ORÍ 25
“Mo Ké Gbàjarè sí Késárì!”
Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa bá a ṣe lè gbèjà ìhìn rere
Ó dá lórí Ìṣe 25:1–26:32
1, 2. (a) Àwọn nǹkan wo ló ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù? (b) Ìbéèrè wo ló lè wá sí wa lọ́kàn bí Pọ́ọ̀lù ṣe ké gbàjarè sí Késárì?
PỌ́Ọ̀LÙ ṣì wà ní àhámọ́ nílùú Kesaríà, àwọn ẹ̀ṣọ́ sì ń ṣọ́ ọ lójú méjèèjì. Láàárín ọjọ́ díẹ̀ tó dé sílùú Jùdíà lọ́dún méjì sẹ́yìn, ó kéré tán, ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn Júù ti gbìyànjú láti pa á. (Ìṣe 21:27-36; 23:10, 12-15, 27) Àmọ́ wọn ò rí i pa, síbẹ̀ wọn ò dẹ̀yìn lẹ́yìn ẹ̀. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù rí i pé ó ṣeé ṣe kọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yẹn tẹ òun láìpẹ́, ó sọ fún gómìnà Róòmù tó ń jẹ́ Fẹ́sítọ́ọ̀sì pé: “Mo ké gbàjarè sí Késárì!”—Ìṣe 25:11.
2 Ṣé bí Pọ́ọ̀lù ṣe ké gbàjarè sí Késárì bá ìfẹ́ Jèhófà mu? Ó yẹ káwa tá à ń fìtara jẹ́rìí nípa Ìjọba Ọlọ́run lákòókò òpin yìí mọ ìdáhùn ìbéèrè yìí. Torí ó ṣe pàtàkì ká mọ̀ bóyá àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù máa wúlò fún wa tó bá dọ̀rọ̀ ká ‘gbèjà ìhìn rere, ká sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin.’—Fílípì 1:7.
Ó “Dúró Níwájú Ìjókòó Ìdájọ́” (Ìṣe 25:1-12)
3, 4. (a) Kí làwọn Júù tó ní kí wọ́n mú Pọ́ọ̀lù wá sí Jerúsálẹ́mù ń gbèrò láti ṣe, báwo ló sì ṣe bọ́ lọ́wọ́ ikú? (b) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, báwo ni Jèhófà ṣe ń ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ lónìí?
3 Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta tí ìjọba Róòmù fi Fẹ́sítọ́ọ̀sì jẹ gómìnà tó ń ṣàkóso Jùdíà, Fẹ́sítọ́ọ̀sì lọ sí Jerúsálẹ́mù.a Nígbà tó débẹ̀ àwọn olórí àlùfáà àtàwọn sàràkí-sàràkí lára àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù láìdáa. Wọ́n mọ̀ pé gómìnà tuntun yìí á fẹ́ ṣe ohun táwọn fẹ́, á sì fẹ́ tẹ́ àwọn Júù tó kù lọ́rùn. Torí náà, wọ́n bẹ Fẹ́sítọ́ọ̀sì pé kó mú Pọ́ọ̀lù wá sí Jerúsálẹ́mù, kó sì fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò níbẹ̀. Àmọ́, iṣẹ́ ibi kan ni wọ́n fẹ́ ṣe. Ṣe ni wọ́n ń gbèrò láti pa Pọ́ọ̀lù lójú ọ̀nà Kesaríà sí Jerúsálẹ́mù. Fẹ́sítọ́ọ̀sì ò fara mọ́ ohun tí wọ́n sọ, ó wá sọ pé ‘káwọn tó wà nípò àṣẹ láàárín wọn bá òun lọ sí Kesaríà, kí wọ́n sì fẹ̀sùn kan Pọ́ọ̀lù, tó bá jẹ́ pé òótọ́ ló ti ṣe ohun tí kò tọ́.’ (Ìṣe 25:5) Bí Pọ́ọ̀lù tún ṣe bọ́ lọ́wọ́ ikú nìyẹn o.
4 Ní gbogbo ìgbà tí Pọ́ọ̀lù wà nínú ìṣòro yìí, Jèhófà lo Jésù Kristi Olúwa láti fún un lókun. Ẹ rántí pé nínú ìran kan, Jésù sọ fún àpọ́sítélì rẹ̀ yìí pé: “Mọ́kàn le!” (Ìṣe 23:11) Lóde òní, àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run náà máa ń ní ìṣòro, àwọn èèyàn sì máa ń ṣe inúnibíni sí wa. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kì í gbà wá lọ́wọ́ gbogbo ìṣòro, ó máa ń fún wa lọ́gbọ́n àti okun ká lè fara dà á. Ó tún máa ń fún wa ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá” torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa.—2 Kọ́r. 4:7.
5. Kí ni Fẹ́sítọ́ọ̀sì ṣe nígbà tó ń gbọ́ ẹjọ́ Pọ́ọ̀lù?
5 Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Fẹ́sítọ́ọ̀sì “jókòó sórí ìjókòó ìdájọ́” ní Kesaríà.b Pọ́ọ̀lù àtàwọn tó fẹ̀sùn kàn án dúró níwájú Fẹ́sítọ́ọ̀sì. Ohun tí Pọ́ọ̀lù ò ṣe ni wọ́n sọ pé ó ṣe. Pọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Mi ò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan sí Òfin àwọn Júù tàbí sí tẹ́ńpìlì tàbí sí Késárì.” Ká sòótọ́, àpọ́sítélì yìí ò jẹ̀bi, ó sì yẹ kí wọ́n dá a sílẹ̀. Kí ni Fẹ́sítọ́ọ̀sì wá ṣe? Torí pé ó ń wá ojúure àwọn Júù, ó béèrè lọ́wọ́ Pọ́ọ̀lù pé: “Ṣé o fẹ́ lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí a lè dá ẹjọ́ rẹ níbẹ̀ níwájú mi lórí àwọn nǹkan yìí?” (Ìṣe 25:6-9) Àbẹ́ ò rí nǹkan, ṣé ó tún yẹ kó béèrè irú ìbéèrè yìí? Tí wọ́n bá mú Pọ́ọ̀lù lọ sí Jerúsálẹ́mù pẹ́nrẹ́n, àwọn tó ń ta kò ó ló máa ṣèdájọ́ ẹ̀ fúnra wọn, tí wọ́n á sì pa á. Dípò kí Fẹ́sítọ́ọ̀sì ṣe ohun tó tọ́, ṣe ló yàn láti tẹ́ àwọn èèyàn lọ́rùn kí wọ́n lè gba tiẹ̀. Òun kọ́ lẹni àkọ́kọ́ tó máa ṣerú ẹ̀, Pọ́ńtíù Pílátù tó jẹ́ gómìnà nígbà kan rí náà ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó ń gbọ́ ẹjọ́ Jésù. (Jòh. 19:12-16) Lóde òní, àwọn adájọ́ lè dájọ́ lọ́nà tí kò tọ́ torí kí wọ́n lè rí ojúure àwọn èèyàn. Torí náà, tí wọ́n bá fẹ̀sùn kan àwa èèyàn Ọlọ́run, tí wọ́n sì gbé wa lọ sílé ẹjọ́, kó yẹ kó yà wá lẹ́nu pé àwọn adájọ́ lè dá wa lẹ́bi lórí ohun tá ò ṣe.
6, 7. Kí ló mú kí Pọ́ọ̀lù ké gbàjarè sí Késárì, kí làwa Kristẹni sì rí kọ́ nínú ohun tó ṣe yìí?
6 Bí Fẹ́sítọ́ọ̀sì ṣe ń wá ojúure àwọn Júù yìí lè yọrí sí ikú fún Pọ́ọ̀lù. Torí náà, Pọ́ọ̀lù fi ẹ̀tọ́ tó ní gẹ́gẹ́ bí aráàlú Róòmù gbèjà ara ẹ̀. Ó sọ fún Fẹ́sítọ́ọ̀sì pé: “Mo dúró níwájú ìjókòó ìdájọ́ Késárì, níbi tó yẹ kí a ti dá ẹjọ́ mi. Mi ò ṣe àìdáa kankan sí àwọn Júù, bí ìwọ náà ṣe ń rí i kedere báyìí. . . . Mo ké gbàjarè sí Késárì!” Tẹ́nì kan bá ké gbàjarè sí Késárì, ṣe lonítọ̀hún pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, kò sì ṣeé yí pa dà. Èyí ló mú kí Fẹ́sítọ́ọ̀sì tẹnu mọ́ ọn pé: “Késárì lo ké gbàjarè sí; ọ̀dọ̀ Késárì ni wàá sì lọ.” (Ìṣe 25:10-12) Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ké gbàjarè sí Késárì jẹ́ ká rí i pé àwa Kristẹni lè ṣe ohun kan náà tá a bá bára wa nírú ipò bẹ́ẹ̀. Nígbà táwọn tó ń ta kò wá bá ń “fi òfin bojú láti dáná ìjàngbọ̀n,” àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fi ẹ̀tọ́ tá a ní lábẹ́ òfin gbèjà ìhìn rere.c—Sm. 94:20.
7 Lẹ́yìn ohun tó lé lọ́dún méjì tí wọ́n ti fi Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n láìṣẹ̀, wọ́n fún un láǹfààní láti lọ sọ tẹnu ẹ̀ ní Róòmù. Àmọ́ kó tó lọ, aláṣẹ míì sọ pé òun fẹ́ rí i.
“Mi Ò Ṣàìgbọràn” (Ìṣe 25:13–26:23)
8, 9. Kí nìdí tí Ọba Ágírípà fi ṣèbẹ̀wò sí Kesaríà?
8 Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ fún Fẹ́sítọ́ọ̀sì pé òun ké gbàjarè sí Késárì, Ọba Ágírípà àti Bẹ̀níìsì arábìnrin rẹ̀ ṣe “ìbẹ̀wò àyẹ́sí” sọ́dọ̀ gómìnà tuntun yìí.d Nílùú Róòmù nígbà yẹn, àwọn aláṣẹ máa ń ṣerú ìbẹ̀wò bẹ́ẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn gómìnà tuntun. Yàtọ̀ sí pé Ágírípà wá bá Fẹ́sítọ́ọ̀sì yọ̀ pé ó ti di gómìnà, ó tún lo àkókò yìí láti fi wá bí àárín òun àti Fẹ́sítọ́ọ̀sì ṣe máa gún dáadáa torí ọjọ́ iwájú.—Ìṣe 25:13.
9 Fẹ́sítọ́ọ̀sì sọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù fún Ọba Ágírípà, ọba sì sọ pé òun á fẹ́ gbọ́ tẹnu Pọ́ọ̀lù. Lọ́jọ́ kejì, àwọn alákòóso méjèèjì jókòó sórí ìjókòó ìdájọ́. Oríṣiríṣi nǹkan ni wọ́n ṣe láti wú àwọn èèyàn lórí nígbá tí wọ́n ń wọlé, àmọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ṣe náà ò tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹlẹ́wọ̀n tó wà níwájú wọn máa tó sọ.—Ìṣe 25:22-27.
10, 11. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe bọ̀wọ̀ fún Ọba Ágírípà, àwọn nǹkan wo ni Pọ́ọ̀lù sì sọ fún un nípa irú ẹni tóun jẹ́ tẹ́lẹ̀?
10 Pọ́ọ̀lù fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọba Ágírípà pé ó fún òun láǹfààní láti gbèjà ara òun, ó sì sọ pé ọba yìí jẹ́ ọ̀jáfáfá nínú gbogbo àṣà àti àríyànjiyàn àwọn Júù. Pọ́ọ̀lù wá sọ irú ẹni tóun jẹ́ tẹ́lẹ̀, ó ní: “Ìgbé ayé Farisí ni mo gbé ní ìlànà ẹ̀ya ìsìn tí kò gba gbẹ̀rẹ́ rárá, ti ọ̀nà ìjọsìn wa.” (Ìṣe 26:5) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ṣì jẹ́ Farisí, ó gbà pé Mèsáyà ń bọ̀. Ní báyìí tó ti wá di Kristẹni, ó ń fìgboyà wàásù pé Jésù Kristi ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí náà. Pọ́ọ̀lù wá sọ fún Ágírípà pé ọ̀rọ̀ nípa ìlérí yẹn ló mú káwọn alátakò máa ṣenúnibíni sóun, bẹ́ẹ̀ sì rèé àwọn náà ń retí ìgbà tí Ọlọ́run máa mú ìlérí náà ṣẹ. Àlàyé yìí mú kí Ágírípà túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sóhun tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ sọ.e
11 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ bó ṣe ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni, ó ní: “Ní tèmi, mo gbà tẹ́lẹ̀ pé ó yẹ kí n gbé ọ̀pọ̀ àtakò dìde sí orúkọ Jésù ará Násárẹ́tì. . . . Torí pé inú [àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi] ń bí mi gidigidi, mo bá a débi pé mo ṣe inúnibíni sí wọn ní àwọn ìlú tó wà lẹ́yìn òde pàápàá.” (Ìṣe 26:9-11) Kì í ṣe àsọdùn ni Pọ́ọ̀lù ń sọ o! Torí pé ọ̀pọ̀ ló mọ̀ nípa inúnibíni tó gbóná tó ṣe sáwọn Kristẹni. (Gál. 1:13, 23) Ó ṣeé ṣe kí Ágírípà máa ṣe kàyéfì pé, ‘Kí ló lè mú kírú ọkùnrin yìí yí pa dà?’
12, 13. (a) Àlàyé wo ni Pọ́ọ̀lù ṣe nípa bó ṣe di Kristẹni? (b) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ń “tàpá sí ọ̀pá kẹ́sẹ́”?
12 Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ tẹ̀ lé e dáhùn ìbéèrè tó ṣeé ṣe kó wà lọ́kàn ọba, ó ní: “Nígbà tí mò ń rìnrìn àjò lọ sí Damásíkù pẹ̀lú àṣẹ àti agbára látọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, lójú ọ̀nà ní ọ̀sán gangan, ìwọ Ọba, mo rí ìmọ́lẹ̀ kan tó ju ìtànṣán oòrùn, tó kọ mànà láti ọ̀run yí mi ká àti yí àwọn tí a jọ ń rìnrìn àjò ká. Nígbà tí gbogbo wa sì ṣubú lulẹ̀, mo gbọ́ ohùn kan tó sọ fún mi lédè Hébérù pé: ‘Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù, kí ló dé tí ò ń ṣe inúnibíni sí mi? Tí o bá ń tàpá sí ọ̀pá kẹ́sẹ́, ó máa nira fún ọ.’ Àmọ́ mo sọ pé: ‘Ta ni ọ́, Olúwa?’ Olúwa sì fèsì pé: ‘Èmi ni Jésù, ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí.’ ”f—Ìṣe 26:12-15.
13 Kí ohun àrà yìí tó ṣẹlẹ̀, ṣe ló dà bíi pe Pọ́ọ̀lù ń “tàpá sí ọ̀pá kẹ́sẹ́.” Bó ṣe jẹ́ pé ńṣe ni ẹranko tí wọ́n fi ń kó ẹrù máa ṣe ara ẹ̀ léṣe tó bá ń ta ibi tó mú lára ọ̀pá kẹ́sẹ́ nípàá, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé ńṣe ni Pọ́ọ̀lù ń ṣàkóbá fún ara ẹ̀ bó ṣe ń ta ko ìfẹ́ Ọlọ́run, torí pé ìyẹn ò ní jẹ́ kó ní àjọṣe kankan pẹ̀lú Ọlọ́run. Nígbà tí Jésù tó ti jíǹde fara han Pọ́ọ̀lù lójú ọ̀nà Damásíkù, ó mú kí ọkùnrin olóòótọ́ yìí, tí wọ́n ti ṣì lọ́nà yí èrò ẹ̀ pa dà.—Jòh. 16:1, 2.
14, 15. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn àyípadà tó ti ṣe nígbèésí ayé ẹ̀?
14 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù yìí mú kó yíwà pa dà pátápátá. Ó sọ fún Ágírípà pé: “Mi ò ṣàìgbọràn sí ìran àtọ̀runwá náà, àmọ́ mo jẹ́ iṣẹ́ náà fún àwọn tó wà ní Damásíkù lákọ̀ọ́kọ́, lẹ́yìn náà fún àwọn tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti fún gbogbo ilẹ̀ Jùdíà àti fún àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú, pé kí wọ́n ronú pìwà dà, kí wọ́n sì yíjú sí Ọlọ́run nípa ṣíṣe àwọn iṣẹ́ tó fi ìrònúpìwàdà hàn.” (Ìṣe 26:19, 20) Nínú ìran tí Jésù Kristi fi han Pọ́ọ̀lù lọ́sàn-án ọjọ́ yẹn, Jésù gbé iṣẹ́ pàtàkì kan fún Pọ́ọ̀lù, ọ̀pọ̀ ọdún ló sì fi ṣiṣẹ́ náà. Kí ló wá yọrí sí? Àwọn tó gbọ́ ìhìn rere tí Pọ́ọ̀lù wàásù tí wọ́n sì fara mọ́ ọn, ronú pìwà dà, wọ́n jáwọ́ nínú ìṣekúṣe àti àìṣòótọ́ wọn, wọ́n sì yí pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n wá di ọmọ orílẹ̀-èdè rere, wọ́n ń bọ̀wọ̀ fún òfin àti ètò ìlú, wọ́n sì di ẹni àlàáfíà.
15 Àmọ́, gbogbo ìyẹn ò jọ àwọn Júù tó ń ta ko Pọ́ọ̀lù lójú. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìdí nìyí tí àwọn Júù fi gbá mi mú nínú tẹ́ńpìlì, tí wọ́n sì fẹ́ pa mí. Àmọ́ torí pé mo rí ìrànlọ́wọ́ gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, mò ń jẹ́rìí nìṣó títí di òní yìí fún ẹni kékeré àti ẹni ńlá.”—Ìṣe 26:21, 22.
16. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù nígbà tá a bá ń bá àwọn adájọ́ àtàwọn aláṣẹ sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a gbà gbọ́?
16 Àwa Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ “ṣe tán nígbà gbogbo láti gbèjà” ìgbàgbọ́ wa. (1 Pét. 3:15) A lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe nígbà tó ń bá Ágírípà àti Fẹ́sítọ́ọ̀sì sọ̀rọ̀. Èyí máa ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ń bá àwọn adájọ́ àtàwọn aláṣẹ sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a gbà gbọ́. Tá a bá fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ bí òtítọ́ Bíbélì ṣe tún ìgbésí ayé wa ṣe àti bó ṣe ń ran àwọn tó ń gbọ́rọ̀ wa lọ́wọ́, ó ṣeé ṣe kíyẹn mú káwọn aláṣẹ náà yí èrò wọn pa dà.
“Wàá Sọ Mí Di Kristẹni” (Ìṣe 26:24-32)
17. Kí ni Fẹ́sítọ́ọ̀sì sọ nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń gbèjà ara ẹ̀, báwo ni ìwà ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí sì ṣe jọ ti Fẹ́sítọ́ọ̀sì?
17 Bí Fẹ́sítọ́ọ̀sì àti Ágírípà ṣe ń gbọ́ ọ̀rọ̀ tó ń múni ronú jinlẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù ń sọ nípa ara ẹ̀, ọ̀rọ̀ náà wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an. Kíyè sí ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà: “Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń sọ àwọn nǹkan yìí láti gbèjà ara rẹ̀, Fẹ́sítọ́ọ̀sì kígbe pé: ‘Orí ẹ ti ń dà rú, Pọ́ọ̀lù! Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ti ń dà ẹ́ lórí rú!’ ” (Ìṣe 26:24) Ohun tí Fẹ́sítọ́ọ̀sì sọ yìí ò yàtọ̀ sí èrò àwọn èèyàn lónìí. Lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, agbawèrèmẹ́sìn làwọn tó ń kọ́ni lóhun tí Bíbélì sọ. Ó sì máa ń ṣòro fáwọn ọlọ́gbọ́n ayé láti gba ẹ̀kọ́ Bíbélì nípa àjíǹde àwọn òkú gbọ́.
18. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe dá Fẹ́sítọ́ọ̀sì lóhùn, kí nìyẹn sì mú kí Ágírípà sọ?
18 Pọ́ọ̀lù fún gómìnà náà lésì, ó sọ pé: “Kì í ṣe pé orí mi ń dà rú, Fẹ́sítọ́ọ̀sì Ọlọ́lá Jù Lọ, òótọ́ ọ̀rọ̀ tó mọ́gbọ́n dání ni mò ń sọ. Ká sòótọ́, ọba tí mò ń bá sọ̀rọ̀ ní fàlàlà gan-an mọ̀ nípa àwọn nǹkan yìí dáadáa . . . Ọba Ágírípà, ṣé o gba àwọn Wòlíì gbọ́? Mo mọ̀ pé o gbà wọ́n gbọ́.” Ṣùgbọ́n Ágírípà sọ fún Pọ́ọ̀lù pé: “Ní àkókò díẹ̀ sí i, wàá sọ mí di Kristẹni.” (Ìṣe 26:25-28) Tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ orí ahọ́n ni Ágírípà sọ, ohun kan tó dájú ni pé ìwàásù Pọ́ọ̀lù wọ̀ ọ́ lọ́kàn.
19. Kí ni Ágírípà àti Fẹ́sítọ́ọ̀sì kíyè sí nínú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù?
19 Bí Ágírípà àti Fẹ́sítọ́ọ̀sì ṣe dìde nìyẹn, àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ sì tú ká. “Bí wọ́n ṣe ń fi ibẹ̀ sílẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn sọ̀rọ̀, pé: ‘Ọkùnrin yìí ò ṣe nǹkan kan tó yẹ fún ikú tàbí ìdè ẹ̀wọ̀n.’ Ágírípà wá sọ fún Fẹ́sítọ́ọ̀sì pé: ‘À bá dá ọkùnrin yìí sílẹ̀ ká ní kò ké gbàjarè sí Késárì.’ ” (Ìṣe 26:31, 32) Wọ́n rí i pé ọkùnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ níwájú àwọn yìí ò jẹ̀bi rárá. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí sì lè jẹ́ kí wọ́n máa fi ojú tó dáa wo àwọn Kristẹni.
20. Kí nìdí tó fi dáa bí Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́jọ́ níwájú àwọn aláṣẹ?
20 Kò jọ pé èyíkéyìí nínú àwọn alákòóso tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí di Kristẹni lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún wọn. Ṣé ó wá bọ́gbọ́n mu bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe lọ jẹ́jọ́ níwájú àwọn ọkùnrin yẹn? Bẹ́ẹ̀ ni. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́jọ́ níwájú “àwọn ọba àti àwọn gómìnà” ní Jùdíà yìí fún un láǹfààní láti wàásù fáwọn aláṣẹ náà, bẹ́ẹ̀ sì rèé ì bá má rọrùn fáwọn Kristẹni láti wàásù fún wọn. (Lúùkù 21:12, 13) Bákan náà, àwọn ìrírí tí Pọ́ọ̀lù ní àti bó ṣe dúró gbọin-in bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣenúnibíni sí i fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni níṣìírí.—Fílí. 1:12-14.
21. Àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń bá a nìṣó láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run?
21 Ohun kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ lóde òní. Ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa ń rí bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run láìka inúnibíni àti àtakò sí. A lè láǹfààní láti wàásù fáwọn aláṣẹ tó jẹ́ pé ì bá má ṣeé ṣe fún wa láti dé ọ̀dọ̀ wọn. Tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin tá a sì ń fara dà á, a máa fún àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni níṣìírí, ìyẹn á sì jẹ́ káwọn náà túbọ̀ máa fìgboyà jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba Ọlọ́run.
a Wo àpótí náà, “Pọ́kíọ́sì Fẹ́sítọ́ọ̀sì—Gómìnà Róòmù.”
b Àga kan tí wọ́n gbé sórí pèpéle ni wọ́n ń pè ní “ìjókòó ìdájọ́.” Àwọn èèyàn gbà pé ìdájọ́ tí wọ́n bá ṣe lórí pèpéle gíga yìí labẹ́ gé, kò sì ṣeé yí pa dà. Orí ìjókòó ìdájọ́ ni Pílátù wà nígbà tó pàṣẹ pé kí wọ́n lọ pa Jésù.
c Wo àpótí náà, “À Ń Pe Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Ká Lè Máa Jọ́sìn Láìsí Ìdíwọ́.”
d Wo àpótí náà, “Ọba Hẹ́rọ́dù Ágírípà Kejì.”
e Torí pé Kristẹni ni Pọ́ọ̀lù, ó gbà pé Jésù ni Mèsáyà náà. Àmọ́ lójú àwọn Júù tí wọn ò gba Jésù gbọ́, apẹ̀yìndà ni Pọ́ọ̀lù.—Ìṣe 21:21, 27, 28.
f Ní ti ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé òun ń rìnrìn àjò “ní ọ̀sán gangan,” onímọ̀ Bíbélì kan sọ pé: “Tí kì í bá ṣe pé ọ̀rọ̀ kan jẹ́ kánjúkánjú, ńṣe làwọn arìnrìn-àjò máa ń sinmi nígbà tí oòrùn bá ń mú gan-an lọ́sàn-án. Èyí jẹ́ ká rí i pé inúnibíni tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ lọ ṣe yẹn ká a lára gan-an.”