Ǹjẹ́ Ó Ṣeé Ṣe Kí Ogun Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé Má Jà?
“Àwọn fúnra wọn yóò jẹun, wọn yóò sì nà gbalaja ní ti tòótọ́, kò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.”—Sefanáyà 3:13.
GBOGBO èèyàn ló ń fẹ́ ayé kan tí wọn ò ti ní fi ohun ìjà olóró dẹ́rù bani mọ́. Bí ipò nǹkan ṣe rí láyé tá a wà yìí ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé kò lè ṣeé ṣe. Ìwé ìròyìn The Guardian Weekly sọ pé: “Èrò láti díwọ̀n ìlò àwọn ohun ìjà olóró, láti dín iye tí wọ́n ní kù tàbí láti kúkú rẹ́yìn wọn pátápátá ti ń di ohun ìgbàgbé ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti ní gbogbo ayé lápapọ̀.”
Síbẹ̀, àwọn kan ń sọ̀rọ̀ nípa gudugudu méje táwọn orílẹ̀-èdè ń ṣe lórí ọ̀ràn yìí. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fojú bù ú pé orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìkan ná ohun tó ju bílíọ̀nù méjì owó dọ́là lọ lọ́dún kan láti kòòré ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé. Ó dájú pé kì í ṣe owó kékeré nìyẹn. Àmọ́, mímọ̀ táwọn èèyàn mọ̀ pé orílẹ̀-èdè kan náà yìí ń ná bílíọ̀nù mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n owó dọ́là lọ́dọọdún láti múra sílẹ̀ fún ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kò fi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn balẹ̀.
Àwọn àdéhùn àlàáfíà ńkọ́? Ṣé wọ́n ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé?
Àwọn Àdéhùn Nípa Dídíwọ̀n Àwọn Ohun Ìjà Olóró
Látìgbà táwọn èèyàn ti ń fi àdó olóró jagun, ọ̀pọ̀ àdéhùn ni wọ́n ti ṣe láti díwọ̀n ìlò àwọn ohun ìjà olóró tàbí láti dín iye tí wọ́n ní kù. Díẹ̀ lára irú àwọn àdéhùn bẹ́ẹ̀ ni Àdéhùn Fífòpin sí Bí Ohun Ìjà Ọgbálẹ̀gbáràwé Ṣe Ń Pọ̀ Sí I, Ìpàdé Àpérò Lórí Dídín Ìlò Àwọn Ohun Ìjà Olóró Kù, Ìpàdé Àpérò Lórí Dídín Iye Àwọn Ohun Ìjà Olóró Kù, àti Àdéhùn Ìfòfinde Dídán Gbogbo Ohun Ìjà Olóró Wò. Ṣé àwọn àdéhùn wọ̀nyí kò tíì mú ìbẹ̀rù ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kúrò ni?
Ìlérí tí àwọn tí ọ̀ràn kàn bá ṣe ni yóò mú kí àdéhùn tí wọ́n fọwọ́ sí lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1970 ni Àdéhùn Fífòpin sí Bí Ohun Ìjà Ọgbálẹ̀gbáràwé Ṣe Ń Pọ̀ Sí I wáyé. Nígbà tó fi máa di oṣù December ọdún 2000, àwọn orílẹ̀-èdè tó fọwọ́ sí àdéhùn náà ti di ọgọ́sàn-án ó lé méje [187]. Ṣùgbọ́n, kí àdéhùn yìí tó lè kẹ́sẹ járí, ó sinmi lórí bí àwọn orílẹ̀-èdè tó tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn náà bá ṣe gbárùkù tì í tó, àtàwọn tó ní ohun ìjà olóró àtàwọn tí kò ní. Lábẹ́ àdéhùn yìí, kò sáyè fáwọn orílẹ̀-èdè tí kò ní ohun ìjà olóró láti ṣe irú ohun ìjà bẹ́ẹ̀ tàbí kí wọ́n rà wọ́n, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn orílẹ̀-èdè tó ti to ohun ìjà olóró jọ pelemọ gbọ́dọ̀ wá bí wọ́n ṣe máa kó wọn dà nù. Ṣé wọ́n tẹ̀ lé àdéhùn náà? Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Carey Sublette ṣàlàyé nínú ìwé kan tí wọ́n ń pè ní, “Àwọn Ìbéèrè tí Wọ́n Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Àwọn Ohun Ìjà Olóró” pé: “Bí Àdéhùn Fífòpin sí Bí Ohun Ìjà Ọgbálẹ̀gbáràwé Ṣe Ń Pọ̀ Sí I yìí ò tiẹ̀ ṣeé gbára lé pátápátá, ó ti dá àwọn ilé iṣẹ́ àdáni tó ń ṣe ohun ìjà olóró lọ́wọ́ kọ́, kò sì jẹ́ kí àwọn èèyàn rí àwọn òhun ìjà tí wọ́n ti fi pa mọ́ lò lọ́nà tí kò tọ́.”
Sublette sọ pé, bí àdéhùn náà tiẹ̀ ṣiṣẹ́ díẹ̀, “kò tíì . . . mú kí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè yí èrò wọn padà pátápátá kúró nínú wíwá àwọn ohun ìjà olóró kiri.” Àmọ́ o, ó wá sọ pé, ohun kan ṣoṣo tó tiẹ̀ mú kí wọ́n yí èrò wọn padà débi tó dé yìí gan-an ni ètò abẹ́lẹ̀ kan tí wọ́n ṣe, tó yàtọ̀ pátápátá sí Àdéhùn Fífòpin sí Bí Ohun Ìjà Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé Ṣe Ń Pọ̀ Sí I. Kí àdéhùn èyíkéyìí tó lè lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, àwọn tó fọwọ́ sí àdéhùn náà gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú àdéhùn tí wọ́n ṣe. Ṣé a kàn ṣáà lè fọkàn tán àwọn ìlérí téèyàn bá ṣe? A lè rí ìdáhùn náà nínú ohun tí ìràn èèyàn tí gbé ṣe sẹ́yìn.
Nígbà náà, kí lọ̀nà àbáyọ?
Ríronú Lọ́nà Mìíràn
Ní oṣù December ọdún 2001, àwọn àádọ́fà [110] èèyàn tó gba ẹ̀bùn Nobel fẹnu kò, wọ́n sì fọwọ́ sí ọ̀rọ̀ kan tó sọ pé: “Ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo tó wà fún ojọ́ ọ̀la kò ju pé kí àwọn orílẹ̀-èdè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nípasẹ̀ ìjọba tiwa-n-tiwa. . . . Ká tó lè ṣàṣeyọrí nínú ayé kan tí a ti yí padà, a gbọ́dọ̀ kọ́ láti ronú ní ọ̀nà mìíràn.” Ó dára, “ọ̀nà mìíràn” wo ni wọ́n tún gbọ́dọ̀ gbà ronú? Ṣé ó ṣeé gbà gbọ́ pé àwọn tó ń fi àwọn ohun ìjà olóró da àlàáfíà ayé láàmú yóò kọ́ láti máa ronú lọ́nà mìíràn?
Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀.” (Sáàmù 146:3) Kí nìdí? Bíbélì dáhùn pé: “Ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìdí pàtàkì tó fà á ni pé ọmọ èèyàn ò lágbára láti ṣàkóso ayé lọ́nà tó lè mú àlàáfíà wá. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.”—Oníwàásù 8:9.
Bí agbára èèyàn kò bá ká a láti ṣàkóso ayé, ta ló wá lè ṣe é? Bíbélì ṣèlérí pé àlàáfíà yóò wà nínú ìjọba kan tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé tó sì lágbára láti ṣe é. Ìṣàkóso yìí ni Bíbélì pè ní Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí ọ̀kẹ́ àìmọye ti gbàdúrà fún láìmọ̀ nígbà tí wọ́n ń gba Àdúrà Olúwa pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, . . . kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:9, 10) Jésù Kristi ni Ọmọ Aládé Àlàáfíà àti Ọba Ìjọba yìí. Nígbà tí Bíbélì ń ṣàpèjúwe bí ìṣàkóso rẹ̀ yóò ṣe rí, ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ yanturu ìṣàkóso ọmọ aládé àti àlàáfíà kì yóò lópin.”—Aísáyà 9:6, 7.
Kódà ká sọ pé àwọn “ọ̀tọ̀kùlú” tàbí àwọn olóṣèlú àti gbogbo àwọn tó ń ṣèjọba ènìyàn kọ̀ láti kọ́ ọ̀nà mìíràn tá a lè gbà ronú yìí, ìwọ lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ran ọ̀kẹ́ àìmọye lọ́wọ́ láti nígbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ ìrètí tó wà nínú Bíbélì nípa ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ń ṣe lọ́fẹ̀ẹ́. Bó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i, jọ̀wọ́ kàn sí àwọn tó tẹ ìwé ìròyìn yìí, tàbí kí o lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó bá wà ládùúgbò rẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Nínú ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run, kò ní sí fífi ohun ìjà olóró dẹ́rù bani ní gbogbo ayé