Àkọsílẹ̀ Mátíù
9 Torí náà, ó wọ ọkọ̀ ojú omi, ó sì sọdá lọ sí ìlú rẹ̀.+ 2 Wò ó! wọ́n ń gbé ọkùnrin kan bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní àrùn rọpárọsẹ̀, ó sì dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn. Nígbà tó rí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní, Jésù sọ fún alárùn rọpárọsẹ̀ náà pé: “Mọ́kàn le, ọmọ! A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”+ 3 Àwọn akọ̀wé òfin kan wá ń sọ fún ara wọn pé: “Ọ̀gbẹ́ni yìí ń sọ̀rọ̀ òdì.” 4 Jésù mọ ohun tí wọ́n ń rò, ó wá sọ pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ro ohun burúkú nínú ọkàn yín?+ 5 Bí àpẹẹrẹ, èwo ló rọrùn jù, láti sọ pé, ‘A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ àbí láti sọ pé, ‘Dìde, kí o sì máa rìn’?+ 6 Àmọ́ kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ èèyàn ní àṣẹ láyé láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini—” ó sọ fún alárùn rọpárọsẹ̀ náà pé: “Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o sì máa lọ sílé rẹ.”+ 7 Ọkùnrin náà bá dìde, ó sì lọ sílé rẹ̀. 8 Nígbà tí àwọn èrò rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, ẹni tó fún èèyàn nírú àṣẹ yìí.
9 Lẹ́yìn ìyẹn, bí Jésù ṣe ń kúrò níbẹ̀, ó tajú kán rí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Mátíù, tó jókòó sí ọ́fíìsì àwọn agbowó orí, ó sì sọ fún un pé: “Máa tẹ̀ lé mi.” Ló bá dìde, ó sì tẹ̀ lé e.+ 10 Lẹ́yìn náà, bó ṣe ń jẹun* nínú ilé, wò ó! ọ̀pọ̀ àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jẹun.*+ 11 Àmọ́ nígbà tí àwọn Farisí rí èyí, wọ́n sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí olùkọ́ yín ń bá àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?”+ 12 Nígbà tó gbọ́ ohun tí wọ́n sọ, ó sọ pé: “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn, àmọ́ àwọn tó ń ṣàìsàn nílò rẹ̀.+ 13 Torí náà, ẹ lọ kọ́ ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí: ‘Àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ.’+ Torí kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”
14 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù wá bá a, wọ́n sì bi í pé: “Kí ló dé tí àwa àti àwọn Farisí máa ń gbààwẹ̀ àmọ́ tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ kì í gbààwẹ̀?”+ 15 Jésù sọ fún wọn pé: “Kò sí ohun tó máa mú kí àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó ṣọ̀fọ̀ tí ọkọ ìyàwó+ bá ṣì wà lọ́dọ̀ wọn, àbí ó wà? Àmọ́ ọjọ́ ń bọ̀, tí a máa mú ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn,+ wọ́n máa wá gbààwẹ̀. 16 Kò sí ẹni tó máa rán ègé aṣọ tí kò tíì sún kì mọ́ ara aṣọ àwọ̀lékè tó ti gbó, torí aṣọ tuntun náà máa ya kúrò lára aṣọ àwọ̀lékè náà, ó sì máa ya ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.+ 17 Àwọn èèyàn kì í sì í rọ wáìnì tuntun sínú àpò awọ tó ti gbó. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, àpò náà máa bẹ́, wáìnì á dà nù, àpò náà á sì bà jẹ́. Àmọ́ inú àpò awọ tuntun ni àwọn èèyàn máa ń rọ wáìnì tuntun sí, ohunkóhun ò sì ní ṣe méjèèjì.”
18 Bó ṣe ń sọ àwọn nǹkan yìí fún wọn, wò ó! alákòóso kan tó ti sún mọ́ tòsí forí balẹ̀* fún un, ó sọ pé: “Ọmọbìnrin mi á ti kú báyìí, àmọ́ wá gbé ọwọ́ rẹ lé e, ó sì máa jí.”+
19 Jésù bá dìde, òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀ lé e. 20 Wò ó! obìnrin kan tí ìsun ẹ̀jẹ̀+ ti ń yọ lẹ́nu fún ọdún méjìlá (12) sún mọ́ ọn láti ẹ̀yìn, ó sì fọwọ́ kan wajawaja tó wà létí aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,+ 21 torí ó ń sọ fún ara rẹ̀ ṣáá, pé: “Tí mo bá ṣáà ti fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, ara mi á yá.” 22 Jésù yíjú pa dà, nígbà tó rí i, ó sọ pé: “Mọ́kàn le, ọmọbìnrin! Ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.”+ Láti wákàtí yẹn, ara obìnrin náà yá.+
23 Nígbà tó dé ilé alákòóso náà, tó sì tajú kán rí àwọn tó ń fun fèrè àtàwọn èrò tó ń pariwo,+ 24 Jésù sọ pé: “Ẹ kúrò níbẹ̀, torí ọmọdébìnrin náà ò kú, ó ń sùn ni.”+ Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ́rìn-ín, wọ́n sì ń fi ṣẹlẹ́yà. 25 Gbàrà tí wọ́n ní kí àwọn èrò náà bọ́ síta, ó wọlé, ó di ọwọ́ ọmọdébìnrin náà mú,+ ọmọ náà sì dìde.+ 26 Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yìí tàn ká gbogbo agbègbè yẹn.
27 Bí Jésù ṣe kúrò níbẹ̀, àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì + tẹ̀ lé e, wọ́n ń kígbe pé: “Ṣàánú wa, Ọmọ Dáfídì.” 28 Lẹ́yìn tó wọnú ilé, àwọn ọkùnrin afọ́jú náà wá bá a, Jésù sì bi wọ́n pé: “Ṣé ẹ nígbàgbọ́ pé mo lè ṣe é?”+ Wọ́n dá a lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa.” 29 Ó wá fọwọ́ kan ojú wọn,+ ó sọ pé: “Kó rí bẹ́ẹ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ yín.” 30 Ojú wọn sì ríran. Lẹ́yìn náà, Jésù kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé: “Kí ẹ rí i pé ẹnì kankan kò mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí.”+ 31 Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n jáde, wọ́n sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún gbogbo èèyàn ní gbogbo agbègbè yẹn.
32 Nígbà tí wọ́n ń lọ, wò ó! àwọn èèyàn mú ọkùnrin kan tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu,+ tí kò lè sọ̀rọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀; 33 lẹ́yìn tó sì lé ẹ̀mí èṣù náà jáde, ọkùnrin náà sọ̀rọ̀.+ Ẹnu ya àwọn èrò náà, wọ́n sì sọ pé: “A ò tíì rí irú èyí rí ní Ísírẹ́lì.”+ 34 Àmọ́ àwọn Farisí ń sọ pé: “Agbára alákòóso àwọn ẹ̀mí èṣù ló fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”+
35 Jésù wá bẹ̀rẹ̀ sí í lọ káàkiri gbogbo ìlú àti abúlé, ó ń kọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù wọn, ó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà, ó sì ń wo onírúurú àìsàn àti onírúurú àìlera sàn.+ 36 Nígbà tó rí àwọn èrò, àánú wọn ṣe é,+ torí wọ́n dà bí àgùntàn tí a bó láwọ, tí a sì fọ́n ká láìní olùṣọ́ àgùntàn.+ 37 Ó wá sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Òótọ́ ni, ìkórè pọ̀, àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ò tó nǹkan.+ 38 Torí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè pé kó rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde láti bá a kórè.”+