Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí
20 Mo rí i tí áńgẹ́lì kan ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, ó mú kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ + àti ẹ̀wọ̀n ńlá dání. 2 Ó gbá dírágónì náà+ mú, ejò àtijọ́ náà,+ òun ni Èṣù+ àti Sátánì,+ ó sì dè é fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún. 3 Ó jù ú sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà,+ ó tì í, ó sì gbé èdìdì lé ibi àbáwọlé rẹ̀, kó má bàa ṣi àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́ títí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà fi máa parí. Lẹ́yìn èyí, a gbọ́dọ̀ tú u sílẹ̀ fúngbà díẹ̀.+
4 Mo rí àwọn ìtẹ́, a sì fún àwọn tó jókòó sórí wọn ní agbára láti ṣèdájọ́. Kódà, mo rí ọkàn* àwọn tí wọ́n pa* torí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́ nípa Jésù, tí wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti àwọn tí kò jọ́sìn ẹranko náà tàbí ère rẹ̀, tí wọn ò sì gba àmì náà síwájú orí wọn àti ọwọ́ wọn.+ Wọ́n pa dà wà láàyè, wọ́n sì jọba pẹ̀lú Kristi+ fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún. 5 (Àwọn òkú yòókù+ ò pa dà wà láàyè títí dìgbà tí ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún náà parí.) Èyí ni àjíǹde àkọ́kọ́.+ 6 Aláyọ̀ àti ẹni mímọ́ ni ẹnikẹ́ni tó nípìn-ín nínú àjíǹde àkọ́kọ́;+ ikú kejì+ kò ní àṣẹ lórí wọn,+ àmọ́ wọ́n máa jẹ́ àlùfáà+ Ọlọ́run àti ti Kristi, wọ́n sì máa jọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà.+
7 Gbàrà tí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà bá parí, a máa tú Sátánì sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n rẹ̀, 8 ó sì máa jáde lọ láti ṣi àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé lọ́nà, Gọ́ọ̀gù àti Mágọ́gù, láti kó wọn jọ fún ogun náà. Wọ́n pọ̀ níye bí iyanrìn òkun. 9 Wọ́n lọ káàkiri gbogbo ayé, wọ́n sì wà yí ká ibùdó àwọn ẹni mímọ́ àti ìlú tí a fẹ́ràn. Àmọ́ iná wá láti ọ̀run, ó sì jó wọn run.+ 10 A sì ju Èṣù tó ń ṣì wọ́n lọ́nà sínú adágún iná àti imí ọjọ́, níbi tí ẹranko + náà àti wòlíì èké náà wà;+ wọ́n á sì máa joró* tọ̀sántòru títí láé àti láéláé.
11 Mo rí ìtẹ́ funfun kan tó tóbi àti Ẹni tó jókòó sórí rẹ̀.+ Ayé àti ọ̀run sá kúrò níwájú rẹ̀,+ kò sì sí àyè kankan fún wọn. 12 Mo rí àwọn òkú, ẹni ńlá àti ẹni kékeré, wọ́n dúró síwájú ìtẹ́ náà, a sì ṣí àwọn àkájọ ìwé sílẹ̀. Àmọ́ a ṣí àkájọ ìwé míì; àkájọ ìwé ìyè ni.+ A fi àwọn ohun tí a kọ sínú àkájọ ìwé náà ṣèdájọ́ àwọn òkú bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn ṣe rí.+ 13 Òkun yọ̀ǹda àwọn òkú tó wà nínú rẹ̀, ikú àti Isà Òkú* yọ̀ǹda àwọn òkú tó wà nínú wọn, a sì ṣèdájọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn ṣe rí.+ 14 A sì ju ikú àti Isà Òkú* sínú adágún iná.+ Èyí túmọ̀ sí ikú kejì,+ adágún iná náà.+ 15 Bákan náà, a ju ẹnikẹ́ni tí a kò rí i pé wọ́n kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé ìyè+ sínú adágún iná náà.+