Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì
6 Bí a ṣe ń bá a ṣiṣẹ́,+ à ń rọ̀ yín pé kí ẹ má ṣe gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, kí ẹ sì pàdánù ohun tó wà fún.+ 2 Nítorí ó sọ pé: “Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, mo gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, ní ọjọ́ ìgbàlà, mo ràn ọ́ lọ́wọ́.”+ Wò ó! Ìsinsìnyí gan-an ni àkókò ìtẹ́wọ́gbà. Wò ó! Ìsinsìnyí ni ọjọ́ ìgbàlà.
3 A ò ṣe ohun tó lè fa ìkọ̀sẹ̀ lọ́nàkọnà, kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa má bàa ní àbùkù;+ 4 àmọ́ ní gbogbo ọ̀nà, à ń dámọ̀ràn ara wa bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run,+ nínú ọ̀pọ̀ ìfaradà, nínú ìpọ́njú, nínú àìní, nínú ìṣòro,+ 5 nínú lílù, nínú ẹ̀wọ̀n,+ nínú rúkèrúdò, nínú iṣẹ́ àṣekára, nínú àìsùn, nínú àìrí oúnjẹ jẹ;+ 6 nínú jíjẹ́ mímọ́, nínú ìmọ̀, nínú sùúrù,+ nínú inú rere,+ nínú ẹ̀mí mímọ́, nínú ìfẹ́ tí kò ní ẹ̀tàn,+ 7 nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́, nínú agbára Ọlọ́run;+ nípasẹ̀ àwọn ohun ìjà òdodo+ lọ́wọ́ ọ̀tún* àti lọ́wọ́ òsì,* 8 nínú ògo àti àbùkù, nínú ìròyìn burúkú àti ìròyìn rere. Wọ́n kà wá sí ẹlẹ́tàn, síbẹ̀ a jẹ́ olóòótọ́, 9 bí ẹni tí a kò mọ̀, síbẹ̀ a dá wa mọ̀, bí ẹni tó ń kú lọ,* síbẹ̀, wò ó! a wà láàyè,+ bí ẹni tí wọ́n fìyà jẹ,* síbẹ̀ a kò fà wá lé ikú lọ́wọ́,+ 10 bí ẹni tó ń kárí sọ àmọ́ à ń yọ̀ nígbà gbogbo, bí aláìní àmọ́ à ń sọ ọ̀pọ̀ di ọlọ́rọ̀, bí ẹni tí kò ní nǹkan kan, síbẹ̀ a ní ohun gbogbo.+
11 A ti la ẹnu wa láti bá yín sọ̀rọ̀,* ẹ̀yin ará Kọ́ríńtì, a sì ti ṣí ọkàn wa sílẹ̀ pátápátá. 12 Ìfẹ́ tí a ní sí yín kò ní ààlà,*+ àmọ́ ẹ ti pààlà sí ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí ẹ ní sí wa. 13 Torí náà, mò ń bá yín sọ̀rọ̀ bí ẹni ń bá àwọn ọmọ mi sọ̀rọ̀, ẹ̀yin náà, ẹ ṣí ọkàn yín sílẹ̀ pátápátá.*+
14 Ẹ má fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú* àwọn aláìgbàgbọ́.+ Nítorí àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà tí kò bófin mu ní?+ Tàbí kí ló pa ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn pọ̀?+ 15 Bákan náà, ìṣọ̀kan wo ló wà láàárín Kristi àti Bélíálì?*+ Àbí kí ló pa onígbàgbọ́* àti aláìgbàgbọ́ pọ̀?+ 16 Kí ló pa òrìṣà pọ̀ mọ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run?+ Nítorí àwa jẹ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run alààyè;+ bí Ọlọ́run ṣe sọ pé: “Èmi yóò máa gbé láàárín wọn,+ èmi yóò sì máa rìn láàárín wọn, èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì di èèyàn mi.”+ 17 “‘Nítorí náà, ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jèhófà* wí, ‘ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ mọ́’”;+ “‘màá sì gbà yín wọlé.’”+ 18 “‘Màá di bàbá yín,+ ẹ ó sì di ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mi,’+ ni Jèhófà,* Olódùmarè wí.”