Dáníẹ́lì
6 Ó dáa lójú Dáríúsì kó fi ọgọ́fà (120) baálẹ̀ jẹ lórí gbogbo ìjọba náà.+ 2 Ó fi ìjòyè mẹ́ta ṣe olórí wọn, Dáníẹ́lì+ jẹ́ ọ̀kan lára wọn; àwọn baálẹ̀+ náà á máa jábọ̀ fún wọn, kí ọba má bàa pàdánù ohunkóhun. 3 Dáníẹ́lì sì ń fi hàn pé òun yàtọ̀ sí àwọn ìjòyè yòókù àtàwọn baálẹ̀, torí ẹ̀mí tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wà nínú rẹ̀,+ ọba sì ń gbèrò láti gbé e ga lórí gbogbo ìjọba náà.
4 Ìgbà yẹn ni àwọn ìjòyè àtàwọn baálẹ̀ ń wá ọ̀nà láti fẹ̀sùn kan Dáníẹ́lì lórí ọ̀rọ̀ ìjọba,* àmọ́ wọn ò rí ohunkóhun tó lè mú kí wọ́n fẹ̀sùn kàn án, wọn ò sì rí ìwà ìbàjẹ́ kankan, torí ó ṣeé fọkàn tán, kì í fiṣẹ́ ṣeré, kò sì hùwà ìbàjẹ́ rárá. 5 Àwọn ọkùnrin yìí wá sọ pé: “A ò lè rí ohunkóhun tí a máa fi fẹ̀sùn kan Dáníẹ́lì yìí, àfi tí a bá fi òfin Ọlọ́run rẹ̀ mú un.”+
6 Àwọn ìjòyè àtàwọn baálẹ̀ yìí wá jọ lọ sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ọba Dáríúsì, kí ẹ̀mí rẹ gùn títí láé. 7 Gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ọba, àwọn aṣíwájú, àwọn baálẹ̀, àwọn olóyè jàǹkàn-jàǹkàn àti àwọn gómìnà ti gbìmọ̀ pọ̀ láti fi àṣẹ kan lélẹ̀ látọ̀dọ̀ ọba, kí wọ́n sì kà á léèwọ̀* pé, láàárín ọgbọ̀n (30) ọjọ́, ẹnikẹ́ni tó bá béèrè nǹkan lọ́wọ́ ọlọ́run tàbí èèyàn èyíkéyìí yàtọ̀ sí ìwọ ọba, ká ju onítọ̀hún sínú ihò kìnnìún.+ 8 Ní báyìí, ọba, gbé àṣẹ náà kalẹ̀, kí o sì fọwọ́ sí i,+ kó má ṣeé yí pa dà, gẹ́gẹ́ bí òfin àwọn ará Mídíà àti Páṣíà, tí kò ṣeé fagi lé.”+
9 Torí náà, Ọba Dáríúsì fọwọ́ sí àṣẹ náà àti ìfòfindè náà.
10 Àmọ́, gbàrà tí Dáníẹ́lì gbọ́ pé wọ́n ti fọwọ́ sí àṣẹ náà, ó lọ sínú ilé rẹ̀, èyí tí yàrá orí òrùlé rẹ̀ ní fèrèsé* tó ṣí sílẹ̀, tó kọjú sí ọ̀nà Jerúsálẹ́mù.+ Ẹ̀ẹ̀mẹta lójúmọ́ ló máa ń kúnlẹ̀ láti gbàdúrà, tó sì ń yin Ọlọ́run rẹ̀, bó ṣe máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà ṣáájú àkókò yìí. 11 Ìgbà yẹn ni àwọn ọkùnrin náà já wọlé, wọ́n sì rí i tí Dáníẹ́lì ń béèrè nǹkan lọ́wọ́ Ọlọ́run rẹ̀, tó sì ń bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣojúure sí òun.
12 Wọ́n wá lọ bá ọba, wọ́n sì rán ọba létí òfin tó ṣe, wọ́n ní: “Ṣebí o fọwọ́ sí òfin tó sọ pé, ẹnikẹ́ni tó bá béèrè nǹkan lọ́wọ́ ọlọ́run tàbí èèyàn èyíkéyìí yàtọ̀ sí ìwọ ọba láàárín ọgbọ̀n (30) ọjọ́, ńṣe ni ká ju onítọ̀hún sínú ihò kìnnìún?” Ọba fèsì pé: “Òfin náà ò yí pa dà, gẹ́gẹ́ bí òfin àwọn ará Mídíà àti Páṣíà, tí kò ṣeé fagi lé.”+ 13 Wọ́n sọ fún ọba lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé: “Dáníẹ́lì, ọ̀kan lára àwọn ìgbèkùn Júdà,+ kò ka ìwọ ọba sí, kò sì ka òfin tí o fọwọ́ sí sí, àmọ́ ẹ̀ẹ̀mẹta lójúmọ́ ló ń gbàdúrà.”+ 14 Gbàrà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ìdààmú bá a gidigidi, ó wá ń ro bí òun ṣe lè gba Dáníẹ́lì sílẹ̀; títí ilẹ̀ fi ṣú, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti gbà á sílẹ̀. 15 Níkẹyìn, àwọn ọkùnrin yẹn jọ lọ sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì sọ fún ọba pé: “Ọba, rántí pé òfin àwọn ará Mídíà àti Páṣíà ni pé ìfòfindè tàbí àṣẹ èyíkéyìí tí ọba bá gbé kalẹ̀ kò ṣeé yí pa dà.”+
16 Torí náà, ọba pàṣẹ, wọ́n wá mú Dáníẹ́lì wá, wọ́n sì jù ú sínú ihò kìnnìún.+ Ọba sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Ọlọ́run rẹ tí ò ń fi ìgbà gbogbo sìn máa gbà ọ́ sílẹ̀.” 17 Wọ́n wá gbé òkúta kan wá, wọ́n sì fi dí ẹnu ihò náà, ọba sì fi òrùka àṣẹ rẹ̀ àti òrùka àṣẹ àwọn èèyàn rẹ̀ pàtàkì gbé èdìdì lé e, kí wọ́n má bàa yí ohunkóhun pa dà lórí ọ̀rọ̀ Dáníẹ́lì.
18 Ọba lọ sí ààfin rẹ̀. Ó gbààwẹ̀ mọ́jú, kò gbà kí wọ́n dá òun lára yá,* kò sì rí oorun sùn.* 19 Níkẹyìn, gbàrà tí ilẹ̀ mọ́, ọba dìde, ó sì yára lọ síbi ihò kìnnìún náà. 20 Bó ṣe ń sún mọ́ ihò náà, ó fi ohùn ìbànújẹ́ ké pe Dáníẹ́lì. Ọba bi Dáníẹ́lì pé: “Dáníẹ́lì, ìránṣẹ́ Ọlọ́run alààyè, ṣé Ọlọ́run rẹ tí ò ń fi ìgbà gbogbo sìn gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn kìnnìún?” 21 Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Dáníẹ́lì sọ fún ọba pé: “Ìwọ ọba, kí ẹ̀mí rẹ gùn títí láé. 22 Ọlọ́run mi rán áńgẹ́lì rẹ̀, ó sì dí àwọn kìnnìún náà lẹ́nu,+ wọn ò sì ṣe mí léṣe,+ torí ó rí i pé mi ò mọwọ́ mẹsẹ̀; mi ò sì ṣe ohun burúkú kankan sí ìwọ ọba.”
23 Inú ọba dùn gan-an, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n gbé Dáníẹ́lì jáde kúrò nínú ihò náà. Nígbà tí wọ́n gbé Dáníẹ́lì jáde kúrò nínú ihò náà, kò fara pa rárá, torí pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run rẹ̀.+
24 Ọba wá pàṣẹ, wọ́n mú àwọn ọkùnrin tó fẹ̀sùn* kan Dáníẹ́lì wá, wọ́n sì jù wọ́n sínú ihò kìnnìún, pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn àtàwọn ìyàwó wọn. Àmọ́, wọn ò tíì dé ìsàlẹ̀ ihò náà tí àwọn kìnnìún náà fi bò wọ́n, wọ́n sì fọ́ gbogbo egungun wọn túútúú.+
25 Ọba Dáríúsì wá kọ̀wé sí gbogbo èèyàn, orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà tó ń gbé ní gbogbo ayé pé:+ “Kí àlàáfíà yín pọ̀ gidigidi! 26 Mo pàṣẹ pé ní gbogbo ibi tí mo ti ń ṣàkóso, kí àwọn èèyàn máa bẹ̀rù Ọlọ́run Dáníẹ́lì gidigidi.+ Torí òun ni Ọlọ́run alààyè, ó sì máa wà títí láé. Ìjọba rẹ̀ ò ní pa run láé, àkóso* rẹ̀ sì máa wà títí ayérayé.+ 27 Ó ń gbani sílẹ̀,+ ó ń gbani là, ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ní ọ̀run àti ní ayé,+ torí ó gba Dáníẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́* àwọn kìnnìún.”
28 Nǹkan wá túbọ̀ dáa fún Dáníẹ́lì yìí nínú ìjọba Dáríúsì+ àti nínú ìjọba Kírúsì ará Páṣíà.+