Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì
6 Ṣé ó yẹ kí ẹnikẹ́ni nínú yín tó ní èdèkòyédè pẹ̀lú ẹnì kan+ gbójúgbóyà lọ sí ilé ẹjọ́ níwájú àwọn aláìṣòdodo, tí kì í sì í ṣe níwájú àwọn ẹni mímọ́? 2 Àbí ẹ ò mọ̀ pé àwọn ẹni mímọ́ ló máa ṣèdájọ́ ayé?+ Tó bá sì jẹ́ pé ẹ̀yin lẹ máa ṣèdájọ́ ayé, ṣé ẹ ò mọ bí ẹ ṣe máa gbọ́ ẹjọ́ lórí àwọn ọ̀ràn tí kò tó nǹkan ni? 3 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé àwa la máa ṣèdájọ́ àwọn áńgẹ́lì ni?+ Kí ló wá dé tí a ò lè yanjú àwọn ọ̀ràn ti ayé yìí? 4 Tí ẹ bá wá ní àwọn ọ̀ràn ayé yìí tí ẹ fẹ́ gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀,+ ṣé àwọn ọkùnrin tí ìjọ ń fojú àbùkù wò ló yẹ kí ẹ yàn ṣe onídàájọ́? 5 Mò ń sọ̀rọ̀ kí ojú lè tì yín. Ṣé kò sí ọlọ́gbọ́n kankan láàárín yín tó lè ṣèdájọ́ láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀ ni? 6 Arákùnrin wá ń gbé arákùnrin lọ sí ilé ẹjọ́, ó tún wá jẹ́ níwájú àwọn aláìgbàgbọ́!
7 Ní tòótọ́, ẹ ti pa ara yín láyò bí ẹ ṣe ń pe ara yín lẹ́jọ́. Ẹ ò ṣe kúkú gbà kí wọ́n ṣe àìtọ́ sí yín?+ Ẹ ò ṣe kúkú jẹ́ kí wọ́n lù yín ní jìbìtì? 8 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀ ń ṣe àìtọ́, ẹ sì ń lu jìbìtì, ó tún wá jẹ́ sí àwọn arákùnrin yín!
9 Àbí ẹ ò mọ̀ pé àwọn aláìṣòdodo kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run ni?+ Ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n ṣì yín lọ́nà.* Àwọn oníṣekúṣe,*+ àwọn abọ̀rìṣà,+ àwọn alágbèrè,+ àwọn ọkùnrin tó ń jẹ́ kí ọkùnrin bá wọn lò pọ̀,+ àwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀,*+ 10 àwọn olè, àwọn olójúkòkòrò,+ àwọn ọ̀mùtípara,+ àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn* àti àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run.+ 11 Síbẹ̀, ohun tí àwọn kan lára yín jẹ́ tẹ́lẹ̀ nìyẹn. Àmọ́ a ti wẹ̀ yín mọ́;+ a ti yà yín sí mímọ́;+ a ti pè yín ní olódodo+ ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi àti nípasẹ̀ ẹ̀mí Ọlọ́run wa.
12 Ohun gbogbo ló bófin mu* lójú mi, àmọ́ kì í ṣe ohun gbogbo ló ṣàǹfààní.+ Ohun gbogbo ló bófin mu lójú mi, àmọ́ mi ò ní jẹ́ kí ohunkóhun máa darí mi.* 13 Oúnjẹ wà fún ikùn, ikùn sì wà fún oúnjẹ, àmọ́ Ọlọ́run máa sọ àwọn méjèèjì di asán.+ Ara kò wà fún ìṣekúṣe,* Olúwa ló wà fún,+ Olúwa sì wà fún ara. 14 Àmọ́ Ọlọ́run gbé Olúwa dìde,+ yóò sì gbé àwa náà dìde kúrò nínú ikú+ nípasẹ̀ agbára rẹ̀.+
15 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé ẹ̀yà ara Kristi ni ara yín ni?+ Ṣé ó wá yẹ kí n mú ẹ̀yà ara Kristi kúrò, kí n sì dà á pọ̀ mọ́ ti aṣẹ́wó? Ká má ri! 16 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé ẹni tó bá ní àṣepọ̀ pẹ̀lú aṣẹ́wó á di ara kan pẹ̀lú rẹ̀ ni? Nítorí Ọlọ́run sọ pé “àwọn méjèèjì á sì di ara kan.”+ 17 Àmọ́ ẹni tó bá dara pọ̀ mọ́ Olúwa jẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ nínú ẹ̀mí.+ 18 Ẹ máa sá fún ìṣekúṣe!*+ Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ míì tí èèyàn lè dá wà lóde ara rẹ̀, àmọ́ ẹni tó bá ń ṣe ìṣekúṣe ń ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ̀.+ 19 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé ara yín ni tẹ́ńpìlì+ ẹ̀mí mímọ́ tó wà nínú yín, èyí tí ẹ gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run?+ Bákan náà, ẹ kì í ṣe ti ara yín,+ 20 nítorí a ti rà yín ní iye kan.+ Nítorí náà, ẹ máa yin Ọlọ́run lógo+ nínú ara yín.+