Nehemáyà
9 Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù yìí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kóra jọ; wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀,* wọ́n sì da iyẹ̀pẹ̀ sórí.+ 2 Àwọn àtọmọdọ́mọ Ísírẹ́lì wá ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára gbogbo àwọn àjèjì,+ wọ́n dìde dúró, wọ́n sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àṣìṣe àwọn bàbá wọn.+ 3 Lẹ́yìn náà, wọ́n dìde dúró ní àyè wọn, wọ́n sì fi wákàtí mẹ́ta* ka ìwé Òfin+ Jèhófà Ọlọ́run wọn sókè; wọ́n fi wákàtí mẹ́ta míì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n sì ń wólẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run wọn.
4 Jéṣúà, Bánì, Kádímíélì, Ṣebanáyà, Búnì, Ṣerebáyà,+ Bánì àti Kénánì dúró lórí pèpéle+ àwọn ọmọ Léfì, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì ń sunkún sí Jèhófà Ọlọ́run wọn. 5 Àwọn ọmọ Léfì, ìyẹn Jéṣúà, Kádímíélì, Bánì, Haṣabanéáyà, Ṣerebáyà, Hodáyà, Ṣebanáyà àti Petaháyà sọ pé: “Ẹ dìde, kí ẹ yin Jèhófà Ọlọ́run yín títí láé àti láéláé.*+ Kí wọ́n yin orúkọ rẹ ológo, èyí tí a gbé ga ju gbogbo ìbùkún àti ìyìn lọ.
6 “Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Jèhófà;+ ìwọ lo dá ọ̀run, àní ọ̀run àwọn ọ̀run àti gbogbo ọmọ ogun wọn, ayé àti gbogbo ohun tó wà lórí rẹ̀, àwọn òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú wọn. O pa gbogbo wọn mọ́, àwọn ọmọ ogun ọ̀run sì ń forí balẹ̀ fún ọ. 7 Ìwọ ni Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, tó yan Ábúrámù,+ tó mú un jáde kúrò ní Úrì,+ ìlú àwọn ará Kálídíà, tó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Ábúráhámù.+ 8 O rí i pé ó jẹ́ olóòótọ́ níwájú rẹ,+ torí náà, o bá a dá májẹ̀mú láti fún un ní ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn Pérísì, àwọn ará Jébúsì àti àwọn Gẹ́gáṣì, pé kó fún àwọn ọmọ* rẹ̀;+ o sì mú ìlérí rẹ ṣẹ nítorí pé olódodo ni ọ́.
9 “O rí ìpọ́njú àwọn baba ńlá wa ní Íjíbítì,+ o sì gbọ́ igbe ẹkún wọn ní Òkun Pupa. 10 O wá ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu láti fìyà jẹ Fáráò àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ rẹ̀,+ torí o mọ̀ pé wọ́n ti kọjá àyè wọn+ sí àwọn èèyàn rẹ. O ṣe orúkọ fún ara rẹ, orúkọ náà sì wà títí dòní.+ 11 O pín òkun sí méjì níwájú wọn, kí wọ́n lè gba àárín òkun kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ,+ o fi àwọn tó ń lépa wọn sọ̀kò sínú ibú bí òkúta tí a jù sínú omi tó ń ru gùdù.+ 12 O fi ọwọ̀n ìkùukùu* darí wọn ní ọ̀sán, o sì fi ọwọ̀n iná* darí wọn ní òru, láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀nà tí wọ́n máa gbà.+ 13 O sọ̀ kalẹ̀ sórí Òkè Sínáì,+ o bá wọn sọ̀rọ̀ láti ọ̀run,+ o sì fún wọn ní àwọn ìdájọ́ òdodo, àwọn òfin òtítọ́,* àwọn ìlànà àti àwọn àṣẹ tó dáa.+ 14 O jẹ́ kí wọ́n mọ Sábáàtì mímọ́+ rẹ, o sì fún wọn ní àṣẹ, ìlànà àti òfin nípasẹ̀ Mósè ìránṣẹ́ rẹ. 15 O fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run nígbà tí ebi ń pa wọ́n,+ o fún wọn ní omi látinú àpáta nígbà tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n,+ o sì ní kí wọ́n wọ ilẹ̀ tí o búra* pé wàá fún wọn, kí wọ́n sì gbà á.
16 “Àmọ́, àwọn baba ńlá wa kọjá àyè wọn,+ wọ́n sì ya alágídí,*+ wọn kò fetí sí àwọn àṣẹ rẹ. 17 Wọn ò fetí sílẹ̀,+ wọn ò sì rántí àwọn ohun àgbàyanu tí o ṣe láàárín wọn, àmọ́ wọ́n ya alágídí,* wọ́n sì yan olórí láti kó wọn pa dà sí ipò ẹrú wọn ní Íjíbítì.+ Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tó ṣe tán láti dárí jini* ni ọ́, o jẹ́ ẹni tó ń gba tẹni rò* àti aláàánú, o kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀* sì pọ̀ gidigidi,+ o ò pa wọ́n tì.+ 18 Kódà nígbà tí wọ́n ṣe ère onírin* ọmọ màlúù fún ara wọn, tí wọ́n sì ń sọ pé, ‘Ọlọ́run rẹ nìyí tó mú ọ jáde kúrò ní Íjíbítì,’+ tí wọ́n hu ìwà àìlọ́wọ̀ tó bùáyà, 19 síbẹ̀ ìwọ, nínú àánú ńlá rẹ, o ò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ nínú aginjù.+ Ọwọ̀n ìkùukùu* kò kúrò lórí wọn ní ọ̀sán láti máa darí wọn ní ọ̀nà wọn, ọwọ̀n iná* kò sì kúrò ní òru láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀nà tí wọ́n máa gbà.+ 20 O fún wọn ní ẹ̀mí rere rẹ láti jẹ́ kí wọ́n ní ìjìnlẹ̀ òye,+ o ò fawọ́ mánà rẹ sẹ́yìn kúrò ní ẹnu wọn,+ o sì fún wọn ní omi nígbà tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n.+ 21 Ogójì (40) ọdún lo fi pèsè oúnjẹ fún wọn ní aginjù.+ Wọn ò ṣaláìní nǹkan kan. Aṣọ wọn ò gbó,+ ẹsẹ̀ wọn ò sì wú.
22 “O fún wọn ní àwọn ìjọba àti àwọn èèyàn, o sì pín wọn ní ẹyọ-ẹyọ fún wọn,+ kí wọ́n lè gba ilẹ̀ Síhónì,+ ìyẹn ilẹ̀ ọba Hẹ́ṣíbónì+ àti ilẹ̀ Ógù+ ọba Báṣánì. 23 O mú kí àwọn ọmọ wọn pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run.+ Lẹ́yìn náà, o mú wọn wá sí ilẹ̀ tí o ṣèlérí fún àwọn baba ńlá wọn pé kí wọ́n wọ̀, kí wọ́n sì gbà.+ 24 Torí náà, àwọn ọmọ wọn wọlé, wọ́n sì gba ilẹ̀ náà,+ o ṣẹ́gun àwọn ọmọ Kénáánì tó ń gbé ilẹ̀ náà níwájú wọn,+ o sì fi wọ́n lé wọn lọ́wọ́, látorí àwọn ọba wọn dórí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà, kí wọ́n lè ṣe wọ́n bí wọ́n ṣe fẹ́. 25 Wọ́n gba àwọn ìlú olódi+ àti ilẹ̀ ọlọ́ràá,*+ wọ́n gba àwọn ilé tí oríṣiríṣi ohun rere kún inú rẹ̀, wọ́n gba àwọn kòtò omi tí wọ́n ti gbẹ́ síbẹ̀, àwọn ọgbà àjàrà, àwọn oko ólífì+ àti àwọn igi eléso tó pọ̀ rẹpẹtẹ. Torí náà, wọ́n jẹ, wọ́n yó, wọ́n sì sanra, wọ́n gbádùn oore ńlá rẹ.
26 “Àmọ́, wọ́n ya aláìgbọràn, wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọ,+ wọ́n sì kẹ̀yìn sí Òfin rẹ.* Wọ́n pa àwọn wòlíì rẹ tó kìlọ̀ fún wọn láti mú wọn pa dà sọ́dọ̀ rẹ, wọ́n sì hu ìwà àìlọ́wọ̀ tó bùáyà.+ 27 Nítorí èyí, o fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn,+ wọ́n sì ń kó wàhálà bá wọn.+ Àmọ́, wọ́n á ké pè ọ́ ní àkókò wàhálà wọn, ìwọ náà á sì gbọ́ láti ọ̀run; nítorí àánú ńlá rẹ, wàá fún wọn ní olùgbàlà láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.+
28 “Àmọ́, nígbà tí ara bá ti tù wọ́n, wọ́n á tún ṣe ohun tó burú níwájú rẹ,+ wàá sì fi wọ́n sílẹ̀ sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n á sì jọba lé wọn lórí.*+ Lẹ́yìn náà, wọ́n á pa dà, wọ́n á sì ké pè ọ́ pé kí o ran àwọn lọ́wọ́,+ wàá gbọ́ láti ọ̀run, léraléra lo sì ń gbà wọ́n nítorí àánú ńlá rẹ.+ 29 O máa ń kìlọ̀ fún wọn kí o lè mú wọn pa dà wá sínú Òfin rẹ, síbẹ̀ ṣe ni wọ́n ń kọjá àyè wọn, wọn ò sì fetí sí àwọn àṣẹ rẹ;+ wọ́n ń ṣe ohun tó ta ko ìlànà rẹ, èyí tó máa jẹ́ kẹ́ni tó ba ń pa á mọ́ lè wà láàyè.+ Agídí wọn mú kí wọ́n kẹ̀yìn sí ọ, wọ́n mú kí ọrùn wọn le, wọn ò sì fetí sílẹ̀. 30 Ọ̀pọ̀ ọdún lo fi mú sùúrù fún wọn,+ o sì ń fi ẹ̀mí rẹ kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ, àmọ́ wọn ò gbọ́. Níkẹyìn, o fi wọ́n lé àwọn èèyàn ilẹ̀ tó yí wọn ká lọ́wọ́.+ 31 Nínú àánú ńlá rẹ, o ò pa wọ́n run,+ o ò sì fi wọ́n sílẹ̀, nítorí Ọlọ́run tó ń gba tẹni rò* àti aláàánú ni ọ́.+
32 “Ní báyìí, ìwọ Ọlọ́run wa, Ọlọ́run títóbi, alágbára ńlá, tó sì yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù, tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́, tí ó sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn,+ má fojú kékeré wo gbogbo ìnira tó bá àwa, àwọn ọba wa, àwọn ìjòyè wa,+ àwọn àlùfáà wa,+ àwọn wòlíì wa,+ àwọn baba ńlá wa àti gbogbo àwọn èèyàn rẹ láti ìgbà àwọn ọba Ásíríà+ títí di òní yìí. 33 O ò lẹ́bi kankan nínú gbogbo ohun tó dé bá wa, nítorí òótọ́ lo fi bá wa lò; àwa la hùwà burúkú.+ 34 Ní ti àwọn ọba wa, àwọn ìjòyè wa, àwọn àlùfáà wa àti àwọn baba ńlá wa, wọn ò pa Òfin rẹ mọ́, wọn ò sì fiyè sí àwọn àṣẹ rẹ tàbí àwọn ìránnilétí* rẹ tí o fi kìlọ̀ fún wọn. 35 Kódà nígbà tí wọ́n wà lábẹ́ ìjọba ti ara wọn, tí wọ́n sì ń gbádùn ọ̀pọ̀ ohun rere tí o fún wọn, tí wọ́n ń gbé lórí ilẹ̀ tó fẹ̀, tó sì lọ́ràá* tí o fi jíǹkí wọn, wọn ò sìn ọ́,+ wọn ò sì jáwọ́ nínú ìwà búburú tí wọ́n ń hù. 36 Àwa rèé lónìí, àwa ẹrú,+ bẹ́ẹ̀ ni, ẹrú lórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wa pé kí wọ́n máa jẹ èso rẹ̀ àti ohun rere rẹ̀. 37 Ọ̀pọ̀ àwọn ohun rere tí ilẹ̀ náà ń mú jáde jẹ́ ti àwọn ọba tí o fi ṣe olórí wa nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.+ Wọ́n ń ṣàkóso àwa* àti àwọn ẹran ọ̀sìn wa bó ṣe wù wọ́n, a sì wà nínú wàhálà ńlá.
38 “Pẹ̀lú gbogbo èyí, a wọnú àdéhùn kan, a sì kọ àdéhùn+ náà sílẹ̀, àwọn ìjòyè wa, àwọn ọmọ Léfì wa àti àwọn àlùfáà wa ti fọwọ́ sí i, wọ́n sì gbé èdìdì lé e.”+