“Ohun Gbogbo Ni Ìgbà Tí A Yàn Kalẹ̀ Wà Fún”
“Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, àní ìgbà fún gbogbo àlámọ̀rí lábẹ́ ọ̀run.”—ONÍWÀÁSÙ 3:1.
1. Ìṣòro wo làwa ènìyàn aláìpé ní, kí lèyí sì ti súnni ṣe láwọn ìgbà kan?
ÀWỌN èèyàn sábà máa ń sọ pé, “Ǹ bá ti tètè ṣe é.” Wọ́n sì tún lè kábàámọ̀ pé, “Ǹ bá ti ní sùúrù.” Irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ fi hàn bó ṣe ṣòro tó fún ènìyàn aláìpé láti mọ ìgbà tó tọ́ láti ṣe nǹkan. Ìkùdíẹ̀-káàtó yìí ti ba ọ̀pọ̀ àjọṣe jẹ́. Ó ti yọrí sí ìjákulẹ̀ àti ìbànújẹ́. Èyí tó tiẹ̀ burú jù lọ ni pé, ó ti sọ ìgbàgbọ́ àwọn kan nínú Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀ di ahẹrẹpẹ.
2, 3. (a) Èé ṣe tó fi bọ́gbọ́n mu láti fara mọ́ ìpinnu Jèhófà nípa àwọn ìgbà tí ó ti yàn? (b) Ojú ìwòye tí kò fì síbì kan wo ló yẹ ká ní nípa ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì?
2 Nítorí tí Jèhófà ní ọgbọ́n àti ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn kò ní, ó ṣeé ṣe fún un láti mọ ibi tí ìgbésẹ̀ kan yóò yọrí sí, ìyẹn tó bá fẹ́ mọ̀ ọ́n ni o. Ó lè ‘tìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ mọ ibi tí ọ̀ràn yóò dópin sí.’ (Aísáyà 46:10) Nítorí náà, bó bá fẹ́ yan àkókò tó wọ̀ jù lọ láti ṣe ohunkóhun tó fẹ́ ṣe, kò ní ṣàṣìṣe rárá. Nítorí náà, kàkà tí a ó fi gbára lé òye kíkù díẹ̀ káàtó táa ní láti díwọ̀n àkókò, yóò bọ́gbọ́n mu táa bá lè fara mọ́ ohun tí Jèhófà pinnu ní ti àkókò tí ó yàn!
3 Fún àpẹẹrẹ, àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú máa ń ní sùúrù títí tí àkókò tí Jèhófà yàn pé kí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan ní ìmúṣẹ yóò fi dé. Ọwọ́ wọ́n máa ń dí nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, gbogbo ìgbà ni wọ́n sì máa ń fi ìlànà tó wà nínú Ìdárò 3:26 sọ́kàn, èyí tó sọ pé: “Ó dára kí ènìyàn dúró, àní ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, de ìgbàlà Jèhófà.” (Fi wé Hábákúkù 3:16.) Lọ́wọ́ kan náà, wọ́n gbà gbọ́ pé bí ìdájọ́ tí Jèhófà kéde “bá tilẹ̀ falẹ̀, . . . yóò ṣẹ láìkùnà. Kì yóò pẹ́.”—Hábákúkù 2:3.
4. Báwo ni Ámósì 3:7 àti Mátíù 24:45 ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti fi sùúrù dúró de Jèhófà?
4 Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí a kò bá lóye àwọn ẹsẹ Bíbélì tàbí àlàyé kan táa ṣe nínú àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, ǹjẹ́ ó yẹ ká wá di oníwàǹwára? Dídúró de àkókò tí Jèhófà ti yàn láti mú ọ̀ràn yéni yékéyéké jẹ́ ìwà ọgbọ́n. “Nítorí pé Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ kì yóò ṣe ohun kan láìjẹ́ pé ó ti ṣí ọ̀ràn àṣírí rẹ̀ payá fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.” (Ámósì 3:7) Àgbàyanu ìlérí mà lèyí jẹ́ o! Ṣùgbọ́n o, a gbọ́dọ̀ mọ̀ pé Jèhófà máa ń ṣí ọ̀ràn àṣírí rẹ̀ payá ní àkókò tí ó bá rí i pé ó tọ́. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run ṣe fàṣẹ fún “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti máa pèsè “oúnjẹ [tẹ̀mí] ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu,” fún àwọn ènìyàn tirẹ̀. (Mátíù 24:45) Nítorí náà, kò yẹ kí a jẹ́ kí nǹkan ká wa lára jù, tàbí ká bẹ̀rẹ̀ sí tara pàrà, nítorí pé a ò tí ì ṣàlàyé àwọn ọ̀ràn kan lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, a lè ní ìgbọ́kànlé pé báa bá fi sùúrù dúró de Jèhófà, òun yóò tipasẹ̀ ẹrú olóòótọ́ náà pèsè ohun tí a nílò fún wa “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.”
5. Kí làǹfààní ṣíṣàgbéyẹ̀wò Oníwàásù 3:1-8?
5 Sólómọ́nì Ọba sọ̀rọ̀ nípa oríṣi nǹkan méjìdínlọ́gbọ̀n ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló sì ní “ìgbà tí a yàn kalẹ̀” fún un. (Oníwàásù 3:1-8) Báa bá lóye ohun tí ọ̀rọ̀ Sólómọ́nì túmọ̀ sí àti bó ṣe kàn wá, èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àkókò tí ó tọ́ àti àkókò tí kò tọ́ láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan, ìyẹn ní ti ojú tí Ọlọ́run fi ń wò ó. (Hébérù 5:14) Ìyẹn ẹ̀wẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tó bá ojú ìwòye rẹ̀ mu.
“Ìgbà Sísunkún àti Ìgbà Rírẹ́rìn-ín”
6, 7. (a) Kí làwọn nǹkan tó ń fa kí àwọn èèyàn máa ‘sunkún’ lónìí? (b) Báwo ni ayé ṣe ń gbìyànjú láti fojú kò-tó-nǹkan wo àwọn ipò ajániláyà tó bá ara rẹ̀?
6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “ìgbà sísunkún àti ìgbà rírẹ́rìn-ín” ń bẹ, ta ni kò fẹ́ ìgbà rírẹ́rìn-ín ju ìgbà sísunkún lọ? (Oníwàásù 3:4) Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé, lọ́nà tó pọ̀ jù lọ, ayé tó ń pani lẹ́kún là ń gbé. Àwọn ìròyìn tí ń bani nínú jẹ́ làwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ń gbé jáde. Jìnnìjìnnì máa ń bò wá nígbà táa bá gbọ́ nípa àwọn èwe tí ń yìnbọn pa ẹlẹgbẹ́ wọn nílé ìwé, táa bá gbọ́ nípa àwọn òbí tí ń bá ọmọ wọn ṣe, àwọn ọ̀dàlúrú tí ń pa àwọn tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ tàbí tí wọ́n ń sọ wọ́n di aláàbọ̀ ara, àti nígbà táa bá gbọ́ nípa àwọn àjálù lóríṣiríṣi, èyí tí ń run ẹ̀mí àwọn ènìyàn, tó sì ń ba dúkìá jẹ́. Àwọn ọmọdé tébi ń pa, tí ojú wọn ti sá wọnú àti àwọn olùwá-ibi-ìsádi táa ti lé kúrò nílùú wọn, tí wọ́n ti bẹ́sẹ̀ wọn sọ̀rọ̀ là ń rí lórí tẹlifíṣọ̀n. Àwọn ọ̀rọ̀ tí a kì í gbọ́ tẹ́lẹ̀, irú bí ìpẹ̀yàrun, àrùn éèdì, fífi kòkòrò àrùn ṣe ohun ìjà ogun, àti omíyalé El Niño kò jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ mọ́—ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló sì ń fa jàǹbá tirẹ̀.
7 Kò sí iyè méjì nípa rẹ̀ pé, ayé tí à ń gbé lónìí kún fún ìbànújẹ́ àti ìmí ẹ̀dùn. Síbẹ̀síbẹ̀, bí ẹni pé wọn ò fẹ́ ká mọ bí ọ̀ràn náà ti le tó, àwọn eré tí kò fi ẹ̀mí ìbìkítà nípa ẹni hàn, eré tí kò lórí, tí kò nídìí, nígbà mìíràn eré oníṣekúṣe àti oníwà ipá làwọn eléré ń ṣe láti lè kó wa ṣìnà, ká lè gbàgbé pé ìyà ńlá ń jẹ àwọn mìíràn. Ṣùgbọ́n, ẹ máà jẹ́ ká ka àwàdà òpònú àti ẹ̀rín ẹlẹ́yà táà ń wò nínú irú àwọn eré bẹ́ẹ̀ sí ojúlówó ayọ̀. Ayé Sátánì kò lè mú ìdùnnú tó jẹ́ èso ẹ̀mí Ọlọ́run wá rárá.—Gálátíà 5:22, 23; Éfésù 5:3, 4.
8. Nínú ẹkún àti ẹ̀rín, èwo ló yẹ káwọn Kristẹni fara wọn fún lónìí? Ṣàlàyé.
8 Táa bá mọ bí ìbànújẹ́ ti pọ̀ tó nínú ayé lónìí, a ó mọ̀ pé kì í ṣe àkókò ẹ̀rín la wà yìí rárá. Àkókò yìí kọ́ ló yẹ ká máa fojoojúmọ́ ṣeré ìdárayá, ká máa ṣeré ìnàjú tàbí tí a óò jẹ́ kí “ṣíṣe fàájì” gba ipò lílépa àwọn ohun tẹ̀mí mọ́ wa lọ́wọ́. (Fi wé Oníwàásù 7:2-4.) Kí “àwọn tí ń lo ayé” dà bí “àwọn tí kò lò ó dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́,” ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wí. Èé ṣe? Nítorí “ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà.” (1 Kọ́ríńtì 7:31) Bí ilẹ̀ ọjọ́ kan bá ti ń mọ́, àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ máa gbé ìgbésí ayé wọn pẹ̀lú ìdánilójú pé àkókò tí à ń gbé yìí kì í ṣe àkókò tí èèyàn lè fi ṣeré.—Fílípì 4:8.
Bí Wọ́n Tilẹ̀ Ń Sunkún, Wọ́n Láyọ̀ Tòótọ́!
9. Ipò bíbani nínú jẹ́ wo ló gbayé kan ṣáájú Àkúnya Omi, kí sì ni ìyẹn túmọ̀ sí fún wa lóde òní?
9 Àwọn tí wọ́n gbé ayé nígbà Àkúnya Omi tó kárí ayé láyé ọjọ́sí kò ka ìwàláàyè sí ohun dan-in dan-in. Ìgbòkègbodò wọn ojoojúmọ́ ni wọ́n gbájú mọ́, wọn kò sì sunkún lórí “ìwà búburú ènìyàn [tó] pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ ayé,” wọ́n dágunlá sí kíkún “ti ilẹ̀ ayé wá kún fún ìwà ipá.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:5, 11) Jésù tọ́ka sí ipò tó bani nínú jẹ́ yẹn, ó sì tún sọ pé àwọn ènìyàn òde òní yóò ní irú ìwà bẹ́ẹ̀. Ó wá kìlọ̀ pé: “Bí wọ́n ti wà ní ọjọ́ wọnnì ṣáájú ìkún omi, wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì; wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí.”—Mátíù 24:38, 39.
10. Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó gbé ayé lọ́jọ́ Hágáì ṣe fi hàn pé wọn ò ní ìmọrírì fún àkókò tí Jèhófà yàn?
10 Ní nǹkan bí àádọ́jọ dín lẹ́gbàá [1,850] ọdún lẹ́yìn Ìkún Omi, nígbà ayé Hágáì, ọ̀pọ̀ ọmọ Ísírẹ́lì ló fi irú ìwà àìka ohun tẹ̀mí sí bẹ́ẹ̀ hàn. Nígbà tó kúkú jẹ́ pé ire ara tiwọn ni wọ́n ń wá kiri, wọn ò mọ̀ pé àkókò táwọn ń gbé yẹn ló yẹ káwọn fi ire Jèhófà sí ipò kìíní. A kà pé: “Ní ti àwọn ènìyàn yìí, wọ́n sọ pé: ‘Àkókò kò tíì tó, àkókò tí a óò kọ́ ilé Jèhófà.’ Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti wá nípasẹ̀ Hágáì wòlíì, pé: ‘Àkókò ha nìyí fún ẹ̀yin láti máa gbé nínú àwọn ilé yín tí a fi igi pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe ọ̀ṣọ́ sí, nígbà tí ilé yìí wà ní ipò ahoro? Wàyí o, èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, “Ẹ fi ọkàn-àyà yín sí àwọn ọ̀nà yín.”’”—Hágáì 1:1-5.
11. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?
11 Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní, tí Jèhófà fún ní ẹrù iṣẹ́ àti àǹfààní bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà ayé Hágáì, yóò dára báa bá lè fi ọkàn-àyà wa sí àwọn ọ̀nà wa, kí a sì ronú dáadáa nípa ọ̀nà ìgbésí ayé wa. Ǹjẹ́ a ń ‘sunkún’ lórí ipò ayé àti ẹ̀gàn tó ń mú wá sórí orúkọ Ọlọ́run? Ǹjẹ́ o máa ń dùn wá nígbà táwọn èèyàn bá sọ pé Ọlọ́run ò sí tàbí tí wọn ò tiẹ̀ bìkítà rárá láti pa àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ mọ́? Ǹjẹ́ a máa ń ní irú ẹ̀mí tí àwọn tí a sàmì sí lórí nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lé lẹ́gbàá [2,500] ọdún sẹ́yìn ní? A kà nípa wọn pé: “Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún [ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì akọ̀wé] pé: ‘La àárín ìlú ńlá náà já, àárín Jerúsálẹ́mù, kí o sì sàmì sí iwájú orí àwọn ènìyàn tí ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń kérora nítorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí tí a ń ṣe ní àárín rẹ̀.’”—Ìsíkíẹ́lì 9:4.
12. Báwo ni Ìsíkíẹ́lì 9:5, 6 ṣe ṣe pàtàkì tó fún àwọn ènìyàn lónìí?
12 Bí àkọsílẹ̀ yìí ṣe ṣe pàtàkì tó fún wa lónìí túbọ̀ ń ṣe kedere nígbà tí a ka ìtọ́ni táa fún àwọn ọkùnrin mẹ́fà tí wọ́n ní ohun ìjà tó lè fọ́ni túútúú lọ́wọ́ pé: “Ẹ la ìlú ńlá náà já tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, kí ẹ sì ṣe ìkọlù. Kí ojú yín má ṣe káàánú, ẹ má sì ní ìyọ́nú. Àgbà ọkùnrin, ọ̀dọ́kùnrin àti wúńdíá àti àwọn ọmọ kéékèèké àti àwọn obìnrin ni kí ẹ pa dà nù—títí dórí rírun wọ́n. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sún mọ́ ènìyàn èyíkéyìí tí àmì náà wà lórí rẹ̀, láti ibùjọsìn mi ni kí ẹ sì ti bẹ̀rẹ̀.” (Ìsíkíẹ́lì 9:5, 6) Mímọ̀ táa bá mọ̀ dájú pé òní gan-an ni àkókò sísunkún ni yóò pinnu bóyá a ó la ìpọ́njú ńlá tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán yìí já tàbí a ò ní là á já.
13, 14. (a) Irú àwọn èèyàn wo ni Jésù pè ní aláyọ̀? (b) Ṣàlàyé ìdí tóo fi rò pé àpèjúwe yìí bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mu?
13 Àmọ́ ṣá o, ti pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń “sunkún” lórí ipò ìkáàánú tí ayé wà kò ba ayọ̀ wọn jẹ́. Ayọ̀ wọn ń kún ni! Àwọn ni àwùjọ ènìyàn tó láyọ̀ jù lọ lórí ilẹ̀ ayé lónìí. Jésù jẹ́ ká mọ ohun tó lè fúnni láyọ̀, nígbà tó wí pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, . . . àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, . . . àwọn onínú tútù, . . . àwọn tí ebi ń pa, tí òùngbẹ sì ń gbẹ fún òdodo, . . . àwọn aláàánú, . . . àwọn ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn-àyà, . . . àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà, . . . àwọn tí a ti ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo.” (Mátíù 5:3-10) Ẹ̀rí rẹpẹtẹ ló wà tó fi hàn pé lápapọ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ni àpèjúwe yìí bá mu, ó bá wọn mu ju ètò ẹ̀sìn èyíkéyìí mìíràn lọ.
14 Pàápàá jù lọ láti ìgbà táa ti mú ìjọsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò lọ́dún 1919 ni àwọn ènìyàn Jèhófà, tí wọ́n jẹ́ aláyọ̀, ti rí i pé ó yẹ káwọn máa ‘rẹ́rìn-ín.’ Nípa tẹ̀mí, ayọ̀ wọn kún bíi ti àwọn tí wọ́n padà dé láti Bábílónì ní ọ̀rúndún kẹfà ṣáájú Sànmánì Tiwa: “Nígbà tí Jèhófà kó àwọn òǹdè Síónì jọ padà, àwa dà bí àwọn tí ń lá àlá. Ní àkókò yẹn, ẹnu wa kún fún ẹ̀rín, ahọ́n wa sì kún fún igbe ìdùnnú. . . . Jèhófà ti ṣe ohun ńlá nínú ohun tí ó ṣe fún wa. Àwa ti kún fún ìdùnnú.” (Sáàmù 126:1-3) Síbẹ̀, níbi tí wọ́n ti ń rẹ́rìn-ín tẹ̀mí yìí pàápàá, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fọgbọ́n fi bí àkókò tí àwọn ń gbé ti ṣe pàtàkì tó sọ́kàn. Gbàrà tí ayé tuntun bá ti dé, tí àwọn olùgbé ayé sì ti “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí,” nígbà náà, àkókò yóò dé nígbà tí ẹ̀rín yóò rọ́pò ẹkún títí láé.—1 Tímótì 6:19; Ìṣípayá 21:3, 4.
“Ìgbà Gbígbánimọ́ra àti Ìgbà Yíyẹra fún Gbígbánimọ́ra”
15. Èé ṣe tí àwọn Kristẹni fi máa ń ṣàṣàyàn àwọn ọ̀rẹ́?
15 Àwọn Kristẹni máa ń ṣàṣàyàn àwọn tí wọ́n ń bá dọ́rẹ̀ẹ́. Wọ́n máa ń fi ìkìlọ̀ Pọ́ọ̀lù sọ́kàn pé: “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba sì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.”—Òwe 13:20.
16, 17. Ojú wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wo bíbánidọ́rẹ̀ẹ́, ìfẹ́sọ́nà, àti ìgbéyàwó, èé sì ti ṣe?
16 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kì í kàn yan ọ̀rẹ́ ṣáá, àwọn tí wọ́n ní irú ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà àti òdodo rẹ̀, làwọn ń yàn lọ́rẹ̀ẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọrírì ìfararora àwọn ọ̀rẹ́ wọn, tí wọ́n sì máa ń gbádùn rẹ̀, wọ́n ń fọgbọ́n yẹra fún ẹ̀mí ṣe-bóo-ti-fẹ́, ẹ̀mí ìgbọ̀jẹ̀gẹ́, tó gbalẹ̀ kan láwọn orílẹ̀-èdè kan tó bá dọ̀ràn ìfẹ́sọ́nà. Kàkà tí wọn yóò fi kà á sí ọ̀ràn ṣeréṣeré, wọ́n ka ìfẹ́sọ́nà sí ìgbésẹ̀ pàtàkì tí ń yọrí sí ìgbéyàwó, tó jẹ́ pé kìkì àwọn tí wọ́n ti múra tán ní ti ara, ní ti èrò orí, àti nípa tẹ̀mí—tí wọ́n sì lómìnira láti ṣe bẹ́ẹ̀ lójú ìwòye Ìwé Mímọ́—láti wọnú ìbátan tí yóò wà pẹ́ títí, ni wọ́n ń dáwọ́ lé e.—1 Kọ́ríńtì 7:36.
17 Àwọn kan lè rò pé àṣà àtijọ́ ló jẹ́ láti ní irú ojú ìwòye yẹn nípa ìfẹ́sọ́nà àti ìgbéyàwó. Ṣùgbọ́n àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í jẹ́ kí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe nípa lórí àwọn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ yan ọ̀rẹ́ tàbí tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ìpinnu nípa ìfẹ́sọ́nà àti ìgbéyàwó. Wọ́n mọ̀ pé “a fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Mátíù 11:19) Wọ́n mọ̀ pé kò sẹ́ni tó gbọ́n tó Jèhófà, nítorí náà ọwọ́ dan-in dan-in ni wọ́n fi mú ìmọ̀ràn rẹ̀ tó sọ pé kí wọ́n gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 7:39; 2 Kọ́ríńtì 6:14) Wọ́n ń yẹra fún kíkù gìrì ṣègbéyàwó pẹ̀lú èrò òdì náà pé bí àjọṣe náà ò bá wọ̀, ìkọ̀sílẹ̀ lè fòpin sí i tàbí kóníkálùkù wábi gbà. Wọ́n máa ń mú sùúrù láti wá ẹni tí àjọgbé wọn yóò tu àwọn méjèèjì lára, torí wọ́n mọ̀ pé gbàrà tí wọ́n bá ti jẹ́jẹ̀ẹ́ ìgbéyàwó, òfin Jèhófà ti dè wọ́n, òfin tó sọ pé: “Tí ó fi jẹ́ pé wọn kì í ṣe méjì mọ́, bí kò ṣe ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”—Mátíù 19:6; Máàkù 10:9.
18. Kí ló lè jẹ́ ìpìlẹ̀ ìgbéyàwó aláyọ̀?
18 Ìgbéyàwó jẹ́ àdéhùn gbére, àdéhùn tó ń béèrè pé ká rò ó dáradára. Ó bọ́gbọ́n mu lóòótọ́ pé ọkùnrin kan yóò bi ara rẹ̀ pé, ‘Ṣé ẹni tí ọkàn mi fẹ́ gan-an nìyí?’ Ṣùgbọ́n ó tún ṣe pàtàkì kó béèrè pé, ‘Ṣé èmi gan-an lọkàn obìnrin yìí fẹ́? Ṣé Kristẹni tó dàgbà dénú, tó lè bójú tó àìní rẹ̀ nípa tẹ̀mí ni mí?’ Àwọn ẹni méjì tí ń fẹ́ra wọn sọ́nà ní ẹrù iṣẹ́ kan níwájú Jèhófà, ìyẹn ni láti jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí, kí wọ́n lè fìdí ìgbéyàwó kan tó dúró dáadáa, tí Ọlọ́run yóò sì fọwọ́ sí, múlẹ̀. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Kristẹni tọkọtaya ló lè jẹ́rìí sí i pé, iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ni ìpìlẹ̀ tó dára jù lọ fún ìgbéyàwó aláyọ̀, nítorí ẹ̀mí fífúnni dípò rírí gbà tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ní.
19. Èé ṣe tí àwọn Kristẹni kan fi dúró lápọ̀n-ọ́n?
19 Àwọn Kristẹni kan ‘yẹra fún gbígbánimọ́ra’ nípa yíyàn láti wà lápọ̀n-ọ́n nítorí ìhìn rere. (Oníwàásù 3:5) Àwọn mìíràn sọ pé àwọn yóò ní sùúrù ná títí dìgbà tí àwọn bá rí i pé àwọn tóótun nípa tẹ̀mí láti fa ojú ẹni tó bá wọn mu mọ́ra, kí àwọn tó ṣègbéyàwó. Ṣùgbọ́n o, ẹ máà jẹ́ ká gbàgbé àwọn Kristẹni àpọ́n kan o, àwọn tó jẹ́ pé ìfararora àti àǹfààní inú ìgbéyàwó ń wu àwọn náà, ṣùgbọ́n tí wọn ò tíì lẹ́nì kan. Ẹ jẹ́ ko dá wa lójú pé inú Jèhófà dùn sí wọn ní ti pé bí ṣíṣègbéyàwó ti wà lọ́kàn wọn tó yẹn, wọn kò fi ìlànà àtọ̀runwá báni dọ́rẹ̀ẹ́. Yóò dára táa bá lè fi ìmọrírì hàn fún ìdúróṣinṣin wọn, kí a sì fún wọn ní ìtìlẹyìn tó yẹ.
20. Èé ṣe tí àwọn tọkọtaya pàápàá nígbà mìíràn ṣe lè “yẹra fún gbígbánimọ́ra”?
20 Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ yẹ kí àwọn tọkọtaya pàápàá ‘máa yẹra fún gbígbánimọ́ra’ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan? Dájúdájú ó yẹ bẹ́ẹ̀ láwọn ọ̀nà kan, nítorí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Èyí ni mo sọ, ẹ̀yin ará, pé àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù. Láti ìsinsìnyí lọ, kí àwọn tí wọ́n ní aya dà bí ẹni pé wọn kò ní.” (1 Kọ́ríńtì 7:29) Nítorí èyí, nígbà mìíràn, wọ́n ó fi ayọ̀ àti ìbùkún ìgbéyàwó sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan ná, kí wọ́n lè ráyè gbájú mọ́ àwọn ẹrù iṣẹ́ tó jẹ́ ti ìṣàkóso Ọlọ́run. Ojú ìwòye tó ṣe déédéé lórí ọ̀ràn yìí kò ní sọ ìgbéyàwó wa di ahẹrẹpẹ ṣùgbọ́n yóò fún un lókun nítorí pé yóò máa ṣèrànwọ́ láti rán tọkọtaya létí pé Jèhófà ni wọ́n gbọ́dọ̀ máa wò gẹ́gẹ́ bí ẹni náà gan-an tó lè mú àjọṣe wọn fìdí múlẹ̀ gbọn-in.—Oníwàásù 4:12.
21. Èé ṣe tí kò fi yẹ ká ṣe lámèyítọ́ àwọn tọkọtaya ní ti ọ̀ràn abímọ-a-ò-bímọ?
21 Ní àfikún sí i, àwọn tọkọtaya kan kò bímọ, kí wọ́n bàa lè lómìnira díẹ̀ láti máa bá iṣẹ́ ìsìn wọn sí Ọlọ́run lọ. Ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ gidi ni wọ́n fi hàn yìí, Jèhófà yóò sì san wọ́n lẹ́san rere. Ohun kan rèé o, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì fúnni níṣìírí láti wà ní àpọ́n nítorí ìhìn rere, kò sọ̀rọ̀ tààrà lórí wíwà láìbímọ nítorí ìhìn rere. (Mátíù 19:10-12; 1 Kọ́ríńtì 7:38; fi wé Mátíù 24:19 àti Lúùkù 23:28-30.) Nípa báyìí, àwọn lọ́kọláya ni yóò fúnra wọn pinnu ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe, wọ́n a sì gbé èyí ka ipò wọn àti ẹ̀rí-ọkàn wọn. Ohun yòówù kí tọkọtaya pinnu, kò sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ ṣe lámèyítọ́ wọn.
22. Kí ló ṣe pàtàkì fún wa láti pinnu?
22 Bẹ́ẹ̀ ni, “ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, àní ìgbà fún gbogbo àlámọ̀rí lábẹ́ ọ̀run.” Kódà “ìgbà ogun àti ìgbà àlàáfíà” ń bẹ. (Oníwàásù 3:1, 8) Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe pàtàkì fún wa láti mọ àkókò táa wà báyìí nínú méjèèjì.
Ṣé O Lè Ṣàlàyé?
◻ Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì fún wa láti mọ̀ pé “ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún”?
◻ Èé ṣe tí òní gan-an fi jẹ́ “ìgbà sísunkún”?
◻ Èé ṣe tó fi jẹ́ pé bí àwọn Kristẹni tilẹ̀ ń ‘sunkún,’ síbẹ̀, wọ́n láyọ̀?
◻ Báwo làwọn Kristẹni kan ṣe fi hàn pé àwọn ka àkókò ìsinsìnyí sí “ìgbà láti yẹra fún gbígbánimọ́ra”?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni ń ‘sunkún’ nítorí ipò tí ayé wà. . .
. . . kò sí àní-àní pé, àwọn lènìyàn tó láyọ̀ jù lọ lágbàáyé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíḱún ni ìpìlẹ̀ tó dára jù lọ fún ìgbéyàwó aláyọ̀