ̀dọ̀ yín, kí a má bàa máa fi iṣẹ́ tí ẹlòmíì ti ṣe ní ìpínlẹ̀ rẹ̀ yangàn. 17 “Ṣùgbọ́n ẹni tó bá fẹ́ yangàn, kí ó máa fi Jèhófà* yangàn.”+ 18 Nítorí kì í ṣe ẹni tó ń dámọ̀ràn ara rẹ̀ ni a tẹ́wọ́ gbà,+ bí kò ṣe ẹni tí Jèhófà* dámọ̀ràn.+