Àwọn Ọba Kìíní
8 Ní àkókò yẹn, Sólómọ́nì pe àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ,+ gbogbo olórí àwọn ẹ̀yà àti àwọn olórí agbo ilé ní Ísírẹ́lì.+ Wọ́n wá sọ́dọ̀ Ọba Sólómọ́nì ní Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n lè gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà láti Ìlú Dáfídì,+ ìyẹn Síónì.+ 2 Gbogbo èèyàn Ísírẹ́lì pé jọ síwájú Ọba Sólómọ́nì nígbà àjọyọ̀* ní oṣù Étánímù,* ìyẹn oṣù keje.+ 3 Nítorí náà, gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì wá, àwọn àlùfáà sì gbé Àpótí náà.+ 4 Wọ́n gbé Àpótí Jèhófà wá àti àgọ́ ìpàdé+ pẹ̀lú gbogbo nǹkan èlò mímọ́ tó wà nínú àgọ́. Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì ló gbé wọn wá. 5 Ọba Sólómọ́nì àti gbogbo àpéjọ Ísírẹ́lì, ìyẹn àwọn tó ní kí wọ́n pàdé òun, wà níwájú Àpótí náà. Àgùntàn àti màlúù tí wọ́n fi rúbọ+ pọ̀ débi pé wọn ò ṣeé kà, wọn ò sì níye.
6 Nígbà náà, àwọn àlùfáà gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà wá sí àyè rẹ̀,+ ní yàrá inú lọ́hùn-ún ilé náà, ìyẹn Ibi Mímọ́ Jù Lọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ ìyẹ́ apá àwọn kérúbù.+
7 Torí náà, ìyẹ́ apá àwọn kérúbù náà nà jáde sórí ibi tí Àpótí náà wà, tó fi jẹ́ pé àwọn kérúbù náà ṣíji bo Àpótí náà àti àwọn ọ̀pá rẹ̀.+ 8 Àwọn ọ̀pá+ náà gùn débi pé a lè rí orí wọn láti Ibi Mímọ́ ní iwájú yàrá inú lọ́hùn-ún, ṣùgbọ́n a kò lè rí wọn láti òde. Wọ́n sì wà níbẹ̀ títí di òní yìí. 9 Kò sí nǹkan míì nínú Àpótí náà àfi wàláà òkúta méjì+ tí Mósè kó síbẹ̀+ ní Hórébù, nígbà tí Jèhófà bá àwọn èèyàn Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú+ bí wọ́n ṣe ń jáde bọ̀ láti ilẹ̀ Íjíbítì.+
10 Nígbà tí àwọn àlùfáà jáde láti ibi mímọ́, ìkùukùu+ kún ilé Jèhófà.+ 11 Àwọn àlùfáà kò lè dúró ṣe iṣẹ́ wọn nítorí ìkùukùu náà, torí pé ògo Jèhófà kún ilé Jèhófà.+ 12 Ní àkókò yẹn, Sólómọ́nì sọ̀rọ̀, ó ní: “Jèhófà sọ pé inú ìṣúdùdù tó kàmàmà+ ni òun á máa gbé. 13 Mo ti kọ́ ilé ológo kan parí fún ọ, ibi tó fìdí múlẹ̀ tí wàá máa gbé títí láé.”+
14 Lẹ́yìn náà, ọba yíjú pa dà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í súre fún gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, bí gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì ṣe wà ní ìdúró.+ 15 Ó sọ pé: “Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tó fi ẹnu ara rẹ̀ ṣèlérí fún Dáfídì bàbá mi, tó sì fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú un ṣẹ, tó sọ pé, 16 ‘Láti ọjọ́ tí mo ti mú àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì, mi ò yan ìlú kankan nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí màá kọ́ ilé sí fún orúkọ mi, kí ó lè máa wà níbẹ̀,+ ṣùgbọ́n mo ti yan Dáfídì láti ṣe olórí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.’ 17 Ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn Dáfídì bàbá mi pé kí ó kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ 18 Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ fún Dáfídì bàbá mi pé, ‘Ìfẹ́ ọkàn rẹ ni pé kí o kọ́ ilé fún orúkọ mi, ó sì dára bó ṣe ń wù ọ́ yìí. 19 Àmọ́, ìwọ kọ́ ló máa kọ́ ilé náà, ọmọ tí o máa bí* ló máa kọ́ ilé fún orúkọ mi.’+ 20 Jèhófà ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, torí mo ti jọba ní ipò Dáfídì bàbá mi, mo sì jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì, bí Jèhófà ti ṣèlérí. Mo tún kọ́ ilé kan fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ 21 mo sì ṣe àyè kan síbẹ̀ fún Àpótí tí májẹ̀mú+ Jèhófà wà nínú rẹ̀, èyí tó bá àwọn baba ńlá wa dá nígbà tó ń mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.”
22 Sólómọ́nì wá dúró níwájú pẹpẹ Jèhófà ní iwájú gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, ó tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ sí ọ̀run,+ 23 ó sì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kò sí Ọlọ́run tó dà bí rẹ+ ní ọ̀run lókè tàbí lórí ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀, ò ń pa májẹ̀mú mọ́, o sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀+ hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ tó ń fi gbogbo ọkàn wọn rìn níwájú rẹ.+ 24 O ti mú ìlérí tí o ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì bàbá mi ṣẹ. Ẹnu rẹ lo fi ṣe ìlérí náà, o sì ti fi ọwọ́ ara rẹ mú un ṣẹ lónìí yìí.+ 25 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, mú ìlérí tí o ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì bàbá mi ṣẹ, nígbà tí o sọ pé: ‘Kò ní ṣàìsí ọkùnrin kan láti ìlà ìdílé rẹ níwájú mi tí yóò máa jókòó sórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì, bí àwọn ọmọ rẹ bá ṣáà ti ń fiyè sí ọ̀nà wọn, tí wọ́n sì ń rìn níwájú mi bí ìwọ náà ṣe rìn níwájú mi.’+ 26 Ní báyìí, ìwọ Ọlọ́run Ísírẹ́lì, jọ̀wọ́ mú ìlérí tí o ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì bàbá mi ṣẹ.
27 “Àmọ́, ṣé Ọlọ́run máa gbé inú ayé ni?+ Wò ó! Àwọn ọ̀run, àní, ọ̀run àwọn ọ̀run, kò lè gbà ọ́;+ ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti ilé tí mo kọ́ yìí!+ 28 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run mi, fiyè sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún ojú rere, kí o sì fetí sí igbe ìránṣẹ́ rẹ fún ìrànlọ́wọ́ àti àdúrà tó ń gbà níwájú rẹ lónìí. 29 Kí ojú rẹ wà lára ilé yìí tọ̀sántòru, lára ibi tí o sọ pé, ‘Orúkọ mi yóò wà níbẹ̀,’+ láti fetí sí àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà ní ìdojúkọ ibí yìí.+ 30 Kí o gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ fún ojú rere àti ẹ̀bẹ̀ àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì, tí wọ́n ń sọ nínú àdúrà ní ìdojúkọ ibí yìí; kí o gbọ́ láti ibi tí ò ń gbé ní ọ̀run;+ kí o gbọ́, kí o sì dárí jì wọ́n.+
31 “Nígbà tí ẹnì kan bá ṣẹ ọmọnìkejì rẹ̀, tó mú kó búra,* tó sì mú kó wà lábẹ́ ìbúra* náà, tó bá wá síwájú pẹpẹ rẹ nínú ilé yìí nígbà tó ṣì wà lábẹ́ ìbúra* náà,+ 32 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o gbé ìgbésẹ̀, kí o sì ṣe ìdájọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ, kí o pe ẹni burúkú ní ẹlẹ́bi,* kí o sì jẹ́ kí ohun tó ṣe dà lé e lórí, kí o pe olódodo ní aláìṣẹ̀,* kí o sì san èrè òdodo rẹ̀ fún un.+
33 “Nígbà tí ọ̀tá bá ṣẹ́gun àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì torí pé wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ sí ọ,+ tí wọ́n wá pa dà sọ́dọ̀ rẹ, tí wọ́n gbé orúkọ rẹ ga,+ tí wọ́n gbàdúrà, tí wọ́n sì bẹ̀ ọ́ nínú ilé yìí pé kí o ṣojú rere sí àwọn,+ 34 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì jì wọ́n, kí o sì mú wọn pa dà wá sí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wọn.+
35 “Nígbà tí ọ̀run bá sé pa, tí òjò kò sì rọ̀+ torí pé wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ sí ọ,+ tí wọ́n wá gbàdúrà ní ìdojúkọ ibí yìí, tí wọ́n gbé orúkọ rẹ ga, tí wọ́n sì yí pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn torí pé o rẹ̀ wọ́n wálẹ̀,*+ 36 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ jì wọ́n, ìyẹn àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì, nítorí pé wàá tọ́ wọn sí ọ̀nà+ tó yẹ kí wọ́n máa rìn; kí o sì rọ̀jò sórí ilẹ̀ rẹ+ tí o fún àwọn èèyàn rẹ láti jogún.
37 “Bí ìyàn bá mú ní ilẹ̀ náà+ tàbí tí àjàkálẹ̀ àrùn bá jà, tí ooru tó ń jó ewéko gbẹ tàbí èbíbu+ bá wà, tí ọ̀wọ́ eéṣú tàbí ọ̀yánnú eéṣú* bá wà tàbí tí ọ̀tá wọn bá dó tì wọ́n ní ìlú èyíkéyìí ní ilẹ̀ náà* tàbí tí ìyọnu èyíkéyìí tàbí àrùn bá wáyé,+ 38 àdúrà èyíkéyìí tí ì báà jẹ́, ìbéèrè fún ojú rere+ èyíkéyìí tí ẹnikẹ́ni bá béèrè tàbí èyí tí gbogbo àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì bá béèrè (nítorí pé kálukú ló mọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀),+ tí wọ́n bá tẹ́ ọwọ́ wọn sí apá ibi tí ilé yìí wà, 39 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run, ibi tí ò ń gbé,+ kí o dárí jì wọ́n,+ kí o sì gbé ìgbésẹ̀; kí o san èrè fún kálukú gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà rẹ̀,+ nítorí pé o mọ ọkàn rẹ̀ (ìwọ nìkan lo mọ ọkàn gbogbo èèyàn lóòótọ́),+ 40 kí wọ́n lè máa bẹ̀rù rẹ ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n á fi gbé lórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wa.
41 “Bákan náà, ní ti àjèjì tí kì í ṣe ara àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì, àmọ́ tó wá láti ilẹ̀ tó jìnnà nítorí orúkọ rẹ*+ 42 (nítorí wọ́n máa gbọ́ nípa orúkọ ńlá rẹ+ àti nípa ọwọ́ agbára rẹ pẹ̀lú apá rẹ tó nà jáde), tí ó sì wá gbàdúrà ní ìdojúkọ ilé yìí, 43 nígbà náà, kí o fetí sílẹ̀ láti ọ̀run, ibi tí ò ń gbé,+ kí o sì ṣe gbogbo ohun tí àjèjì náà béèrè lọ́wọ́ rẹ, kí gbogbo aráyé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù rẹ,+ bí àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì ti ń ṣe, kí wọ́n sì mọ̀ pé a ti fi orúkọ rẹ pe ilé tí mo kọ́ yìí.
44 “Tí àwọn èèyàn rẹ bá lọ bá ọ̀tá wọn jà lójú ogun bí o ṣe rán wọn,+ tí wọ́n sì gbàdúrà+ sí Jèhófà ní ìdojúkọ ìlú tí o yàn+ àti ilé tí mo kọ́ fún orúkọ rẹ,+ 45 nígbà náà, kí o gbọ́ àdúrà wọn láti ọ̀run àti ẹ̀bẹ̀ wọn pé kí o ṣojú rere sí àwọn, kí o sì ṣe ìdájọ́ nítorí wọn.
46 “Tí wọ́n bá ṣẹ̀ ọ́ (nítorí kò sí èèyàn tí kì í dẹ́ṣẹ̀),+ tí inú rẹ ru sí wọn, tí o fi wọ́n sílẹ̀ fún ọ̀tá, tí àwọn tó mú wọn sì kó wọn lẹ́rú lọ si ilẹ̀ ọ̀tá, bóyá èyí tó jìnnà tàbí èyí tó wà nítòsí;+ 47 tí wọ́n bá ro inú ara wọn wò ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ,+ tí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ rẹ,+ tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ pé kí o ṣojú rere sí àwọn ní ilẹ̀ àwọn tó mú wọn lẹ́rú,+ tí wọ́n sọ pé, ‘A ti ṣẹ̀, a sì ti ṣàṣìṣe; a ti ṣe ohun búburú,’+ 48 tí wọ́n sì fi gbogbo ọkàn wọn+ àti gbogbo ara* wọn pa dà sọ́dọ̀ rẹ ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá tó kó wọn lọ sóko ẹrú, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ ní ìdojúkọ ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wọn àti ìlú tí o yàn àti ilé tí mo kọ́ fún orúkọ rẹ,+ 49 nígbà náà, láti ibi tí ò ń gbé ní ọ̀run,+ kí o gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn pé kí o ṣojú rere sí àwọn, kí o sì ṣe ìdájọ́ nítorí wọn, 50 kí o dárí ji àwọn èèyàn rẹ tó ṣẹ̀ ọ́, kí o dárí gbogbo bí wọ́n ṣe tẹ ìlànà rẹ lójú jì wọ́n. Kí o jẹ́ kí wọ́n rójú àánú àwọn tó kó wọn lẹ́rú, kí wọ́n sì ṣàánú wọn+ 51 (nítorí èèyàn rẹ àti ogún rẹ ni wọ́n,+ àwọn tí o mú jáde kúrò ní Íjíbítì,+ láti ibi iná tí a fi ń yọ́ irin).+ 52 Kí o ṣí ojú rẹ sí ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ pé kí o ṣojú rere sí òun+ àti sí ẹ̀bẹ̀ àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì pé kí o ṣojú rere sí àwọn, kí o máa fetí sí wọn nígbàkigbà tí wọ́n bá ké pè ọ́.*+ 53 Nítorí o ti yà wọ́n sọ́tọ̀ láti jẹ́ ogún rẹ nínú gbogbo aráyé,+ bí o ṣe gba ẹnu Mósè ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀, nígbà tí ò ń mú àwọn baba ńlá wa jáde kúrò ní Íjíbítì, ìwọ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”
54 Gbàrà tí Sólómọ́nì parí gbogbo àdúrà yìí sí Jèhófà àti ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún ojú rere, ó dìde kúrò níwájú pẹpẹ Jèhófà, níbi tí ó kúnlẹ̀ sí, tí ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ sí ọ̀run.+ 55 Ó dúró, ó gbóhùn sókè, ó sì súre fún gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, ó ní: 56 “Ìyìn ni fún Jèhófà, tí ó fún àwọn èèyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì ní ibi ìsinmi bí ó ti ṣèlérí.+ Kò sí ìkankan nínú gbogbo ìlérí tí ó ṣe nípasẹ̀ Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó lọ láìṣẹ.+ 57 Kí Jèhófà Ọlọ́run wa wà pẹ̀lú wa, bí ó ṣe wà pẹ̀lú àwọn baba ńlá wa.+ Kí ó má ṣe fi wá sílẹ̀, kí ó má sì pa wá tì.+ 58 Kí ó mú kí ọkàn wa máa fà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀,+ kí a lè máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, kí a sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, àwọn ìlànà rẹ̀ àti àwọn ìdájọ́ rẹ̀ tí ó pa láṣẹ pé kí àwọn baba ńlá wa máa pa mọ́. 59 Kí àwọn ọ̀rọ̀ tí mo fi bẹ Jèhófà fún ojú rere máa wà lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa tọ̀sántòru, kí ó lè máa ṣe ìdájọ́ nítorí ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn èèyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan bá ṣe gbà, 60 kí gbogbo aráyé lè mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.+ Kò sí ẹlòmíì!+ 61 Torí náà, ẹ fi gbogbo ọkàn yín+ sin Jèhófà Ọlọ́run wa láti máa rìn nínú àwọn ìlànà rẹ̀ àti láti máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ bíi ti òní yìí.”
62 Ọba àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ wá rú ẹbọ púpọ̀ níwájú Jèhófà.+ 63 Sólómọ́nì rú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ sí Jèhófà: Ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) màlúù àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àgùntàn ni ó fi rúbọ. Bí ọba àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ṣayẹyẹ ṣíṣí ilé Jèhófà+ nìyẹn. 64 Ní ọjọ́ yẹn, ọba ní láti ya àárín àgbàlá tó wà níwájú ilé Jèhófà sí mímọ́, torí ibẹ̀ ló ti máa rú ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà pẹ̀lú àwọn apá tó lọ́ràá lára àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀, nítorí pé pẹpẹ bàbà+ tó wà níwájú Jèhófà kéré ju ohun tó lè gba àwọn ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà pẹ̀lú àwọn apá tó lọ́ràá+ lára àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀. 65 Ní àkókò yẹn, Sólómọ́nì ṣe àjọyọ̀+ náà pẹ̀lú gbogbo Ísírẹ́lì, wọ́n jẹ́ ìjọ ńlá láti Lebo-hámátì* títí dé Àfonífojì Íjíbítì,+ wọ́n wà níwájú Jèhófà Ọlọ́run wa fún ọjọ́ méje àti ọjọ́ méje míì, ó jẹ́ ọjọ́ mẹ́rìnlá (14) lápapọ̀. 66 Ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé e,* ó ní kí àwọn èèyàn náà máa lọ, wọ́n súre fún ọba, wọ́n sì lọ sí ilé wọn, inú wọn ń dùn, ayọ̀ sì kún ọkàn wọn nítorí gbogbo oore+ tí Jèhófà ṣe fún Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀ àti Ísírẹ́lì àwọn èèyàn rẹ̀.