Ayé Yóò Rí Bí Ọlọ́run Ṣe Fẹ́ Kó Rí Láìpẹ́ Sígbà Tá A Wà Yìí
ỌLỌ́RUN sọ fún Ádámù àti Éfà nígbà tí wọ́n ṣì wà nínú Párádísè pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.
Nígbà tí Ọlọ́run sọ fún Ádámù àti Éfà pé kí wọ́n ṣèkáwọ́ ilẹ̀ ayé, kì í ṣe pé kí wọ́n kàn máa ro apá kan lára rẹ̀ tàbí kí wọ́n máa bójú tó o ló ní lọ́kàn. Ńṣe ló fẹ́ kí àwọn àtàwọn ọmọ wọn mú kí ọgbà náà máa gbòòrò sí i títí gbogbo ayé á fi di Párádísè. Àmọ́, tọkọtaya àkọ́kọ́ yìí dẹ́ṣẹ̀, Ọlọ́run sì lé wọn jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì. (Jẹ́nẹ́sísì 3:23, 24) Síbẹ̀, ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé kò lè ṣeé ṣe fún ọmọ aráyé láti ṣèkáwọ́ ayé mọ́.
Ó máa ṣeé ṣe fáwọn èèyàn onígbọràn láti ṣèkáwọ́ ayé nítorí pé Ọlọ́run yóò bù kún wọn. Nígbà tí Ọlọ́run ń bù kún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un, àwọn irúgbìn wọn ń ṣe dáadáa lóko bẹ́ẹ̀ làwọn nǹkan ọ̀gbìn inú ọgbà wọn ń so wọ̀ǹtì-wọnti. Irú ohun tí yóò sì ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ nìyẹn nígbà tí ilẹ̀ ayé bá di Párádísè ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Ìlérí tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni pé: “Dájúdájú, ilẹ̀ ayé yóò máa mú èso rẹ̀ wá; Ọlọ́run, tí í ṣe Ọlọ́run wa, yóò bù kún wa.” (Sáàmù 67:6) Èyí fi hàn pé pápá oko tútù, òkè ńlá, igi, òdòdó, odò tàbí agbami òkun tó wà nínú ayé yóò yọ̀. (Sáàmù 96:11-13; 98:7-9) Ewéko tutù yọ̀yọ̀, ẹyẹ ẹlẹ́wà lóríṣiríṣi, onírúurú ẹranko àwòyanu, àtàwọn ọmọlúwàbí èèyàn ló máa kún orí ilẹ̀ ayé wa yìí lọ́jọ́ iwájú.
Ayé Tuntun Máa Tó Dé!
Ayé tuntun tí Jèhófà Ọlọ́run ṣèlérí ti sún mọ́lé. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) Táwọn kan bá ka ohun tí Pétérù kọ yìí, wọ́n lè máa ronú pé ayé tá à ń gbé yìí ò lè di Párádísè láé. Wọ́n á máa wò ó pé ńṣe ni Ọlọ́run máa fi ọ̀run àti ayé mìíràn rọ́pò ọ̀run tá à ń wò lókè yìí àti ayé tá à ń gbé yìí. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nìyẹn?
Kí ni “ọ̀run tuntun” yìí? Èyí kì í ṣe ọ̀run tó wà lókè yìí, níbi tí ìràwọ̀ àti òṣùpá wà. (Sáàmù 19:1, 2) Nínú àwọn ẹsẹ tó ṣáájú, Pétérù sọ̀rọ̀ nípa “ọ̀run” tó dúró fún ìjọba èèyàn tó wà nípò tó ga gan-an ju tàwọn tí wọ́n ń ṣàkóso lé lórí. (2 Pétérù 3:10-12) “Ọ̀run” yìí ò ṣàkóso ayé bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, torí náà ó di dandan kí ọ̀run náà pa run. (Jeremáyà 10:23; Dáníẹ́lì 2:44) Ìjọba Ọlọ́run ni “ọ̀run tuntun” tí yóò rọ́pò ìjọba èèyàn tó wà lónìí, àwọn tó sì máa ṣe ìjọba yìí ni Jésù Kristi Ọba àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n jẹ́ ajùmọ̀jogún pẹ̀lú rẹ̀, tí wọn yóò jíǹde sí ọ̀run.—Róòmù 8:16, 17; Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1, 3.
Nígbà tí Pétérù mẹ́nu kan “ayé tuntun,” kò ní in lọ́kàn pé Ọlọ́run fẹ́ dá ilẹ̀ ayé mìíràn. Jèhófà ti ṣe ilẹ̀ ayé ní àṣepé látilẹ̀wá káwọn èèyàn lè máa gbénú rẹ̀ títí ayérayé. (Sáàmù 104:5) Nígbà míì, Bíbélì máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ilẹ̀ ayé” nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀dá èèyàn. (Jẹ́nẹ́sísì 11:1) Àwọn tí wọ́n ti sọ ara wọn di ara ayé burúkú tá à ń gbé yìí ni wọ́n para pọ̀ jẹ́ ayé tí Ọlọ́run máa tó pa run. Bákan náà ni Ọlọ́run ṣe fi Ìkún Omi ìgbà ayé Nóà pa ayé tó dúró fún àwọn èèyàn tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run run. (2 Pétérù 3:5-7) Kí wá ni “ayé tuntun” túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí àwùjọ ẹ̀dá èèyàn tuntun, ìyẹn àwọn tó ń fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run, tí wọ́n jẹ́ “adúróṣánṣán nínú ọkàn-àyà wọn.” (Sáàmù 125:4; 1 Jòhánù 2:17) “Ọ̀run tuntun” ni gbogbo òfin táwọn èèyàn á máa tẹ̀ lé nínú “ayé tuntun” yẹn yóò ti máa wá. Àwọn ọkùnrin olóòótọ́ tó máa wà lórí ilẹ̀ ayé yóò sì rí sí i pé àwọn èèyàn pa àwọn òfin náà mọ́.
Àwọn Ohun Tuntun Tó Jẹ́ Àgbàyanu Ń Bọ̀ Lọ́nà!
Ká má purọ́, ilé tó dára gan-an ni ilẹ̀ ayé tí Jèhófà dá fún àwa ọmọ aráyé láti máa gbé. Òun fúnra rẹ̀ sọ pé gbogbo ohun tí òun dá nígbà náà “dára gan-an ni.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Sátánì Èṣù ti Ádámù àti Éfà láti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5; Ìṣípayá 12:9) Àmọ́, Ọlọ́run yóò fún àwọn adúróṣánṣán ní “ìyè tòótọ́” láìpẹ́. Ìyẹn ni “ìyè àìnípẹ̀kun” táwọn èèyàn máa gbádùn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nínú Párádísè tí gbogbo nǹkan ti máa wà ní pípé. (1 Tímótì 6:12, 19) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wá wo díẹ̀ lára àwọn ohun táwọn èèyàn máa gbádùn lásìkò yẹn.
Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, Jésù yóò ká Sátánì lọ́wọ́ kò tí kò fi ní lè yọ aráyé lẹ́nu. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Mo sì rí áńgẹ́lì kan [Máíkẹ́lì olú-áńgẹ́lì, ìyẹn Jésù Kristi] tí ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run wá pẹ̀lú kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ àti ẹ̀wọ̀n ńlá ní ọwọ́ rẹ̀. Ó sì gbá dírágónì náà mú, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí í ṣe Èṣù àti Sátánì, ó sì dè é fún ẹgbẹ̀rún ọdún. Ó fi í sọ̀kò sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà, ó tì í, ó sì fi èdìdì dí i lórí rẹ̀, kí ó má bàa ṣi àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́ títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò fi dópin.” (Ìṣípayá 20:1-3; 12:12) Yàtọ̀ sí pé Sátánì ò ní lágbára lórí àwọn èèyàn nígbà tó bá wà nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan lọmọ aráyé tún máa gbádùn lábẹ́ ìṣàkóso Kristi.
Ìwà ibi, ìwà ọ̀daràn àti ogun kò ní sí mọ́. Bíbélì ṣèlérí pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà. Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:10, 11, 29) Jèhófà Ọlọ́run yóò “mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 46:9) Láìsí àní-àní, ńṣe ni àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé àlàáfíà àti ààbò yóò wà!
Oúnjẹ aládùn tí ń ṣara lóore yóò pọ̀ yanturu. Ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù kọ ọ́ lórin pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.” (Sáàmù 72:16) Lákòókò náà, kò sẹ́ni tí ebi tí ń kọ́ni lóòyì yóò máa pa.
Kò sẹ́ni tí yóò ní àìsàn tàbí àrùn kankan lára. Dájúdájú, “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24; 35:5, 6) Nígbà tí Jésù Kristi wà lórí ilẹ̀ ayé, ó wo àwọn adẹ́tẹ̀ sàn, ó mú àwọn arọ lára dá, ó sì lajú àwọn afọ́jú. (Mátíù 9:35; Máàkù 1:40-42; Jòhánù 5:5-9) Wá fojú inú wo ohun ribiribi tí Jésù máa ṣe ná nínú ayé tuntun! Ronú nípa bí ayọ̀ ṣe máa gba ibi gbogbo kan nígbà táwọn afọ́jú, odi, arọ àti adití bá rí ìmúláradá.
Nígbà tí aráyé onígbọràn bá dé ipò ìjẹ́pípé, ara àwọn arúgbó á padà di ti ọ̀dọ́. Kò ní sí awò ojú, ọ̀pá ìtìlẹ̀, ọ̀pá ìkẹ́sẹ̀, àga arọ, ilé ìwòsàn àti egbòogi mọ́. Áà, àyípadà tó máa wà nígbà tára wa bá tún jí pépé padà bí ara ọ̀dọ́ á mà ga o! (Jóòbù 33:25) Oorun àsùngbádùn tí a ó máa sùn á jẹ́ kí ara wa máa jí pépé láti lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aláyọ̀ lójoojúmọ́.
Àjíǹde àwọn èèyàn wa tó ti kú àtàwọn míì yóò múnú wa dùn. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Ìdùnnú á ṣubú láyọ̀ nígbà tá a bá ń kí àwọn èèyàn bí Ébẹ́lì, Nóà, Ábúráhámù, Sárà, Jóòbù, Mósè, Rúùtù, Dáfídì, Èlíjà, Ẹ́sítérì àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn bẹ́ẹ̀ káàbọ̀! Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn mìíràn ni yóò tún jíǹde. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lára wọn ni kò mọ̀ nípa Jèhófà tẹ́lẹ̀, síbẹ̀ inú àwọn tó ti múra tán láti kọ́ wọn nípa Ọlọ́run, nípa àwọn ohun tó fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú àti nípa Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀, yóò dùn láti rí wọn. Bí àwọn tó jíǹde sì ṣe ń mọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá wọn, ìmọ̀ Jèhófà yóò bo gbogbo ilẹ̀ ayé.
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a ó lè máa jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà títí ayé. A óò ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ kan, ìyẹn ni pé a ó máa “fi ayọ̀ yíyọ̀ sin Jèhófà,” a ó sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn láti kọ́ ilé dáradára, láti gbin nǹkan ọ̀gbìn àti láti ṣèkáwọ́ ilẹ̀ ayé lẹ́yìn-ọ̀-rẹ́yìn. (Sáàmù 100:1-3; Aísáyà 65:21-24) Ohun ayọ̀ gbáà ni yóò jẹ́ láti máa gbé nínú Párádísè ẹlẹ́wà, níbi tí ilẹ̀ á ti máa méso jáde dáadáa tí àlàáfíà á sì jọba, èyí tí yóò mú kí gbogbo ẹ̀dá máa fi ìyìn fún orúkọ mímọ́ Jèhófà!—Sáàmù 145:21; Jòhánù 17:3.
Ìdánwò Ìkẹyìn fún Ìran Èèyàn
Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, Kristi yóò lo ẹbọ ìràpadà rẹ̀ láti fi ṣe gbogbo aráyé onígbọràn láǹfààní. Bí àkókò sì ṣe ń lọ, kò ní sí ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, àwọn èèyàn yóò sì wá di ẹni pípé. (1 Jòhánù 2:2; Ìṣípayá 21:1-4) Tí àwọn ìṣòro tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù dá sílẹ̀ bá ti wá kúrò tán pátápátá, àwọn èèyàn tí wọ́n ti di ẹni pípé yóò lè máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run lọ́nà tó pé pérépéré, wọ́n á máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ lérò, lọ́rọ̀, níṣe, àti nínú ìjọsìn wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n yóò “wá sí ìyè” lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nígbà tí wọ́n bá di ẹni pípé láìsí ẹ̀ṣẹ̀ kankan. (Ìṣípayá 20:5) Dájúdájú, àyípadà yìí àti ayé tó ti di Párádísè yóò gbé ògo Jèhófà yọ!
Lẹ́yìn tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá ti pé, Jésù yóò tú Sátánì Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sílẹ̀ fúngbà díẹ̀ kúrò nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ tí wọ́n ti wà fún ẹgbẹ̀rún ọdún. (Ìṣípayá 20:1-3) Ọlọ́run yóò wá fún wọn láyè fún ìgbà ìkẹyìn láti gbìyànjú láti yí àwọn èèyàn lọ́kàn padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan á jẹ́ kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gbà wọ́n lọ́kàn, pàbó ni ọ̀tẹ̀ Sátánì yìí yóò já sí. Jèhófà yóò pa gbogbo àwọn onímọtara-ẹni-nìkan tí wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ run pa pọ̀ pẹ̀lú Sátánì àti gbogbo àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀. Ìwà ibi kì yóò sì sí mọ́. Gbogbo àwọn olubi ni yóò pa rẹ́ ráúráú, Ọlọ́run yóò sì fún àwọn olódodo ní ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun.—Ìṣípayá 20:7-10.
Ǹjẹ́ Wàá Wà Níbẹ̀?
Jèhófà Ọlọ́run ti ṣèlérí ayọ̀ ayérayé fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè kò ní súni rárá. Àní, ńṣe ni ìgbésí ayé yóò máa lárinrin nìṣó bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, torí pé ìmọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run kò ní lópin. (Róòmù 11:33) Ìgbà gbogbo ni wàá máa rí ohun tuntun tí wàá fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò á sì wà fún ọ láti gba ìmọ̀ kún ìmọ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé o ò kàn ní gbé àádọ́rin tàbí ọgọ́rin ọdún péré láyé, ńṣe ni wàá wà láàyè títí gbére.—Sáàmù 22:26; 90:10; Oníwàásù 3:11.
Bó o bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, inú rẹ yóò máa dùn gan-an láti ṣe ohun tó fẹ́. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòhánù 5:3) Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun ṣèdíwọ́ fún ọ láti hùwà òdodo tó máa múnú Jèhófà Ọlọ́run dùn. Máa fi ìrètí àgbàyanu tí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ kó o ní sọ́kàn. Pinnu pé ìfẹ́ Jèhófà ni wàá máa ṣe, má sì ṣe yẹsẹ̀ láé. Nípa báyìí, yóò ṣojú rẹ nígbà tí ayé bá rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí níbẹ̀rẹ̀, tí ilẹ̀ ayé sì di Párádísè títí ayé.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Ìbùkún Ọlọ́run ló jẹ́ kí oko àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa méso jáde lọ́pọ̀ yanturu
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn ohun alárinrin wo lò ń retí láti gbádùn nínú Párádísè?