Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí
4 Lẹ́yìn èyí, wò ó! mo rí ilẹ̀kùn kan tó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run, ohùn tí mo sì kọ́kọ́ gbọ́ tó ń bá mi sọ̀rọ̀ dún bíi kàkàkí, ó sọ pé: “Máa bọ̀ lókè níbí, màá sì fi àwọn ohun tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ hàn ọ́.” 2 Lẹ́yìn èyí, mo wà nínú agbára ẹ̀mí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, sì wò ó! ìtẹ́ kan wà ní àyè rẹ̀ ní ọ̀run, ẹnì kan sì jókòó sórí ìtẹ́ náà.+ 3 Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́ náà rí bí òkúta jásípérì+ àti òkúta sádísì,* òṣùmàrè kan tó dà bí òkúta émírádì sì wà yí ká ìtẹ́ náà.+
4 Ìtẹ́ mẹ́rìnlélógún (24) wà yí ká ìtẹ́ náà, mo rí àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún (24)+ tí wọ́n wọ aṣọ funfun, wọ́n jókòó sórí àwọn ìtẹ́ náà, wọ́n sì dé adé wúrà. 5 Mànàmáná+ àti ohùn àti ààrá+ sì ń jáde wá láti ibi ìtẹ́ náà; fìtílà méje tó ní iná ń jó níwájú ìtẹ́ náà, àwọn yìí sì túmọ̀ sí ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run.+ 6 Ohun kan tó rí bí òkun tó ń dán bíi gíláàsì+ wà níwájú ìtẹ́ náà, ó dà bíi kírísítálì.
Ẹ̀dá alààyè mẹ́rin+ tí ojú kún iwájú àti ẹ̀yìn wọn wà ní àárín ìtẹ́ náà* àti yí ká ìtẹ́ náà. 7 Ẹ̀dá alààyè àkọ́kọ́ dà bíi kìnnìún,+ ẹ̀dá alààyè kejì dà bí akọ ọmọ màlúù,+ ẹ̀dá alààyè kẹta+ ní ojú bíi ti èèyàn, ẹ̀dá alààyè kẹrin+ sì dà bí ẹyẹ idì tó ń fò.+ 8 Ní ti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìyẹ́ mẹ́fà tí ojú kún ara rẹ̀ yí ká àti lábẹ́.+ Tọ̀sántòru ni wọ́n ń sọ pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà*+ Ọlọ́run, Olódùmarè, tó ti wà tipẹ́, tó wà báyìí, tó sì ń bọ̀.”+
9 Nígbàkigbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá fi ògo àti ọlá fún Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́, Ẹni tó wà láàyè títí láé àti láéláé,+ tí wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, 10 àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún (24) náà+ á wólẹ̀ níwájú Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́, wọ́n á jọ́sìn Ẹni tó wà láàyè títí láé àti láéláé, wọ́n á sì fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n á sọ pé: 11 “Jèhófà,* Ọlọ́run wa, ìwọ ló tọ́ sí láti gba ògo+ àti ọlá+ àti agbára,+ torí ìwọ lo dá ohun gbogbo,+ torí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.”