Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Fara Da Ìṣáátá?
ÀWỌN èwe tí ìwà tàbí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà múra yàtọ̀ sí ti àwọn ẹgbẹ́ wọn lè di ẹni tí a ń ṣáátá tìkà-tẹ̀gbin. Ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn èwe Kristẹni nìyẹn, tí ìwà wọn sábà máa ń yàtọ̀ gedegbe sí ti àwọn ọ̀dọ́ mìíràn. Kristi kò ha sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tòótọ́ pé: “Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú”?—Jòhánù 15:20.
Báwo ni èyí ṣe kan àwọn èwe tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Àwọn ènìyàn máa ń fi àwọn kan lára wọn ṣẹ̀sín nítorí pé wọn kì í ṣe ayẹyẹ àwọn ọdún kan; wọ́n ń ṣàríwísí àwọn kan nítorí pé wọn kì í kí àsíá. Wọ́n tilẹ̀ ń fìtínà àwọn mélòó kan lára wọn nítorí pé wọn kì í ṣe ajoògùnyó, nítorí pé wọ́n máa ń sòótọ́, àti nítorí pé wọ́n ń rọ̀ mọ́ àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n ìwà rere Bíbélì.
Irú nǹkan báwọ̀nyí kì í ṣe tuntun. Kódà, àpọ́sítélì Pétérù wí fún àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní pé: “Nítorí ẹ kò bá a lọ ní sísáré pẹ̀lú [àwọn ènìyàn ayé] . . . , ó rú wọn lójú, wọ́n sì ń bá a lọ ní sísọ̀rọ̀ yín tèébútèébú.” (1 Pétérù 4:4) Àwọn ìtumọ̀ mìíràn sọ pé, wọ́n “ń pè yín lórúkọ tí ẹ kì í jẹ́” (Knox) tàbí, “Wọ́n ń fìwọ̀sí lọ̀ yín.”—Today’s English Version.
Ǹjẹ́ wọ́n ti fi ọ́ ṣẹ̀sín rí nítorí ohun tí o gbà gbọ́? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, mọ́kàn le. Kì í ṣe ìwọ nìkan ló ń ṣẹlẹ̀ sí! Inú rẹ yóò sì dùn láti mọ̀ pé o lè kọ́ bí o ṣe lè fara da àìfararọ tó wà nínú kí a máa ṣáátá rẹ nítorí ìgbàgbọ́ rẹ.
Ìdí Tí Wọ́n Ṣe Máa Ń Fini Ṣẹ̀sín
Kí nìdí tí àwọn kan ṣe máa ń fi àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn àti ìwà wọn yàtọ̀ sí tiwọn ṣe yẹ̀yẹ́? Nígbà mìíràn, ohun tí ń ṣe àwọn abúmọ́ni náà ló ń ṣe àwọn afiniṣẹ̀sín—ó máa ń jẹ́ nítorí pé ọkàn wọn kò balẹ̀. Ó lè jẹ́ nítorí àtigbayì lójú àwọn ẹgbẹ́ wọn ni wọ́n ṣe ń fi ẹ́ ṣẹ̀sín. Ó lè jẹ́ pé bí àwọn tí ń fìtínà ẹ bá dá wà, díẹ̀ lára wọn ló máa fẹ́—tàbí ló lè gbóyà—láti ṣe ọ̀fíntótó ẹ ní gbangba.
Yàtọ̀ sí ìyẹn, gẹ́gẹ́ bí Pétérù ṣe kọ ọ́, “ó rú” àwọn afiniṣẹ̀sín kan “lójú.” Òtítọ́ ni, bí o ṣe ń hùwà lè máa rú wọn lójú ní gidi. Fún àpẹẹrẹ, bí o bá jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó lè máa ṣàjèjì sí wọn lóòótọ́ pé o kì í bá wọn kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ayẹyẹ ọdún kan. Wọ́n tilẹ̀ lè ti gbọ́ àwọn nǹkan kan nípa àwa Ẹlẹ́rìí lẹ́nu àwọn alátakò paraku.
Ohun yòówù kó fà á, nígbà tí a bá ń fi ọ̀rọ̀ ẹ̀sín gún ọ lára, o lè gbà pẹ̀lú òwe inú Bíbélì náà pé: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà.” (Òwe 12:18) Ṣùgbọ́n rántí pé ó lè máà jẹ́ pé àwọn tí ń sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ kórìíra rẹ ni wọ́n ṣe ń sọ ọ́. Ó lè jẹ́ pé ohun tí òwe Bíbélì náà sọ ni wọ́n ń ṣe gẹ́lẹ́—wọ́n “ń sọ̀rọ̀ láìronú.”
Síbẹ̀, fífini ṣẹ̀sín lè dunni gan-an, bí ìgbà táa dọ́gbẹ́ síni lára ni oró rẹ̀ tilẹ̀ máa ń rí. O tilẹ̀ lè ronú nípa jíjuwọ́sílẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ rẹ kí wọ́n lè dẹ́kun fífìwọ̀sí lọ̀ ẹ́. Nígbà náà, báwo lo ṣe lè kojú ìṣáátá nítorí ìgbàgbọ́ rẹ?
Gbígbèjà Ara Rẹ
Àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé: Nígbà gbogbo, “ẹ wà ní ìmúratán . . . láti ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ yín ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n kí ẹ máa ṣe bẹ́ẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Pétérù 3:15) Láti gbèjà ìgbàgbọ́ rẹ ń béèrè pé kí o gba ìmọ̀ pípé sínú àti pé kí o lóye ìdí fún ìgbàgbọ́ rẹ.
Bó ti wù kó rí, o tún gbọ́dọ̀ mọ bí o ṣe máa ṣàlàyé ara rẹ fún àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” tàbí, gẹ́gẹ́ bí The Bible in Basic English ṣe sọ ọ́, “láìgbéraga.” Kò yẹ kí ìmọ̀ Bíbélì àti àwọn ohun tí o kọ́ nínú rẹ̀ mú kí o ronú pé o ṣe pàtàkì ju àwọn mìíràn lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí o gbìyànjú láti ní ìṣarasíhùwà bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tó kọ̀wé nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ pé: “Mo ti fi ara mi ṣe ẹrú fún gbogbo ènìyàn, kí n lè jèrè àwọn ènìyàn púpọ̀ jù lọ.”—1 Kọ́ríńtì 9:19.
Tí o bá rí i pé o ń ṣojo nípa gbígbèjà ìgbàgbọ́ rẹ, má ṣe jọ̀gọ̀nù. Ọ̀pọ̀ èwe Ẹlẹ́rìí ló ti ní irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀. Jamal sọ pé: “Nígbà tí mo wà ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, n kò mọ bí mo ṣe lè ṣàlàyé ìdí tí n kì í fi í ṣọdún tàbí tí n kì í fi í kí àsíá tàbí ìdí tí mo tilẹ̀ fi máa ń lọ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé.” Báwo ló ṣe wá ṣe é? “Bàbá mi kò yéé ràn mí lọ́wọ́ títí mo fi lè ṣàlàyé àwọn nǹkan wọ̀nyẹn, nǹkan wá yàtọ̀ gbáà.” Bí o kò bá lè ṣàlàyé ìgbàgbọ́ rẹ fún àwọn ẹlòmíràn, o lè ní kí òbí kan tàbí ẹlòmíràn tó dàgbà dénú nínú ìjọ Kristẹni ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye ìmọ̀ Ọlọ́run dáadáa.—Éfésù 3:17-19.
Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí sọ pé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ran òun lọ́wọ́ láti fìgboyà sọ̀rọ̀ ní ilé ẹ̀kọ́. Ó sọ pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, tí àwọn ọmọ kíláàsì mi bá bẹ̀rẹ̀ sí í fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí pé mo jẹ́ Ẹlẹ́rìí, n kì í mọ ohun tí màá sọ. Nísinsìnyí tí mo ti di ajíhìnrere alákòókò-kíkún, mo máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gan-an, ó sì ṣeé ṣe fún mi láti máa fún wọn lésì. Kíka àwọn àpilẹ̀kọ tuntun nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ń ràn mí lọ́wọ́ láti máa bá àwọn ẹlẹgbẹ́ mi nílé ìwé sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ mi.”
Òtítọ́ ni pé ipò nǹkan méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kò lè rí bákan náà. Nítorí náà, àwọn ipò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yóò béèrè pé kí a kojú wọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Ṣùgbọ́n, bí ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tí wọ́n ń sọ bá bí ọ nínú, kò bójú mu rárá láti “fi ibi san ibi.” (Róòmù 12:17-21) Bí ìwọ náà bá wá bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, bó ti wù kí o mọ àpárá dá tó, yóò wulẹ̀ tapo sí ìṣòro náà ni tàbí kó tilẹ̀ ru ìṣáátá síwájú sí i sókè. Nítorí náà, àwọn kan ti rí i pé ó sàn jù kí àwọn kọtí ikún sí ìwọ̀sí náà.
Nínú àwọn ọ̀ràn kan, bí ìgbà tí ọ̀rọ̀ kan bá wulẹ̀ jẹ́ láti fi dẹ́rìn-ín pani, ó tilẹ̀ lè bọ́gbọ́n mu láti bá wọn rẹ́rìn-ín dípò kí a fara ya. (Oníwàásù 7:9) Bí ẹni tí ń ṣáátá ẹ bá rí i pé àwọn ohun tí òun ń sọ kò tu irun kan lára ẹ, ó lè má fìtínà rẹ mọ́.—Fi wé Òwe 24:29; 1 Pétérù 2:23.
Sísọ̀rọ̀ Jáde
Àmọ́, àwọn ìgbà kan wà tí ó lè ṣeé ṣe láti fọgbọ́n ṣàlàyé ṣókí nípa ìgbàgbọ́ rẹ. Ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá gbìyànjú ẹ̀, ó sì yọrí sí rere. Ó sọ pé: “Kíláàsì ni mò ń lọ nígbà tí àwọn ọmọ ilé ìwé bíi mélòó kan bẹ̀rẹ̀ sí fi Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe yẹ̀yẹ́. Mo fẹ́ sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n wọ́n kàn kúrò níbẹ̀ ni, wọ́n sì ń fi mí rẹ́rìn-ín—àyàfi ọ̀kan lára wọn tí kò bá wọn ṣe bẹ́ẹ̀.” Akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí náà ṣàlàyé pé: “Ọmọdébìnrin kan tí ń jẹ́ Jaimee wá bá mi, ó sì sọ fún mi pé òun ní ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.a Ó sọ pé òun ti ka ibi tó pọ̀ nínú rẹ̀, òun sì fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ohun tí a gbà gbọ́. Mo bẹ̀rẹ̀ sí bá Jaimee ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Nítorí pé ohun tó ṣẹlẹ̀ náà fún èwe Ẹlẹ́rìí náà níṣìírí, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ọ̀dọ́ mìíràn sọ̀rọ̀. Ó sọ pé: “Mo máa ń bẹ àwọn ọmọ ilé ìwé mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n fìfẹ́ hàn wò déédéé, tó sì dá mi lójú pé wọn ò ní pẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́.”
Lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, irú ohun kan náà ṣẹlẹ̀ sí akẹ́kọ̀ọ́ kan ní orílẹ̀-èdè Liberia ní Áfíríkà. Ní kíláàsì tí wọ́n ti ń kọ́ nípa ìgbépọ̀ ẹ̀dá, ó fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣàlàyé pé òun gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ nínú ìṣẹ̀dá dípò ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n. Lákọ̀ọ́kọ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ ń ṣàríwísí gidigidi. Ṣùgbọ́n olùkọ́ wọ́n jẹ́ kí ó ṣàlàyé ìgbàgbọ́ rẹ̀ fún àwọn ọmọ kíláàsì náà, lẹ́yìn náà, olùkọ́ náà gba ìwé Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation?b
Lẹ́yìn tí olùkọ́ náà ka ìwé náà tán, ó sọ fún àwọn ọmọ kíláàsì pé: “Kò sẹ́lẹ́gbẹ́ ìwé yìí o. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwé sáyẹ́ǹsì tó dára jù lọ, tó sọ nípa ìṣẹ̀dá, tí mo tí ì kà rí.” Lẹ́yìn náà, olùkọ́ náà ṣàlàyé pé òun ní in lọ́kàn láti lo ìwé Creation náà papọ̀ pẹ̀lú ìwé àkànlò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn láàárín sáà ìkẹ́kọ̀ọ́ méjì tí wọn máa mú, ó sì ní kí olúkúlùkù ọmọ kíláàsì lọ wá bí wọ́n ṣe máa rí ẹ̀dà tiwọn gba lọ́wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà tí í ṣe Ẹlẹ́rìí. Wọ́n gba ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìwé náà, ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ ló sì yí èrò wọn nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà padà!
Ìgbàgbọ́ Tí A Bá Dán Wò Ló Lágbára
Lóòótọ́, o lè máa banú jẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nítorí iye àwọn tí kò ṣàjọpín—tàbí mọrírì—ìdúró rẹ tí a gbé karí Bíbélì. (Fi wé Sáàmù 3:1, 2.) Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ṣàjọpín ìgbàgbọ́ rẹ. (Òwe 27:17) Àmọ́, bí kò bá sí àwọn èwe tí ẹ jọ ń ṣe ìsìn kan náà ní ilé ìwé rẹ tàbí ní àdúgbò rẹ ńkọ́?
Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, rántí pé Jèhófà Ọlọ́run ni Ọ̀rẹ́ rẹ títóbi jù lọ, ó sì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Òun ni olórí ẹni tí Sátánì Èṣù ti ń ṣáátá láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún wá. Nípa bẹ́ẹ̀, ó dá wa lójú pé inú Jèhófà yóò dùn tí o bá dúró gbọn-ingbọn-in lórí ìgbàgbọ́ rẹ. Irú ipa ọ̀nà bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ kí ó lè ‘fún Sátánì, ẹni tí ń ṣáátá rẹ̀, lésì.’—Òwe 27:11.
Kò sí ni, àwọn ènìyàn yóò máa dán ìgbàgbọ́ rẹ wò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. (2 Tímótì 3:12) Síbẹ̀, àpọ́sítélì Pétérù mú un dá wa lójú pé ìjójúlówó ìgbàgbọ́ wa “níye lórí púpọ̀púpọ̀ ju wúrà tí ń ṣègbé láìka fífi tí a fi iná dá an wò sí.” (1 Pétérù 1:7) Nípa bẹ́ẹ̀, tí wọ́n bá tìtorí ìgbàgbọ́ rẹ pẹ̀gàn rẹ, ńṣe ni kí o wò ó bí àǹfààní láti mú ìgbàgbọ́ rẹ lókun àti láti fi ìfaradà rẹ hàn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé ìfaradà ń ṣamọ̀nà sí “ipò ìtẹ́wọ́gbà.” (Róòmù 5:3-5) Bẹ́ẹ̀ ni, ìfẹ́-ọkàn láti jèrè ojú rere Jèhófà yóò fún ẹ ní ìmóríyá tó lágbára láti lè fara dà á tí wọ́n bá ń tìtorí ìgbàgbọ́ rẹ ṣáátá rẹ!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.
b Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ǹjẹ́ o lè ṣàlàyé ìgbàgbọ́ rẹ?