Ẹ Wa Alaafia Ki Ẹ Si Maa Lepa rẹ̀”
“Ẹ jẹ ki Jehofa di gbigbegalọla, ẹni ti o ni inudidun ninu alaafia iranṣẹ rẹ̀.”—SAAMU 35:27, NW.
1. Alaafia wo ni a ngbadun lonii?
IRU ayọ wo ni o jẹ ninu aye ti a pin yẹlẹyẹlẹ yii lati wa ni alaafia! Iru inudidun wo ni o jẹ lati sin Jehofa, “Ọlọrun alaafia,” ati lati ṣajọpin ninu awọn ibukun “majẹmu alaafia” rẹ̀! Bawo ni o ti tunilara to, laaarin awọn ikimọlẹ igbesi-aye, lati mọ “alaafia Ọlọrun ti o ju imọran gbogbo lọ” ati lati ni iriri ‘ide alaafia’ ti o so awọn eniyan Ọlọrun pọ ṣọkan laika orilẹ-ede, ede, ẹya-iran, tabi ipilẹ ẹgbẹ-oun-ọgba ti wọn lè jẹ si!—1 Tẹsalonika 5:23; Esekiẹli 37:26; Filipi 4:7; Efesu 4:3.
2, 3. (a) Nigba ti awọn eniyan Ọlọrun lapapọ yoo farada a, ki ni le ṣẹlẹ si Kristian kọọkan? (b) Ki ni Bibeli rọ̀ wa lati ṣe?
2 Gẹgẹ bi Ẹlẹrii Jehofa, awa mọriri alaafia yii. Bi o ti wu ki o ri, awa ko le ronu pe nini alaafia daju lọjọkọjọ. Alaafia ni a kò lè pamọ laiṣiṣẹ fun un kiki nitori pe awa ndarapọ mọ ijọ Kristian tabi o ṣẹlẹ pe a jẹ́ apakan idile Kristian. Nigba ti awọn aṣẹku ẹni ami ororo ati alabaakẹgbẹ wọn ti “awọn agutan miiran” yoo farada a titi de opin gẹgẹ bi agbo kan, ẹnikọọkan le padanu alaafia wọn ki wọn sì ṣubu.—Johanu 10:16; Matiu 24:13; Roomu 11:22; 1 Kọrinti 10:12.
3 Apọsteli Pọọlu kilọ fun awọn Kristian ẹni ami ororo ọjọ rẹ̀ pe: “Ẹ kiyesara, ará, ki ọkan buburu ti aigbagbọ ki o maṣe wa ninu ẹnikẹni yin, ni lilọ kuro lọdọ Ọlọrun alaaye.” (Heberu 3:12) Ikilọ yii ṣeefisilo pẹlu fun ogunlọgọ nla. Nitori naa Bibeli rọ awọn Kristian pe: “Ẹ wa alaafia ki ẹ si maa lepa rẹ̀. Nitori oju Jehofa wà lara awọn olododo, eti rẹ̀ sì ṣí sí adura ẹ̀bẹ̀ wọn; ṣugbọn oju Jehofa lodisi awọn wọnni ti nṣe awọn ohun buburu.”—1 Peteru 3:10-12, NW; Saamu 34:14, 15.
“Ṣíṣìkẹ́ Ẹran-ara”
4. Ki ni o lè dí alaafia wa pẹlu Ọlọrun lọwọ?
4 Ki ni o le di ilepa alaafia wa lọwọ? Pọọlu mẹnukan ohun kan nigba ti o wipe: “Ṣíṣìkẹ́ ẹran-ara tumọsi iku, ṣugbọn ṣíṣìkẹ́ ẹmi tumọsi iye ati alaafia; nitori pe ṣíṣìkẹ́ ẹran-ara tumọsi iṣọta pẹlu Ọlọrun.” (Roomu 8:6, 7, NW) Niti “ẹran-ara,” Pọọlu tọka si ipo ẹṣẹ wa gẹgẹ bi eniyan alaipe ti o ti jogun awọn itẹsi ti o kun fun ẹṣẹ. Jijuwọsilẹ fun awọn itẹsi ẹran-ara abẹ̀ṣẹ̀ yoo run alaafia wa. Bi Kristian kan ba nhu iwapalapala, parọ́, jalè, jẹ oogun yó tabi ni awọn ọna miiran rú ofin atọrunwa laironupiwada, ko tun si alaafia laaarin rẹ̀ ati Jehofa mọ. (Owe 15:8, 29; 1 Kọrinti 6:9, 10; Iṣipaya 21:8) Ju bẹẹ lọ, bi oun ba yọnda ki awọn ohun ti ara tubọ ṣepataki fun un ju awọn ohun tẹmi lọ, alaafia rẹ pẹlu Ọlọrun ni a halẹmọ lọna wiwuwo.—Matiu 6:24; 1 Johanu 2:15-17.
5. Ki ni lilepa alaafia ni ninu?
5 Ni odikeji ẹ̀wẹ̀, Pọọlu wipe: “Ṣíṣìkẹ́ ẹmi tumọsi iye ati alaafia.” Alaafia jẹ apakan awọn eso ti ẹmi, bi a ba si kọ́ ọkan-aya wa lati mọriri awọn ohun tẹmi, ni gbigbadura fun ẹmi Ọlọrun lati ran wa lọwọ ninu eyi, nigba naa awa yoo yẹra fun “ṣíṣìkẹ́ ẹran-ara.” (Galatia 5:22-24) Ni 1 Peteru 3:10-12, alaafia ni a sopọ mọ iwa-ododo. (Roomu 5:1) Peteru wipe lilepa alaafia ni ninu ‘yiyipada kuro ninu ohun buburu ki o si ṣe ohun rere.’ Ẹmi Ọlọrun le ràn wa lọwọ lati “lepa òdodo” ki ó sì tipa bayii pa alaafia wa pẹlu Ọlọrun mọ́.—1 Timoti 6:11, 12.
6. Ki ni ọkan lara ẹrù-iṣẹ́ awọn alagba niti alaafia ijọ?
6 Lilepa alaafia jẹ idaniyan pataki fun awọn alagba ninu ijọ. Fun apẹẹrẹ, bi ẹnikan ba gbiyanju lati mu awọn iṣe aṣa aimọ wọle, awọn alagba ni ẹru iṣẹ lati daabobo ijọ nipa gbigbiyanju lati fibawi tọ́ ẹlẹṣẹ naa sọna. Bi oun ba gba ibawi naa, oun yoo jere alaafia rẹ̀ pada. (Heberu 12:11) Bi bẹẹ kọ, oun ni a lè lé jade ki a baa le pa ipo ibatan alalaafia ijọ pẹlu Jehofa mọ́.—1 Kọrinti 5:1-5.
Alaafia Pẹlu Awọn Arakunrin Wa
7. Ifihanjade ‘ṣíṣìkẹ́ ẹran-ara’ wo ni Pọọlu kilọ fun awọn ara Kọrinti nipa rẹ̀?
7 ‘Ṣíṣìkẹ́ ẹran-ara’ le run kii ṣe kiki alaafia wa pẹlu Ọlọrun ṣugbọn ipo ibatan rere wa pẹlu awọn Kristian yooku. Pọọlu kọwe si awọn ara Kọrinti pe: “Ẹyin jẹ ti ara sibẹ: nitori niwọnbi ilara ati ija, ati iyapa ba wa laaarin yin, ẹyin ko ha jẹ ti ara ẹ ko ha sì nrin gẹgẹ bi eniyan?” (1 Kọrinti 3:3) Owu ati kèéta jẹ odikeji alaafia gan-an.
8. (a) Ki ni o le ṣẹlẹ si ẹnikan ti o fa owú ati kèéta ninu ijọ? (b) Lori ki ni alaafia wa pẹlu Ọlọrun sinmi le?
8 Yiyọ alaafia ijọ lẹnu nipa dida owú ati kèéta silẹ lewu gan-an. Ni sisọrọ nipa animọ ti o tanmọ alaafia gẹgẹ bi eso ti ẹmi, apọsteli Johanu kilọ pe: “Bi ẹnikẹni ba wipe, emi fẹran Ọlọrun, ti o si koriira arakunrin rẹ̀, èké ni: nitori ẹni ti ko fẹran arakunrin rẹ̀ ti o ri, bawo ni yoo ti ṣe le fẹran Ọlọrun ti oun kò ri?” (1 Johanu 4:20) Ni ọna ti o farajọra, bi ẹnikan ba da owu tabi kèéta silẹ laaarin awọn ara, njẹ oun ha lè wa ni alaafia pẹlu Ọlọrun bí? Dajudaju bẹẹkọ! A rọ̀ wa pe: “Ẹ maa baa lọ lati maa yọ̀, lati jẹ ki a maa tun yin ṣe bọsipopada, ki a maa tù yin ninu, ki a maa ronu ni ifohunṣọkan, ki a maa gbe ni alaafia; Ọlọrun ifẹ ati alaafia yoo si wà pẹlu yin.” (2 Kọrinti 13:11, NW) Bẹẹni bi awa ba nbaa lọ lati maa gbe ni alaafia pẹlu araawa ẹnikinni keji, nigba naa Ọlọrun ifẹ ati alaafia yoo wa pẹlu wa.
9. Bawo ni a ṣe mọ̀ pe nigba miiran awọn Kristian yoo ni aifohunṣọkan ti wọn yoo sì ṣi araawọn loye?
9 Eyi ko tumọsi pe awọn edekoyede laaarin awọn Kristian kì yoo wà lae. Ni awọn ọsẹ ti o tẹle Pẹntikọsti, aifohunṣọkan kan wà ninu ijọ Kristian titun nipa ipinfunni ounjẹ oojọ. (Iṣe 6:1) Ni akoko kan aifohunṣọkan laaarin Pọọlu ati Banabba ṣamọna si “irujade ibinu mimuna.” (Iṣe 15:39, NW) Pọọlu nilati gba Yuodia ati Sintike, ti wọn jẹ arabinrin rere ati onitara laisi iyemeji niyanju, “lati ni ero-inu kan naa ninu Oluwa.” (Filipi 4:2, NW) Abajọ ti Jesu ṣe fi ẹkunrẹrẹ imọran funni lori bi a o ti yanju awọn ohun ti ndi alaafia lọwọ laaarin awọn Kristian ti o si tẹnumọ ijẹkanjukanju bibojuto iru awọn iṣoro bẹẹ lọgan! (Matiu 5:23-25; 18:15-17) Oun ki ba tí funni ni imọran yii bi oun kò ba fojusọna fun iṣoro laaarin awọn ọmọlẹhin rẹ̀.
10. Awọn ipo wo ni o maa ndide ninu ijọ nigba miiran, ẹru-iṣẹ wo sì ni eyi gbekari gbogbo awọn ti o mu lọwọ?
10 Nigba naa, lonii, o ṣeeṣe daadaa pe ki a ṣẹ̀ ẹnikan nipa ọ̀rọ̀ kan ti a ko ronu jinlẹ sọ tabi nipa ohun ti a woye pe o jẹ abuku lati ọ̀dọ̀ Kristian ẹlẹgbẹ wa kan. Iru iwa kan ti ẹnikan nhu lè bí ẹlomiran ninu lọna mimuna. Animọ iwa le forigbari. Awọn kan le tako ipinnu awọn alagba lọna lile. Laaarin ẹgbẹ awọn alagba funraarẹ, alagba kan le jẹ ọlọkan lile ki o si gbiyanju lati jẹgaba lori awọn alagba yooku. Laika otitọ naa pe iru awọn nnkan bẹẹ maa nṣẹlẹ si, awa ṣi nilati wa alaafia ki a si lepa rẹ̀. Ipenija naa ni lati bojuto awọn iṣoro wọnyi ni ọna Kristian ki a baa le pa “ide alaafia ti nsonipọ ṣọkan” mọ́.—Efesu 4:3, NW.
11. Awọn ipese wo ni Jehofa ti ṣe lati ràn wa lọwọ lati lepa alaafia pẹlu araawa ẹnikinni keji?
11 Bibeli wipe: “Ẹ jẹ ki Jehofa di gbigbegalọla, ẹni ti o ni inudidun ninu alaafia iranṣẹ rẹ̀.” (Saamu 35:27, NW) Bẹẹni, Jehofa fẹ ki a wa ni alaafia. Fun idi yii, o ti ṣe ipese pataki meji lati ran wa lọwọ lati pa alaafia mọ́ laaarin araawa ati pẹlu rẹ̀. Ọkan ni ẹmi mimọ, eyi ti alaafia jẹ eso rẹ̀ kan, papọ pẹlu awọn animọ alalaafia ti o tanmọ ọ, iru bii ipamọra, iṣoore, iwatutu, ati ikora-ẹni-nijanu. (Galatia 5:22, 23) Omiran ni ọgbọ́n atọrunwa, nipa eyi ti a kà pe: “Ọgbọ́n ti o ti oke wá á kọkọ mọ́, lẹhin naa a ni alaafia, a lọgbọn ninu, a muratan lati ṣegbọran, a kun fun aanu ati awọn eso rere.”—Jakọbu 3:17, 18, NW.
12. Ki ni awa nilati ṣe bi a ba dí alaafia wa pẹlu awọn arakunrin wa lọwọ?
12 Nitori naa, nigba ti a ba dí alaafia wa pẹlu awọn ẹlomiran lọwọ, awa nilati gbadura fun ọgbọ́n lati oke lati fihan wa bi awa ṣe nilati huwa, awa si nilati beere fun ẹmi mimọ lati fun wa lokun lati ṣe ohun ti o tọ̀nà. (Luuku 11:13; Jakọbu 1:5; 1 Johanu 3:22) Ni ibamu pẹlu adura wa, nigba naa awa le wo inu orisun ọgbọ́n atọrunwa naa, Bibeli, fun itọsọna, ki a si tun yẹ iwe ikẹkọọ Bibeli ti o wa larọọwọto wò fun imọran lori bi a o ṣe fi awọn Iwe Mimọ silo. (2 Timoti 3:16) Awa tun le fẹ lati gba imọran lati ọ̀dọ̀ awọn alagba ninu ijọ. Igbesẹ ti o kẹhin yoo jẹ lati tẹle itọsọna ti a rigba. Aisaya 54:13 wipe: “A o si kọ gbogbo awọn ọmọ rẹ lati ọ̀dọ̀ Oluwa [“Jehofa,” NW] wá; alaafia awọn ọmọ rẹ yoo sì pọ.” Eyi dọgbọn tumọsi pe alaafia wa sinmi lori fifi ti a fi awọn nnkan ti Jehofa nkọ wa si ìlò.
“Alayọ Ni Awọn Ti Nwa Alaafia”
13, 14. (a) Ki ni ọrọ Jesu naa “awọn ti nwa alaafia” tumọsi? (b) Bawo ni awa ṣe le di olùwá alaafia?
13 Ninu Iwaasu rẹ̀ lori Oke, Jesu wipe: “Alayọ ni awọn ti nwa alaafia, niwọnbi a o ti pe wọn ni ‘ọmọkunrin Ọlọrun.’” (Matiu 5:9, NW) “Awọn ti nwa alaafia” nihin-in ko tumọsi ẹni ti o kan ṣe jẹ́jẹ́ lọna ti ẹ̀dá. Ọrọ Giriiki naa ni ipilẹṣẹ tumọsi “awọn olùwá alaafia.” Olùwá alaafia kan jáfáfá ninu mimu alaafia padabọsipo nigba ti a ba di i lọwọ. Ṣugbọn, ni pataki ju, olùwá alaafia kan nlakaka lati yẹra fun didi alaafia lọwọ lakọọkọ ná. ‘Alaafia nṣakoso ọkan-aya rẹ̀.’ (Kolose 3:15) Bi awọn iranṣẹ Ọlọrun ba lakaka lati jẹ olùwá alaafia, nigba naa awọn iṣoro laaarin wọn ni yoo mọniwọn.
14 Didi olùwá alaafia kan ni mimọ awọn ailera tiwa funraawa ninu. Fun apẹẹrẹ, Kristian kan le ni inúfùfù tabi ki o jẹ atètèbínú ati ẹni ti o rọrun lati ṣẹ̀. Nigba ti ó bá wà ni abẹ ikimọlẹ, awọn ìmí-ẹ̀dùn rẹ̀ le mu ki o gbagbe awọn ilana Bibeli. Eyi kii ṣe ohun ti ko le ṣẹlẹ laaarin awọn ẹda eniyan alaipe. (Roomu 7:21-23) Laika eyiini si, iṣọta, kèéta, ati ìbínú fùfù ni a to lẹsẹẹsẹ gẹgẹ bi awọn iṣẹ ti ẹran-ara. (Galatia 5:19-21, NW) Bi a ba ri iru awọn itẹsi bẹẹ ninu araawa—tabi ti a ba mu wọn wá si afiyesi wa lati ọ̀dọ̀ awọn ẹlomiran—awa nilati maa fi titaratitara gbadura lemọlemọ fun ẹmi Jehofa lati mu ikora-ẹni-nijanu ati iwapẹlẹ dagba ninu wa. Nitootọ, olukuluku nilati lakaka lati mu iru awọn animọ bẹẹ dàgbà gẹgẹ bi apakan akopọ animọ titun rẹ̀.—Efesu 4:23, 24; Kolose 3:10, 15.
15. Bawo ni ọgbọ́n lati oke ṣe jẹ odikeji patapata si agídí alainironu?
15 Ni igba kọọkan, ijọ kan tabi ẹgbẹ awọn alagba kan ni ẹnikan ti o lágídí le yọlẹnu, ti o ntẹpẹlẹ mọ ọna tirẹ̀ nigbagbogbo. Nitootọ, nigba ti o ba kan ofin Ọlọrun, Kristian kan nilati jẹ aduro gbọnyin ni ironu, ani ki o ma tilẹ ṣeetẹsihin-in sọhun-un paapaa. Bi a ba sì nimọlara pe a ni ero rere ti o lè ṣanfaani fun awọn ẹlomiran, ko si ohun ti o buru pẹlu sisọ ero-inu wa jade ni kedere, niwọn igba ti a ba ti ṣalaye awọn ìdí ti a ni. Ṣugbọn awa ko fẹ dabi awọn wọnni ninu aye ti wọn jẹ “alaiṣee ba ṣe adehun.” (2 Timoti 3:1-4, NW) Ọgbọ́n lati oke wa jẹ alalaafia, eyi ti o ba ironu mu. Awọn wọnni ti ihuwa wọn jẹ iru ti alagidi alaile tẹsihin-in sọhun-un nilati kọbiara si imọran Pọọlu si awọn ara Filipi lati ‘maṣe ohunkohun lati inu ògo asan.’—Filipi 2:3, NW.
16. Bawo ni imọran Pọọlu ninu iwe Filipi ṣe ràn wá lọwọ lati ṣẹpa ògo-asán?
16 Ninu lẹta yẹn kan naa, Pọọlu rọ̀ wa pe pẹlu otitọ inu ni ki a fi ‘irẹlẹ ọkan kà á sí pe awọn ẹlomiran lọla ju wa lọ.’ Eyi gan-an ni idakeji ògo asán. Kristian ògbóṣáṣá kan kii kọ́kọ́ ronu nipa fifi ipa mu awọn ero tirẹ̀ ṣẹ, yiyẹra fun itiju, tabi didaabobo ipo tabi ọla-aṣẹ tirẹ̀ fúnraarẹ̀. Eyi yoo lodisi igbaniniyanju Pọọlu lati ‘maa mojuto, kii ṣe kiki anfaani ara-ẹni ninu awọn ọran tirẹ̀ fúnraarẹ̀ nikan, ṣugbọn ninu anfaani ara-ẹni wọnni ti wọn jẹ ti awọn ẹlomiran pẹlu.’—Filipi 2:4, NW; 1 Peteru 5:2, 3, 6.
Awọn Ọ̀rọ̀ Alalaafia
17. Ilokulo ahọ́n wo ni o le dí alaafia lọwọ ninu ijọ?
17 Ẹni ti nlepa alaafia ni pataki nilati ṣọra nipa bi o ti nlo ahọ́n. Jakọbu kilọ pe: “Ahọ́n jẹ ẹ̀yà kekere, o sì nfọnnu ohun nla. Wo igi nla ti ina kekere nsun jona!” (Jakọbu 3:5) Òfófó ti o le panilara, ṣiṣariwisi awọn ẹlomiran lẹhin wọn, awọn ọ̀rọ̀ alaininuure ti o sì lekoko, kíkùnsínú ati rirahun, ati pẹlu ipọnnile alábòsí nitori anfaani ara-ẹni—gbogbo iwọnyi jẹ iṣẹ ẹran-ara ti ndi alaafia awọn eniyan Ọlọrun lọwọ.—1 Kọrinti 10:10; 2 Kọrinti 12:20; 1 Timoti 5:13; Juuda 16.
18. (a) Bí ọran ba di ti lilo ahọ́n nilokulo laimọọmọ, ki ni igbesẹ titọ fun gbogbo ẹni ti ọran kan? (b) Nigba ti ibinu ba mu ki ẹni kan sọ awọn ọ̀rọ̀ ti ndunniwọra jade, bawo ni awọn Kristian ti wọn ti dagbadenu ṣe nhuwa pada?
18 Nitootọ, Jakọbu wipe: “Ahọ́n ni ẹnikẹni ko le tu loju.” (Jakọbu 3:8) Ani awọn Kristian ògbóṣáṣá paapaa nigba miiran nsọ awọn ohun ti wọn nfi pẹlu otitọ inu kabaamọ nigbẹhin. Gbogbo wa nireti pe awọn miiran yoo dárí iru awọn aṣiṣe bẹẹ jì wa gan-an gẹgẹ bi awa ti ndariji wọn. (Matiu 6:12) Nigba miiran irujade ibinu mimuna le mu awọn ọ̀rọ̀ adunniwọra jade. Nigba naa olùwá alaafia kan yoo ranti pe “idahun pẹlẹ yi ibinu pada; ṣugbọn ọ̀rọ̀ lile ni nru ibinu soke.” (Owe 15:1) Niye-igba, oun yoo wulẹ nilati míkanlẹ̀ ti yoo sì kọ lati fi awọn ọ̀rọ̀ ti ntubọ munibinu dahunpada si awọn ọ̀rọ̀ ibinu ẹnikan. Lẹhin-ọ-rẹhin, nigba ti ibinu ba rọlẹ̀, olùwá alaafia abanikẹdun kan mọ bi a ti ngboju fo awọn nnkan ti a sọ ni akoko igbonara. Kristian onirẹlẹ yoo sì mọ bi a ti ntọrọ aforiji yoo sì gbiyanju lati wo ọgbẹ́ ibanujẹ ti o ti dasilẹ sàn. O jẹ àmì agbara ihuwa rere lati lè fi tootọtootọ wi pe, “Mo tọrọ àforíjì.”
19. Ẹkọ wo ni a ri kọ lati inu bi Pọọlu ati Jesu ṣe funni ni imọran?
19 Ahọ́n ni a lè nilati lò lati gba awọn ẹlomiran nimọran. Pọọlu ba Peteru wi kikankikan nigba ti o huwa lọna aitọ ni Antioku. Jesu sì funni ni imọran lilekoko ninu ihin-iṣẹ rẹ̀ si awọn ijọ meje. (Galatia 2:11-14; Iṣipaya, ori 2 ati 3) Bi awa ba yẹ awọn apẹẹrẹ wọnyi wò daradara, a ó loye pe imọran ni ko nilati tutu debi pe koko rẹ̀ ni a ó padanu. Ṣugbọn, Jesu ati Pọọlu ko lekoko tabi rorò. Imọran wọn kii ṣe ọna lati fihan pe a ja wọn kulẹ. Wọn fi tọkantọkan gbiyanju lati ran awọn arakunrin wọn lọwọ. Bi ẹni naa ti o nfunni ni imọran ba fi òye mọ̀ pe oun ko ṣakoso ahọ́n oun ni kikun, oun lè yàn lati danuduro diẹ ki o si farabalẹ fun ìgbà diẹ ki o to sọ ohunkohun. Bi bẹẹ kọ, oun le sọ awọn ọ̀rọ̀ lile ki o sì fa iṣoro ti o buru ju eyi ti oun ngbiyanju lati yanju.—Owe 12:18.
20. Ki ni o nilati ṣakoso gbogbo ohun ti a sọ si tabi nipa awọn arakunrin ati arabinrin wa?
20 Gẹgẹ bi a ti mẹnukan an tẹlẹ, alaafia ati ifẹ baratan timọtimọ gẹgẹ bi awọn eso ti ẹmi. Bi ohun ti a ba nsọ si awọn arakunrin wa—tabi nipa wọn—ba jẹ ifihan ifẹ wa fun wọn nigba gbogbo, nigba naa yoo fikun alaafia ijọ naa. (Johanu 15:12, 13) Awọn ọrọ isọjade wa gbọdọ jẹ “pẹlu oore-ọfẹ, ti a fi iyọ̀ dùn.” (Kolose 4:6, NW) Wọn gbọdọ ladun, ki a wi bẹẹ, ki o fa ọkan-aya mọra. Jesu gbani ni imọran pe: “Ẹ ni iyọ̀ ninu araayin, ki ẹ sì maa wa ni alaafia laaarin araayin.”—Maaku 9:50.
“Sa Gbogbo Ipa Rẹ”
21. Ki ni o ṣe kedere nipa awọn eniyan Ọlọrun ni awọn ipade ọsọọsẹ ati nigba awọn apejọ ati awọn apejọpọ?
21 Onisaamu naa kọwe pe: “Kiyesi i, o ti dara o si ti dùn to fun awọn ará lati maa jumọ gbé ní irẹpọ!” (Saamu 133:1) Nitootọ, inu wa maa ndun lati wà pẹlu awọn arakunrin wa, paapaa ni awọn ipade wa ọsọọsẹ ati nigba awọn apejọ ati awọn apejọpọ nla. Ni iru awọn akoko bẹẹ alaafia wa han gbangba ani si awọn ara ita paapaa.
22. (a) Alaafia eke wo ni awọn orilẹ ede yoo ronu pe ọwọ́ awọn ti tẹ, ni ṣiṣamọna si ki ni? (b) Alaafia tootọ wo ni majẹmu alaafia ti Ọlọrun nṣamọna si?
22 Laipẹ awọn orilẹ-ede yoo ronu pe ọwọ́ awọn ti tẹ̀ alaafia laisi Jehofa. Ṣugbọn nigba ti wọn ba nwipe, “Alaafia ati ailewu” iparun òjijì yoo wa sori gbogbo awọn ti wọn ko wà ni alaafia pẹlu Ọlọrun. (1 Tẹsalonika 5:3) Lẹhin iyẹn, Ọmọ Alade Alaafia titobi naa yoo tẹsiwaju pẹlu wiwo araye san kuro ninu iyọrisi onijaaba ti ipadanu alaafia eniyan pẹlu Ọlọrun ni ipilẹṣẹ. (Aisaya 9:6, 7; Iṣipaya 22:1, 2) Lẹhin naa, majẹmu alaafia ti Ọlọrun yoo yọrisi ìtòròminimini kari aye. Ani awọn ẹranko ẹhanna inu papa yoo niriiri isinmi kuro lọwọ ainifẹẹ.—Saamu 37:10, 11; 72:3-7; Aisaya 11:1-9; Iṣipaya 21:3, 4.
23. Bi awa ba ṣìkẹ́ ireti fun aye titun alalaafia, ki ni a nilati ṣe nisinsinyi?
23 Iru akoko ologo wo ni iyẹn yoo jẹ! Ẹyin ha nwo iwaju pẹlu iharagaga fun un bi? Bi o ba ri bẹẹ nigba naa, “ẹ maa lepa alaafia pẹlu eniyan gbogbo.” Ẹ wa alaafia nisinsinyi, pẹlu awọn arakunrin yin, ati ni pataki pẹlu Jehofa. Bẹẹ ni, “bi ẹyin ti nreti iru nnkan wọnyi, ẹ mura giri, ki a le baa yin ni alaafia, ni ailabawọn, ati ni ailabuku ni oju rẹ̀.”—Heberu 12:14; 2 Peteru 3:14.
Iwọ Ha Ranti Bi?
◻ Ki ni o lè ba alaafia wa pẹlu Jehofa jẹ patapata?
◻ Iru awọn aṣiloye wo ni o lè jẹ ọranyan lati yanju ninu ijọ?
◻ Ipese wo ni Jehofa ti ṣe lati ràn wa lọwọ lati wa alaafia ki a si maa lepa rẹ̀?
◻ Awọn ìṣesí ẹran-ara wo ni o le dí alaafia ijọ lọwọ, bawo sì ni awa ṣe le dojukọ wọn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Alaafia pọ yanturu laaarin awọn wọnni ti a kọ lati ọ̀dọ̀ Jehofa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Bawo ni alaafia awọn arakunrin ti wọn nṣiṣẹsin ni iṣọkan ti dùn tó!