Ẹ́kísódù
14 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ṣẹ́rí pa dà, kí wọ́n sì pàgọ́ síwájú Píháhírótì, láàárín Mígídólì àti òkun, níbi tí wọ́n á ti máa rí Baali-séfónì lọ́ọ̀ọ́kán.+ Kí ẹ pàgọ́ síbi tó dojú kọ ọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun. 3 Fáráò yóò wá sọ nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ṣe ni wọ́n ń rìn gbéregbère káàkiri ilẹ̀. Wọ́n ti há sí aginjù.’ 4 Màá jẹ́ kí ọkàn Fáráò le,+ ó máa lépa wọn, màá sì ṣe ara mi lógo nípasẹ̀ Fáráò àti gbogbo ọmọ ogun rẹ̀.+ Ó dájú pé àwọn ará Íjíbítì yóò mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”+ Ohun tí wọ́n sì ṣe nìyẹn.
5 Nígbà tó yá, wọ́n ròyìn fún ọba Íjíbítì pé àwọn èèyàn náà ti sá lọ. Lójú ẹsẹ̀, Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yí ọkàn pa dà nípa àwọn èèyàn náà,+ wọ́n sì sọ pé: “Kí la ṣe yìí, kí ló dé tí a yọ̀ǹda àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n má ṣe ẹrú wa mọ́?” 6 Ló bá múra àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sì kó àwọn èèyàn rẹ̀ dání.+ 7 Ó yan ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) kẹ̀kẹ́ ẹṣin tó dáa, ó sì kó wọn dání pẹ̀lú gbogbo kẹ̀kẹ́ ẹṣin yòókù ní Íjíbítì, jagunjagun sì wà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. 8 Bí Jèhófà ṣe jẹ́ kí ọkàn Fáráò ọba Íjíbítì le nìyẹn, ó sì ń lépa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àmọ́ ọkàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì balẹ̀* bí wọ́n ṣe ń lọ.+ 9 Àwọn ará Íjíbítì wá ń lépa wọn,+ gbogbo ẹṣin tó ń fa kẹ̀kẹ́ Fáráò àti àwọn agẹṣin rẹ̀ àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì fẹ́rẹ̀ẹ́ lé wọn bá nígbà tí wọ́n pàgọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun, nítòsí Píháhírótì, tí wọ́n ti dojú kọ Baali-séfónì.
10 Nígbà tí Fáráò ń sún mọ́ tòsí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wòkè, wọ́n sì rí i pé àwọn ará Íjíbítì ń lépa wọn. Ẹ̀rù wá bẹ̀rẹ̀ sí í ba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe Jèhófà.+ 11 Wọ́n sọ fún Mósè pé: “Ṣé torí kò sí ibi ìsìnkú ní Íjíbítì lo ṣe mú wa wá sínú aginjù ká lè kú síbí?+ Kí ló dé tí o mú wa kúrò ní Íjíbítì? 12 Ṣebí ohun tí a sọ fún ọ ní Íjíbítì ni pé, ‘Fi wá sílẹ̀, ká lè máa sin àwọn ará Íjíbítì’? Torí ó sàn ká máa sin àwọn ará Íjíbítì ju ká wá kú sí aginjù.”+ 13 Mósè wá sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ má bẹ̀rù.+ Ẹ dúró gbọn-in, kí ẹ sì rí bí Jèhófà ṣe máa gbà yín là lónìí.+ Torí àwọn ará Íjíbítì tí ẹ rí lónìí yìí, ẹ ò ní rí wọn mọ́ láé.+ 14 Jèhófà fúnra rẹ̀ máa jà fún yín,+ ẹ ó sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.”
15 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ké pè mí? Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n tú àgọ́ wọn ká. 16 Ní tìrẹ, mú ọ̀pá rẹ, kí o na ọwọ́ rẹ sórí òkun, kí o sì pín in níyà, kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè gba orí ilẹ̀ kọjá láàárín òkun. 17 Ní tèmi, màá jẹ́ kí ọkàn àwọn ará Íjíbítì le, kí wọ́n lè lépa wọn wọnú òkun, kí n sì ṣe ara mi lógo nípasẹ̀ Fáráò àti gbogbo ọmọ ogun rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti àwọn agẹṣin rẹ̀.+ 18 Ó dájú pé àwọn ará Íjíbítì yóò mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá tipasẹ̀ Fáráò, àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti àwọn agẹṣin rẹ̀ ṣe ara mi lógo.”+
19 Áńgẹ́lì Ọlọ́run tòótọ́+ tó ń lọ níwájú àwùjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò níwájú, ó sì bọ́ sí ẹ̀yìn wọn, ọwọ̀n ìkùukùu* tó wà níwájú wọn wá bọ́ sí ẹ̀yìn wọn, ó sì dúró síbẹ̀.+ 20 Ó wà láàárín àwùjọ àwọn ará Íjíbítì àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ Ó mú kí òkùnkùn ṣú lápá kan. Àmọ́ lápá kejì, ó mú kí ìmọ́lẹ̀ wà ní òru yẹn.+ Torí náà, àwùjọ kìíní ò dé ọ̀dọ̀ àwùjọ kejì ní gbogbo òru yẹn.
21 Ni Mósè bá na ọwọ́ rẹ̀ sórí òkun;+ Jèhófà sì mú kí atẹ́gùn líle fẹ́ wá láti ìlà oòrùn ní gbogbo òru yẹn, ó sì bi òkun náà sẹ́yìn. Ó mú kí ìsàlẹ̀ òkun di ilẹ̀ gbígbẹ,+ omi náà sì pínyà.+ 22 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá gba orí ilẹ̀ kọjá láàárín òkun,+ omi náà sì dà bí ògiri ní apá ọ̀tún àti ní apá òsì wọn.+ 23 Àwọn ará Íjíbítì ń lé wọn, gbogbo ẹṣin Fáráò, àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti àwọn agẹṣin rẹ̀ sì tẹ̀ lé wọn wọ àárín òkun.+ 24 Nígbà ìṣọ́ òwúrọ̀,* Jèhófà wo àwùjọ àwọn ará Íjíbítì látinú ọwọ̀n iná* àti ìkùukùu,+ ó sì mú kí àwùjọ àwọn ará Íjíbítì dà rú. 25 Ó ń mú kí àgbá kẹ̀kẹ́ yọ kúrò lára àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn, ìyẹn sì ń mú kó nira fún wọn láti wa àwọn kẹ̀kẹ́ náà, àwọn ará Íjíbítì sì ń sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ ká fọwọ́ kan Ísírẹ́lì rárá o, torí Jèhófà ń gbèjà wọn, ó sì ń bá àwa ọmọ Íjíbítì jà.”+
26 Ni Jèhófà bá sọ fún Mósè pé: “Na ọwọ́ rẹ sórí òkun, kí omi náà lè pa dà, kó sì bo àwọn ará Íjíbítì, àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn àti àwọn agẹṣin wọn.” 27 Ni Mósè bá na ọwọ́ rẹ̀ sórí òkun, bí ilẹ̀ sì ṣe ń mọ́ bọ̀, òkun náà pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀. Bí àwọn ará Íjíbítì ṣe ń sá pa dà, Jèhófà bi àwọn ará Íjíbítì ṣubú sáàárín òkun.+ 28 Omi náà rọ́ pa dà, ó sì bo àwọn kẹ̀kẹ́ ogun, àwọn agẹṣin àti gbogbo ọmọ ogun Fáráò tó lépa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọnú òkun.+ Kò sí ìkankan nínú wọn tó yè é.+
29 Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba orí ilẹ̀ kọjá láàárín òkun,+ omi náà sì dà bí ògiri ní apá ọ̀tún àti ní apá òsì wọn.+ 30 Bí Jèhófà ṣe gba Ísírẹ́lì là lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì lọ́jọ́ yẹn nìyẹn,+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì rí òkú àwọn ará Íjíbítì ní etíkun. 31 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún rí agbára* ńlá tí Jèhófà fi bá àwọn ará Íjíbítì jà, àwọn èèyàn náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀rù Jèhófà, wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà àti Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀.+