Ìsíkíẹ́lì
11 Ẹ̀mí gbé mi sókè, ó sì gbé mi wá sí ẹnubodè ìlà oòrùn ilé Jèhófà, ìyẹn ẹnubodè tó dojú kọ ìlà oòrùn.+ Mo rí ọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) níbi àbáwọ ẹnubodè náà, Jasanáyà ọmọ Ásúrì àti Pẹlatáyà ọmọ Bẹnáyà tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn èèyàn náà sì wà lára wọn.+ 2 Ó wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, àwọn ọkùnrin yìí ló ń gbèrò ibi, tí wọ́n sì ń gbani nímọ̀ràn ìkà ní* ìlú yìí. 3 Wọ́n ń sọ pé, ‘Ṣebí àkókò yìí ló yẹ ká kọ́ ilé?+ Ìlú náà* ni ìkòkò oúnjẹ,*+ àwa sì ni ẹran.’
4 “Torí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí wọn. Sọ tẹ́lẹ̀, ọmọ èèyàn.”+
5 Ẹ̀mí Jèhófà wá bà lé mi,+ ó sì sọ fún mi pé: “Sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Òótọ́ lẹ sọ, ilé Ísírẹ́lì, mo sì mọ ohun tí ẹ̀ ń rò.* 6 Ẹ ti fa ikú ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìlú yìí, ẹ sì ti fi òkú àwọn èèyàn kún ojú ọ̀nà rẹ̀.”’”+ 7 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Òkú àwọn èèyàn tí ẹ fọ́n ká sí ìlú náà ni ẹran, ìlú náà sì ni ìkòkò oúnjẹ.+ Àmọ́ wọ́n máa mú ẹ̀yin alára kúrò níbẹ̀.’”
8 “‘Ẹ̀ ń bẹ̀rù idà,+ òun ni màá sì fi bá yín jà,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 9 ‘Èmi yóò mú yín jáde kúrò nínú rẹ̀, màá mú kí ọwọ́ àwọn àjèjì tẹ̀ yín, màá sì dá yín lẹ́jọ́.+ 10 Idà ni yóò pa yín.+ Èmi yóò dá yín lẹ́jọ́ ní ààlà Ísírẹ́lì,+ ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.+ 11 Ìlú náà kò ní jẹ́ ìkòkò oúnjẹ fún yín, ẹ̀yin kọ́ lẹ sì máa di ẹran inú rẹ̀; èmi yóò dá yín lẹ́jọ́ ní ààlà Ísírẹ́lì, 12 ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà. Torí ẹ kò rìn nínú àwọn ìlànà mi, ẹ kò sì tẹ̀ lé àwọn ìdájọ́ mi,+ àmọ́ ẹ tẹ̀ lé ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tó yí yín ká.’”+
13 Bí mo ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà tán, Pẹlatáyà ọmọ Bẹnáyà kú. Ni mo bá dojú bolẹ̀, mo sì ké jáde pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Ṣé o máa pa àwọn tó ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì run ni?”+
14 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 15 “Ọmọ èèyàn, àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù ti sọ fún àwọn arákùnrin rẹ tó ní ẹ̀tọ́ láti ṣe àtúnrà àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ má ṣe sún mọ́ Jèhófà rárá. Àwa la ni ilẹ̀ náà; wọ́n ti fún wa bí ohun ìní.’ 16 Torí náà, sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo mú kí wọ́n lọ sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì fọ́n wọn ká sí àwọn ilẹ̀ náà,+ èmi yóò di ibi mímọ́ fún wọn fúngbà díẹ̀, ní àwọn ilẹ̀ tí wọ́n lọ.”’+
17 “Torí náà, sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò mú yín kúrò láàárín àwọn èèyàn, màá kó yín jọ láti àwọn ilẹ̀ tí mo fọ́n yín ká sí, màá sì fún yín ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.+ 18 Wọ́n á pa dà síbẹ̀, wọ́n á sì mú gbogbo ohun ìríra àti gbogbo iṣẹ́ tó ń ríni lára kúrò nínú rẹ̀.+ 19 Èmi yóò mú kí ọkàn wọn ṣọ̀kan,*+ màá sì fi ẹ̀mí tuntun sínú wọn;+ màá mú ọkàn òkúta kúrò lára wọn,+ màá sì fún wọn ní ọkàn ẹran,*+ 20 kí wọ́n lè máa pa àwọn àṣẹ mi mọ́, kí wọ́n máa tẹ̀ lé ìdájọ́ mi, kí wọ́n sì máa rìn nínú rẹ̀. Wọ́n á wá di èèyàn mi, èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn.”’
21 “‘“Ṣùgbọ́n ní ti àwọn tí ọkàn wọn ṣì ń fà sí àwọn ohun tó ń ríni lára tó sì ń kóni nírìíra tí wọ́n ń ṣe, màá fi ìwà wọn san wọ́n lẹ́san,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.’”
22 Àwọn kérúbù náà wá na ìyẹ́ apá wọn, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn,+ ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì wà lórí wọn.+ 23 Ògo Jèhófà + wá gbéra kúrò ní ìlú náà, ó sì dúró lórí òkè tó wà ní ìlà oòrùn ìlú náà.+ 24 Ẹ̀mí wá gbé mi sókè nínú ìran tí ẹ̀mí Ọlọ́run mú kí n rí, ó gbé mi wá sọ́dọ̀ àwọn tó wà ní ìgbèkùn ní Kálídíà. Bí mi ò ṣe rí ìran tí mo rí mọ́ nìyẹn. 25 Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ gbogbo ohun tí Jèhófà fi hàn mí fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn.