Diutarónómì
9 “Gbọ́, ìwọ Ísírẹ́lì, ò ń sọdá Jọ́dánì lónìí,+ láti wọ ilẹ̀ náà kí o lè lọ lé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tóbi, tí wọ́n sì lágbára jù ọ́ lọ kúrò,+ àwọn ìlú tó tóbi, tí wọ́n sì mọ odi rẹ̀ kan ọ̀run,*+ 2 àwọn èèyàn tó tóbi tí wọ́n sì ga, àwọn ọmọ Ánákímù+ tí ẹ mọ̀, tí ẹ sì gbọ́ tí wọ́n sọ nípa wọn pé, ‘Ta ló lè ko àwọn ọmọ Ánákì lójú?’ 3 Torí náà, kí o mọ̀ lónìí pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa sọdá ṣáájú rẹ.+ Ó jẹ́ iná tó ń jóni run,+ ó sì máa pa wọ́n run. Ó máa tẹ̀ wọ́n lórí ba níṣojú yín kí ẹ lè tètè lé wọn jáde,* kí ẹ sì pa wọ́n run, bí Jèhófà ṣe ṣèlérí fún ọ.+
4 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá lé wọn kúrò níwájú rẹ, má sọ lọ́kàn rẹ pé, ‘Òdodo mi ló mú kí Jèhófà mú mi wá gba ilẹ̀ yìí.’+ Torí ìwà burúkú àwọn orílẹ̀-èdè yìí+ ni Jèhófà ṣe máa lé wọn kúrò níwájú rẹ. 5 Kì í ṣe torí pé o jẹ́ olódodo tàbí olóòótọ́ nínú ọkàn rẹ ló máa jẹ́ kí o lọ gba ilẹ̀ wọn. Àmọ́ ìwà burúkú àwọn orílẹ̀-èdè yìí ló máa mú kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ lé wọn kúrò níwájú rẹ,+ kí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà búra nípa rẹ̀ fún àwọn baba ńlá yín, Ábúráhámù,+ Ísákì+ àti Jékọ́bù+ sì lè ṣẹ. 6 Torí náà, mọ̀ pé kì í ṣe torí òdodo rẹ ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe máa fún ọ ní ilẹ̀ dáradára yìí kí o lè gbà á, torí alágídí* ni ọ́.+
7 “Rántí, má sì gbàgbé bí o ṣe múnú bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní aginjù.+ Láti ọjọ́ tí ẹ ti kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì títí ẹ fi dé ibí yìí lẹ ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà.+ 8 Kódà ní Hórébù, ẹ múnú bí Jèhófà, Jèhófà sì bínú gidigidi sí yín débi pé ó ṣe tán láti pa yín run.+ 9 Nígbà tí mo lọ sórí òkè láti gba àwọn wàláà òkúta,+ àwọn wàláà májẹ̀mú tí Jèhófà bá yín dá,+ ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru+ ni mo fi wà lórí òkè náà, tí mi ò jẹ, tí mi ò sì mu. 10 Jèhófà wá fún mi ní àwọn wàláà òkúta méjì tí ìka Ọlọ́run kọ̀wé sí, gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá yín sọ ní òkè náà látinú iná ní ọjọ́ tí ẹ pé jọ* sì wà lára rẹ̀.+ 11 Lẹ́yìn ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru náà, Jèhófà fún mi ní wàláà òkúta méjì, àwọn wàláà májẹ̀mú náà, 12 Jèhófà sì sọ fún mi pé, ‘Gbéra, tètè sọ̀ kalẹ̀ kúrò níbí, torí pé àwọn èèyàn rẹ tí o mú kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì ti hùwà ìbàjẹ́.+ Wọ́n ti yára kúrò ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún wọn pé kí wọ́n máa rìn. Wọ́n ti ṣe ère onírin* fún ara wọn.’+ 13 Jèhófà wá sọ fún mi pé, ‘Mo ti rí àwọn èèyàn yìí, wò ó! alágídí* ni wọ́n.+ 14 Dá mi dá wọn, màá pa wọ́n run, màá sì pa orúkọ wọn rẹ́ lábẹ́ ọ̀run, sì jẹ́ kí n sọ ìwọ di orílẹ̀-èdè tó lágbára tó sì pọ̀ jù wọ́n lọ.’+
15 “Mo bá yíjú pa dà, mo sì sọ̀ kalẹ̀ lórí òkè náà nígbà tí iná ń jó lórí rẹ̀,+ wàláà májẹ̀mú méjì náà sì wà ní ọwọ́ mi méjèèjì.+ 16 Nígbà náà, mo rí i pé ẹ ti ṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín! Ẹ ti ṣe ọmọ màlúù onírin* fún ara yín. Ẹ ti yára kúrò ní ọ̀nà tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí ẹ máa rìn.+ 17 Mo bá mú wàláà méjèèjì, mo fi ọwọ́ mi méjèèjì là á mọ́lẹ̀, mo sì fọ́ ọ túútúú níṣojú yín.+ 18 Mo wá wólẹ̀ níwájú Jèhófà, bíi ti àkọ́kọ́, fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru. Mi ò jẹ, mi ò sì mu,+ torí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ dá bí ẹ ṣe ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, tí ẹ sì ń múnú bí i. 19 Bí Jèhófà ṣe bínú sí yín gidigidi bà mí lẹ́rù gan-an,+ torí ó ṣe tán láti pa yín run. Àmọ́, Jèhófà tún fetí sí mi nígbà yẹn.+
20 “Jèhófà bínú sí Áárónì débi pé ó ṣe tán láti pa á run,+ àmọ́ mo bá Áárónì náà bẹ̀bẹ̀ nígbà yẹn. 21 Lẹ́yìn náà, mo mú ohun tí ẹ ṣe tó mú kí ẹ dẹ́ṣẹ̀, ìyẹn ọmọ màlúù náà,+ mo sì dáná sun ún; mo fọ́ ọ túútúú, mo sì lọ̀ ọ́ kúnná títí ó fi di lẹ́búlẹ́bú bí eruku, mo sì dà á sínú odò tó ń ṣàn látorí òkè náà.+
22 “Bákan náà, ẹ tún múnú bí Jèhófà ní Tábérà,+ Másà+ àti ní Kiburoti-hátááfà.+ 23 Nígbà tí Jèhófà ní kí ẹ lọ láti Kadeṣi-bánéà,+ tó sì sọ pé, ‘Ẹ gòkè lọ gba ilẹ̀ tó dájú pé màá fún yín!’ ẹ tún ṣe ohun tó lòdì sí àṣẹ tí Jèhófà Ọlọ́run yín pa,+ ẹ ò gbà á gbọ́,+ ẹ ò sì ṣègbọràn sí i. 24 Àtìgbà tí mo ti mọ̀ yín lẹ ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà.
25 “Torí náà, mo fi ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru+ wólẹ̀ níwájú Jèhófà, mo wólẹ̀ bẹ́ẹ̀ torí Jèhófà sọ pé òun máa pa yín run. 26 Mo bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Jèhófà, mo sì sọ pé, ‘Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, má pa àwọn èèyàn rẹ run. Ohun ìní* rẹ ni wọ́n jẹ́,+ àwọn tí o fi títóbi rẹ rà pa dà, tí o sì fi ọwọ́ agbára mú kúrò ní Íjíbítì.+ 27 Rántí àwọn ìránṣẹ́ rẹ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù.+ Má wo ti agídí àwọn èèyàn yìí àti ìwà burúkú wọn pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.+ 28 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn tó wà ní ilẹ̀ tí o ti mú wa kúrò lè máa sọ pé: “Jèhófà ò lè mú wọn dé ilẹ̀ tó ṣèlérí pé òun máa fún wọn, torí náà, ó mú wọn wá sínú aginjù kó lè pa wọ́n torí ó kórìíra wọn.”+ 29 Èèyàn rẹ ni wọ́n, ohun ìní* rẹ+ ni wọ́n sì jẹ́, àwọn tí o fi agbára ńlá rẹ àti apá rẹ tí o nà jáde mú kúrò.’+