Ìsíkíẹ́lì
24 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀ ní ọdún kẹsàn-án, ní oṣù kẹwàá, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, kọ ọjọ́ òní* sílẹ̀, àní ọjọ́ òní yìí. Ọba Bábílónì ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbógun ti Jerúsálẹ́mù lónìí yìí.+ 3 Pa òwe* nípa ọlọ̀tẹ̀ ilé náà, kí o sì sọ nípa wọn pé:
“‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
“Gbé ìkòkò oúnjẹ* kaná; gbé e sórí iná, kí o sì da omi sínú rẹ̀.+
4 Kó ẹran tí wọ́n gé sínú rẹ̀,+ gbogbo èyí tó dáa,
Itan àti èjìká; fi àwọn egungun tó dára jù kún inú rẹ̀.
5 Mú àgùntàn tó dára jù nínú agbo ẹran,+ kí o sì kó igi sábẹ́ ìkòkò náà yí ká.
Bọ ẹran náà, kí o sì se àwọn egungun náà nínú rẹ̀.”’
6 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
‘O gbé, ìwọ ìlú tó ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀,+ ìkòkò oúnjẹ tó ti dípẹtà, tí wọn ò sì ha ìpẹtà rẹ̀ kúrò!
Kó o jáde ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan;+ má ṣe ṣẹ́ kèké lé wọn.
7 Torí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà nínú rẹ̀;+ ó dà á sórí àpáta lásán.
Kò dà á sórí ilẹ̀ kó lè fi iyẹ̀pẹ̀ bò ó.+
8 Kí ìbínú lè ru sókè láti gbẹ̀san,
Mo ti da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí àpáta tó ń dán,
Kí nǹkan má bàa bo ẹ̀jẹ̀ náà.’+
9 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí,
‘O gbé, ìwọ ìlú tó ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀!+
Èmi yóò to igi jọ pelemọ.
10 Kó igi náà jọ, kí o sì dáná sí i,
Bọ ẹran náà dáadáa, yọ́ omi rẹ̀, sì jẹ́ kí àwọn egungun rẹ̀ jóná.
11 Gbé ìkòkò náà ka ẹyin iná lófìfo kó lè gbóná,
Kí bàbà tí wọ́n fi ṣe é lè pọ́n yòò.
Ìdọ̀tí inú rẹ̀ yóò yọ́ kúrò,+ ìpẹtà rẹ̀ yóò sì jóná.
12 Ó ń dáni lágara, ó sì ń tánni lókun,
Torí ìpẹtà tó wà lára rẹ̀ kò ṣí kúrò.+
Jù ú sínú iná pẹ̀lú ìpẹtà rẹ̀!’
13 “‘Ìwà àìnítìjú rẹ ló mú kí o di aláìmọ́.+ Mo wẹ̀ ọ́ títí kí o lè mọ́, àmọ́ ìwà àìmọ́ rẹ kò kúrò. Ìwọ kì yóò mọ́ títí ìbínú mi sí ọ fi máa rọlẹ̀.+ 14 Èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀. Yóò rí bẹ́ẹ̀. Ohun tí mo sọ ni màá ṣe, mi ò ní kẹ́dùn, mi ò sì ní pèrò dà.+ Wọ́n á fi ìwà àti ìṣe rẹ dá ọ lẹ́jọ́,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
15 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 16 “Ọmọ èèyàn, mo máa tó mú ẹni tí o fẹ́ràn kúrò lọ́dọ̀ rẹ lójijì.+ Má ṣe ṣọ̀fọ̀;* má ṣe sunkún, má sì da omi lójú. 17 Banú jẹ́, àmọ́ má ṣe jẹ́ kó hàn síta, má tẹ̀ lé àṣà àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ òkú.+ Wé láwàní rẹ,+ kí o sì wọ bàtà rẹ.+ Má bo ẹnu* rẹ,+ má sì jẹ oúnjẹ tí àwọn ẹlòmíì bá gbé wá fún ọ.”*+
18 Àárọ̀ ni mo bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀, ìyàwó mi sì kú ní alẹ́. Torí náà, nígbà tí ilẹ̀ mọ́, mo ṣe ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ fún mi. 19 Àwọn èèyàn náà ń sọ fún mi pé: “Ṣé o ò ní sọ fún wa bí àwọn ohun tí ò ń ṣe yìí ṣe kàn wá?” 20 Mo fún wọn lésì pé: “Jèhófà ti bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, 21 ‘Sọ fún ilé Ísírẹ́lì pé: “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Mo máa tó sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́,+ ibi pàtàkì tí ẹ fi ń yangàn, tí ẹ fẹ́ràn gidigidi, tó sì máa ń wù yín.* Idà ni wọn yóò fi pa àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin tí ẹ fi sílẹ̀.+ 22 Ẹ ó sì wá ṣe bí mo ti ṣe. Ẹ ò ní bo ẹnu yín, ẹ ò sì ní jẹ oúnjẹ tí àwọn ẹlòmíì bá gbé wá fún yín.+ 23 Láwàní yín yóò wà lórí yín, bàtà yín yóò sì wà ní ẹsẹ̀ yín. Ẹ ò ní ṣọ̀fọ̀, ẹ ò sì ní sunkún. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ ó rọ dà nù nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín,+ ẹ ó sì banú jẹ́ láàárín ara yín. 24 Ìsíkíẹ́lì ti di àmì fún yín.+ Ohun tó ṣe ni ẹ̀yin náà yóò ṣe. Nígbà tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ ó wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.’”’”
25 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, ní ọjọ́ tí mo bá mú ibi ààbò wọn kúrò lọ́dọ̀ wọn, ohun tó rẹwà tó ń fún wọn láyọ̀, tí wọ́n fẹ́ràn gidigidi, tó sì máa ń wù wọ́n,* pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn ọkùnrin àti obìnrin,+ 26 ẹni tó bá sá àsálà yóò wá ròyìn rẹ̀ fún ọ.+ 27 Ní ọjọ́ yẹn, ìwọ yóò la ẹnu rẹ, wàá bá ẹni tó sá àsálà sọ̀rọ̀, o ò sì ní ya odi mọ́.+ Ìwọ yóò di àmì fún wọn, wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”