Ẹ́sírà
3 Nígbà tí oṣù keje+ pé, tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti wà nínú àwọn ìlú wọn, wọ́n kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú èrò tó ṣọ̀kan. 2 Jéṣúà+ ọmọ Jèhósádákì pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ àlùfáà àti Serubábélì+ ọmọ Ṣéálítíẹ́lì+ pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ dìde, wọ́n sì mọ pẹpẹ Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kí wọ́n lè máa rú àwọn ẹbọ sísun lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin Mósè,+ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́.
3 Nítorí náà, wọ́n mọ pẹpẹ náà sí ibi tó wà tẹ́lẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ń bà wọ́n,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í rú àwọn ẹbọ sísun sí Jèhófà lórí rẹ̀, àwọn ẹbọ sísun òwúrọ̀ àti ti ìrọ̀lẹ́.+ 4 Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà lákọsílẹ̀,+ ojoojúmọ́ ni wọ́n sì máa ń rú iye ẹbọ sísun tó yẹ kí wọ́n rú lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan.+ 5 Lẹ́yìn èyí, wọ́n rú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo + àti ẹbọ tó wà fún àwọn òṣùpá tuntun+ àti àwọn tó wà fún gbogbo àsìkò àjọyọ̀ tí a yà sí mímọ́+ fún Jèhófà, títí kan àwọn ọrẹ àtinúwá tí ẹnì kọ̀ọ̀kan fínnúfíndọ̀ mú wá+ fún Jèhófà. 6 Láti ọjọ́ kìíní oṣù keje,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rú àwọn ẹbọ sísun sí Jèhófà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò tíì fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì Jèhófà lélẹ̀.
7 Wọ́n fún àwọn agékùúta+ àti àwọn oníṣẹ́ ọnà+ lówó, wọ́n tún kó oúnjẹ àti ohun mímu pẹ̀lú òróró fún àwọn ọmọ Sídónì àti àwọn ará Tírè, torí wọ́n kó gẹdú igi kédárì láti Lẹ́bánónì gba orí òkun wá sí Jópà,+ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Kírúsì ọba Páṣíà fún wọn.+
8 Ní ọdún kejì, lẹ́yìn tí wọ́n wá sínú ilé Ọlọ́run tòótọ́ ní Jerúsálẹ́mù, ní oṣù kejì, Serubábélì ọmọ Ṣéálítíẹ́lì àti Jéṣúà ọmọ Jèhósádákì àti ìyókù àwọn arákùnrin wọn, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì pẹ̀lú gbogbo àwọn tó jáde wá sí Jerúsálẹ́mù láti ìgbèkùn+ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà; wọ́n yan àwọn ọmọ Léfì, láti ẹni ogún (20) ọdún sókè láti jẹ́ alábòójútó lórí iṣẹ́ ilé Jèhófà. 9 Torí náà, Jéṣúà àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú Kádímíélì àti àwọn ọmọ rẹ̀, ìyẹn àwọn ọmọ Júdà, dara pọ̀ láti máa bójú tó àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé Ọlọ́run tòótọ́, bákan náà, àwọn ọmọ Hénádádì+ àti àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn, tí àwọn náà jẹ́ ọmọ Léfì dara pọ̀ mọ́ wọn.
10 Nígbà tí àwọn kọ́lékọ́lé fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì Jèhófà lélẹ̀,+ àwọn àlùfáà wọ aṣọ iṣẹ́ wọn, wọ́n mú kàkàkí+ dání, àwọn ọmọ Léfì, ìyẹn àwọn ọmọ Ásáfù mú síńbálì* dání, wọ́n dìde dúró láti yin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Dáfídì ọba Ísírẹ́lì fi lélẹ̀.+ 11 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn kọrin,+ wọ́n ń yin Jèhófà, wọ́n sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, “nítorí ó jẹ́ ẹni rere; ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí Ísírẹ́lì sì wà títí láé.”+ Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn èèyàn kígbe sókè láti yin Jèhófà nítorí wọ́n ti fi ìpìlẹ̀ ilé Jèhófà lélẹ̀. 12 Ọ̀pọ̀ lára àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì pẹ̀lú àwọn olórí agbo ilé, ìyẹn àwọn àgbààgbà tó mọ bí ilé náà ṣe rí tẹ́lẹ̀,+ sunkún kíkankíkan nígbà tí wọ́n rí i tí à ń fi ìpìlẹ̀ ilé yìí lélẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn míì sì ń kígbe ayọ̀ bí ohùn wọn ṣe ròkè tó.+ 13 Nítorí náà, àwọn èèyàn ò mọ ìyàtọ̀ nínú igbe ayọ̀ àti igbe ẹkún náà, torí igbe àwọn èèyàn náà ròkè débi pé àwọn tó wà ní ibi tó jìnnà réré ń gbọ́ igbe wọn.