Àìsáyà
42 Wò ó! Ìránṣẹ́ mi,+ tí mò ń tì lẹ́yìn!
Àyànfẹ́ mi,+ ẹni tí mo* tẹ́wọ́ gbà!+
3 Kò ní ṣẹ́ esùsú* kankan tó ti fọ́,
Kò sì ní pa òwú àtùpà kankan tó ń jó lọ́úlọ́ú tí wọ́n fi ọ̀gbọ̀ ṣe.+
Ó máa fi òótọ́ ṣe ìdájọ́ òdodo.+
4 Kò ní rẹ̀ ẹ́, a ò sì ní tẹ̀ ẹ́ rẹ́ títí ó fi máa fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀ ní ayé;+
Àwọn erékùṣù sì ń dúró de òfin* rẹ̀.
5 Ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, sọ nìyí,
Ẹlẹ́dàá ọ̀run àti Atóbilọ́lá tó nà án jáde,+
Ẹni tó tẹ́ ayé àti èso rẹ̀,+
Ẹni tó fún àwọn èèyàn inú rẹ̀ ní èémí,+
Tó sì fún àwọn tó ń rìn lórí rẹ̀ ní ẹ̀mí:+
6 “Èmi Jèhófà, ti pè ọ́ nínú òdodo;
Mo ti di ọwọ́ rẹ mú.
Màá dáàbò bò ọ́, màá sì fi ọ́ ṣe májẹ̀mú fún àwọn èèyàn náà+
Àti bí ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,+
7 Kí o lè la àwọn ojú tó fọ́,+
Láti mú ẹlẹ́wọ̀n jáde kúrò nínú àjà ilẹ̀
Àti àwọn tó jókòó sínú òkùnkùn jáde kúrò ní ẹ̀wọ̀n.+
8 Èmi ni Jèhófà. Orúkọ mi nìyẹn;
Èmi kì í fi ògo mi fún ẹlòmíì,*
Èmi kì í sì í fi ìyìn mi fún àwọn ère gbígbẹ́.+
9 Wò ó, àwọn nǹkan àkọ́kọ́ ti ṣẹlẹ̀;
Ní báyìí, mò ń kéde àwọn nǹkan tuntun.
Kí wọ́n tó rú yọ, mo sọ fún yín nípa wọn.”+
10 Ẹ kọ orin tuntun sí Jèhófà,+
Ẹ yìn ín láti àwọn ìkángun ayé,+
Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń lọ sínú òkun àti gbogbo ohun tó kún inú rẹ̀,
Ẹ̀yin erékùṣù àti àwọn tó ń gbé inú wọn.+
Kí àwọn tó ń gbé níbi àpáta kígbe ayọ̀;
Kí wọ́n ké jáde láti orí àwọn òkè.
13 Jèhófà máa jáde lọ bí akíkanjú ọkùnrin.+
Ó máa mú kí ìtara rẹ̀ sọjí bíi ti jagunjagun.+
Ó máa kígbe, àní, ó máa kígbe ogun;
Ó máa fi hàn pé òun lágbára ju àwọn ọ̀tá òun lọ.+
14 “Ó ti pẹ́ tí mo ti dákẹ́.
Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́, mo sì kóra mi níjàánu.
Bí obìnrin tó fẹ́ bímọ,
Màá kérora, màá mí hẹlẹhẹlẹ, màá sì mí gúlegúle lẹ́ẹ̀kan náà.
15 Màá sọ àwọn òkè ńlá àti àwọn òkè kéékèèké di ahoro,
Màá sì mú kí gbogbo ewéko wọn gbẹ dà nù.
Ohun tí màá ṣe fún wọn nìyí, mi ò sì ní fi wọ́n sílẹ̀.”
17 A máa dá wọn pa dà, ojú sì máa tì wọ́n gidigidi,
Àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé ère gbígbẹ́,
Àwọn tó ń sọ fún àwọn ère onírin* pé: “Ẹ̀yin ni ọlọ́run wa.”+
19 Ta ló fọ́jú yàtọ̀ sí ìránṣẹ́ mi,
Tó dití bí ẹni tí mo rán níṣẹ́?
Ta ló fọ́jú bí ẹni tí a san lẹ́san,
Tó fọ́jú bí ìránṣẹ́ Jèhófà?+
20 O rí ọ̀pọ̀ nǹkan, àmọ́ o ò kíyè sí i.
O la etí rẹ sílẹ̀, àmọ́ o ò gbọ́.+
21 Nítorí òdodo rẹ̀,
Inú Jèhófà máa dùn láti mú kí òfin* níyì, kó sì ṣe é lógo.
22 Àmọ́ wọ́n ti kó àwọn èèyàn yìí lẹ́rù, wọ́n sì ti kó ohun ìní wọn lọ;+
Wọ́n ti sé gbogbo wọn mọ́ inú ihò, wọ́n sì ti fi wọ́n pa mọ́ sínú ẹ̀wọ̀n.+
Wọ́n ti kó ẹrù wọn láìsí ẹni tó máa gbà wọ́n sílẹ̀,+
Wọ́n sì ti kó ohun ìní wọn láìsí ẹni tó máa sọ pé: “Ẹ kó o pa dà!”
23 Ta ló máa gbọ́ èyí nínú yín?
Ta ló máa fiyè sílẹ̀, kó sì fetí sílẹ̀ torí àkókò tó ń bọ̀?
24 Ta ló ti mú kí wọ́n kó ohun ìní Jékọ́bù,
Tó sì mú kí wọ́n kó ẹrù Ísírẹ́lì?
Ṣebí Jèhófà ni, Ẹni tí a ṣẹ̀?
Ó jẹ gbogbo ohun tó yí i ká run, àmọ́ kò fiyè sí i.+
Ó jó o, àmọ́ kò fọkàn sí i.+