Sí Àwọn Ará Gálátíà
1 Pọ́ọ̀lù, àpọ́sítélì, tí kì í ṣe látọwọ́ àwọn èèyàn tàbí nípasẹ̀ èèyàn kan, bí kò ṣe nípasẹ̀ Jésù Kristi+ àti Ọlọ́run tó jẹ́ Baba,+ ẹni tó gbé e dìde kúrò nínú ikú 2 àti gbogbo àwọn ará tó wà pẹ̀lú mi, sí àwọn ìjọ tó wà ní Gálátíà:
3 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Baba wa àti Jésù Kristi Olúwa wà pẹ̀lú yín. 4 Ó fi ara rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa,+ kó lè gbà wá sílẹ̀ nínú ètò àwọn nǹkan* búburú ìsinsìnyí,+ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run àti Baba wa,+ 5 ẹni tí ògo jẹ́ tirẹ̀ títí láé àti láéláé. Àmín.
6 Ó yà mí lẹ́nu pé ẹ ti sáré yà kúrò* lọ́dọ̀ Ẹni tó fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Kristi pè yín, ẹ sì ń lọ sínú oríṣi ìhìn rere míì.+ 7 Kì í kúkú ṣe pé ìhìn rere míì wà; àmọ́ àwọn kan wà tó ń dá wàhálà sílẹ̀ fún yín,+ tí wọ́n sì fẹ́ yí ìhìn rere nípa Kristi po. 8 Àmọ́ ṣá o, bí àwa tàbí áńgẹ́lì kan láti ọ̀run bá kéde ohun kan fún yín pé ó jẹ́ ìhìn rere, àmọ́ tó yàtọ̀ sí ìhìn rere tí a ti kéde fún yín, kí ó di ẹni ègún. 9 Bí a ṣe sọ ṣáájú, mo tún ń sọ ọ́ báyìí pé, Ẹnikẹ́ni tí ì báà jẹ́ tó bá ń kéde ohun kan fún yín pé ó jẹ́ ìhìn rere, àmọ́ tó yàtọ̀ sí ìhìn rere tí ẹ ti gbà, kí ó di ẹni ègún.
10 Ṣé ojú rere èèyàn ni mò ń wá báyìí ni àbí ti Ọlọ́run? Àbí ìfẹ́ èèyàn ni mo fẹ́ ṣe? Tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ èèyàn ni mo ṣì ń ṣe, á jẹ́ pé èmi kì í ṣe ẹrú Kristi. 11 Ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ìhìn rere tí mo kéde fún yín kì í ṣe látọ̀dọ̀ èèyàn;+ 12 nítorí mi ò gbà á lọ́wọ́ èèyàn, bẹ́ẹ̀ ni a ò fi kọ́ mi, àmọ́ ó jẹ́ nípasẹ̀ ìfihàn látọwọ́ Jésù Kristi.
13 Ẹ ti gbọ́ nípa ìwà mi tẹ́lẹ̀ nínú Ìsìn Àwọn Júù,+ pé mò ń ṣe inúnibíni tó gbóná* sí ìjọ Ọlọ́run, mo sì ń dà á rú;+ 14 mò ń tẹ̀ síwájú nínú Ìsìn Àwọn Júù ju ọ̀pọ̀ nínú àwọn tí a jọ jẹ́ ẹgbẹ́ lórílẹ̀-èdè mi, torí mo ní ìtara púpọ̀ fún àṣà àwọn baba mi.+ 15 Àmọ́ nígbà tí Ọlọ́run, ẹni tó yọ mí nínú ikùn ìyá mi, tó sì pè mí nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀,+ rí i pé ó dára 16 láti ṣí Ọmọ rẹ̀ payá nípasẹ̀ mi, kí n lè kéde ìhìn rere nípa rẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè,+ mi ò lọ fọ̀rọ̀ lọ ẹnikẹ́ni* lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀; 17 bẹ́ẹ̀ ni mi ò lọ sí Jerúsálẹ́mù lọ́dọ̀ àwọn tó jẹ́ àpọ́sítélì ṣáájú mi, àmọ́ mo lọ sí Arébíà, lẹ́yìn náà, mo pa dà sí Damásíkù.+
18 Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, mo lọ sí Jerúsálẹ́mù+ lọ́dọ̀ Kéfà,*+ mo sì lo ọjọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) lọ́dọ̀ rẹ̀. 19 Àmọ́ mi ò rí ìkankan nínú àwọn àpọ́sítélì yòókù, àfi Jémíìsì+ àbúrò Olúwa. 20 Ní ti àwọn ohun tí mò ń kọ sí yín, mo fi dá yín lójú níwájú Ọlọ́run pé mi ò parọ́.
21 Lẹ́yìn ìyẹn, mo lọ sí agbègbè Síríà àti ti Sìlíṣíà.+ 22 Àmọ́ àwọn ìjọ Jùdíà tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi kò dá mi mọ̀. 23 Wọ́n kàn máa ń gbọ́ pé: “Ọkùnrin tó ń ṣe inúnibíni sí wa tẹ́lẹ̀+ ti ń kéde ìhìn rere nípa ẹ̀sìn* tí òun fúnra rẹ̀ ń gbógun tì tẹ́lẹ̀.”+ 24 Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í yin Ọlọ́run lógo nítorí mi.