Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì
9 Ṣé mi ò lómìnira ni? Ṣé èmi kì í ṣe àpọ́sítélì ni? Ṣé mi ò rí Jésù Olúwa wa rí ni?+ Ṣé ẹ kì í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ mi nínú Olúwa ni? 2 Ká tiẹ̀ ní mi ò jẹ́ àpọ́sítélì fún àwọn ẹlòmíì, ó dájú hán-ún pé mo jẹ́ bẹ́ẹ̀ fún yín! Nítorí ẹ̀yin ni èdìdì tó jẹ́rìí sí i pé mo jẹ́ àpọ́sítélì nínú Olúwa.
3 Ohun tí mo fi gbèjà ara mi lọ́dọ̀ àwọn tó ń wádìí mi wò nìyí: 4 A ní ẹ̀tọ́* láti jẹ àti láti mu, àbí a kò ní? 5 A ní ẹ̀tọ́ láti máa mú ìyàwó tó jẹ́ onígbàgbọ́*+ lẹ́yìn bíi ti àwọn àpọ́sítélì yòókù àti àwọn arákùnrin Olúwa + àti Kéfà,*+ àbí a kò ní? 6 Àbí ṣé èmi àti Bánábà+ nìkan ni kò ní ẹ̀tọ́ láti fi iṣẹ́ tí a fi ń gbọ́ bùkátà sílẹ̀ ni? 7 Ọmọ ogun wo ló ń ná owó ara rẹ̀ sórí iṣẹ́ tó ń ṣe? Ta ló ń gbin ọgbà àjàrà tí kì í jẹ èso rẹ̀?+ Àbí ta ló ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran tí kì í jẹ lára wàrà agbo ẹran náà?
8 Ṣé èrò èèyàn ló mú kí n sọ àwọn nǹkan tí mò ń sọ ni? Ṣé Òfin kò sọ bákan náà ni? 9 Torí ó wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin Mósè pé: “O ò gbọ́dọ̀ di ẹnu akọ màlúù nígbà tó bá ń pa ọkà.”+ Ṣé ti àwọn akọ màlúù ni Ọlọ́run ń rò ni? 10 Àbí torí wa ló ṣe sọ ọ́? Nítorí tiwa ló ṣe wà lákọsílẹ̀, torí ó yẹ kí ẹni tó ń túlẹ̀ àti ẹni tó ń pa ọkà máa retí pé wọ́n á pín nínú rẹ̀.
11 Tí a bá fúnrúgbìn nǹkan tẹ̀mí láàárín yín, ṣé ó pọ̀ jù ni tí a bá kórè nǹkan tara lọ́dọ̀ yín?+ 12 Tí àwọn míì bá ní ẹ̀tọ́ yìí lórí yín, ṣé èyí táwa ní kò ju tiwọn lọ fíìfíì ni? Síbẹ̀, a ò lo ẹ̀tọ́*+ yìí, àmọ́ à ń fara da ohun gbogbo ká má bàa dènà ìhìn rere nípa Kristi lọ́nàkọnà.+ 13 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé àwọn ọkùnrin tó ń ṣe iṣẹ́ mímọ́ máa ń jẹ àwọn nǹkan tẹ́ńpìlì àti pé àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nídìí pẹpẹ máa ń gba ìpín nídìí pẹpẹ?+ 14 Lọ́nà yìí pẹ̀lú, Olúwa pàṣẹ pé kí àwọn tó ń kéde ìhìn rere máa jẹ nípasẹ̀ ìhìn rere.+
15 Àmọ́ mi ò tíì lo ìkankan nínú àwọn ìpèsè yìí.+ Ní tòótọ́, mi ò ṣe àkọsílẹ̀ àwọn nǹkan yìí torí kí a lè ṣe wọ́n fún mi, torí ó sàn kí n kú ju kí n jẹ́ kí ẹnì kan gba ẹ̀tọ́ tí mo ní láti ṣògo!+ 16 Ní báyìí, tí mo bá ń kéde ìhìn rere, kì í ṣe ohun tí mo lè màá fi ṣògo, nítorí dandan ni fún mi. Ní tòótọ́, mo gbé tí mi ò bá kéde ìhìn rere! + 17 Tí mo bá ń ṣe é tinútinú, èrè wà fún mi; síbẹ̀ tí kò bá ti inú mi wá, iṣẹ́ ìríjú kan ṣì wà ní ìkáwọ́ mi.+ 18 Kí wá ni èrè mi? Òun ni pé nígbà tí mo bá ń kéde ìhìn rere, kí n lè máa kéde rẹ̀ láìgba owó, kí n má bàa ṣi àṣẹ* tí mo ní lórí ìhìn rere lò.
19 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò sí lábẹ́ ẹnì kankan, mo fi ara mi ṣe ẹrú gbogbo èèyàn, kí n lè jèrè ọ̀pọ̀ èèyàn tí mo bá lè jèrè. 20 Nítorí àwọn Júù, mo dà bíi Júù, kí n lè jèrè àwọn Júù;+ nítorí àwọn tó wà lábẹ́ òfin, mo dà bí ẹni tó wà lábẹ́ òfin, bó tiẹ̀ jẹ́ pé èmi fúnra mi ò sí lábẹ́ òfin, kí n lè jèrè àwọn tó wà lábẹ́ òfin.+ 21 Nítorí àwọn tó wà láìní òfin mo dà bí aláìní òfin, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò wà láìní òfin sí Ọlọ́run, àmọ́ mo wà lábẹ́ òfin sí Kristi,+ kí n lè jèrè àwọn tó wà láìní òfin. 22 Nítorí àwọn aláìlera, mo di aláìlera, kí n lè jèrè àwọn aláìlera.+ Mo ti di ohun gbogbo nítorí gbogbo èèyàn, kí n lè gba àwọn kan là ní gbogbo ọ̀nà tí mo bá lè gbé e gbà. 23 Torí náà, mò ń ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere, kí n lè sọ ọ́ fún àwọn ẹlòmíì.+
24 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé nínú gbogbo àwọn tó ń sá eré ìje, ẹnì kan ló máa gba ẹ̀bùn ni? Ẹ sáré lọ́nà tí ẹ fi lè gbà á.+ 25 Gbogbo àwọn tó ń kópa nínú ìdíje* ló máa ń kíyè sára nínú ohun gbogbo. Lóòótọ́, wọ́n ń ṣe é kí wọ́n lè gba adé tó lè bà jẹ́,+ àmọ́ àwa ń ṣe bẹ́ẹ̀ ká lè gba èyí tí kò lè bà jẹ́.+ 26 Nítorí náà, mi ò sáré láìnídìí,+ mi ò sì ju ẹ̀ṣẹ́ mi kí n lè máa gbá afẹ́fẹ́; 27 àmọ́ mò ń lu ara mi kíkankíkan,*+ mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú, kó lè jẹ́ pé, lẹ́yìn tí mo bá ti wàásù fún àwọn ẹlòmíì, kí èmi fúnra mi má bàa di ẹni tí a kò tẹ́wọ́ gbà* lọ́nà kan ṣáá.