Sáàmù
Sí olùdarí; lórí Jédútúnì.*+ Ti Ásáfù. Orin.
77 Màá fi ohùn mi ké pe Ọlọ́run;
Màá ké pe Ọlọ́run, yóò sì gbọ́ mi.+
2 Ní ọjọ́ wàhálà mi, mo wá Jèhófà.+
Ní òru, mi ò dẹ́kun* títẹ́wọ́ àdúrà sí i.
Síbẹ̀, mi* ò gba ìtùnú.
4 Ìwọ mú kí ojú mi là sílẹ̀;
Wàhálà bá mi, mi ò sì lè sọ̀rọ̀.
5 Mo rántí ìgbà àtijọ́,+
Àwọn ọdún tó ti kọjá tipẹ́tipẹ́.
7 Ṣé títí láé ni Jèhófà máa ta wá nù ni?+
Ṣé kò ní ṣojú rere sí wa mọ́ láé ni?+
8 Ṣé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ti dáwọ́ dúró títí ayé ni?
Ṣé ìlérí rẹ̀ máa já sí asán fún gbogbo ìran ni?
9 Ṣé Ọlọ́run ti gbàgbé láti ṣojú rere ni,+
Àbí, ṣé ìbínú rẹ̀ ti dínà àánú rẹ̀ ni? (Sélà)
10 Ṣé ó yẹ kí n máa sọ ní gbogbo ìgbà pé: “Ohun tó ń kó ìdààmú bá* mi ni pé:+
Ẹni Gíga Jù Lọ ti kọ ẹ̀yìn* sí wa”?
11 Màá rántí àwọn iṣẹ́ Jáà;
Màá rántí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu tí o ti ṣe tipẹ́tipẹ́.
13 Ọlọ́run, àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ mímọ́.
Ìwọ Ọlọ́run, ọlọ́run wo ló tóbi bí rẹ?+
14 Ìwọ ni Ọlọ́run tòótọ́, tó ń ṣe àwọn ohun àgbàyanu.+
O ti fi agbára rẹ han àwọn èèyàn.+
16 Omi rí ọ, ìwọ Ọlọ́run;
Omi rí ọ, ó sì dà rú.+
Ibú omi ru gùdù.
17 Àwọsánmà da omi sílẹ̀.
Ojú ọ̀run tó ṣú dẹ̀dẹ̀ sán ààrá,
Àwọn ọfà rẹ sì ń fò síbí sọ́hùn-ún.+