ORÍ 26
“A Dárí Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ Jì Ọ́”
MÁTÍÙ 9:1-8 MÁÀKÙ 2:1-12 LÚÙKÙ 5:17-26
JÉSÙ DÁRÍ JI ALÁRÙN RỌPÁRỌSẸ̀ KAN Ó SÌ WÒ Ó SÀN
Ìròyìn nípa Jésù ti wá délé dóko báyìí. Ọ̀pọ̀ ló wá láti ibi tó jìn gan-an kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ kí wọ́n sì rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ń ṣe. Àmọ́ lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ó pa dà sí Kápánáúmù níbi tó ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu tó sì kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Kíá làwọn ará ìlú tó wà létí Òkun Gálílì yìí ti gbọ́ pé Jésù ti pa dà dé. Torí náà, ọ̀pọ̀ ló wá sí ilé tó dé sí. Farisí làwọn kan nínú wọn, àwọn míì sì jẹ́ olùkọ́ Òfin, Gálílì àti Jùdíà títí kan Jerúsálẹ́mù sì ni wọ́n ti wá.
“Ọ̀pọ̀ èèyàn wá kóra jọ, débi pé kò sí àyè kankan mọ́ nínú ilé, kódà kò sí àyè lẹ́nu ọ̀nà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ọ̀rọ̀ náà fún wọn.” (Máàkù 2:2) Ní báyìí, ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ kan máa tó ṣẹlẹ̀. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sì máa jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jésù ní agbára láti mú ìyà tó ń jẹ aráyé kúrò á sì fún gbogbo àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀ ní ìlera pípé.
Nígbà tí Jésù ń kọ́ni nínú yàrá tó kún fọ́fọ́ yẹn, àwọn ọkùnrin mẹ́rin gbé ọkùnrin kan tó ní àrùn rọpárọsẹ̀ wá. Ọ̀rẹ́ wọn ni ọkùnrin náà, wọ́n sì fẹ́ kí Jésù wò ó sàn. Àmọ́ wọn ò lè “gbé e tààràtà dé ọ̀dọ̀ Jésù” torí èrò tó wà níbẹ̀. (Máàkù 2:4) Ẹ wo bó ṣe máa dùn wọ́n tó. Kí ni wọ́n wá ṣe? Ńṣe ni wọ́n gun òrùlé ilé náà, wọ́n sì dá ihò lu sí i. Wọ́n wá gba ojú ihò náà sọ alárùn rọpárọsẹ̀ náà kalẹ̀ sínú ilé náà.
Ṣé Jésù wá bínú sí wọn? Rárá o! Ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní wú u lórí débi tó fi sọ fún alárùn rọpárọsẹ̀ náà pé: “A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.” (Mátíù 9:2) Àmọ́ ṣé Jésù lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji àwọn èèyàn lóòótọ́? Àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí bẹ̀rẹ̀ sí í bínú sí Jésù, wọ́n sì ń ronú pé: “Kí ló dé tí ọkùnrin yìí ń sọ̀rọ̀ báyìí? Ọ̀rọ̀ òdì ló ń sọ. Ta ló lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini yàtọ̀ sí Ọlọ́run nìkan?”—Máàkù 2:7.
Àmọ́ Jésù ti fòye mọ ohun tí wọ́n ń rò lọ́kàn, ó wá sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ro àwọn nǹkan yìí lọ́kàn yín? Èwo ló rọrùn jù, láti sọ fún alárùn rọpárọsẹ̀ náà pé, ‘A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ àbí láti sọ pé, ‘Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o sì máa rìn’?” (Máàkù 2:8, 9) Ó dájú pé Jésù lè dárí ji ọkùnrin náà lọ́lá ẹbọ ìràpadà tí Jésù máa san.
Lẹ́yìn náà, Jésù ṣe ohun táá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun ní àṣẹ láti dárí jini lórí ilẹ̀ ayé. Ó yíjú sí alárùn rọpárọsẹ̀ náà, ó sì pàṣẹ fún un pé: “Mò ń sọ fún ọ, Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o sì máa lọ sílé rẹ.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ọkùnrin náà dìde, ó gbé ibùsùn rẹ̀, ó sì rìn jáde níwájú gbogbo wọn. Ẹnu ya àwọn tó wà níbẹ̀, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, wọ́n sọ pé: “A ò rí irú èyí rí”!—Máàkù 2:11, 12.
Ó gba àfiyèsí pé Jésù mẹ́nu kan ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àìsàn, ó sì jẹ́ kó ṣe kedere pé ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lè mú kéèyàn rí ìwòsàn gbà. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ádámù tó jẹ́ òbí wa àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀, gbogbo wa sì ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú látọ̀dọ̀ rẹ̀. Àmọ́ lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, Jésù máa dárí ji gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń sìn ín. Nígbà yẹn, kò ní sí àìsàn mọ́ títí láé.—Róòmù 5:12, 18, 19.