Jóṣúà
18 Nígbà náà, gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé jọ sí Ṣílò,+ wọ́n sì to àgọ́ ìpàdé síbẹ̀,+ torí wọ́n ti ṣẹ́gun ilẹ̀ náà.+ 2 Àmọ́ ó ṣì ku ẹ̀yà méje nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọn ò tíì pín ogún fún. 3 Jóṣúà wá sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ìgbà wo lẹ máa tó lọ gba ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín ti fún yín?+ 4 Ẹ fún mi ní ọkùnrin mẹ́ta látinú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan kí n lè rán wọn jáde; kí wọ́n lọ rìn káàkiri ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì ṣètò bí wọ́n á ṣe pín in gẹ́gẹ́ bí ogún wọn. Kí wọ́n wá pa dà sọ́dọ̀ mi. 5 Kí wọ́n pín in sí ọ̀nà méje láàárín ara wọn.+ Júdà ṣì máa wà ní ilẹ̀ rẹ̀ lápá gúúsù,+ ilé Jósẹ́fù pẹ̀lú ṣì máa wà ní ilẹ̀ wọn lápá àríwá.+ 6 Ohun tí ẹ máa ṣe ni pé kí ẹ pín ilẹ̀ náà sí ọ̀nà méje, kí ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi níbí, màá sì ṣẹ́ kèké lé e+ níbí fún yín níwájú Jèhófà Ọlọ́run wa. 7 Àmọ́ a ò ní fún àwọn ọmọ Léfì ní ìpín kankan láàárín yín,+ torí pé iṣẹ́ àlùfáà Jèhófà ni ogún wọn;+ Gádì, Rúbẹ́nì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè+ ti gba ogún wọn lápá ìlà oòrùn Jọ́dánì, èyí tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà fún wọn.”
8 Àwọn ọkùnrin náà múra láti lọ, Jóṣúà sì pàṣẹ fún àwọn tó máa ṣètò bí wọ́n á ṣe pín ilẹ̀ náà pé: “Ẹ lọ rìn káàkiri ilẹ̀ náà, kí ẹ ṣètò bí ẹ ṣe máa pín in, kí ẹ wá pa dà sọ́dọ̀ mi, màá sì ṣẹ́ kèké lé e níbí fún yín níwájú Jèhófà ní Ṣílò.”+ 9 Ni àwọn ọkùnrin náà bá lọ, wọ́n rìn káàkiri ilẹ̀ náà, wọ́n fi àwọn ìlú ibẹ̀ pín in sí ọ̀nà méje, wọ́n sì kọ ọ́ sínú ìwé. Lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà sọ́dọ̀ Jóṣúà níbi tí wọ́n pàgọ́ sí ní Ṣílò. 10 Jóṣúà wá ṣẹ́ kèké fún wọn ní Ṣílò níwájú Jèhófà.+ Ibẹ̀ ni Jóṣúà ti pín ilẹ̀ náà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn.+
11 Kèké mú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ní ìdílé-ìdílé, ilẹ̀ tí wọ́n sì fi kèké pín fún wọn wà láàárín àwọn èèyàn Júdà+ àtàwọn èèyàn Jósẹ́fù.+ 12 Ní apá àríwá, ààlà wọn bẹ̀rẹ̀ láti Jọ́dánì, ó dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Jẹ́ríkò+ ní àríwá, ó dé orí òkè lápá ìwọ̀ oòrùn, ó sì lọ títí dé aginjù Bẹti-áfénì.+ 13 Ààlà náà tún lọ láti ibẹ̀ dé Lúsì, ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ tó wà lápá gúúsù Lúsì, ìyẹn Bẹ́tẹ́lì;+ ààlà náà dé Ataroti-ádárì+ lórí òkè tó wà ní gúúsù Bẹti-hórónì Ìsàlẹ̀.+ 14 Wọ́n pààlà náà ní apá ìwọ̀ oòrùn, ó sì yí gba gúúsù láti ibi òkè tó dojú kọ Bẹti-hórónì lápá gúúsù; ó parí sí Kiriati-báálì, ìyẹn Kiriati-jéárímù,+ ìlú Júdà. Èyí ni apá ìwọ̀ oòrùn.
15 Apá gúúsù bẹ̀rẹ̀ láti ìkángun Kiriati-jéárímù, ààlà náà sì lọ sápá ìwọ̀ oòrùn; ó dé ibi ìsun omi Néfítóà.+ 16 Ààlà náà lọ dé ìkángun òkè tó dojú kọ Àfonífojì Ọmọ Hínómù,+ èyí tó wà ní Àfonífojì* Réfáímù+ lápá àríwá, ó sì lọ dé Àfonífojì Hínómù, dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn ará Jébúsì+ ní gúúsù, títí dé Ẹ́ń-rógélì.+ 17 Wọ́n pààlà náà lápá àríwá, ó sì lọ dé Ẹ́ń-ṣímẹ́ṣì títí dé Gélílótì, èyí tó wà níwájú ibi tí wọ́n ń gbà gòkè ní Ádúmímù,+ ó wá lọ dé ibi òkúta+ Bóhánì+ ọmọ Rúbẹ́nì. 18 Ó dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ apá àríwá níwájú Árábà, ó sì lọ dé Árábà. 19 Ààlà náà tún lọ dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ apá àríwá Bẹti-hógílà,+ ó sì parí sí ibi tí omi ti ya wọ ilẹ̀ lápá àríwá Òkun Iyọ̀,*+ ní ìpẹ̀kun Jọ́dánì lápá gúúsù. Èyí ni ààlà náà lápá gúúsù. 20 Jọ́dánì sì ni ààlà rẹ̀ lápá ìlà oòrùn. Èyí ni ogún àwọn àtọmọdọ́mọ Bẹ́ńjámínì ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí àwọn ààlà rẹ̀ yí ká.
21 Àwọn ìlú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ní ìdílé-ìdílé nìyí: Jẹ́ríkò, Bẹti-hógílà, Emeki-késísì, 22 Bẹti-árábà,+ Sémáráímù, Bẹ́tẹ́lì,+ 23 Áfímù, Párà, Ọ́fírà, 24 Kefari-ámónì, Ófínì àti Gébà,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú méjìlá (12) pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.
25 Gíbíónì,+ Rámà, Béérótì, 26 Mísípè, Kéfírà, Mósáhì, 27 Rékémù, Iripéélì, Tárálà, 28 Séélà,+ Ha-éléfì, Jẹ́búsì, ìyẹn Jerúsálẹ́mù,+ Gíbíà+ àti Kíríátì, gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́rìnlá (14), pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.
Èyí ni ogún àwọn àtọmọdọ́mọ Bẹ́ńjámínì ní ìdílé-ìdílé.