Àwọn Ọba Kìíní
10 Nígbà náà, ọbabìnrin Ṣébà gbọ́ bí ìròyìn Sólómọ́nì ṣe ń gbé ògo orúkọ Jèhófà yọ,+ torí náà, ó wá láti fi àwọn ìbéèrè* tó ta kókó dán an wò.+ 2 Ó dé Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn abọ́barìn* tó gbayì,+ pẹ̀lú àwọn ràkúnmí tó ru òróró básámù+ àti wúrà tó pọ̀ gan-an àti àwọn òkúta iyebíye. Ó lọ sọ́dọ̀ Sólómọ́nì, ó sì bá a sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. 3 Sólómọ́nì dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀. Kò sí ohun tó ṣòro* fún ọba láti ṣàlàyé fún un.
4 Nígbà tí ọbabìnrin Ṣébà rí gbogbo ọgbọ́n Sólómọ́nì+ àti ilé tó kọ́,+ 5 oúnjẹ orí tábìlì rẹ̀,+ bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ń jókòó, bó ṣe ṣètò iṣẹ́ àwọn tó ń gbé oúnjẹ fún un àti aṣọ tí wọ́n ń wọ̀, àwọn agbọ́tí rẹ̀ àti àwọn ẹbọ sísun tó ń rú déédéé ní ilé Jèhófà, ẹnu yà á gan-an.* 6 Nítorí náà, ó sọ fún ọba pé: “Òótọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní ilẹ̀ mi nípa àwọn àṣeyọrí* rẹ àti ọgbọ́n rẹ. 7 Àmọ́ mi ò gba ìròyìn náà gbọ́ títí mo fi wá fojú ara mi rí i. Wò ó! Ohun tí mo gbọ́ kò tiẹ̀ tó ìdajì rárá. Ọgbọ́n rẹ àti aásìkí rẹ kọjá àwọn ohun tí mo gbọ́. 8 Aláyọ̀ ni àwọn èèyàn rẹ, aláyọ̀ sì ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wọ́n ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n ń fetí sí ọgbọ́n rẹ!+ 9 Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí ọ tí ó fi gbé ọ gorí ìtẹ́ Ísírẹ́lì. Nítorí ìfẹ́ àìnípẹ̀kun tí Jèhófà ní sí Ísírẹ́lì, ó fi ọ́ jọba láti máa dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́ àti láti máa ṣe òdodo.”
10 Lẹ́yìn náà, ó fún ọba ní ọgọ́fà (120) tálẹ́ńtì* wúrà àti òróró básámù+ tó pọ̀ gan-an àti àwọn òkúta iyebíye.+ Kò tún sẹ́ni tó kó irú òróró básámù tó pọ̀ wọlé bí èyí tí ọbabìnrin Ṣébà kó wá fún Ọba Sólómọ́nì.
11 Ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun tí Hírámù fi kó wúrà láti Ófírì+ tún kó àwọn gẹdú igi álígọ́mù+ tó pọ̀ gan-an wá àti àwọn òkúta iyebíye.+ 12 Ọba fi àwọn gẹdú igi álígọ́mù náà ṣe àwọn òpó fún ilé Jèhófà àti fún ilé* ọba, títí kan àwọn háàpù àti àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín fún àwọn akọrin.+ Wọn ò tún kó irú igi álígọ́mù bẹ́ẹ̀ wọlé mọ́, a kò sì rí irú rẹ̀ mọ́ títí di òní yìí.
13 Ọba Sólómọ́nì náà fún ọbabìnrin Ṣébà ní gbogbo ohun tó fẹ́ àti ohun tó béèrè, yàtọ̀ síyẹn, Sólómọ́nì fúnra rẹ̀ tún fún un láwọn nǹkan míì.* Lẹ́yìn náà, ó kúrò níbẹ̀, ó sì pa dà sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+
14 Ìwọ̀n wúrà tí wọ́n ń kó wá fún Sólómọ́nì lọ́dọọdún jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti ọgọ́ta ó lé mẹ́fà (666) tálẹ́ńtì wúrà,+ 15 yàtọ̀ sí èyí tó ń wá látọ̀dọ̀ àwọn oníṣòwò àti èrè látọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́jà àti látọ̀dọ̀ gbogbo ọba àwọn ará Arébíà àti àwọn gómìnà ilẹ̀ náà.
16 Ọba Sólómọ́nì fi àyọ́pọ̀ wúrà ṣe igba (200) apata ńlá,+ (ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] ṣékélì* wúrà ni ó lò sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn),+ 17 ó sì fi àyọ́pọ̀ wúrà ṣe ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) asà* (wúrà mínà* mẹ́ta ni ó lò sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn). Lẹ́yìn náà, ọba kó wọn sínú Ilé Igbó Lẹ́bánónì.+
18 Ọba tún fi eyín erin ṣe ìtẹ́ ńlá kan,+ ó sì fi wúrà tí a yọ́ mọ́ bò ó.+ 19 Àtẹ̀gùn mẹ́fà ni ìtẹ́ náà ní, ó tún ní ìbòrí ribiti kan lẹ́yìn, ibi ìgbápálé wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì ìjókòó náà, ère kìnnìún+ kọ̀ọ̀kan sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ibi ìgbápálé náà. 20 Àwọn kìnnìún tó dúró lórí àtẹ̀gùn mẹ́fà náà jẹ́ méjìlá (12), ọ̀kọ̀ọ̀kan wà ní eteetí àtẹ̀gùn kọ̀ọ̀kan. Kò sí ìjọba kankan tó ṣe irú rẹ̀ rí.
21 Gbogbo ohun èlò tí Ọba Sólómọ́nì fi ń mu nǹkan jẹ́ wúrà, gbogbo ohun èlò Ilé Igbó Lẹ́bánónì+ sì jẹ́ ògidì wúrà. Kò sí ìkankan tí wọ́n fi fàdákà ṣe, nítorí fàdákà kò já mọ́ nǹkan kan nígbà ayé Sólómọ́nì.+ 22 Ọba ní ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun Táṣíṣì+ lórí òkun pẹ̀lú ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun ti Hírámù. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún mẹ́ta ni ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun Táṣíṣì máa ń kó wúrà àti fàdákà, eyín erin,+ àwọn ìnàkí àti àwọn ẹyẹ ọ̀kín wọlé.
23 Nítorí náà, ọrọ̀+ àti ọgbọ́n+ Ọba Sólómọ́nì pọ̀ ju ti gbogbo àwọn ọba yòókù láyé. 24 Àwọn èèyàn láti ibi gbogbo láyé ń wá sọ́dọ̀* Sólómọ́nì kí wọ́n lè gbọ́ ọgbọ́n tí Ọlọ́run fi sí i lọ́kàn.+ 25 Kálukú wọn ń mú ẹ̀bùn wá, ìyẹn àwọn ohun èlò fàdákà, àwọn ohun èlò wúrà, àwọn aṣọ, ìhámọ́ra, òróró básámù, àwọn ẹṣin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,* wọ́n sì ń mú wọn wá lọ́dọọdún.
26 Sólómọ́nì sì ń kó kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹṣin* jọ; ó ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (1,400) kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) ẹṣin,*+ ó sì kó wọn sí àwọn ìlú kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti sí tòsí ọba ní Jerúsálẹ́mù.+
27 Ọba mú kí fàdákà tó wà ní Jerúsálẹ́mù pọ̀ rẹpẹtẹ bí òkúta, ó sì mú kí igi kédárì pọ̀ rẹpẹtẹ bí àwọn igi síkámórè tó wà ní Ṣẹ́fẹ́là.+
28 Íjíbítì ni wọ́n ti ń kó àwọn ẹṣin wá fún Sólómọ́nì, àwùjọ àwọn oníṣòwò ọba á sì ra agbo ẹṣin* náà ní iye kan.+ 29 Ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) fàdákà ni wọ́n ń ra kẹ̀kẹ́ ẹṣin kọ̀ọ̀kan láti Íjíbítì, àádọ́jọ (150) fàdákà sì ni wọ́n ń ra ẹṣin kọ̀ọ̀kan; wọ́n á wá fi wọ́n ránṣẹ́ sí gbogbo ọba àwọn ọmọ Hétì+ àti àwọn ọba Síríà.