Jẹ́nẹ́sísì
25 Ábúráhámù fẹ́ ìyàwó míì, Kétúrà ni orúkọ rẹ̀. 2 Nígbà tó yá, ó bí Símíránì, Jókíṣánì, Médánì, Mídíánì,+ Íṣíbákì àti Ṣúáhì.+
3 Jókíṣánì bí Ṣébà àti Dédánì.
Àwọn ọmọ Dédánì ni Áṣúrímù, Létúṣímù àti Léúmímù.
4 Àwọn ọmọ Mídíánì ni Eéfà, Éférì, Hánókù, Ábíídà àti Élídáà.
Ọmọ Kétúrà ni gbogbo wọn.
5 Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù fún Ísákì + ní gbogbo ohun tó ní, 6 àmọ́ Ábúráhámù fún àwọn ọmọ tí àwọn wáhàrì* rẹ̀ bí fún un ní ẹ̀bùn. Nígbà tó ṣì wà láàyè, ó ní kí wọ́n máa lọ sí apá ìlà oòrùn kúrò lọ́dọ̀ Ísákì ọmọ+ rẹ̀, sí ilẹ̀ Ìlà Oòrùn. 7 Ọjọ́ ayé Ábúráhámù jẹ́ ọdún márùndínlọ́gọ́sàn-án (175). 8 Ábúráhámù mí èémí ìkẹyìn, ó sì kú, ó darúgbó, ayé rẹ̀ sì dára, wọ́n wá kó o jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀.* 9 Ísákì àti Íṣímáẹ́lì ọmọ rẹ̀ sin ín sí ihò Mákípẹ́là lórí ilẹ̀ Éfúrónì ọmọ Sóhárì, ọmọ Hétì, tó wà níwájú Mámúrè,+ 10 ilẹ̀ tí Ábúráhámù rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hétì. Ibẹ̀ ni wọ́n sin Ábúráhámù sí, pẹ̀lú Sérà+ ìyàwó rẹ̀. 11 Lẹ́yìn tí Ábúráhámù kú, Ọlọ́run ṣì ń bù kún Ísákì+ ọmọ rẹ̀, Ísákì sì ń gbé nítòsí Bia-laháí-róì.+
12 Ìtàn Íṣímáẹ́lì+ ọmọ Ábúráhámù nìyí, ẹni tí Hágárì+ ọmọ ilẹ̀ Íjíbítì tó jẹ́ ìránṣẹ́ Sérà bí fún Ábúráhámù.
13 Orúkọ àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì nìyí, orúkọ wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé tí wọ́n ti wá: Àkọ́bí Íṣímáẹ́lì ni Nébáótì,+ lẹ́yìn náà ó bí Kídárì,+ Ádíbéélì, Míbúsámù,+ 14 Míṣímà, Dúmà, Máásà, 15 Hádádì, Témà, Jétúrì, Náfíṣì àti Kédémà. 16 Àwọn yìí ni ọmọ Íṣímáẹ́lì, orúkọ wọn sì nìyí, gẹ́gẹ́ bí ibi tí wọ́n ń gbé àti ibùdó* wọn, wọ́n jẹ́ ìjòyè méjìlá (12) ní àwọn agbo ilé+ wọn. 17 Ọjọ́ ayé Íṣímáẹ́lì jẹ́ ọdún mẹ́tàdínlógóje (137). Ó mí èémí ìkẹyìn, ó sì kú, wọ́n kó o jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀.* 18 Wọ́n tẹ̀ dó sí Háfílà+ nítòsí Ṣúrì,+ tó sún mọ́ Íjíbítì, títí lọ dé Ásíríà. Wọ́n sì ń gbé nítòsí gbogbo àwọn arákùnrin+ wọn.*
19 Ìtàn Ísákì ọmọ Ábúráhámù+ nìyí.
Ábúráhámù bí Ísákì. 20 Ẹni ogójì (40) ọdún ni Ísákì nígbà tó fẹ́ Rèbékà, ọmọ Bẹ́túẹ́lì+ ará Arémíà ní ilẹ̀ Padani-árámù, òun ni arábìnrin Lábánì ará Arémíà. 21 Ísákì sì ń bẹ Jèhófà nítorí ìyàwó rẹ̀, torí pé ó yàgàn; Jèhófà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, Rèbékà ìyàwó rẹ̀ sì lóyún. 22 Àwọn ọmọ inú rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn+ jà, débi tó fi sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé bó ṣe máa ń rí nìyí, ǹjẹ́ kò ní sàn kí n kú?” Torí náà, ó wádìí lọ́wọ́ Jèhófà. 23 Jèhófà sì sọ fún un pé: “Orílẹ̀-èdè méjì ló wà nínú ikùn+ rẹ, èèyàn méjì tó yàtọ̀ síra máa tinú rẹ+ jáde; orílẹ̀-èdè kan máa lágbára ju ìkejì+ lọ, ẹ̀gbọ́n sì máa sin àbúrò.”+
24 Nígbà tí àsìkò tó máa bímọ tó, wò ó! ìbejì ló wà ní inú rẹ̀. 25 Èyí àkọ́kọ́ sì jáde, ó pupa látòkè délẹ̀, ó dà bí aṣọ onírun,+ torí náà, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Ísọ̀.*+ 26 Lẹ́yìn náà, àbúrò rẹ̀ jáde, ó sì di gìgísẹ̀ Ísọ̀+ mú, torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Jékọ́bù.*+ Ẹni ọgọ́ta (60) ọdún ni Ísákì nígbà tí Rèbékà bí àwọn ọmọ náà.
27 Bí àwọn ọmọ náà ṣe ń dàgbà, Ísọ̀ di ọdẹ+ tó já fáfá, inú igbó ló sábà máa ń lọ, àmọ́ Jékọ́bù jẹ́ aláìlẹ́bi, inú àgọ́+ ló máa ń wà. 28 Ísákì nífẹ̀ẹ́ Ísọ̀ torí ó máa ń fún un ní ẹran ìgbẹ́ jẹ, àmọ́ Rèbékà nífẹ̀ẹ́ Jékọ́bù.+ 29 Lọ́jọ́ kan, Jékọ́bù ń se ọbẹ̀ nígbà tí Ísọ̀ dé láti oko ọdẹ, ó sì ti rẹ̀ ẹ́ gan-an. 30 Torí náà Ísọ̀ sọ fún Jékọ́bù pé: “Jọ̀ọ́, sáré fún mi lára* ọbẹ̀ pupa tí ò ń sè yẹn,* torí ó ti rẹ̀ mí!”* Ìdí nìyẹn tí orúkọ rẹ̀ fi ń jẹ́ Édómù.*+ 31 Jékọ́bù wá fèsì pé: “Kọ́kọ́ ta ogún ìbí rẹ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí+ fún mi!” 32 Ísọ̀ dá a lóhùn pé: “Èmi tí mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú! Kí ni ogún ìbí fẹ́ dà fún mi?” 33 Jékọ́bù sọ pé: “Kọ́kọ́ búra fún mi!” Ló bá búra fún un, ó sì ta ogún ìbí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí fún Jékọ́bù.+ 34 Jékọ́bù wá fún Ísọ̀ ní búrẹ́dì àti ọbẹ̀ ẹ̀wà lẹ́ńtìlì, ó jẹ, ó sì mu. Ó dìde, ó sì ń lọ. Bí Ísọ̀ ṣe fi hàn pé òun ò mọyì ogún ìbí rẹ̀ nìyẹn.