Àwọn Ènìyàn Tí A Kọ́ Láti Nífẹ̀ẹ́
ÌFẸ́ jẹ́ ìkúndùn tí a gbé karí ìjọnilójú, inúure, tàbí àwọn ìfẹ́ ọkàn àjùmọ̀ní. Ìfẹ́ jẹ́ ìfàmọ́ni ọlọ́yàyà. Kò mọ tara rẹ̀ nìkan, kì í yẹ̀, ó sì ń fi ìdàníyàn onínúure hàn fún ire àwọn ẹlòmíràn. Ìfẹ́ ni òdì kejì gan-an fún ìríra. Ẹnì kan tí ìríra bá ń sún ṣe nǹkan máa ń ro ti ara rẹ̀ nìkan; ẹni tí ìfẹ́ bá ń sún ṣe nǹkan ń ro ti àwọn ẹlòmíràn.
Ìfẹ́ tàbí ìríra—èwo ló ń jọba lórí ìgbésí ayé rẹ? Èyí kì í wulẹ̀ ṣe ìbéèrè kan tí kò ṣe pàtàkì, nítorí pé ọjọ́ ọ̀la rẹ ayérayé sinmi lórí ohun tí ìdáhùn náà bá jẹ́. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ń kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ nígbà tí wọ́n ń gbé nínú ayé kan tí a ti kọ́ láti kórìíra. Wọ́n ń ṣe èyí nípa gbígbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ. Wọn kò wulẹ̀ máa sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́; wọ́n ń tiraka gidigidi láti máa fi hùwà.
Bí o bá ti lọ sí ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí, ohun tí o rí níbẹ̀ lè ti wú ọ lórí. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà ní ìṣọ̀kan nínú ìjọsìn, láìka ọmọ orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ sí. Wọ́n jẹ́ ojúlówó ẹgbẹ́ àwọn ará kan kárí ayé. O lè ṣàkíyèsí èyí nínú àwọn ìjọ wọn ládùúgbò àti ní àwọn àpéjọpọ̀ wọn, ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ibi tí ó ti hàn gbangba jù lọ ní ohun tí wọ́n ń pè ní àwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn àwùjọ olùyọ̀ǹda ara ẹni tí ń gbé pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ ní ṣíṣe ìmújáde àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti pípín wọn kiri. Ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan, àwọn kan lára wọn ń bójú tó iṣẹ́ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe níbẹ̀. Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni èyí, nítorí—bí ó ti rí ní 1997—ó kan àwọn ìjọ tí ó lé ní 82,000 ní ilẹ̀ 233. Láti kájú àìní yìí, àwọn ènìyàn tí ó lé ní 16,000 ń ṣiṣẹ́ ní àwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì jákèjádò ayé, títí kan orílé iṣẹ́ àgbáyé àti àwọn onírúurú ẹ̀ka kéékèèké tí ó wà ní ilẹ̀ 103.
Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ orílẹ̀-èdè tí a fìdí ọ́fíìsì ẹ̀ka náà sọlẹ̀ sí ló pọ̀ jù nínú ọ̀pọ̀ jù lọ ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Ṣùgbọ́n kì í jẹ́ àwọn nìkan pátápátá. Àwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì kan ní Àwọn Ẹlẹ́rìí láti onírúurú orílẹ̀-èdè, ìran, tàbí ẹ̀yà nínú, tí wọ́n sì ti wà nínú onírúurú ìsìn tẹ́lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìdílé Bẹ́tẹ́lì tí ó ní iye ènìyàn tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 1,200 nínú, tí ó wà ní Selters, Germany, wọ́n wá láti nǹkan bí 30 orílẹ̀-èdè. Kí ló mú kí wọ́n lè máa gbé pọ̀, kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ pọ̀, kí wọ́n sì máa jọ́sìn pa pọ̀ ní àlàáfíà àti ìṣọ̀kan, nínú àyíká tí kò ti sí ìríra? Wọ́n ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì nínú Kólósè 3:14, tí ó wí pé:
“Ẹ Fi Ìfẹ́ Wọ Ara Yín Láṣọ”
Kò sí ẹni tí a bí taṣọtaṣọ lọ́rùn, kò sì sí ẹni tí aṣọ ń dé ọrùn rẹ̀ nípa wíwulẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa aṣọ. Wíwọ ara ẹni láṣọ kan ṣíṣe àwọn ìpinnu pàtó, kí a sì wá sapá láti mú wọn ṣẹ. Lọ́nà kan náà, kò sí ẹni tí a bí ìfẹ́ mọ́ bí aṣọ. Wíwulẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ kò tó. Ó gba ìsapá.
Wíwọṣọ ní ète mélòó kan. Ó ń dáàbò bo ara, ó ń bo àṣírí ibi tí kò ṣeé rí tàbí àìpé ara, ó sì ń fi irú ẹni tí ẹnì kan jẹ́ hàn dé àyè kan. Ìfẹ́ rí bákan náà. Ó ń ṣiṣẹ́ bí ààbò nítorí pé ìfẹ́ fún àwọn ìlànà òdodo àti fún ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ bíbẹ́tọ̀ọ́mu máa ń mú kí a yẹra fún ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tàbí ọ̀gangan ibi tí ó lè léwu. Ó ń dáàbò bo ipò ìbátan ara ẹni, tí ó gbọ́dọ̀ ṣọ̀wọ́n fún wa. O túbọ̀ ṣeé ṣe kí a nífẹ̀ẹ́ ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́, ó sì túbọ̀ ṣeé ṣe kí ẹni tí ó bá ń fà sẹ́yìn kúrò nínú pípa àwọn ẹlòmíràn lára má ṣe ní ìpalára fúnra rẹ̀.
Ìfẹ́ máa ń bo àwọn ìhà tí kó ṣeé rí nínú àkópọ̀ ìwà wa, èyí tí ó lè jẹ́ ìdààmú fún àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa. A kò ha ní ìtẹ̀sí rírọrùn láti gbójú fo àwọn àṣìṣe kéékèèké tí àwọn ènìyàn tí ó nífẹ̀ẹ́ bá ṣe ju ti àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó ní ìgbéraga, ìjọra-ẹni-lójú, ìnìkànjọpọ́n, tí wọn kò sì nífẹ̀ẹ́ lọ bí?
Àwọn ènìyàn tí ó fi ìfẹ́ wọ ara wọn láṣọ ń gbé ẹwà àkópọ̀ ìwà bíi ti Kristi yọ. Nígbà tí ó jẹ́ pé ẹwà ara kò kọjá awọ ara, ẹwà tẹ̀mí wọnú gbogbo ara ẹnì kan. Ó ṣeé ṣe kí o mọ àwọn ènìyàn kan tí o kà sí arẹwà, kì í ṣe nítorí ìrísí òde ara wọn, ṣùgbọ́n ó jẹ́ nítorí ojúlówó àkópọ̀ ìwà ọlọ́yàyà tí wọ́n ní. Ní ìhà kejì, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa ti bá àwọn arẹwà lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin pàdé, tí ó jẹ́ pé, ní kété tí a bá ti rí irú ẹni tí wọ́n jẹ́ gan-an ni wọ́n ti ń pàdánù gbogbo ohun tí ń fani mọ́ra lára wọn. Ẹ wo bí ó ti gbádùn mọ́ni tó láti wà láyìíká àwọn ènìyàn tí wọ́n ti fi ìfẹ́ wọ ara wọn láṣọ!
Fífi Ìfẹ́ Rọ́pò Ìríra
Ìwádìí kan tí a ṣe nípa 145,958 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Germany ní 1994 fi hàn pé a lè fi ìfẹ́ rọ́pò ìríra.
Lọ́nà kan tàbí òmíràn, ọtí àmujù, ìjoògùnyó, ìwà ọ̀daràn, tẹ́tẹ́ títa, àti ìwà tí ń da àwùjọ rú tàbí ìwà ipá, para pọ̀ jẹ́ àfihàn ìmọtara-ẹni-nìkan, tí ó tètè máa ń fa ìríra. Àmọ́ ìpín 38.7 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò sọ pé àwọn ti borí ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú àwọn ìṣòro wọ̀nyí, kí àwọn lè dójú ìlà àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga ti Bíbélì, tí Àwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣagbátẹrù rẹ̀. Ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti fún àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo rẹ̀ lórí ìwà híhù ló mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pèsè ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́, tí ó sábà ń jẹ́ ní ẹnì kan sí ẹnì kan. Láàárín ọdún márùn-ún tó kọjá (1992 sí 1996), 1,616,894 ènìyàn láti 233 ilẹ̀ ni a ràn lọ́wọ́ láti ṣe ìyípadà, ní jíjẹ́ kí ìfẹ́ tí ń ṣẹ́gun ohun gbogbo kápá ìríra.
Nípa lílo ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan nínú ìgbéyàwó, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ní ipò ìbátan dídúró déédéé. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, ìdajì tàbí ìdá mẹ́ta gbogbo ìgbéyàwó ń já sí ìkọ̀sílẹ̀. Àmọ́ ìwádìí tí a mẹ́nu bà lókè tọ́ka sí i pé, títí di báyìí ná, ìpín 4.9 péré nínú ọgọ́rùn-ún lára Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ni ó ti ṣe ìkọ̀sílẹ̀ tàbí tí ó ti pínyà kúrò lọ́dọ̀ àwọn alábàá-ṣègbéyàwó wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, ohun kan tí a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé ni pé, ọ̀pọ̀ lára àwọn wọ̀nyí ti ṣe ìkọ̀sílẹ̀ ṣáájú kí wọ́n tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Níwọ̀n bí Ọlọ́run Ìfẹ́ ti jẹ́ Olùkọ́ni Atóbilọ́lá tí ń kọ́ àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ní ọ̀nà rẹ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà darí ìfẹ́ wọn sí i, ṣáájú ohunkóhun mìíràn. Láìdàbí àwọn ènìyàn míràn, tí wọ́n lè jẹ́ “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run,” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi Ọlọ́run sí ipò kíní. (Tímótì Kejì 3:4) Ní ìyàtọ̀ sí àwọn ọ̀nà ayé tí kò ní ìlànà yí, Ẹlẹ́rìí kan tí a lè mú bí àpẹẹrẹ ń lo wákàtí 17.5 lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nínú àwọn ìgbòkègbodò ìsìn. Ó ṣe kedere pé Àwọn Ẹlẹ́rìí ní ẹ̀mí ìsìn. Ohun tí ń mú kí wọ́n láyọ̀ nìyẹn. Jésù wí pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.”—Mátíù 5:3.
Òǹkọ̀wé Orin Dáfídì 118 sọ pé, ìránṣẹ́ tòótọ́ ti Ọlọ́run kò ní ìdí láti bẹ̀rù àwọn ẹ̀dá ènìyàn. “Olúwa ń bẹ fún mi, èmi kì yóò bẹ̀rù; kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?” (Ẹsẹ 6) Ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Ọlọ́run ń mú ọ̀kan lára àwọn okùnfà ìkórìíra àti ìbẹ̀rù àwọn ẹ̀dá ènìyàn míràn kúrò.
Ní mímọ̀ pé Ọlọ́run ‘kún fun ìyọ́nú, ó sì pọ̀ ní àánú àti òtítọ́,’ Kristẹni kan yóò sakun láti mú ìbínú kúrò nínú ìgbésí ayé rẹ̀, nítorí pé ó lè jẹ́ okùnfà míràn fún ìkórìíra. Mímú àwọn èso ẹ̀mí Ọlọ́run dàgbà, títí kan ìwà tútù àti ìkóra-ẹni-níjàánu, yóò ràn án lọ́wọ́ láti ṣàṣeparí èyí.—Orin Dáfídì 86:15; Gálátíà 5:22, 23.
Kristẹni tòótọ́ kan jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kì í sì í ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ kí ó rò lọ. (Róòmù 12:3) Ó ń mú ìfẹ́ dàgbà nínú ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ní ìyàtọ̀ sí ìríra, a “kì í tán” ìfẹ́ “ní sùúrù. Kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.”—Kọ́ríńtì Kíní 13:5.
Dájúdájú, ìbẹ̀rù, ìbínú, tàbí èrò ìpalára lè mú kí àwọn ènìyàn kórìíra. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí ìkórìíra nípa fífi ìpìlẹ̀ rẹ̀ dù ú. Láìṣe àní-àní, ìfẹ́ ni ipá tó lágbára jù lọ lágbàáyé nítorí “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”—Jòhánù Kíní 4:8.
Láìpẹ́, Ìkórìíra Kì Yóò Sí Mọ́ Láé
Ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìríra kò lè máa wà lọ títí nítorí pé wọn kì í ṣe ara ànímọ́ ìwà Jèhófà Ọlọ́run. Ó di dandan kí a mú wọn kúrò, kí a fi ìfẹ́, tí yóò wà títí ayérayé rọ́pò wọn. Bí ó bá jẹ́ pé ayé kan tí kò ti sí ìríra, tí ó sì kún fún ìfẹ́, ni irú èyí tí ìwọ ń yán hànhàn fún, jẹ́ kí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣàlàyé àwọn ohun tí a béèrè fún láti wà níbẹ̀ fún ọ láti inú Bíbélì.
Dájúdájú, yóò dára kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa béèrè pé, ‘Ànímọ́ wo ló ń jọba lórí ìgbésí ayé mi, ìfẹ́ tàbí ìríra?’ Èyí kì í wulẹ̀ ṣe ìbéèrè kan tí kò ṣe pàtàkì. Ẹni tó bá ń tẹ̀ lé elénìní Ọlọ́run, ọlọ́run ìríra, kì yóò wà láàyè pẹ́. Ẹni tí ó bá ń tẹ̀ lé Jèhófà, Ọlọ́run ìfẹ́, ni yóò wà láàyè títí láéláé!—Jòhánù Kíní 2:15-17.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn ènìyàn lè fi ìfẹ́ wọ ara wọn láṣọ lónìí pàápàá