Àkọsílẹ̀ Jòhánù
16 “Mo ti sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, kí ẹ má bàa kọsẹ̀. 2 Àwọn èèyàn máa lé yín kúrò nínú sínágọ́gù.+ Kódà, wákàtí náà ń bọ̀, nígbà tí ẹnikẹ́ni tó bá pa yín+ máa rò pé ṣe lòun ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run. 3 Àmọ́ wọ́n máa ṣe àwọn nǹkan yìí torí pé wọn ò tíì wá mọ Baba, wọn ò sì tíì wá mọ̀ mí.+ 4 Síbẹ̀, mo ti sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, kó lè jẹ́ pé tí wákàtí tí wọ́n máa ṣẹlẹ̀ bá dé, ẹ máa rántí pé mo sọ fún yín.+
“Mi ò kọ́kọ́ sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, torí mo wà pẹ̀lú yín. 5 Àmọ́ ní báyìí, mò ń lọ sọ́dọ̀ Ẹni tó rán mi;+ síbẹ̀ ìkankan nínú yín ò bi mí pé, ‘Ibo lò ń lọ?’ 6 Àmọ́ torí pé mo sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, ẹ̀dùn ọkàn ti bá yín gidigidi.+ 7 Síbẹ̀, òótọ́ ni mò ń sọ fún yín, torí yín ni mo ṣe ń lọ. Ìdí ni pé tí mi ò bá lọ, olùrànlọ́wọ́ náà+ ò ní wá sọ́dọ̀ yín; àmọ́ tí mo bá lọ, màá rán an sí yín. 8 Tí ó bá sì dé, ó máa fún ayé ní ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀, nípa òdodo àti nípa ìdájọ́: 9 lákọ̀ọ́kọ́, nípa ẹ̀ṣẹ̀,+ torí pé wọn ò ní ìgbàgbọ́ nínú mi;+ 10 lẹ́yìn náà, nípa òdodo, torí pé mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba, ẹ ò sì ní rí mi mọ́; 11 lẹ́yìn náà, nípa ìdájọ́, torí pé a ti dá alákòóso ayé yìí lẹ́jọ́.+
12 “Mo ṣì ní ọ̀pọ̀ nǹkan tí mo fẹ́ sọ fún yín, àmọ́ ẹ ò ní lè gbà á báyìí. 13 Àmọ́ tí ìyẹn* bá dé, ẹ̀mí òtítọ́,+ ó máa darí yín sínú gbogbo òtítọ́, torí kì í ṣe èrò ara rẹ̀ ló máa sọ, àmọ́ ohun tó gbọ́ ló máa sọ, ó sì máa kéde àwọn nǹkan tó ń bọ̀ fún yín.+ 14 Ó máa yìn mí lógo,+ torí pé ó máa gbà lára ohun tó jẹ́ tèmi, ó sì máa kéde rẹ̀ fún yín.+ 15 Gbogbo ohun tí Baba ní jẹ́ tèmi.+ Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ pé ó máa gbà lára ohun tó jẹ́ tèmi, ó sì máa kéde rẹ̀ fún yín. 16 Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ ò ní rí mi mọ́,+ bákan náà, ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ máa rí mi.”
17 Ni àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bá sọ fún ara wọn pé: “Kí ló ní lọ́kàn nígbà tó sọ fún wa pé, ‘Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ ò ní rí mi, bákan náà, ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ máa rí mi’ àti pé, ‘torí pé mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba?” 18 Torí náà, wọ́n ń sọ pé: “Kí ló ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé, ‘ní ìgbà díẹ̀ sí i’? A ò mọ ohun tó ń sọ.” 19 Jésù mọ̀ pé wọ́n fẹ́ bi òun ní ìbéèrè, torí náà, ó sọ fún wọn pé: “Ṣé torí mo sọ pé: ‘Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ ò ní rí mi, bákan náà, ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ máa rí mi,’ lẹ ṣe ń bi ara yín lọ́rọ̀ yìí? 20 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹ máa sunkún, ẹ sì máa pohùn réré ẹkún, àmọ́ ayé máa yọ̀; ẹ̀dùn ọkàn máa bá yín, àmọ́ ẹ̀dùn ọkàn yín máa di ayọ̀.+ 21 Tí obìnrin kan bá fẹ́ bímọ, ẹ̀dùn ọkàn máa ń bá a torí pé wákàtí rẹ̀ ti tó, àmọ́ tó bá ti bí ọmọ náà, kò ní rántí ìpọ́njú náà mọ́ torí inú rẹ̀ máa dùn pé a ti bí èèyàn kan sí ayé. 22 Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin, ẹ̀dùn ọkàn bá yín báyìí; àmọ́ màá tún rí yín, inú yín sì máa dùn,+ ẹnì kankan ò sì ní gba ayọ̀ yín mọ́ yín lọ́wọ́. 23 Ní ọjọ́ yẹn, ẹ ò ní bi mí ní ìbéèrè kankan rárá. Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, tí ẹ bá béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ Baba,+ ó máa fún yín ní orúkọ mi.+ 24 Títí di báyìí, ẹ ò tíì béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi. Ẹ béèrè, ẹ sì máa rí gbà, kí ayọ̀ yín lè kún rẹ́rẹ́.
25 “Àfiwé ni mo fi sọ àwọn nǹkan yìí fún yín. Wákàtí náà ń bọ̀ nígbà tí mi ò ní lo àfiwé láti bá yín sọ̀rọ̀ mọ́, àmọ́ màá sọ fún yín nípa Baba lọ́nà tó ṣe kedere. 26 Ní ọjọ́ yẹn, ẹ máa béèrè nǹkan lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi; ohun tí mo sọ yìí ò túmọ̀ sí pé màá bá yín béèrè. 27 Torí Baba fúnra rẹ̀ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún yín, torí pé ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún mi,+ ẹ sì ti gbà gbọ́ pé mo wá bí aṣojú Ọlọ́run.+ 28 Mo wá bí aṣojú Baba, mo sì ti wá sí ayé. Mo ti wá ń kúrò ní ayé báyìí, mo sì ń lọ sọ́dọ̀ Baba.”+
29 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ pé: “Wò ó! Ọ̀rọ̀ rẹ ti ṣe kedere báyìí, o ò lo àfiwé. 30 A ti wá mọ̀ báyìí pé o mọ ohun gbogbo, o ò sì nílò kí ẹnikẹ́ni bi ọ́ ní ìbéèrè. Èyí mú ká gbà gbọ́ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lo ti wá.” 31 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ṣé ẹ ti gbà gbọ́ báyìí? 32 Ẹ wò ó! Wákàtí náà ń bọ̀, ní tòótọ́, ó ti dé, nígbà tí wọ́n máa tú ẹnì kọ̀ọ̀kan yín ká sí ilé rẹ̀, ẹ sì máa fi èmi nìkan sílẹ̀.+ Àmọ́ mi ò dá wà, torí pé Baba wà pẹ̀lú mi.+ 33 Mo ti sọ àwọn nǹkan yìí fún yín kí ẹ lè ní àlàáfíà nípasẹ̀ mi.+ Ẹ máa ní ìpọ́njú nínú ayé, àmọ́ ẹ mọ́kàn le! Mo ti ṣẹ́gun ayé.”+