Sáàmù
ל [Lámédì]
10 Jèhófà, kí nìdí tí o fi dúró lókèèrè?
Kí nìdí tí o fi fara pa mọ́ ní àkókò wàhálà?+
2 Ẹni burúkú ń fi ìgbéraga lépa ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́,+
Àmọ́ èrò ibi tó gbà máa yí dà lé e lórí.+
Kì í bọ̀wọ̀ fún Jèhófà.
4 Ìgbéraga kì í jẹ́ kí ẹni burúkú ṣe ìwádìí kankan;
Gbogbo èrò rẹ̀ ni pé: “Kò sí Ọlọ́run.”+
5 Àwọn ọ̀nà rẹ̀ ń yọrí sí rere,+
Àmọ́ àwọn ìdájọ́ rẹ ga kọjá òye rẹ̀;+
Ó ń fi gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣẹ̀sín.*
6 Ó ń sọ lọ́kàn rẹ̀ pé: “Mìmì kan ò ní mì mí;*
Láti ìran dé ìran
Mi ò ní rí àjálù láé.”+
פ [Péè]
8 Ó ń lúgọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ibùdó;
Ó ń pa àwọn aláìṣẹ̀ láti ibi tó fara pa mọ́ sí.+
ע [Áyìn]
Ojú rẹ̀ ń wá àwọn tó rin àrìnfẹsẹ̀sí.+
9 Ó ń dúró níbi tó fara pa mọ́ sí bíi kìnnìún nínú ihò rẹ̀.*+
Ó ń dúró láti mú ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
Ó ń mú ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́ nígbà tó bá pa àwọ̀n rẹ̀ dé.+
10 Ẹni tó bá kó sí i lọ́wọ́ yóò di àtẹ̀rẹ́, yóò sì ṣubú lulẹ̀;
Àwọn tó rin àrìnfẹsẹ̀sí yóò kó sínú akóló rẹ̀.*
11 Ó sọ lọ́kàn rẹ̀ pé: “Ọlọ́run ti gbàgbé.+
Ó ti gbé ojú rẹ̀ kúrò.
Kò sì ní fiyè sí i láé.”+
ק [Kófì]
12 Jèhófà dìde.+ Ọlọ́run, gbé ọwọ́ rẹ sókè.+
Má gbàgbé àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.+
13 Kí nìdí tí ẹni burúkú kò fi bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run?
Ó sọ lọ́kàn rẹ̀ pé: “O ò ní pè mí wá jíhìn.”
ר [Réṣì]
14 Àmọ́, o rí ìjàngbọ̀n àti ìdààmú.
Ò ń wò ó, o sì gbé ìgbésẹ̀.+
ש [Ṣínì]
16 Jèhófà ni Ọba títí láé àti láéláé.+
Àwọn orílẹ̀-èdè ti ṣègbé kúrò láyé.+
ת [Tọ́ọ̀]
17 Àmọ́ Jèhófà, wàá gbọ́ ẹ̀bẹ̀ àwọn oníwà pẹ̀lẹ́.+