Jóṣúà
15 Ilẹ̀ tí wọ́n pín+ fún ẹ̀yà Júdà ní ìdílé-ìdílé lọ dé ààlà Édómù,+ aginjù Síínì, dé ìpẹ̀kun Négébù lápá gúúsù. 2 Ààlà wọn lápá gúúsù bẹ̀rẹ̀ láti ìkángun Òkun Iyọ̀,*+ láti ibi tí omi ti ya wọ ilẹ̀, tó dojú kọ gúúsù. 3 Ó sì lọ sápá gúúsù dé ibi tí wọ́n ń gbà gòkè ní Ákírábímù,+ ó dé Síínì, ó gba gúúsù lọ sí Kadeṣi-báníà,+ ó dé Hésírónì, lọ dé Ádáárì, ó sì yí gba ọ̀nà Káríkà. 4 Ó tún lọ dé Ásímónì,+ títí dé Àfonífojì Íjíbítì,+ ààlà náà sì parí sí Òkun.* Èyí ni ààlà wọn lápá gúúsù.
5 Ààlà wọn lápá ìlà oòrùn jẹ́ Òkun Iyọ̀* títí dé ìpẹ̀kun Jọ́dánì, ààlà náà ní igun apá àríwá jẹ́ ibi tí òkun ti ya wọ ilẹ̀, ní ìpẹ̀kun Jọ́dánì.+ 6 Ààlà náà lọ dé Bẹti-hógílà,+ ó sì kọjá lọ lápá àríwá Bẹti-árábà,+ ààlà náà sì dé ibi òkúta Bóhánì+ ọmọ Rúbẹ́nì. 7 Ààlà náà tún dé Débírì ní Àfonífojì* Ákórì,+ ó sì yí gba apá àríwá lọ sí Gílígálì,+ tó wà níwájú ibi tí wọ́n ń gbà gòkè ní Ádúmímù, ní gúúsù àfonífojì, ààlà náà dé ibi omi Ẹ́ń-ṣímẹ́ṣì,+ ó sì parí sí Ẹ́ń-rógélì.+ 8 Ààlà náà dé Àfonífojì Ọmọ Hínómù,+ ó dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn ará Jébúsì+ ní gúúsù, ìyẹn Jerúsálẹ́mù,+ ààlà náà dé orí òkè tó dojú kọ Àfonífojì Hínómù lápá ìwọ̀ oòrùn, èyí tó wà ní ìkángun Àfonífojì* Réfáímù lápá àríwá. 9 Wọ́n pààlà náà látorí òkè dé ibi ìsun omi Néfítóà,+ ó sì lọ dé àwọn ìlú Òkè Éfúrónì; wọ́n tún pààlà dé Báálà, ìyẹn Kiriati-jéárímù.+ 10 Ààlà náà yí láti Báálà gba apá ìwọ̀ oòrùn lọ sí Òkè Séírì, ó kọjá lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Òkè Jéárímù ní àríwá, ìyẹn Kẹ́sálónì, ó lọ sí Bẹti-ṣémẹ́ṣì,+ ó sì dé Tímúnà.+ 11 Ààlà náà tún lọ dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Ẹ́kírónì+ lápá àríwá, wọ́n sì pààlà náà dé Ṣíkẹ́rónì, ó kọjá lọ sí Òkè Báálà, ó dé Jábínéélì, ààlà náà sì parí sí òkun.
12 Ààlà náà lápá ìwọ̀ oòrùn ni Òkun Ńlá*+ àti èbúté rẹ̀. Èyí ni ààlà àwọn àtọmọdọ́mọ Júdà ní ìdílé-ìdílé yí ká.
13 Ó fún Kélẹ́bù+ ọmọ Jéfúnè, ní ìpín láàárín àwọn àtọmọdọ́mọ Júdà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Jóṣúà, ìpín náà ni Kiriati-ábà, (Ábà ni bàbá Ánákì), ìyẹn Hébúrónì.+ 14 Kélẹ́bù lé àwọn ọmọ Ánákì+ mẹ́ta kúrò níbẹ̀, ìyẹn: Ṣéṣáì, Áhímánì àti Tálímáì,+ àwọn àtọmọdọ́mọ Ánákì. 15 Ó sì gòkè látibẹ̀ lọ bá àwọn tó ń gbé Débírì+ jà. (Kiriati-séférì ni Débírì ń jẹ́ tẹ́lẹ̀.) 16 Kélẹ́bù sọ pé: “Ẹni tó bá pa Kiriati-séférì run, tó sì gbà á, màá fún un ní Ákúsà ọmọ mi pé kó fi ṣe aya.” 17 Ótíníẹ́lì+ ọmọ Kénásì,+ arákùnrin Kélẹ́bù sì gbà á. Torí náà, ó fún un ní Ákúsà+ ọmọ rẹ̀ pé kó fi ṣe aya. 18 Nígbà tí ọmọbìnrin náà ń lọ sílé, ó rọ ọmọkùnrin náà pé kó tọrọ ilẹ̀ lọ́wọ́ bàbá òun. Ọmọbìnrin náà wá sọ̀ kalẹ̀ látorí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀.* Kélẹ́bù sì bi í pé: “Kí lo fẹ́?”+ 19 Ó sọ pé: “Jọ̀ọ́, bù kún mi, o ti fún mi ní ilẹ̀ kan ní gúúsù;* tún fún mi ní Guloti-máímù.”* Torí náà, ó fún un ní Gúlótì Òkè àti Gúlótì Ìsàlẹ̀.
20 Èyí ni ogún ẹ̀yà Júdà ní ìdílé-ìdílé.
21 Àwọn ìlú tó wà ní ìkángun ẹ̀yà Júdà lápá ibi tí ààlà Édómù+ wà ní gúúsù nìyí: Kábúséélì, Édérì, Jágúrì, 22 Kínà, Dímónà, Ádádà, 23 Kédéṣì, Hásórì, Ítínánì, 24 Sífù, Télémù, Béálótì, 25 Hasori-hádátà àti Kerioti-hésírónì, ìyẹn Hásórì, 26 Ámámù, Ṣímà, Móládà,+ 27 Hasari-gádà, Hẹ́ṣímónì, Bẹti-pélétì,+ 28 Hasari-ṣúálì, Bíá-ṣébà,+ Bisiotáyà, 29 Báálà, Ímù, Ésémù, 30 Élítóládì, Kẹ́sílì, Hóómà,+ 31 Síkílágì,+ Mádímánà, Sánsánà, 32 Lẹ́báótì, Ṣílíhímù, Áyínì àti Rímónì,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29), pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.
33 Ní Ṣẹ́fẹ́là,+ àwọn ìlú náà ni: Éṣítáólì, Sórà,+ Áṣínà, 34 Sánóà, Ẹ́ń-gánímù, Tápúà, Énámù, 35 Jámútì, Ádúlámù,+ Sókọ̀, Ásékà,+ 36 Ṣááráímù,+ Ádítáímù àti Gédérà pẹ̀lú Gédérótáímù,* gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́rìnlá (14), pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.
37 Sénánì, Hádáṣà, Migidali-gádì, 38 Díléánì, Mísípè, Jókítéélì, 39 Lákíṣì,+ Bósíkátì, Ẹ́gílónì, 40 Kábónì, Lámámù, Kítílíṣì, 41 Gédérótì, Bẹti-dágónì, Náámà àti Mákédà,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́rìndínlógún (16), pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.
42 Líbínà,+ Étérì, Áṣánì,+ 43 Ífítà, Áṣínà, Nésíbù, 44 Kéílà, Ákísíbù àti Máréṣà, gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́sàn-án pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.
45 Ẹ́kírónì, àwọn àrọko rẹ̀* àtàwọn ìgbèríko rẹ̀; 46 láti Ẹ́kírónì sí apá ìwọ̀ oòrùn, gbogbo ibi tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Áṣídódì pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.
47 Áṣídódì,+ àwọn àrọko rẹ̀* àti àwọn ìgbèríko rẹ̀; Gásà,+ àwọn àrọko rẹ̀ àti àwọn ìgbèríko rẹ̀, dé Àfonífojì Íjíbítì àti Òkun Ńlá* pẹ̀lú ibi tó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.+
48 Ní agbègbè olókè, Ṣámírù, Játírì,+ Sókọ̀, 49 Dánà, Kiriati-sánà, ìyẹn Débírì, 50 Ánábù, Éṣítémò,+ Ánímù, 51 Góṣénì,+ Hólónì àti Gílò,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mọ́kànlá (11), pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.
52 Árábù, Dúmà, Éṣánì, 53 Jánímù, Bẹti-tápúà, Áfékà, 54 Húmítà, Kiriati-ábà, ìyẹn Hébúrónì+ àti Síórì, gbógbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́sàn-án pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.
55 Máónì,+ Kámẹ́lì, Sífù,+ Jútà, 56 Jésírẹ́lì, Jókídéámù, Sánóà, 57 Kénì, Gíbíà àti Tímúnà;+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́wàá pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.
58 Hálíhúlù, Bẹti-súrì, Gédórì, 59 Máárátì, Bẹti-ánótì àti Élítékónì, gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́fà pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.
60 Kiriati-báálì, ìyẹn Kiriati-jéárímù+ àti Rábà, ó jẹ́ ìlú méjì pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.
61 Ní aginjù, Bẹti-árábà,+ Mídínì, Sékákà, 62 Níbúṣánì, Ìlú Iyọ̀ àti Ẹ́ń-gédì,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́fà pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.
63 Àmọ́ àwọn ọkùnrin Júdà kò lè lé àwọn ará Jébúsì+ tó ń gbé Jerúsálẹ́mù+ lọ,+ torí náà àwọn ará Jébúsì ṣì ń gbé pẹ̀lú àwọn èèyàn Júdà ní Jerúsálẹ́mù títí di òní yìí.