Sí Fílémónì
1 Pọ́ọ̀lù, tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n+ nítorí Kristi Jésù, àti Tímótì+ arákùnrin wa, sí Fílémónì, ẹni ọ̀wọ́n tí a jọ ń ṣiṣẹ́, 2 àti sí Áfíà arábìnrin wa àti Ákípọ́sì+ tí a jọ jẹ́ ọmọ ogun àti sí ìjọ tó wà ní ilé rẹ:+
3 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà Ọlọ́run tó jẹ́ Baba wa àti ti Jésù Kristi Olúwa máa wà pẹ̀lú rẹ.
4 Mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi nígbà gbogbo tí mo bá rántí rẹ nínú àdúrà mi,+ 5 bí mo ṣe ń gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ rẹ àti ìfẹ́ tí o ní sí Jésù Olúwa àti sí gbogbo ẹni mímọ́. 6 Àdúrà mi ni pé kí ìgbàgbọ́ jẹ́ kí o mọ gbogbo ohun rere tí Kristi mú kí a ní. 7 Arákùnrin mi, nígbà tí mo gbọ́ nípa ìfẹ́ rẹ, inú mi dùn gan-an, ara sì tù mí torí pé o ti mú kí ara tu àwọn ẹni mímọ́.*
8 Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnu mi gbà á láti pàṣẹ fún ọ pé kí o ṣe ohun tó tọ́ torí bí mo ṣe jẹ́ sí Kristi, 9 mi ò ní ṣe bẹ́ẹ̀, màá rọ̀ ẹ́ torí ìfẹ́ tí o ní àti bí o ṣe mọ̀ pé àgbàlagbà ni mí tí mo sì tún wà lẹ́wọ̀n báyìí torí Kristi Jésù. 10 Mò ń bẹ̀ ọ́ nítorí Ónísímù+ ọmọ mi, tí mo di bàbá rẹ̀+ nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n.* 11 Kò wúlò fún ọ tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí, ó ti wúlò fún èmi àti ìwọ. 12 Ó ti di ẹni bí ọkàn mi,* mo sì ń rán an pa dà sọ́dọ̀ rẹ.
13 Nítorí ìwọ ò sí níbí, ó wù mí kó ṣì wà lọ́dọ̀ mi, kó lè máa ràn mí lọ́wọ́ lákòókò yìí tí mo wà lẹ́wọ̀n nítorí ìhìn rere.+ 14 Àmọ́ mi ò fẹ́ ṣe ohunkóhun láìjẹ́ pé o fọwọ́ sí i, kí ohun rere tí o fẹ́ ṣe lè ti ọkàn rẹ wá, kó má sì jẹ́ àfipáṣe.+ 15 Ó lè jẹ́ torí èyí ló fi sá kúrò fún ìgbà díẹ̀,* kó lè pa dà sọ́dọ̀ rẹ títí láé, 16 kì í ṣe bí ẹrú mọ́,+ àmọ́ bí ẹni tó ju ẹrú lọ, bí arákùnrin ọ̀wọ́n.+ Bó ṣe jẹ́ sí mi gan-an nìyẹn, kí n má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ bó ṣe jẹ́ sí ọ nípa tara àti nínú Olúwa. 17 Torí náà, tí o bá kà mí sí ọ̀rẹ́* rẹ, fi ìfẹ́ gbà á tọwọ́tẹsẹ̀ bí o ṣe máa gbà mí. 18 Yàtọ̀ síyẹn, tó bá ti ṣẹ̀ ọ́ lọ́nàkọnà tàbí tó jẹ ọ́ ní gbèsè ohunkóhun, kà á sí mi lọ́rùn. 19 Èmi Pọ́ọ̀lù ni mò ń fi ọwọ́ ara mi kọ̀wé yìí: Màá san án pa dà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ náà jẹ mí ní gbèsè ara rẹ. 20 Arákùnrin mi, mo fẹ́ kí o ṣe nǹkan yìí fún mi torí bí a ṣe jẹ́ nínú Olúwa. Jọ̀ọ́, jẹ́ kí ara tù mí* torí bí a ṣe jẹ́ sí Kristi.
21 Mò ń kọ̀wé sí ọ torí ó dá mi lójú pé o máa ṣe ohun tí mo sọ. Mo sì mọ̀ pé wàá ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá. 22 Bákan náà, mo tún fẹ́ kí o bá mi ṣètò ibi tí màá dé sí, torí mo ní ìrètí pé wọ́n á jẹ́ kí n pa dà sọ́dọ̀ yín,* lọ́lá àdúrà tí ẹ̀ ń gbà fún mi.+
23 Épáfírásì+ tí a jọ wà lẹ́wọ̀n torí Kristi Jésù ń kí ọ, 24 Máàkù, Àrísítákọ́sì,+ Démà+ àti Lúùkù+ tí gbogbo wa jọ ń ṣiṣẹ́ tún kí ọ.
25 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Kristi Olúwa máa wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí o fi hàn.