Jẹ́nẹ́sísì
13 Ábúrámù kúrò ní Íjíbítì lọ sí Négébù,+ òun àti ìyàwó rẹ̀ àti gbogbo ohun tó ní, pẹ̀lú Lọ́ọ̀tì. 2 Ábúrámù ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran ọ̀sìn, fàdákà àti wúrà.+ 3 Ó ń pàgọ́ láti ibì kan dé ibòmíì lẹ́nu ìrìn àjò rẹ̀ láti Négébù lọ dé Bẹ́tẹ́lì, títí ó fi dé ibi tó pàgọ́ sí tẹ́lẹ̀ láàárín Bẹ́tẹ́lì àti Áì,+ 4 níbi tó mọ pẹpẹ sí tẹ́lẹ̀. Ibẹ̀ ni Ábúrámù ti ké pe orúkọ Jèhófà.
5 Lọ́ọ̀tì, tó ń bá Ábúrámù rìnrìn àjò, pẹ̀lú ní àwọn àgùntàn, màlúù àti àwọn àgọ́. 6 Wọn ò sì lè jọ wà níbì kan náà torí ilẹ̀ náà ò gba gbogbo wọn; ohun ìní wọn ti pọ̀ gan-an débi pé wọn ò lè jọ máa gbé pọ̀ mọ́. 7 Torí náà, ìjà ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn tó ń da ẹran ọ̀sìn Ábúrámù àti àwọn tó ń da ẹran ọ̀sìn Lọ́ọ̀tì. (Nígbà yẹn, àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn Pérísì ń gbé ní ilẹ̀ náà.)+ 8 Ábúrámù wá sọ fún Lọ́ọ̀tì+ pé: “Jọ̀ọ́, kò yẹ kí ìjà wáyé láàárín èmi àti ìwọ àti láàárín àwọn tó ń da ẹran mi àti àwọn tó ń da ẹran rẹ, torí arákùnrin ni wá. 9 Ṣebí gbogbo ilẹ̀ ló wà níwájú rẹ yìí? Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lọ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Tí o bá lọ sí apá òsì, èmi á lọ sí apá ọ̀tún; àmọ́ tí o bá lọ sí apá ọ̀tún, èmi á lọ sí apá òsì.” 10 Lọ́ọ̀tì wá gbójú sókè, ó sì rí i pé gbogbo agbègbè Jọ́dánì+ lómi dáadáa, (kí Jèhófà tó pa Sódómù àti Gòmórà run), bí ọgbà Jèhófà,+ bí ilẹ̀ Íjíbítì, títí lọ dé Sóárì.+ 11 Lọ́ọ̀tì wá yan gbogbo agbègbè Jọ́dánì fún ara rẹ̀, ó sì ṣí ibùdó rẹ̀ lọ sí ìlà oòrùn. Bí wọ́n ṣe lọ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ nìyẹn. 12 Ábúrámù ń gbé ilẹ̀ Kénáánì, àmọ́ Lọ́ọ̀tì ń gbé láàárín àwọn ìlú tó wà ní agbègbè náà.+ Nígbà tó yá, ó pàgọ́ rẹ̀ sí tòsí Sódómù. 13 Èèyàn burúkú ni àwọn ará Sódómù, ẹlẹ́ṣẹ̀ paraku ni wọ́n jẹ́ lójú Jèhófà.+
14 Jèhófà sọ fún Ábúrámù lẹ́yìn tí Lọ́ọ̀tì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ pé: “Jọ̀ọ́ gbójú sókè níbi tí o wà, kí o sì wo àríwá àti gúúsù, ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn, 15 torí gbogbo ilẹ̀ tí o rí yìí ni màá fún ìwọ àti ọmọ* rẹ, yóò sì di ohun ìní yín títí láé.+ 16 Màá mú kí ọmọ* rẹ pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, tó fi jẹ́ pé tí ẹnikẹ́ni bá lè ka erùpẹ̀ ilẹ̀ ni wọ́n á tó lè ka+ ọmọ* rẹ. 17 Dìde, kí o sì rin ilẹ̀ náà já, kí o rin gígùn àti fífẹ̀ rẹ̀, torí ìwọ ni màá fún.” 18 Ábúrámù sì ń gbé inú àgọ́. Nígbà tó yá, ó lọ ń gbé láàárín àwọn igi ńlá Mámúrè,+ tó wà ní Hébúrónì;+ ó sì mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà.+